-
Bá A Ṣe Lè Mú Kí Àwọn Ìbátan Wa Tí Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí Nífẹ̀ẹ́ Òtítọ́Ilé Ìṣọ́—2014 | March 15
-
-
Ní ọ̀rúndún kìíní, Áńdérù wà lára àwọn tó kọ́kọ́ dá Jésù mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó kọ́kọ́ lọ sọ fún? “[Áńdérù] rí arákùnrin tirẹ̀, Símónì, ó sì wí fún un pé: ‘Àwa ti rí Mèsáyà náà’ (èyí tí ó túmọ̀ sí ‘Kristi,’ nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀).” Áńdérù mú Pétérù lọ sọ́dọ̀ Jésù, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí Pétérù ní àǹfààní láti di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Jòh. 1:35-42.
-
-
Bá A Ṣe Lè Mú Kí Àwọn Ìbátan Wa Tí Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí Nífẹ̀ẹ́ Òtítọ́Ilé Ìṣọ́—2014 | March 15
-
-
Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Áńdérù àti Kọ̀nílíù gbà ran àwọn ìbátan wọn lọ́wọ́?
Áńdérù àti Kọ̀nílíù ò kàn fi ọwọ́ lẹ́rán láìṣe nǹkan kan. Áńdérù ló fi Pétérù mọ Jésù, Kọ̀nílíù sì ṣètò bí àwọn ìbátan rẹ̀ á ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù. Àmọ́ Áńdérù àti Kọ̀nílíù ò fipá mú àwọn ìbátan wọn, wọn ò sì dọ́gbọ́n tàn wọ́n kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Kristi. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé káwa náà máa sọ àwọn nǹkan tá a mọ̀ fáwọn ìbátan wa, ká wá bí wọ́n ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì tún mọ àwọn ará. Síbẹ̀, a ò ní gbàgbé pé wọ́n ní òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n, a ò sì ní máa fipá mú wọn. Ká lè mọ bá a ṣe lè máa ran àwọn ìbátan wa lọ́wọ́, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ìyẹn Jürgen àti Petra.
-