Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Bá Kú?
ỌLỌ́RUN ò dá àwa èèyàn láti máa kú. (Róòmù 8:20, 21) Ìdí ẹ̀ nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jèhófà kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ikú fún Ádámù, kò jẹ́ kó rí i bíi gbèsè tí ẹ̀dá gbọ́dọ̀ máa san, àmọ́ ó jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àìgbọràn tí wọ́n ṣe sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ádámù lóye ohun tí ikú túmọ̀ sí, nítorí pé á ti rí ẹran tó kú rí.
Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó sì jẹ ìyà tó tọ́ sí àìgbọ́ràn rẹ̀ nítorí pé ó kú ní ẹni ọdún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé ọgbọ̀n [930]. (Jẹ́nẹ́sísì 5:5; Róòmù 6:23) Àìgbọràn rẹ̀ yìí ló mú kí Ọlọ́run yọ ọ́ kúrò lára àwọn tó para pọ̀ wà nínú ìdílé rẹ̀, kò sì yẹ lẹ́ni tá ò bá máa pè ní ọmọ Ọlọ́run mọ́. (Diutarónómì 32:5) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àbájáde búburú tí èyí mú wá fún aráyé, ó sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 5:12.
Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ìrònú Ẹni Tó Bá Ti Kú?
Bíbélì tún sọ pé: “Àtúbọ̀tán kan ni ó wà ní ti àwọn ọmọ aráyé àti àtúbọ̀tán kan ní ti ẹranko, àtúbọ̀tán kan náà sì ni wọ́n ní. Bí èkíní ti ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; ẹ̀mí kan ṣoṣo sì ni gbogbo wọ́n ní, ìyẹn ni ó fi jẹ́ pé ènìyàn kò ní ọlá ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni gbogbo rẹ̀. Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ. Inú ekuru ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.” (Oníwàásù 3:19, 20) Kí ni pípadà sínú ekuru túmọ̀ sí?
Gbólóhùn náà “padà sí ekuru” rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run kọ́kọ́ sọ fún ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Èyí túmọ̀ sí pé bíi tàwọn ẹranko, ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara làwa èèyàn náà. A kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí tó wulẹ̀ gbé ara èèyàn wọ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bá a bá ti kú a ò tún lè ronú mọ́. Bíbélì sọ nípa ẹni tó ti kú pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.
Bó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe ń rí nìyí, ibo gan-an wá làwọn òkú wà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìdáhùn tó ṣe kedere pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Dípò kí ikú jẹ́ ọ̀rẹ́ tí ń sin èèyàn lọ sínú ayé tó sàn jù, “ọ̀tá ìkẹyìn” ni Bíbélì pè é, nítorí pé ó máa ń fòpin sí gbogbo ìgbòkègbodò ẹ̀dá èèyàn. (1 Kọ́ríńtì 15:26; Oníwàásù 9:10) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé béèyàn bá ti kú, tiẹ̀ ti gbé nìyẹn?
Ìròyìn Ayọ̀ Nípa Ikú
Fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ti kú, ńṣe ni ikú dà bí oorun àsùnjí. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ rí nípa ọ̀rẹ́ wọn kan tó ti kú pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.” Nígbà tí Jésù ń lọ síbi ibojì ìrántí tí wọ́n sin Lásárù sí, ó rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ṣọ̀fọ̀. Nígbà tó débẹ̀, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣí ibojì náà, ó sì kígbe pé: “Lásárù, jáde wá!” Ọkùnrin tó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin náà sì jáde látinú ibojì. (Jòhánù 11:11-14, 39, 43, 44) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ara Lásárù ti ń jẹrà, jíjí tí Jésù jí i dìde fi hàn pé Ọlọ́run lè rántí gbogbo nǹkan pátá nípa ẹni tó ti kú, ì báà jẹ́ ìwà wọn, ohun tí wọ́n ti kó sọ́pọlọ àti bí wọ́n ṣe rí. Ó lè mú kí wọ́n tún wà láàyè. Ìgbà kan sì tún wà tí Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [ìyẹn ohùn Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.
Bíbélì tún fún wa ní ìròyìn ayọ̀ sí i nígbà tó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Kò sẹ́ni táá máa lọ sin èèyàn ẹ̀ tó kú sí itẹ́ òkú mọ́ nítorí pé kò ní síkú tó ń sọ̀kò ìbànújẹ́ sílé ẹni mọ́. Bíbélì sọ pé: “Ikú kì yóò sì sí mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Ṣé ìwọ náà wá gbà báyìí pé kò sóhun tó ń bani nínú jẹ́ nínú ojú tí Bíbélì fi wo ọ̀ràn àwọn tó bá ti kú?
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Ǹjẹ́ àwọn òkú mọ ohunkóhun?—Oníwàásù 9:5.
◼ Ṣé béèyàn bá ti kú, tiẹ̀ ti gbé nìyẹn?—Jòhánù 5:28, 29.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]
“Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4