Bí Òtítọ́ Ṣe Ń Sọ Wá Di Òmìnira
1 Ní àkókò kan, Jésù sọ fún àwọn Júù tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ pé: “Ẹ ó . . . mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Òmìnira tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kọjá òmìnira tí ìjọba orílẹ̀-èdè lè fúnni, ó jẹ́ òmìnira tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn, àtolówó àti tálákà, àtọ̀mọ̀wé àti púrúǹtù. Jésù kọ́ni ní òtítọ́ tí yóò sọ àwọn èèyàn dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣàlàyé, “olúkúlùkù ẹni tí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” (Jòhánù 8:34) Láìsí àní-àní, à ń yán hànhàn fún àkókò náà nígbà tí a óò “dá [gbogbo èèyàn onígbọràn] sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, [tí wọn] yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run”!—Róòmù 8:21.
2 Mímọ òtítọ́ nípa Jésù àti ipa tó ń kó nínú mímú kí ète Ọlọ́run ṣẹ ló ń mú irú òmìnira tí à ń wí yìí wá. Ó tún kan níní ìmọ̀ nípa ẹbọ ìràpadà náà tí Jésù fi ara rẹ̀ rú nítorí wa. (Róòmù 3:24) Àní lákòókò yìí pàápàá, títẹ́wọ́ gba òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì àti fífi tinútinú ṣègbọràn sí i ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn òmìnira dé àyè kan, irú bí òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, àìnírètí, àti onírúurú àwọn àṣà tó lè pa wá lára.
3 Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Ìbẹ̀rù àti Àìnírètí: A ò nídìí láti sọ̀rètí nù nítorí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé nítorí pé a mọ ìdí tí ìwà ibi fi wà, a sì mọ̀ pé Ọlọ́run yóò mú un kúrò lórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. (Sm. 37:10, 11; 2 Tím. 3:1; Ìṣí. 12:12) Síwájú sí i, òtítọ́ ń sọ wá dòmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké nípa ipò tí àwọn òkú wà. A mọ̀ pé àwọn òkú kò lè ṣe wá níbi, pé wọn kò sí nínú ìdálóró ayérayé kankan, àti pé Ọlọ́run kì í fi ikú pa àwọn èèyàn nítorí kí wọ́n bàa lè wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run.—Oníw. 9:5; Ìṣe 24:15.
4 Irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ló fún bàbá àti ìyá kan lókun nígbà tí ọmọ wọn kú nínú jàǹbá ọkọ̀. Ìyá náà sọ pé: “Òfò ńláǹlà lèyí jẹ́ nínú ìgbésí ayé wa kò sì sí ohunkóhun tó lè dí i títí di ìgbà tá a fi máa rí ọmọkùnrin wa padà nípasẹ̀ àjíǹde. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé fúngbà díẹ̀ ni ìbànújẹ́ wa.”
5 Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Àwọn Àṣà Tí Ń Pani Lára: Òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì lè yí ìrònú àti ìwà ẹnì kan padà, èyí á sì yọrí sí òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. (Éfé. 4:20-24) Jíjẹ́ ẹni tí kì í ṣe màgòmágó àti òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ kára lè ṣèrànwọ́ láti dín àìríná-àìrílò kù. (Òwe 13:4) Fífi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn ń mú kí àjọṣe ẹni pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn di èyí tó túbọ̀ dán mọ́rán sí i. (Kól. 3:13, 14) Bíbọ̀wọ̀ fún ipò orí Kristẹni máa ń dín gbọ́nmi-sí-i omi-ò-tó kù nínú ìdílé. (Éfé. 5:33–6:1) Yíyẹra fún ìmutípara, ìwà pálapàla, sìgá mímu, àtàwọn oògùn olóró tó máa ń di bárakú máa ń jẹ́ kí ìlera túbọ̀ sunwọ̀n sí i.—Òwe 7:21-23; 23:29, 30; 2 Kọ́r. 7:1.
6 Ó ṣòro fún ọ̀dọ́kùnrin kan láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró tó ti di bárakú fún un láti ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn. Lọ́jọ́ kan, ó pàdé akéde kan tó ń fìwé lọ àwọn èèyàn ní òpópónà. Ó gba ìwé, Ẹlẹ́rìí náà sì ṣe ètò láti kàn sí i ní ilé rẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀. Oṣù méjì lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà jáwọ́ pátápátá nínú lílo oògùn olóró, lẹ́yìn tó sì ti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mẹ́jọ, ó ṣèrìbọmi. Jíjáwọ́ tó jáwọ́ nínú àṣà yìí sún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà láti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
7 Ran Àwọn Mìíràn Lọ́wọ́ Láti Ní Òmìnira: Ó lè má rọrùn fún àwọn tó ti fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn jẹ́ ẹrú fún àwọn ẹ̀kọ́ èké láti lóye òmìnira tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń fúnni. Láti mú kí ẹ̀kọ́ Bíbélì wọ̀ wọ́n lọ́kàn, ó yẹ kí ẹni tó ń kọ́ wọn ṣe àkànṣe ìsapá àti ìmúrasílẹ̀ tó pegedé. (2 Tím. 4:2, 5) Kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ‘pípòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè.’ (Aísá. 61:1) Òmìnira Kristẹni ṣeyebíye gan-an ni. Ìyè àìnípẹ̀kun ni yóò sì túmọ̀ sí fún ẹni tó bá ní in.—1 Tím. 4:16.