Ojú Ìwòye Bíbélì
Ta Ni Sátánì? Ṣó Wà Lóòótọ́?
ÀWỌN ọ̀mọ̀wé kan wà lóde òní tí wọ́n ń sọ pé kò sẹ́ni tó ń jẹ́ Sátánì. Wọ́n láwọn èèyàn ló wulẹ̀ ń fojú inú wò ó pé ẹnì kan wà tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Irú àríyànjiyàn bí èyí ò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Akéwì kan tó ń jẹ́ Charles-Pierre Baudelaire tiẹ̀ sọ ní nǹkan bí igba ọdún sẹ́yìn pé: “Ọgbọ́n àrékérekè tí Èṣù máa ń lò jù lọ ni mímú káwa èèyàn gbà gbọ́ pé òun ò sí.”
Ṣé Sátánì wà lóòótọ́? Bó bá wà, ibo ló ti wá? Ṣé òun ni agbára àìrí tó ń fa gbogbo ìṣòro tó ń dààmú aráyé? Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni ọwọ́jà ìwà ibi rẹ̀ ò ṣe ní tó wa?
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ẹ̀
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ni Sátánì wà àti pé lọ́run, níbi táwọn áńgẹ́lì wà, ló ń gbé. (Jóòbù 1:6) Ó là wá lọ́yẹ̀ nípa ìwà abèṣe àti ìwà àìláàánú tó kún ọwọ́ ẹ̀, títí kan gbogbo iṣẹ́ ibi tó máa ń ṣe. (Jóòbù 1:13-19; 2:7, 8; 2 Tímótì 2:26) Kódà, a lè kà nípa ìjíròrò tó wáyé láàárín Ọlọ́run, Jésù àti Sátánì nínú Bíbélì.—Jóòbù 1:7-12; Mátíù 4:1-11.
Báwo ni Sátánì ṣe wá dẹni tó ń hùwà ibi? Kó tó di pé Ọlọ́run dá èèyàn ló ti kọ́kọ́ dá Ọmọkùnrin tó jẹ́ “àkọ́bí” rẹ̀ tá a wá mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn sí Jésù. (Kólósè 1:15) Nígbà tó ṣe, Ọlọ́run dá àwọn áńgẹ́lì, Bíbélì sì pe àwọn náà ní “ọmọ Ọlọ́run.” (Jóòbù 38:4-7) Ẹni pípé àti olódodo ni gbogbo wọn. Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì yẹn pàpà sọ ara ẹ̀ di Sátánì.
Sátánì kọ́ lorúkọ tí Ọlọ́run sọ ọ́ nígbà tó dá a. Orúkọ kan tó firú ẹni tó jẹ́ hàn ni, ó sì túmọ̀ sí “Elénìní; Ọ̀tá; Afẹ̀sùnkanni.” Wàyí o, nítorí pé ó yàn láti máa ṣàtakò sí Ọlọ́run, bí orúkọ yìí ṣe mọ́ ọn lórí nìyẹn.
Ìgbéraga ru bo ẹ̀dá ẹ̀mí yìí lójú, ó sì ń wọ́nà àtidi aláṣẹ bíi ti Ọlọ́run. Ó fẹ́ káwọn míì máa jọ́sìn òun. Kódà, nígbà tí Jésù, tó jẹ́ àkọ́bí Ọlọ́run wà lórí ilẹ̀ ayé, Sátánì gbìdánwò láti mú kí Jésù “jọ́sìn [òun] lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.”—Mátíù 4:9.
Sátánì ò “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” (Jòhánù 8:44) Ó ń dọ́gbọ́n sọ pé òpùrọ́ ni Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì rèé òun fúnra ẹ̀ ni onírọ́. Ó sọ fún Éfà pé ó lè dà bí Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun gan-an ló ń wù pé kóun dà bí Ọlọ́run. Ó ṣáà ń lo ọgbọ́n àrékérekè títí tọ́wọ́ ẹ̀ fi tẹ ohun tó ń fi ìmọtara-ẹni lépa. Ó mú kí Éfà rí òun bí ẹni tó ga ju Ọlọ́run lọ. Éfà náà sì sọ ọ́ di ọlọ́run nípa ṣíṣègbọràn sí i.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7.
Iná ọ̀tẹ̀ tí áńgẹ́lì tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olóòótọ́ yìí dá ló mú kó sọ ara ẹ̀ di Sátánì, ìyẹn elénìní àti ọ̀tá Ọlọ́run àti ti gbogbo ẹ̀dá. Lára orúkọ tó tún sọ ara ẹ̀ ni “Èṣù,” tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Nígbà tó ṣe, òléwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá yìí mú káwọn áńgẹ́lì míì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2; 1 Pétérù 3:19, 20) Àwọn áńgẹ́lì yìí ò mú kí ọ̀ràn túbọ̀ rọjú sí i fáráyé. Nítorí pé wọ́n ń ṣàfarawé ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan Sátánì, “ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:11; Mátíù 12:24.
Báwo Ni Agbára Ẹ̀tàn Sátánì Ṣe Pọ̀ Tó?
Ọmọ kan lè jẹ oúnjẹ tí màmá ẹ̀ gbé pa mọ́ sínú kọ́bọ́ọ̀dù, kó sì nu ẹnu ẹ̀ nù kí àṣírí má bàa tú. Àmọ́ bí màmá ẹ̀ bá dé, kò ní ṣàìmọ̀ pé ẹnì kan ti jẹ oúnjẹ tóun gbé pa mọ́, torí pé oúnjẹ náà ò lè jẹ ara ẹ̀. Bí Sátánì, tó jẹ́ “apànìyàn” láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá ṣe ń ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn, kì í fẹ́ kí àṣírí òun tú rárá. (Jòhánù 8:44; Hébérù 2:14) Nígbà tí Sátánì ń bá Éfà sọ̀rọ̀, ńṣe ló fi ejò ṣe bojúbojú. Kò tíì yé wá nǹkan fi ṣe bojúbojú títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí. Ó ti “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́” kí wọ́n má bàa mọ bí agbára ẹ̀tàn ẹ̀ ṣe pọ̀ tó.—2 Kọ́ríńtì 4:4.
Àmọ́ ṣá o, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì ni ọ̀daràn tó sọ ayé wa yìí dìdàkudà. Ó pè é ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 16:11) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Sátánì mọ bó ṣe ń lo “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” láti fi “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (1 Jòhánù 2:16; Ìṣípayá 12:9) Òun lẹni tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń wárí fún.
Ńṣe ni gbogbo ẹni bá ń ṣègbọràn sí Sátánì ń sọ ọ́ di ọlọ́run wọn bí Éfà ti ṣe. Nítorí náà, Sátánì ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Lára àbájáde ìṣàkóso rẹ̀ ni àgàbàgebè àti irọ́; ogun, ìdálóró àti ìparun; ìwà ọ̀daràn, ìwọra àti ìwà ìbàjẹ́.
Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ò Fi Ní Rí Ẹ Tàn Jẹ
Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká ‘pa agbára ìmòye wa mọ́, ká máa kíyè sára.’ Torí kí ni? Nítorí pé “Elénìní [wa], Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó gbàrònú ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ, síbẹ̀ ó fini lọ́kàn balẹ̀ láti mọ̀ pé àwọn tí ò bá pa agbára ìmòye wọn mọ́ nìkan, ìyẹn àwọn tí ò bá kíyè sára, ni ‘Sátánì lè fi ọgbọ́n àyínìke borí.’—2 Kọ́ríńtì 2:11.
Ó ṣe pàtàkì ká gbà pé lóòótọ́ ni Sátánì wà, ká sì jẹ́ kí Ọlọ́run ‘fìdí wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,’ kó sì ‘sọ wá di alágbára.’ Nípa bẹ́ẹ̀, a ó lè ‘mú ìdúró wa lòdì sí Sátánì,’ a ó sì pa ara wa mọ́ sọ́dọ̀ Ọlọ́run.—1 Pétérù 5:9, 10.
ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?
◼ Ibo ni Sátánì ti wá?—Jóòbù 38:4-7; Jòhánù 8:44.
◼ Báwo ni Sátánì ṣe ń tan aráyé jẹ tó?—Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 12:9.
◼ Kí la lè ṣe tá a fi lè gba ara wa lọ́wọ́ àrékérekè ìwà ibi Sátánì?—1 Pétérù 5:8-10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ṣé Sátánì ni agbára àìrí tó ń fa gbogbo ìṣòro tó ń yọ ayé wa yìí lẹ́nu?