A Pa Wọn Mọ́ Láàyè La Ìpọ́njú Ńlá Já
“Awọn wọnyi ni awọn tí wọ́n jáde wá lati inú ìpọ́njú ńlá naa, wọ́n sì ti fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.”—ÌṢÍPAYÁ 7:14, NW.
1. Àwọn wo ni yóò kí àwọn tí a jí dìde káàbọ̀ nínú àjíǹde ti ilẹ̀-ayé?
NÍGBÀ tí a bá jí àìmọye àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dìde nínú “àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo,” a kì yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀-ayé kan tí ó ṣófo. (Iṣe 24:15, NW) Wọn yóò jí sínú àyíká tí a ti mú lẹ́wà síi wọn yóò sì rí i pé ibùgbé, aṣọ, àti oúnjẹ tí ó pọ̀ yanturu ni a ti pèsè sílẹ̀ fún wọn. Ta ni yóò pèsè gbogbo nǹkan wọ̀nyí sílẹ̀? Ó hàn gbangba pé, ṣáájú kí àjíǹde orí ilẹ̀-ayé tó bẹ̀rẹ̀ àwọn ènìyàn yóò wà tí wọn yóò máa gbé nínú ayé titun náà. Àwọn wo? Bibeli fi hàn pé wọn yóò jẹ́ àwọn olùla ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ wá já. Nínú gbogbo ẹ̀kọ́ Bibeli, kò sí iyèméjì pé èyí ni o fanimọ́ra jùlọ—pé a óò pa àwọn olùṣòtítọ́ kan mọ́ láàyè la ìpọ́njú ńlá já tí wọn kì yóò sì níláti kú láé. Ìwé Mímọ́ jẹ́rìí sí ìrètí yìí.
Gẹ́gẹ́ Bí Ọjọ́ Noa Ti Rí
2, 3. (a) Àwọn ìjọra wo ni a fàyọ láàárín ọjọ́ Noa àti àkókò wa? (b) Kí ni lílàájá tí Noa àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún-Omi já fi hàn?
2 Ní Matteu 24:37-39 (NW), Jesu Kristi ṣe ìfiwéra láàárín ọjọ́ Noa àti àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, níbi tí a bá ara wa báyìí. Ó wí pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn ọjọ́ Noa ti rí, bẹ́ẹ̀ naa ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yoo rí. Nitori bí wọ́n ti wà ní awọn ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún-omi, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, awọn ọkùnrin ń gbéyàwó a sì ń fi awọn obìnrin fúnni ninu ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ naa tí Noa wọ inú ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyèsí i títí ìkún-omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ naa ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yoo rí.”
3 Ìkún-Omi tí ó kárí ayé náà gbá gbogbo àwọn tí kò fiyèsí ìhìn-iṣẹ́ ìkìlọ̀ Ọlọrun lọ. Ṣùgbọ́n, kò gbá Noa àti ìdílé rẹ̀ lọ. Wọ́n “wọ inú ọkọ̀ áàkì,” gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ. Nítorí ìfọkànsìn wọn fún Ọlọrun, Jehofa pèsè ọ̀nà àsálà fún wọn. Peteru Kejì 2:5, 9 tọ́ka sí lílàájá Noa àti ìdílé rẹ̀ nígbà tí ó sọ pé: “Oun [Ọlọrun] . . . pa Noa, oníwàásù òdodo, mọ́ láìséwu pẹlu awọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé awọn aláìṣèfẹ́ Ọlọrun. Jehofa mọ bí a ti í dá awọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfọkànsin Ọlọrun nídè kúrò ninu àdánwò.” Jesu fi àwọn ọjọ́ Noa wéra pẹ̀lú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn láti fi hàn pé àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò kì yóò fetísí ìhìn-iṣẹ́ ìkìlọ̀ Ọlọrun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́rìí sí i pé Noa àti ìdílé rẹ̀ ṣègbọràn sí Jehofa Ọlọrun, wọ́n wọ inú ọkọ̀ áàkì, wọ́n sì la Ìkún-Omi náà já. Lílàájá Noa àti ìdílé rẹ̀ tọ́ka sí lílàájá àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ti Ọlọrun ní òpin ayé yìí.
Àpẹẹrẹ Kan Ní Ọ̀rúndún Kìn-ín-ní
4. Ní ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jesu, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó yọrí sí ìparun Jerusalemu ní 70 C.E.?
4 Jesu tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò wáyé ní òpin ayé yìí. Ní Matteu 24:21, 22 (NW), a kà pé: “Nitori nígbà naa ni ìpọ́njú ńlá yoo wà irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Níti tòótọ́, láìjẹ́ pé a ké awọn ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran-ara kankan tí à bá gbàlà; ṣugbọn nítìtorí awọn àyànfẹ́ a óò ké awọn ọjọ́ wọnnì kúrú.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní nínú Sànmání Tiwa. Ní 66 C.E., ìlú-ńlá Jerusalemu ni àwọn ọmọ ogun Romu lábẹ́ Cestius Gallus sàgatì. Àwọn ọmọ ogun Romu ti dé orí wíwó ògiri tẹ́ḿpìlì náà palẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù sì ti ṣetán láti túúbá. Bí ó ti wù kí ó rí, láìròtẹ́lẹ̀ àti láìsí ìdí kan tí ó ṣe gúnmọ́, Cestius Gallus kó ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò. Ní rírí i pé àwọn ará Romu ti fà sẹ́yìn, àwọn Kristian gbégbèésẹ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu, tí ó ti sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí awọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerusalemu ká, nígbà naa ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti súnmọ́lé. Nígbà naa ni kí awọn wọnnì tí ń bẹ ní Judea bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí awọn òkè-ńlá, kí awọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí awọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní awọn ibi ìgbèríko máṣe wọ inú rẹ̀.” (Luku 21:20, 21, NW) Àwọn Júù tí a ti sọ di Kristian, àwọn àyànfẹ́, pa ìlú-ńlá Jerusalemu tí a ti ké ègbé lé lórí náà tì ní kíákíá a sì tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ó dé sórí rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ní 70 C.E., àwọn ọ̀wọ́ ọmọ ogun Romu lábẹ́ Ọ̀gágun Titus padà wá. Wọ́n dóti Jerusalemu yíká, wọ́n sàgati ìlú-ńlá náà, wọ́n sì pa á run.
5. Ní ọ̀nà wo ni a gbà ké ìpọ́njú tí ó dé sórí Jerusalemu ní 70 C.E. kúrú?
5 Josephus òpìtàn Júù ròyìn pé 1,100,000 àwọn Júù ni ó kú, nígbà tí 97,000 làájá tí a sì kó wọn lọ sì ìgbèkùn. Dájúdájú àwọn Júù olùlàájá wọnnì tí kì í ṣe Kristian kọ́ ni “awọn àyànfẹ́” inú àsọtẹ́lẹ̀ Jesu. Jesu ti sọ, nígbà tí ó ń bá orílẹ̀-èdè Júù ọlọ̀tẹ̀ náà sọ̀rọ̀ pé: “Wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín. Nitori mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin kì yoo rí mi lọ́nàkọnà lati ìsinsìnyí lọ títí ẹ óò fi wí pé, ‘Alábùkúnfún ni ẹni naa tí ń bọ̀ ní orúkọ Jehofa!’” (Matteu 23:38, 39, NW) Kò sí àkọsílẹ̀ tí ó sọ pé, àwọn Júù tí a sé mọ́ Jerusalemu, tẹ́wọ́gba Jesu gẹ́gẹ́ bíi Messia, pé wọ́n di Kristian, tí wọ́n sì rí ojúrere Jehofa nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ké ìpọ́njú tí ó wá sórí Jerusalemu ní 70 C.E. kúrú. Ìsàgatì tí àwọn ọmọ ogun Romu ṣe kẹ́yìn yìí kò pẹ́ lọ títí. Èyí yọ̀ǹda fún àwọn Júù mélòókan láti làájá, kódà bí ó tilẹ̀ túmọ̀ sí kí a wulẹ̀ rán wọn jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹrú sí onírúurú àwọn apá Ilẹ̀-Ọba Romu.
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá ti Àwọn Olùlàájá
6, 7. (a) Ìlú-ńlá onísìn wo ni a máa tó parun, gẹ́gẹ́ bí apákan ìpọ́njú wo tí kò ní àfiwé? (b) Kí ni Johannu sọtẹ́lẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá ayé yìí tí ń bọ̀wá?
6 Nígbà tí ó jẹ́ pé ìparun Jerusalemu ní 70 C.E. mú “ìpọ́njú ńlá” kan níti gidi wá sórí ìlú ńlá onísìn yẹn, ìmúṣẹ títóbi jù tí ọ̀rọ̀ Jesu ní kò tí ì ní ìmúṣẹ. Ìlú-ńlá títóbi jù tí ó jẹ́ onísìn, Babiloni Ńlá, ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé, yóò jìyà ìpọ́njú ńlá tí ń ṣekúpani tí ìpọ́njú aláìlẹ́gbẹ́ lórí ìyókù ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan Satani yóò sì tẹ̀lé e. (Matteu 24:29, 30; Ìṣípayá 18:21) Ní nǹkan bí ọdún 26 lẹ́yìn ìparun Jerusalemu, aposteli Johannu, nínú Ìṣípayá 7:9-14, kọ̀wé nípa ìpọ́njú tí yóò gba gbogbo ayé kan yìí. Ó fi hàn pé ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn ènìyàn yóò là á já.
7 Àwọn olùlàájá wọ̀nyí, tí a pè ní “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” ni a dá fi hàn yàtọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ onípinnu tí wọ́n gbé. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 7:14 (NW), ti sọ, ọ̀kan lára àwọn alàgbà 24 ní ọ̀run sọ fún Johannu pé: “Awọn wọnyi ni awọn tí wọ́n jáde wá lati inú ìpọ́njú ńlá naa, wọ́n sì ti fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.” Bẹ́ẹ̀ni, ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń kókìkí Jehofa gẹ́gẹ́ bí orísun ìgbàlà wọn. Wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jesu tí a ta sílẹ̀ wọ́n sì ní ìdúró òdodo níwájú Ẹlẹ́dàá wọn àti Ọba rẹ̀ tí ó ti yànsípò, Jesu Kristi.
8. Irú ipò-ìbátan dídára wo ni ó wà láàárín “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àti àwọn àṣẹ́kù lára àwọn arákùnrin ẹni-àmì-òróró Jesu?
8 Lónìí, iye mẹ́ḿbà ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó million márùn-ún ń gbé lábẹ́ ipò aṣáájú gbígbéṣẹ́ ti Jesu Kristi Ọba ọ̀run náà. Wọ́n wà ní ìtẹríba fún Kristi wọ́n sì wà nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni-àmì-òróró tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé. Nípa ìwà tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà hù sí àwọn ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí, Jesu sọ pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan ninu awọn kíkéré jùlọ ninu awọn arákùnrin mi wọnyi, ẹ̀yin ti ṣe é fún mi.” (Matteu 25:40, NW) Nítorí pé wọ́n ṣe ìrànlọ́wọ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan fún àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin Kristi, a ṣèdájọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà pé wọ́n ṣe rere fún Jesu fúnra rẹ̀. Èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ipò-ìbátan tí kò léwu pẹ̀lú Jesu Kristi àti Jehofa Ọlọrun. Wọ́n ti ní àǹfààní láti darapọ̀ mọ́ àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró nínú dídi Ẹlẹ́rìí Ọlọrun àti àwọn tí ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn.—Isaiah 43:10, 11; Joeli 2:31, 32.
Wíwà Lójúfò
9, 10. (a) Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti lè di ìdúró òdodo wa mú níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn? (b) Báwo ni a ṣe níláti hùwà kí a baà lè “wà lójúfò”?
9 Ogunlọ́gọ̀ ńlá náà gbọ́dọ̀ mú ìdúró wọn níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn láìjuwọ́sílẹ̀, èyí tí ó béèrè fún ṣíṣọ́nà títí dé òpin. Jesu sọ èyí lọ́nà tí ó ṣe kedere nígbà tí ó wí pé: “Ẹ kíyèsí ara yín kí ọkàn-àyà yín má baà di èyí tí a dẹrùpa pẹlu àjẹjù ati ìmutíyó kẹ́ri ati awọn àníyàn ìgbésí-ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yoo sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nitori yoo dé bá gbogbo awọn wọnnì tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀-ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà naa, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà kí ẹ lè kẹ́sẹjárí ní yíyèbọ́ ninu gbogbo nǹkan wọnyi tí a ti yàntẹ́lẹ̀ lati ṣẹlẹ̀, ati ní dídúró níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn.”—Luku 21:34-36, NW.
10 Láti lè kẹ́sẹjárí nínú dídúró níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn, a gbọ́dọ̀ ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, èyí tí a kì yóò ní bí a bá yọ̀ǹda kí ìrònú ayé nípa ìdarí lórí wa. Ìrònú ayé ń tannijẹ ó sì lè ti ènìyàn sínú fífi adùn ti ara kẹ́ ara rẹ̀ bàjẹ́ tàbí láti di ẹni tí ìṣòro ìgbésí-ayé bò mọ́lẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi ní fi ire Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ mọ́. (Matteu 6:33) Irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ń sọ ẹnì kan di aláìlera nípa tẹ̀mí ó sì lè mú kí ó di ẹni tí ń dágunlá sí àwọn ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ sí Ọlọrun àti àwọn ẹlòmíràn. Ó lè di aláìṣiṣẹ́mọ́ tàbí kí ó fi àyè rẹ̀ nínú ìjọ sínú ewu nípa dídá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, bóyá kí ó tilẹ̀ fi ìṣarasíhùwà àìronúpìwàdà hàn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá gbọ́dọ̀ kíyèsí ara rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọrun yìí àti àwọn àṣà rẹ̀.—Johannu 17:16.
11. Ìfisílò ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti la Armageddoni já?
11 Láti ṣe èyí, Jehofa ti pèsè ohun tí a nílò nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àti ètò-àjọ rẹ̀ tí ó ṣeé fojúrí. A gbọ́dọ̀ lo àǹfààní ìwọ̀nyí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Síwájú síi, a gbọ́dọ̀ kún fún àdúrà kí a sì jẹ́ onígbọràn sí Ọlọrun bí a bá retí láti rí ojúrere rẹ̀ gbà. Ohun kan ni pé, a gbọ́dọ̀ mú ìkórìíra gidigidi dàgbà fún ohun tí ó burú. Onipsalmu náà sọ pé: “Èmi kò bá ẹni asán jókòó, bẹ́ẹ̀ni èmi kì yóò bá àwọn aláyìídáyidà wọlé. Èmi ti kórìíra ìjọ àwọn olùṣe búburú; èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn búburú jókòó. Máṣe kó ọkàn mi pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ènìyàn ẹ̀jẹ̀.” (Orin Dafidi 26:4, 5, 9) Nínú ìjọ Kristian, tọmọdé tàgbà pẹ̀lú níláti pààlà sí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kò ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa. Láti rí ojúrere Ọlọrun gbà, a ń làkàkà láti jẹ́ aláìlẹ́gàn àti aláìléèérí nínú ayé. (Orin Dafidi 26:1-5; Jakọbu 1:27; 4:4) Nípa bẹ́ẹ̀, a óò ní ìdánilójú pé ní Armageddoni, Jehofa kì yóò gbá wa lọ sínú ikú pẹ̀lú àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọrun.
Àwọn Kan “Kì Yoo Kú Rárá”
12, 13. (a) Ṣáájú kí ó tó jí Lasaru dìde, ọ̀rọ̀ wo ni Jesu sọ tí Marta kò lóye? (b) Kí ni Jesu kò ní lọ́kàn nípa àwọn kan ‘tí wọn kì yóò kú rárá’?
12 Ó jẹ́ ohun tí ń runilọ́kàn sókè láti máa fọkàn ronú nípa líla òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí já àti pé ó ṣeé ṣe kí a má kú rárá. Èyí ni ìrètí náà tí Jesu nawọ́ rẹ̀ sí wa. Kété ṣáájú jíjí Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó ti kú dìde, Jesu sọ fún Marta arábìnrin Lasaru pé: “Emi ni àjíǹde ati ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu mi, bí ó tilẹ̀ kú, yoo yè; ati olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ ninu mi kì yoo kú rárá láé. Iwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” Marta ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde, ṣùgbọ́n kò lóye gbogbo ohun tí Jesu ń sọ.—Johannu 11:25, 26, NW.
13 Jesu kò ní in lọ́kàn pé àwọn aposteli rẹ̀ olùṣòtítọ́ yóò máa bá a lọ láti wàláàyè nínú ẹran-ara tí wọn kì yóò sì kú. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ó fi hàn lẹ́yìn náà pé àwọn aposteli òun yóò kú. (Johannu 21:16-23) Níti tòótọ́, fífi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n ní Pentekosti 33 C.E. túmọ̀ sí pé wọ́n níláti kú láti lè gba ogún-ìní wọn ti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà. (Ìṣípayá 20:4, 6) Nípa bẹ́ẹ̀, bí àkókò ti ń kọjá lọ, gbogbo àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní kú. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdí kan wà tí Jesu fi sọ ohun tí ó sọ. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa wíwàláàyè láìkú rárá yóò ní ìmúṣẹ.
14, 15. (a) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jesu nípa àwọn kan ‘tí kì yóò kú rárá’ yóò ṣe ní ìmúṣẹ? (b) Báwo ni ipò ayé yìí ṣe rí, ṣùgbọ́n ìrètí wo ní àwọn olódodo ní?
14 Ohun kan ni pé, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ kì yóò ní ìrírí ikú àìnípẹ̀kun láéláé. (Ìṣípayá 20:6) Bákan náà àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ń tọ́ka sí àkókò kan pàtó nígbà tí Ọlọrun yóò dásí ọ̀ràn ẹ̀dá ènìyàn tí yóò sì gbá ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀-ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní ọjọ́ Noa. Àwọn olùṣòtítọ́ tí a bá rí tí ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ní àkókò yẹn kò níláti tipasẹ̀ ìdájọ́ Ọlọrun kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi Noa àti ìdílé rẹ̀, wọn yóò ní àǹfààní láti wàláàyè la ìparun ayé kan já. Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ fìdí múlẹ̀, níwọ̀n bí a ti gbé e ka orí àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli tí a sì fi àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ hàn. (Fiwé Heberu 6:19; 2 Peteru 2:4-9.) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fi hàn pé láìpẹ́ ayé ìsinsìnyí tí ó kún fún àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ aláìṣòdodo yóò dópin nínú ìparun. Ipò tí a ń rí ní lọ́ọ́lọ́ọ́ kò ṣeé yípadà, nítorí ayé ti burú rékọjá àtúnṣe. Ohun tí Ọlọrun sọ nípa ayé ti ọjọ́ Noa jẹ́ òtítọ́ nípa ayé ti òde-òní pẹ̀lú. Ìwà ibi kún ọkàn-àyà èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú aráyé, kìkì ibi sì ni èrò inú wọn nígbà gbogbo.—Genesisi 6:5.
15 Jehofa ti yọ̀ǹda fún àwọn ènìyàn láti ṣàkóso ilẹ̀-ayé fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún láìsí ìdásí àtọ̀runwá, ṣùgbọ́n àkókò wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán. Láìpẹ́ Jehofa yóò pa gbogbo àwọn ẹni ibi tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé run, gan-an gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ. (Orin Dafidi 145:20; Owe 2:21, 22) Bí ó ti wù kí ó rí, òun kì yóò pa àwọn olódodo run pẹ̀lú àwọn ẹni ibi. Ọlọrun kò tí ì ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí! (Fiwé Genesisi 18:22, 23, 26.) Èéṣe tí òun yóò fi pa àwọn wọnnì tí wọ́n ń sakun láti fi ìṣòtítọ́, pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọrun sìn ín run? Kìkì ohun tí ó bọ́gbọ́nmu ni pé kí àwọn olùṣòtítọ́ olùjọsìn Jehofa tí wọ́n bá wàláàyè nígbà tí ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀ rí ojúrere rẹ̀ kí a má sì pa wọ́n run, gan-an gẹ́gẹ́ bí a kò ṣe pa Noa àti ìdílé rẹ̀ run nígbà tí ayé búburú ti ọjọ́ rẹ̀ wá sí òpin lójijì. (Genesisi 7:23) Wọn yóò ní ààbò àtọ̀runwá wọn yóò sì la òpin ayé yìí já.
16. Àwọn ohun ìyanu wo ni yóò ṣẹlẹ̀ nínú ayé titun, kí ni yóò sì túmọ̀ sí fún àwọn olùlàájá?
16 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Nínú ayé titun náà, àwọn ìbùkún tí ń múniláradà yóò ṣàn wá sọ́dọ̀ aráyé bí a bá ṣe ń lo àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jesu ní kíkún. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa “odò omi ìyè” ìṣàpẹẹrẹ “tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì, tí ń ṣàn jáde lati ibi ìtẹ́ Ọlọrun ati ti Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa wá sí ìsàlẹ̀ gba àárín ọ̀nà fífẹ̀ rẹ̀. Awọn igi ìyè sì wà ní ìhà ìhín odò naa ati ní ìhà ọ̀hún tí ń mú irè-oko méjìlá ti èso jáde, tí ń so awọn èso wọn ní oṣooṣù. Ewé awọn igi naa sì wà fún wíwo awọn orílẹ̀-èdè sàn.” (Ìṣípayá 22:1, 2, NW) Ohun àgbàyanu ni ó jẹ́ láti sọ, pé ‘wíwoni sàn’ wémọ́ ṣíṣẹ́gun ikú tí a jogún lọ́dọ̀ Adamu fúnra rẹ̀! “Òun óò gbé ikú mì láéláé; Oluwa Jehofa yóò nu omijé nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Isaiah 25:8) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn wọnnì tí wọ́n ń la ìpọ́njú ńlá náà já bọ́ sínú ayé titun kì yóò dojúkọ ikú láé!
Ìrètí Tí Ó Dájú
17. Báwo ni ìrètí náà pé àwọn kan yóò la Armageddoni já tí wọn ‘kì yóò sì kú rárá’ ṣe dájú tó?
17 A ha lè ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú ìrètí tí ń mú háà ṣeni yìí bí? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni! Jesu sọ fún Marta pé àkókò kan yóò wà nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa wàláàyè láìkú rárá. (Johannu 11:26) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní orí 7 Ìṣípayá tí Jesu fifún Johannu, a ṣí i payá pé ogunlọ́gọ̀ ńlá kan jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá, tí wọ́n sì làájá. A ha lè gba Jesu Kristi àti àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn Ìkún-Omi ọjọ́ Noa gbọ́ bí? Dájúdájú! Síwájú síi, Bibeli ní àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn nípa àwọn ìgbà tí Ọlọrun pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ́ láàyè la àkókò ìdájọ́ àti ìṣubú àwọn orílẹ̀-èdè já. A ha níláti máa retí ohun tí ó dínkù sí ìyẹn ní àkókò òpin yìí bí? Ohunkóhun ha wà tí kò ṣeé ṣe fún Ẹlẹ́dàá náà bí?—Fiwé Matteu 19:26.
18. Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú ti wíwàláàyè nínú ayé titun òdodo ti Jehofa?
18 Nípa ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìṣòtítọ́ nísinsìnyí, a ní ìdánilójú ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé titun rẹ̀. Fún àìlóǹkà àràádọ́ta ọ̀kẹ́, ìyè nínú ètò titun náà yóò wá nípasẹ̀ àjíǹde. Síbẹ̀, ní ọjọ́ wa, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn Jehofa—bẹ́ẹ̀ni, ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ẹnikẹ́ni kò lè kà tàbí díwọ̀n—yóò ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti jíjẹ́ ẹni tí a pa mọ́ láàyè la ìpọ́njú ńlá náà já. Wọn kì yóò sì níláti kú rárá.
Jọ̀wọ́ Ṣàlàyé
◻ Báwo ni a ṣe fúnni ní àpẹẹrẹ ìṣáájú ní ọjọ́ Noa pé àwọn kan yóò la Armageddoni já?
◻ Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe kí a baà lè mú ìdúró wa nígbà tí Jesu bá wá láti mú ìdájọ́ Jehofa ṣẹ?
◻ Èéṣe tí a fi lè sọ pé àwọn olùla Armageddoni já “kì yóò kú rárá”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn Kristian la ìpọ́njú Jerusalemu já