Ǹjẹ́ Ipò Òṣì Lè Dópin Jáé?
SÓLÓMỌ́NÌ ọlọ́gbọ́n Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.” (Oníwàásù 4:1) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé à ń ni lára wọ̀nyí ló jẹ́ òtòṣì bákan náà.
A ò lè fi kìkì ọ̀ràn owó díwọ̀n ipò òṣì. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìsọfúnni oníṣirò tí Báńkì Àgbáyé gbé jáde ní June 2002, “wọ́n fojú bù ú pé lọ́dún 1998, owó tí àwọn èèyàn lágbàáyé tí iye wọn lé ní bílíọ̀nù kan ń ná lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lójúmọ́ kò tó dọ́là kan . . . nígbà tí iye èèyàn tó kù díẹ̀ kó pé bílíọ̀nù mẹ́ta ń ná iye tó dín sí dọ́là méjì lójúmọ́.” Wọ́n sọ pé lóòótọ́ ni iye yẹn kéré sí iye tí wọ́n ti fojú bù tẹ́lẹ̀, “àmọ́ iye yìí ṣì ga jù tá a bá ń sọ nípa àwọn èèyàn tí ń jìyà nítorí ipò òṣì.”
Ǹjẹ́ ipò òṣì lè dópin láé? Jésù Kristi sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ní àwọn òtòṣì nígbà gbogbo pẹ̀lú yín.” (Jòhánù 12:8) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ipò òṣì àti gbogbo wàhálà tó ń fà kò ní dópin láé ni? Rárá o, òótọ́ ni pé Jésù ò ṣèlérí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé gbogbo wọn ló máa lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ wá torí ohun tó sọ yìí gbà pé kò sọ́nà àbáyọ fáwọn òtòṣì.
Pẹ̀lú bí gbogbo ìsapá ẹ̀dá èèyàn àti gbogbo ìlérí tí wọ́n ń ṣe pé àwọn á mú ipò òṣì kúrò ṣe já sí pàbó, Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé kò ní sí ipò òṣì mọ́ láìpẹ́. Kódà, Jésù polongo “ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” (Lúùkù 4:18) Ìhìn rere yìí ní nínú ìlérí náà pé ipò òṣì máa tó di ohun àtijọ́. Èyí á ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá mú ipò àwọn nǹkan padà sí bó ṣe yẹ lórí ilẹ̀ ayé.
Ayé á mà yàtọ̀ gan-an nígbà náà o! Jésù Kristi Ọba tí ń bẹ lọ́run “yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.” Àní, “yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.” —Sáàmù 72:13, 14.
Míkà 4:4 sọ nípa àkókò yẹn pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.” Ìjọba Ọlọ́run á mú gbogbo ìṣòro tó ń bá ẹ̀dá èèyàn fínra kúrò, kódà ó máa mú àìsàn àti ikú pàápàá kúrò. Ọlọ́run “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.
O lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí yìí nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló sọ ọ́. O ò ṣe kúkú fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Fọ́tò FAO/M. Marzot