ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 16
Rọ̀ Mọ́ Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ipò Táwọn Òkú Wà
‘À ń fìyàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ní ìmísí àti ọ̀rọ̀ àṣìṣe tó ní ìmísí.’—1 JÒH. 4:6.
ORIN 73 Fún Wa Ní Ìgboyà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń tan àwọn èèyàn jẹ? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ỌJỌ́ pẹ́ tí Sátánì tó jẹ́ “baba irọ́” ti ń tan àwọn èèyàn jẹ, kódà ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀. (Jòh. 8:44) Lára ẹ̀kọ́ èké tó fi ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ni pé ọkàn èèyàn kì í kú. Ẹ̀kọ́ èké yìí ló bí àwọn àṣà tó wọ́pọ̀ lónìí àti ìgbàgbọ́ òdì nípa àwọn òkú. Fún ìdí yìí, àwọn ará wa kan lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní láti “jà fitafita torí ìgbàgbọ́” wọn nígbà tẹ́nì kan nínú ìdílé wọn tàbí ládùúgbò wọn bá kú.—Júùdù 3.
2 Tí àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí aládùúgbò rẹ bá retí pé kó o bá wọn lọ́wọ́ sáwọn àṣà yìí, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dúró lórí ohun tí Bíbélì sọ? (Éfé. 6:11) Báwo lo ṣe lè tu Kristẹni kan téèyàn rẹ̀ kú nínú, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kó má bàa lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀? Àpilẹ̀kọ yìí máa jíròrò àwọn ìlànà tí Jèhófà fún wa lórí kókó yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò táwọn òkú wà.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA IPÒ TÁWỌN ÒKÚ WÀ
3. Kí ni àbájáde irọ́ àkọ́kọ́ tí Sátánì pa?
3 Ọlọ́run ò fẹ́ káwa èèyàn máa kú. Àmọ́ tí Ádámù àti Éfà bá máa wà láàyè títí láé, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jèhófà. Òfin tó fún wọn ò sì nira, ó ní: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ lẹ máa kú.’ (Jẹ́n. 2:16, 17) Nígbà tí Sátánì máa gbé ìṣe ẹ̀ dé, ó fi ejò bojú, ó sì sọ fún Éfà pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú.” Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà gba irọ́ yẹn gbọ́, ó sì jẹ èso náà. Nígbà tó yá, ọkọ rẹ̀ náà jẹ èso yẹn. (Jẹ́n. 3:4, 6) Bó ṣe di pé aráyé ń dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ń kú nìyẹn.—Róòmù 5:12.
4-5. Báwo ni Sátánì ṣe ń bá a lọ láti máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà?
4 Ádámù àti Éfà kú bí Ọlọ́run ṣe sọ. Àmọ́ Sátánì ò ṣíwọ́ irọ́ pípa. Nígbà tó yá, ó tún pa àwọn irọ́ míì nípa ipò táwọn òkú wà. Lára irọ́ náà ni pé téèyàn bá kú, ohun kan wà tó máa ń jáde lára ẹ̀ táá sì máa rìn káàkiri. Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ti gbà tan irọ́ yìí kálẹ̀, ó sì ń ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà títí dòní olónìí.—1 Tím. 4:1.
5 Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gba irọ́ yìí gbọ́? Sátánì mọ bí ọ̀rọ̀ ikú ṣe máa ń rí lára wa, ìyẹn ló sì ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kú nínú wa, ó ṣe tán Ọlọ́run dá wa pé ká máa wà láàyè títí láé. (Oníw. 3:11) Kódà, a kì í fẹ́ gbọ́rọ̀ ikú sétí rárá, torí pé ọ̀tá wa ni.—1 Kọ́r. 15:26.
6-7. (a) Ṣé gbogbo èèyàn ló gba irọ́ Sátánì gbọ́? Ṣàlàyé. (b) Báwo ni Bíbélì ṣe gbà wá lọ́wọ́ ìbẹ̀rù?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti daṣọ bo òtítọ́ nípa àwọn òkú, síbẹ̀ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá mọ ipò táwọn òkú wà àti ìrètí tí wọ́n ní, wọ́n sì ń sọ ọ́ fáráyé gbọ́. (Oníw. 9:5, 10; Ìṣe 24:15) Òtítọ́ yìí ń tuni nínú, ó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé kò sídìí láti máa bẹ̀rù ikú. Bí àpẹẹrẹ, a kì í bẹ̀rù òkú, bẹ́ẹ̀ la kì í ronú pé aburú kan ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. A mọ̀ pé wọ́n ti kú, wọn ò sì lè ṣe ẹnikẹ́ni ní jàǹbá. Bí ẹni tó sun oorun àsùnwọra lọ̀rọ̀ wọn rí. (Jòh. 11:11-14) Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé àwọn òkú ò mọ̀ bóyá ọjọ́ ti lọ tàbí kò tíì lọ. Torí náà, tó bá dìgbà àjíǹde, ṣe làwọn tó ti kú lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn máa wò ó bíi pé ìṣẹ́jú kan sẹ́yìn làwọn kú.
7 Ó dájú pé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn òkú ṣe kedere, kò lọ́jú pọ̀, ó sì bọ́gbọ́n mu. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní ti irọ́ tí Sátánì ń pa torí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò bá làákàyè mu rárá! Yàtọ̀ sí pé irọ́ yẹn ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, ó tún ń tàbùkù sí Ẹlẹ́dàá wa. Ká lè lóye bí irọ́ tí Sátánì pa ṣe burú tó, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni irọ́ Sátánì ṣe ń tàbùkù sí Jèhófà? Báwo ló ṣe mú kó dà bíi pé ẹbọ ìràpadà Jésù kò wúlò? Báwo sì ni irọ́ yìí ṣe pa kún ìṣòro àti ẹ̀dùn ọkàn táwọn èèyàn ń ní?
IRỌ́ SÁTÁNÌ TI ṢÀKÓBÁ TÓ PỌ̀ GAN-AN
8. Bó ṣe wà nínú Jeremáyà 19:5, báwo ni irọ́ tí Sátánì pa nípa àwọn òkú ṣe tàbùkù sí Jèhófà?
8 Àwọn irọ́ Sátánì tàbùkù sí Jèhófà. Lára àwọn irọ́ náà ni pé àwọn òkú máa ń joró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Ẹ wo bí ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run! Lọ́nà wo? Ńṣe ni ẹ̀kọ́ burúkú yìí ń jẹ́ kó dà bíi pé Jèhófà fìwà jọ Sátánì tó jẹ́ ìkà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà. (1 Jòh. 4:8) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára rẹ? Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà? Pàápàá tá a bá rántí pé Jèhófà kórìíra ìwà ìkà.—Ka Jeremáyà 19:5.
9. Báwo ni irọ́ Sátánì ṣe mú kó dà bíi pé ẹbọ ìràpadà Kristi tí Jòhánù 3:16 àti 15:13 sọ nípa rẹ̀ kò wúlò?
9 Àwọn irọ́ Sátánì mú kó dà bíi pé ẹbọ ìràpadà Kristi kò wúlò. (Mát. 20:28) Irọ́ míì tí Sátánì pa ni pé ọkàn àwọn èèyàn kì í kú. Tó bá jẹ́ òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn, á jẹ́ pé wọ́n ti ní ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kò sídìí tí Kristi fi ní láti kú fún wa ká lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ má sì gbàgbé pé ìràpadà Kristi ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Ọlọ́run àti Jésù gbà fi ìfẹ́ hàn sí wa. (Ka Jòhánù 3:16; 15:13.) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà àti Jésù bí ẹ̀kọ́ èké yẹn ṣe mú kó dà bíi pé wọ́n kàn fi ẹ̀bùn iyebíye yìí ṣòfò!
10. Báwo ni irọ́ Sátánì ṣe pa kún ìṣòro àti ẹ̀dùn ọkàn táwọn èèyàn ní?
10 Irọ́ Sátánì ń pa kún ìṣòro àti ẹ̀dùn ọkàn táwọn èèyàn ní. Wọ́n lè sọ fún àwọn òbí tí ọmọ wọn kú pé Ọlọ́run tó fún wọn lọ́mọ náà ló gbà á, àti pé ọmọ náà wà lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ṣé irọ́ yìí máa ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú àbí ṣe ló tún ń dá kún un? Ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì wà lára ohun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ìgbà yẹn fi kẹ́wọ́ láti máa dá àwọn èèyàn lóró, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń finá sun àwọn tó bá ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Ìwé kan sọ ohun tó ṣeé ṣe kó fà á táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yẹn fi ń dáná sun àwọn tó ta ko ẹ̀kọ́ wọn. Wọ́n gbà pé báwọn ṣe ń finá sun wọ́n yẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé iná ọ̀run àpáàdì kọjá kèrémí, nípa bẹ́ẹ̀ ó ṣeé ṣe káwọn alátakò ṣọ́ọ̀ṣì yẹn ronú pìwà dà kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ iná ọ̀run àpáàdì. Láwọn ilẹ̀ kan, ìbẹ̀rù òkú ti mú kí wọ́n máa júbà àwọn tí wọ́n pè ní alálẹ̀ tàbí àwọn baba ńlá wọn, wọ́n sì máa ń rúbọ tàbí gbàdúrà sí wọn kí wọ́n lè rí ìbùkún gbà. Àwọn míì máa ń wá ojúure òkú kó má bàa fìyà jẹ wọ́n. Ó ṣeni láàánú pé kàkà kí àwọn ẹ̀kọ́ èké Sátánì yẹn mú ìtura bá àwọn èèyàn, ìnira, àníyàn àti ìpayà ló ń kó bá wọn.
BÓ O ṢE LÈ RỌ̀ MỌ́ OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
11. Kí ló lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ fúngun mọ́ wa láti ṣe ohun tó ta ko Bíbélì?
11 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa mú ká ṣègbọràn sí Jèhófà kódà táwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ bá ń fúngun mọ́ wa pé ká lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìsìnkú tó ta ko Bíbélì. Wọ́n lè sọ pé a ò nífẹ̀ẹ́ ẹni tó kú náà la ò ṣe fẹ́ lọ́wọ́ nínú ohun táwọn ń ṣe. Wọ́n sì lè sọ pé ìpinnu wa máa bí òkú yẹn nínú, kó sì wá ṣe àwọn ní ìjàǹbá. Kí la lè ṣe tá ò fi ní lọ́wọ́ sóhun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì mélòó kan àti bá a ṣe lè fi wọ́n sílò.
12. Tó bá kan ọ̀rọ̀ àwọn òkú, àwọn àṣà wo ni kò bá Bíbélì mu?
12 Ẹ rí i dájú pé ẹ “ya ara yín sọ́tọ̀,” ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà tí kò bá Bíbélì mu. (2 Kọ́r. 6:17) Ní agbègbè kan ní Caribbean, ọ̀pọ̀ gbà pé téèyàn bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ á ṣì máa rìn kiri láti fìyà jẹ àwọn tó fojú pọ́n ọn nígbà tó wà láyé. Ìwé kan sọ pé ẹ̀mí òkú náà tiẹ̀ lè fa ìṣòro fáwọn ará ìlú. Láwọn ilẹ̀ kan ní Áfíríkà, wọ́n sábà máa ń daṣọ bo dígí, wọ́n á sì kọ ojú fọ́tò òkú náà sí ògiri. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn kan gbà pé ẹni tó kú náà ò gbọ́dọ̀ rí àwòrán ara rẹ̀! Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà kò gba àwọn nǹkan yìí gbọ́, torí náà a kì í bá wọn lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó ń gbé irọ́ Sátánì lárugẹ.—1 Kọ́r. 10:21, 22.
13. Tí o kò bá mọ ohun tó yẹ kó o ṣe nípa àṣà kan, kí ni Jémíìsì 1:5 sọ pé kó o ṣe?
13 Tí o kò bá mọ̀ bóyá àṣà kan bá Bíbélì mu tàbí kò bá a mu, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n láti ṣèpinnu tó tọ́. (Ka Jémíìsì 1:5.) Lẹ́yìn náà, ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. O sì lè kàn sáwọn alàgbà ìjọ rẹ. Fi sọ́kàn pé wọn ò ní ṣèpinnu fún ẹ, àmọ́ wọ́n lè tọ́ka sáwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, bí irú èyí tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí, ṣe lò ń kọ́ “agbára ìfòyemọ̀” rẹ, èyí á sì jẹ́ kó o lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Héb. 5:14.
14. Kí la lè ṣe tá ò fi ní mú àwọn míì kọsẹ̀?
14 “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹ má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀.” (1 Kọ́r. 10:31, 32) Nígbà tá a bá ń pinnu bóyá ká lọ́wọ́ nínú àṣà kan tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká tún ronú nípa bí ìpinnu wa ṣe máa rí lára àwọn Kristẹni bíi tiwa àtàwọn míì. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀. (Máàkù 9:42) Bákan náà, a ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa bí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, àá fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn sì máa fògo fún Jèhófà. Kò ní bójú mu ká máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí ká máa bẹnu àtẹ́ lu àṣà wọn. Ká rántí pé ìfẹ́ lágbára gan-an. Tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń fúngun mọ́ wa, tá a sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ó ṣeé ṣe kí ọkàn wọn rọ̀.
15-16. (a) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o jẹ́ káwọn míì mọ ohun tó o gbà gbọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan. (b) Báwo lọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 1:16 ṣe kàn wá?
15 Jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. (Àìsá. 43:10) Tó o bá ti jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò rẹ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, á rọrùn fún ẹ láti kọ̀ tí wọ́n bá ní kó o lọ́wọ́ nínú àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Francisco tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì, ó sọ pé: “Nígbà témi àti Carolina ìyàwó mi ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ la ti sọ fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa pé a ò ní máa bá wọn lọ́wọ́ nínú ṣíṣe ètùtù fún òkú mọ́. Ọ̀rọ̀ dójú ẹ̀ nígbà tí ẹ̀gbọ́n ìyàwó mi kú. Lọ́dọ̀ wa, wọ́n sábà máa ń ṣe ètùtù kan. Wọ́n máa ń wẹ̀ fún òkú lọ́nà àkànṣe, wọ́n á sì ní kẹ́nì kan tó sún mọ́ òkú náà sùn síbi tí wọ́n da omi tí wọ́n fi wẹ òkú náà sí fún odindi ọjọ́ mẹ́ta. Wọ́n gbà pé ìyẹn ni wọ́n fi máa tu ẹ̀mí òkú náà lójú. Nígbà tọ́rọ̀ náà ṣẹlẹ̀, ìyàwó mi làwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ yàn pé kó sùn síbi tí wọ́n da omi òkú náà sí.”
16 Kí wá ni Francisco àtìyàwó rẹ̀ ṣe? Francisco sọ pé: “Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú bí i, a ò lọ́wọ́ nínú àṣà náà. Ìpinnu yìí múnú bí àwọn mọ̀lẹ́bí ìyàwó mi gan-an. Wọ́n fẹ̀sùn kàn wá pé a kì í bọ̀wọ̀ fún òkú, torí náà àwọn ò ní dé ilé wa mọ́, ká má sì pe àwọn tá a bá nílò ìrànwọ́. A ò bá wọn jiyàn ní gbogbo ìgbà tínú ń bí wọn yẹn, ó ṣe tán a kúkú ti sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún wọn. Kódà, àwọn kan lára wọn gbèjà wa, wọ́n ní a ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a kì í lọ́wọ́ sírú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn mọ̀lẹ́bí ìyàwó mi fọwọ́ wọ́nú, a sì jẹ́ kọ́rọ̀ wa túbọ̀ yé wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn kan lára wọn wá sílé wa, wọ́n sì ní ká fún àwọn ní ìtẹ̀jáde wa.” Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní tijú àtisọ ohun tá a gbà gbọ́ nípa ipò táwọn òkú wà, àá sì dúró lórí ìgbàgbọ́ wa.—Ka Róòmù 1:16.
MÁA TU ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀ NÍNÚ, KÓ O SÌ DÚRÓ TÌ WỌ́N
17. Kí la lè ṣe fún Kristẹni kan tó ń ṣọ̀fọ̀?
17 Tí èèyàn arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá kú, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ “ọ̀rẹ́ tòótọ́ . . . , ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.” (Òwe 17:17) Báwo la ṣe lè jẹ́ “ọ̀rẹ́ tòótọ́” pàápàá lásìkò tí àwọn mọ̀lẹ́bí ń fúngun mọ́ ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà pé kó lọ́wọ́ nínú àṣà tí kò bá Bíbélì mu? Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìlànà Bíbélì méjì táá jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè tu ẹni náà nínú.
18. Kí nìdí tí Jésù fi sunkún, kí nìyẹn sì kọ́ wa?
18 “Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.” (Róòmù 12:15) A lè má mọ ohun tá a máa sọ fún ẹnì kan tó ń ṣọ̀fọ̀. Àmọ́ ká rántí pé omijé wa sọ púpọ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Lásárù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù kú, Màríà, Màtá àtàwọn míì sunkún nítorí pé èèyàn wọn lẹni tó kú náà. Nígbà tí Jésù débẹ̀ lọ́jọ́ kẹrin, òun náà “da omi lójú,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde. (Jòh. 11:17, 33-35) Bí Jésù ṣe sunkún jẹ́ ká mọ bí ikú Lásárù ṣe máa rí lára Jèhófà. Ó tún fi hàn pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà. Kò sí àní-àní pé ohun tí Jésù ṣe yẹn tu Màríà àti Màtá nínú. Lọ́nà kan náà, tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀, tá a sì fi ìmọ̀lára tòótọ́ hàn, wọ́n á gbà pé a nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ló yí àwọn ká.
19. Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ inú Oníwàásù 3:7 sílò tá a bá ń tu Kristẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?
19 “Ìgbà dídákẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníw. 3:7) Ohun míì tó o lè ṣe láti tu ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú ni pé kó o tẹ́tí sí i. Ó ṣe pàtàkì kó o fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, má sì jẹ́ káwọn ọ̀rọ̀ tó dà bí “ọ̀rọ̀ ẹhànnà” bí ẹ nínú. (Jóòbù 6:2, 3) Ó ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ máa fúngun mọ́ ọn pé kó lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Torí náà, ẹ jọ gbàdúrà pa pọ̀. Bẹ “Olùgbọ́ àdúrà” pé kó fún un lókun àti ọgbọ́n táá jẹ́ kó lè ṣèpinnu tó tọ́. (Sm. 65:2) Tó bá ṣeé ṣe, ẹ jọ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan pa pọ̀. O sì lè ka àpilẹ̀kọ kan tó bá ipò rẹ̀ mu nínú àwọn ìwé wa fún un, irú bí ìtàn ìgbésí ayé ẹnì kan.
20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 A mà dúpẹ́ o pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ ipò táwọn òkú wà, ó sì tún jẹ́ kó dá wa lójú pé a máa pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú nígbà àjíǹde! (Jòh. 5:28, 29) Torí náà, ẹ jẹ́ ká rọ̀ mọ́ òtítọ́ yìí lọ́rọ̀ àti níṣe, ká sì máa sọ ọ́ fáwọn míì nígbàkigbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí ohun míì tí Sátánì ń lò láti mú káwọn èèyàn wà nínú òkùnkùn, ìyẹn sì ni ìbẹ́mìílò. Àá rí ìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra fún àwọn àṣà àti eré ìnàjú tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ.
ORIN 24 Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà
a Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti tan àwọn èèyàn jẹ nípa ipò táwọn òkú wà. Èyí sì ti mú káwọn èèyàn máa lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà táwọn míì bá fẹ́ kó o lọ́wọ́ sírú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀.
b ÀWÒRÁN: Tọkọtaya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tu mọ̀lẹ́bí wọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nínú torí pé èèyàn rẹ̀ kú.
c ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn tí arákùnrin kan ti ṣèwádìí ohun tí Bíbélì sọ nípa àṣà ìsìnkú, ó fìrẹ̀lẹ̀ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀.
d ÀWÒRÁN: Àwọn alàgbà yìí dúró ti arákùnrin kan téèyàn rẹ̀ kú, wọ́n sì ń tù ú nínú.