Ṣé “Ọlọ́run” Ni Ọ̀rọ̀ Náà àbí Ọ̀rọ̀ Náà Jẹ́ “ọlọ́run kan”?
ÌBÉÈRÈ yìí máa ń jẹ yọ nígbà táwọn atúmọ̀ èdè bá ń túmọ̀ ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú Ìwé Ìhìn Rere Jòhánù. Bá a ṣe túmọ̀ ẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun rèé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.” (Jòhánù 1:1) Apá tó gbẹ̀yìn ẹsẹ Bíbélì yìí nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì fi hàn pé Ọ̀rọ̀ náà wá “láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” tàbí kí wọ́n sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. (A New Translation of the Bible, látọwọ́ James Moffatt àti New English Bible) Àmọ́, báwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì ṣe tú apá tó gbẹ̀yìn ẹsẹ yẹn rèé: “Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà.”—Ìtúmọ̀ The Holy Bible, ìyẹn New International Version àti Jerusalem Bible.
Gírámà èdè Gíríìkì àtàwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn kedere pé bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí tọ̀nà àti pé “Ọ̀rọ̀ náà,” yàtọ̀ sí “Ọlọ́run” tí ẹsẹ Bíbélì yẹn kọ́kọ́ mẹ́nu bà. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lè máa kọminú sí ìtumọ̀ yìí torí pé èdè Gíríìkì tí wọ́n ń sọ láwọn ìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ò ní ọ̀rọ̀ tó lè fìyàtọ̀ sáàárín àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó àtàwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtó. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ìtumọ̀ Bíbélì ní èdè táwọn èèyàn kan ń sọ léyìí tó ju ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn lọ.
Èdè yẹn ni èdè ìbílẹ̀ Coptic tí wọ́n ń pè ní Sahidic. Èdè Coptic yìí ni wọ́n ń sọ nílùú Íjíbítì ní ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí Jésù parí iṣẹ́ ìwàásù tó wá ṣe láyé, Sahidic sì jẹ́ apá kan èdè ìbílẹ̀ Coptíc tí wọ́n ń sọ nígbà yẹn. Ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ nípa àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì lédè Coptic yìí pé: “Níwọ̀n bí wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì ti [Septuagint] àti [Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì] sí èdè Coptic ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [1,800] ọdún sẹ́yìn, inú [àwọn ìwé tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Gíríìkì] ni wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Coptic, àwọn ìwé tí wọ́n fọwọ́ kọ wọ̀nyẹn sì ti wà tipẹ́ ṣáájú àwọn tó wà báyìí tá a lè fi jẹ́rìí sáwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì.”
Ìdí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wà tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ìtúmọ̀ Bíbélì lédè ìbílẹ̀ Coptic tí wọ́n ń pè ní Sahidic. Ìdí àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́ bá a ti mẹ́nu bà á ṣáájú ni pé, ó jẹ́ ká mọ báwọn Kristẹni ṣe lóye Ìwé Mímọ́ látìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ títí di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méje [1,700] ọdún sẹ́yìn, ìyẹn kí Mẹ́talọ́kan tó di ẹ̀kọ́ ìsìn. Ìdí kejì ni pé, apá pàtàkì kan wà tí gírámà èdè Coptic àti ti èdè Gẹ̀ẹ́sì fi jọra. Àwọn èdè Syriac, Latin, àti Coptic ni wọ́n kọ́kọ́ tú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì sí. Bíi ti èdè Gíríìkì tí wọ́n ń sọ nígbà yẹn, èdè Syriac àti Latin ò láwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi máa ń fìyàtọ̀ sáwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó àtàwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtó. Àmọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn wà lédè Coptic. Yàtọ̀ síyẹn, Ọ̀mọ̀wé Thomas O. Lambdin sọ nínú ìwé rẹ̀ tó kọ nípa èdè Sahidic ti Coptic, ìyẹn Introduction to Sahidic Coptic, pé: “Ìlànà tó jọra ni èdè Coptic àti èdè Gẹ̀ẹ́sì fi máa ń fìyàtọ̀ sáwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó àtàwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtó.”
Torí náà, ìtúmọ̀ Bíbélì lédè Coptic fún wa lẹ́rìí tó jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe lóye ìwé Jòhánù 1:1 sí nígbà yẹn. Ẹ̀rí wo nìyẹn? Nígbà tí wọ́n ń tú ìwé Jòhánù 1:1 sí Sahidic ti èdè Coptic, ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtó ni wọ́n lò fún “ọlọ́run” tó wà níparí ẹsẹ yẹn. Torí náà, lédè Yorùbá, ohun tó máa túmọ̀ sí ni: “Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ọlọ́run kan.” Ó ṣe kedere pé àwọn tó túmọ̀ Bíbélì nígbà yẹn mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jòhánù nínú orí kìíní ẹsẹ kìíní ìwé rẹ̀ ò túmọ̀ sí pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè. Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ọlọ́run kan, àmọ́ kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
JÒHÁNÙ 1:1. ÌWÉ TÍ WỌ́N FI ÈDÈ SAHIDIC TI COPTIC KỌ; P. CHESTER BEATTY-813; ÌTÚMỌ̀ INTERLINEAR
Ní àtètèkọ́ṣe wà Ọ̀rọ̀ náà
sì Ọ̀rọ̀ náà wà pẹ̀lú
Ọlọ́run náà sì ọlọ́run kan jẹ́
Ọ̀rọ̀ náà
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Chester Beatty Library