Ojú Ìwòye Bíbéì
Ojú Wo Ló Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Fi Wo Máàsì?
ÀWỌN Kátólíìkì olùfọkànsìn fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Pope John Paul Kejì tí ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé, ó “tún tẹnu mọ́ ọn” lẹ́nu àìpẹ́ yìí “pé ṣọ́ọ̀ṣì kà á sí ẹ̀ṣẹ̀ bí Kátólíìkì kan bá pa Máàsì jẹ.” Kí ni Máàsì? Ǹjẹ́ ohun kan náà ni ṣọ́ọ̀ṣì àti Bíbélì sọ nípa kókó ẹ̀kọ́ náà?
Nínú ìwé náà, Things Catholics Are Asked About, àlùfáà Kátólíìkì náà, Martin J. Scott, fi àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí túmọ̀ Máàsì pe: “Máàsì ni ìrúbọ aláìlẹ́jẹ̀ ti Ara àti Ẹ̀jẹ̀ Kristi. Kálífárì ni ìrúbọ ẹlẹ́jẹ̀ ti Kristi. Máàsì jẹ́ ìrúbọ tó ṣe pàtàkì bíi ti orí àgbélébùú. Èyí kì í ṣe àkànlò èdè, kì í ṣe àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ tàbí àsọdùn.” Ó tún sọ pé: “A gbà pé Máàsì náà ló gbé Ọmọ Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti orí pẹpẹ wa, tí ó sì fi Í rúbọ sí Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan.”
Ǹjẹ́ Ìwé Mímọ́ Ti Ẹ̀kọ́ Máàsì Lẹ́yìn?
Àwọn tí ń ṣe ìsìn Kátólíìkì lójú méjèèjì gbà gbọ́ pé a gbé Máàsì karí ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, wọ́n ń tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ní àkókò tí a ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Bí Jésù ṣe ń pín búrẹ́dì àti wáìnì fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó tọ́ka sí búrẹ́dì pé: “Èyí yìí ni ara mi.” Nígbà tó ń tọ́ka sí wáìnì, ó wí pé: “Èyí yìí ni ẹ̀jẹ̀ mi.” (Mátíù 26:26-28)a Àwọn Kátólíìkì gbà gbọ́ pé nígbà tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó yí búrẹ́dì àti wáìnì náà padà sí ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gidi ni. Àmọ́, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia (1967) kìlọ̀ pé: “A kò gbọ́dọ̀ dara dé àwọn ọ̀rọ̀ náà ‘Èyí yìí ni ara mi’ tàbí ‘Èyí yìí ni ẹ̀jẹ̀ mi’ jù lọ́nà olówuuru. . . . Nítorí pé nínú àwọn gbólóhùn bíi ‘ìgbẹ̀yìn ayé ni ìkórè’ (Mát 13.39) tàbí ‘èmi ni àjàrà tòótọ́’ (Jòh 15.1) [ọ̀rọ̀ ìṣe náà “láti di”] túmọ̀ sí láti fi hàn tàbí láti ṣojú fún nìkan.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tí kò ṣeé jàníyàn yìí pàápàá gbà pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 26:26-28 kò fẹ̀rí hàn pé a yí búrẹ́dì àti wáìnì náà padà sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.
Ẹni kan lè rántí pé Jésù fìgbà kan sọ pé: “Èmi ni oúnjẹ ìyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá. . . . Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ara mi tó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:51, 54) Àwọn kan lára àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní olówuuru ẹ̀rù sì bà wọ́n. (Jòhánù 6:60) Àmọ́, a wá lè béèrè pé, Ṣé Jésù yí ara rẹ̀ padà sí búrẹ́dì ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ni? Ó dájú pé kò ṣe bẹ́ẹ̀! Ó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà àpèjúwe ni. Ó fi ara rẹ̀ wé búrẹ́dì nítorí pé òun yóò fún ìran ènìyàn ní ìyè nípa fífi ara rẹ̀ rúbọ. Jòhánù 6:35, 40 mú un ṣe kedere pé jíjẹ àti mímu yóò jẹ́ nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi.
Níwọ̀n bí Máàsì ti jẹ́ ààtò pàtàkì nínú Ìjọ Kátólíìkì, ẹnì kan lè rò pé ó yẹ kí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tì í lẹ́yìn. Wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia (ẹ̀dà ti 1913) ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ pé: “Olórí orísun ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wa . . . ni àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, tó jẹ́ pé láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ló ti ń polongo ìníyelórí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ [ìpàrọwà] Ẹbọ Máàsì.” Dájúdájú, a kò gbé Máàsì ti Kátólíìkì karí Bíbélì, bíkòṣe orí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́.
Bó ti wù ká fi tọkàntọkàn gbà á tó, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó lòdì sí Bíbélì. Jésù bá àwọn aṣáájú ìsìn tó wà nígbà ayé rẹ̀ wí pé: “Ẹ ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín.” (Mátíù 15:6) Níwọ̀n bí Jésù ti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí pàtàkì, ẹ jẹ́ kí a lo Ìwé Mímọ́ láti yẹ ẹ̀kọ́ nípa Máàsì wò.
Fífi Kristi Rúbọ—Nígbà Mélòó?
Ìjọ Kátólíìkì kọ́ni pé gbogbo ìgbà tí a bá ṣayẹyẹ Máàsì ni a fi Jésù rúbọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tẹnu mọ́ ọn pe kì í ṣe pé ó kú ní ti gidi àti pé ìrúbọ náà jẹ́ aláìlẹ́jẹ̀. Ǹjẹ́ Bíbélì fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ojú ìwòye yìí? Ṣàkíyèsí Hébérù 10:12, 14: “[Jésù] ti rú ẹbọ kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀, lẹ́yìn náà ó jókòó títí láé ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Nípa ọrẹ ẹbọ kan ṣoṣo yẹn, òun ti sọ àwọn tí a ń sọ di mímọ́ di pípé títí láé.”
Àmọ́ ẹnì kan tí ń ṣe Kátólíìkì lójú méjèèjì lè ṣàtakò pé: ‘Ṣé kò yẹ kí Jésù máa fi ara rẹ̀ rúbọ ní gbogbo ìgbà ni? Ọ̀pọ̀ ìgbà ni gbogbo wa máa ń dẹ́ṣẹ̀.’ A kọ ìdáhùn Bíbélì nípa èyí sínú Hébérù 9:25, 26 pé: “[Kristi] kò ní láti máa fi ara rẹ̀ rúbọ léraléra. . . . Ó ti fi ara rẹ̀ hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní òpin ayé láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa fífi ara rẹ̀ rúbọ.” Ṣàkíyèsí èyí dáradára pé: Kristi “kò ní láti máa fi ara rẹ̀ rúbọ léraléra.” Ní Róòmù 5:19, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ pé: “Nípa àìgbọràn ènìyàn kan [Ádámù], ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọràn ẹnì kan [Jésù], a óò sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.” Àìgbọràn kan ṣoṣo tí Ádámù ṣe sọ gbogbo wa di ẹrú fún ikú; ìràpadà kan ṣoṣo tí Jésù ṣe ti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún gbogbo àwa tí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ yẹn láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà nísinsìnyí àti láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.
Ìyàtọ̀ wo ló wà níbẹ̀, yálà a fi Jésù rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo tàbí a fi rúbọ lọ́pọ̀ ìgbà? Ó jẹ́ ọ̀ràn fífi ìmọrírì hàn fún ìníyelórí ẹbọ Jésù. Ìyẹn ni ẹ̀bùn tó tóbi jù lọ tí a tí ì fúnni—ẹ̀bùn kan tó níye lórí gan-an, tó pé, tí kò sì sí ìdí láti tún un gbà mọ́.
Dájúdájú, ẹbọ Jésù jẹ́ ohun tó yẹ ká máa rántí. Àmọ́ ìyàtọ̀ wà nínú rírántí ìṣẹ̀lẹ̀ kan àti títún un ṣe. Fún àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tó ń ṣayẹyẹ ìrántí ọjọ́ ìgbéyàwó wọn lè rántí ọjọ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó, láìsí pé wọ́n tún ìgbéyàwó náà ṣe. Lọ́dọọdún, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣayẹyẹ àjọ̀dún ikú Jésù, wọ́n ń ṣe é lọ́nà tí Jésù pa láṣẹ—“ní ìrántí,” kì í ṣe ní ìrúbọ, òun. (Lúùkù 22:19) Láfikún sí i, jálẹ̀ ọdún ni àwọn Kristẹni wọ̀nyí ń tiraka láti mú ipò ìbátan ọlọ́yàyà dàgbà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi nípa mímú ìgbésí ayé wọn, ìṣe wọn, àti ìgbàgbọ́ wọn wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí yíyí èrò inú wọn padà. Àmọ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí náà láyọ̀ ní mímọ̀ pé bí àwọn bá fi ìṣòtítọ́ ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́yìn dípò àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, a óò bù kún wọn. Àti pé bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ Jésù, tí a dà sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, yóò wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.—1 Jòhánù 1:8, 9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fà yọ nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ láti inú New Jerusalem Bible ti Kátólíìkì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Máàsì Giles Mímọ́ (ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
[Credit Line]
Erich Lessing/Art Resource, NY