Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àparò ni Ọlọ́run fi bọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù?
▪ Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè lóko ẹrú Íjíbítì, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àparò fún wọn láti jẹ.—Ẹ́kísódù 16:13; Númérì 11:31.
Àparò jẹ́ ẹ̀dá abìyẹ́, kò sì fí bẹ́ẹ̀ tóbi, ó gùn tó àtẹ́lẹwọ́, ó sì wúwo tó ọgọ́rùn-ún gíráàmù (100 g). Wọ́n máa ń pamọ ní apá ibi tó pọ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Éṣíà àti Yúróòpù. Nítorí pé àwọn àparò máa ń ṣí kiri, wọ́n máa ń ṣí lọ sí Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà àti Arébíà láti lọ lo ìgbà òtútù níbẹ̀. Lákòókò tí wọ́n bá ń ṣí lọ sáwọn àgbègbè míì, àgbájọ wọn máa ń fò gba ìlà oòrùn etí Òkun Mẹditaréníà, wọ́n á sì fò gba àgbègbè Sínáì tí omi yíká kọjá.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ti sọ, ìyẹn, The New Westminster Dictionary of the Bible, àwọn àparò “máa ń yára gan-an, wọ́n sì máa ń fò dáadáa, wọ́n máa ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ gbé wọn lọ, àmọ́ tí afẹ́fẹ́ kò bá gba ibi tí wọ́n dorí kọ tàbí tí ó bá rẹ̀ wọ́n nítorí wọ́n ti ń fò bọ̀ láti ọ̀nà tó jìn, ńṣe ni àgbájọ àwọn àparò náà máa jábọ́, tí wọn ò sì ní lè ṣe nǹkan kan.” Kí wọ́n tún tó lè bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjo wọn, wọ́n ní láti sinmi nílẹ̀ níbẹ̀ fún ọjọ́ kan tàbí méjì, lákòókò yìí, ó máa ń rọrùn fún àwọn èèyàn láti mú wọn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún, àwọn ará Íjíbítì máa ń kó àwọn àparò tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta lọ́dún lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míì fún àwọn tó fẹ́ jẹ́ ẹ.
Ìgbà ìrúwé ni ìgbà méjèèjì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ àparò. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé àwọn àparò máa ń fò kọjá dáadáa ní àgbègbè Sínáì lákòókò yẹn, síbẹ̀ Jèhófà ló mú kí ‘ẹ̀fúùfù fẹ́’ tó sì gbá àwọn àparò náà lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Númérì 11:31.
Kí ni “àjọyọ̀ ìyàsímímọ́” tí ìwé Jòhánù 10:22 sọ?
▪ Ọlọ́run pa á láṣẹ fún àwọn Júù láti máa ṣe àjọyọ̀ mẹ́ta lọ́dọọdún. Wọ́n ń ṣe Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé, Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì bí ìrúwé bá ń parí lọ àti Àjọyọ̀ Ìkórè ní ìgbà ìwọ́wé. Àmọ́, “ìgbà òtútù” ni wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ tí ìwé Jòhánù 10:22 sọ, òun ni wọ́n sì máa ń fi ṣèrántí bí wọ́n ṣe tún tẹ́ńpìlì Jèhófà yà sí mímọ́ lọ́dún 165 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọjọ́ mẹ́jọ ni wọ́n fi ń ṣe àjọyọ̀ yìí, ó máa ń bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Chislev, èyí tó sún mọ́ ìgbà òtútù. Kí ló mú kí wọ́n máa ṣe àjọyọ̀ yìí?
Lọ́dún 168 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ilẹ̀ Síríà tó ń ṣàkóso, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Áńtíókọ́sì Kẹrin (Epiphanes), sapá láti fòpin sí ìjọsìn àti àṣà àwọn Júù, nítorí náà, ó ní kí wọ́n ṣe pẹpẹ tí wọ́n á ti máa bọ̀rìṣà sórí ibi tí pẹpẹ Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Ó sì rúbọ sí Súúsì òrìṣà ilẹ̀ Gíríìsì lórí pẹpẹ náà.
Ohun tó ṣe yìí múnú bí àwọn Mákábì. Júdásì Mákábì tó jẹ́ aṣáájú àwọn Júù nígbà yẹn bá a jà, ó sì gba Jerúsálẹ́mù pa dà lọ́wọ́ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì náà, lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n fọ́ pẹpẹ tí wọ́n ti sọ di eléèérí náà, wọ́n sì kọ́ pẹpẹ tuntun pa dà síbẹ̀. Nígbà tó pé ọdún kẹta lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ pẹpẹ tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ di aláìmọ́, ni Júdásì tún tẹ́ńpìlì tó ti fọ̀ mọ́ yìí yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Láti ìgbà yẹn làwọn Júù ti ń ṣe “Àjọyọ̀ ìyàsímímọ́” yìí (tó ń jẹ́ chanuk·kahʹ lédè Hébérù) ní oṣù December. Lóde òní, ohun tí wọ́n ń pe àjọyọ̀ náà ni Hánúkà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Àwòrán júdásì mákábì ní ìlú lyon, ọdún 1553
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]
Látinú ìwé Wood’s Bible Animals, 1876