ORÍ KẸTÀDÍNLÓGÚN
“Kò Sí Ẹni Tí Ó Ní Ìfẹ́ Tí Ó Tóbi Ju Èyí Lọ”
1-4. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Gómìnà Pílátù fi Jésù han àwọn jàǹdùkú tí wọ́n kóra jọ síwájú ààfin rẹ̀? (b) Kí ni Jésù ṣe ní gbogbo àkókò tí wọ́n ń fàbùkù kàn án tí wọ́n sì ń fi gbogbo ìyà yẹn jẹ ẹ́, àwọn ìbéèrè pàtàkì wo nìyẹn sì mú kó jẹ yọ?
“WÒ Ó! Ọkùnrin náà!” Gbólóhùn tí Gómìnà Róòmù Pọ́ńtíù Pílátù sọ rèé nígbà tó ń fi Jésù Kristi han àwọn jàǹdùkú tí wọ́n fìbínú kóra jọ síwájú ààfin gómìnà náà láàárọ̀ ọjọ́ Àjọ Ìrékọjá lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. (Jòhánù 19:5) Kò tíì ju ọjọ́ mélòó kan lọ sẹ́yìn táwọn èèyàn yìí ń kókìkí Jésù nígbà tó ń wọ Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run yàn. Àmọ́ nídàájí òní, àwọn ogunlọ́gọ̀ náà ti yáa sọ ara wọn di ọ̀tá Jésù, wọn ò rí i bí Ọba mọ́.
2 Wọ́n wọ Jésù láṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ rí bí àwọ̀ àlùkò táwọn ọlọ́lá máa ń wọ̀, wọ́n sì dé e ládé. Àmọ́ ṣe ni wọ́n fi ń ṣẹlẹ́yà torí pé ó pe ara rẹ̀ lọ́ba. Ara tí wọ́n ti fi ẹgba bẹ́ pẹ́rẹpẹ̀rẹ tó sì ń ṣẹ̀jẹ̀ pòròpòrò ni wọ́n wọ aṣọ sí. Adé tí wọ́n fi ẹ̀gún hun ni wọ́n fi dé e lórí, wọ́n sì tẹ adé yìí mọ́ orí rẹ̀ tí wọ́n ti dọ́gbẹ́ sí tó ti ń ṣẹ̀jẹ̀. Àwọn èèyàn tí àwọn olórí àlùfáà mú orí wọn gbóná náà kọ ọkùnrin tí wọ́n ń wò ní iwájú wọn tí wọ́n ti nà bíi kó kú náà. Ariwo táwọn àlùfáà ń pa ni pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!” Nítorí pé wọ́n ti pa á nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, kò sọ́rọ̀ méjì lẹ́nu wọn ju pé: “Ó yẹ kí ó kú” lọ.—Jòhánù 19:1-7.
3 Pẹ̀lú ìgboyà, Jésù fara da àbùkù àti ìjìyà yẹn láìbọ́hùn, kò sì bara jẹ́.a Ó ti múra tán pátápátá láti kú. Lọ́sàn-án ọjọ́ Àjọyọ̀ Ìrékọjá yẹn, Jésù kú sórí òpó igi oró.—Jòhánù 19:17, 18, 30.
4 Bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ yìí, á jẹ́ kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé ọ̀rẹ́ nígbà dídùn àti nígbà kíkan ni Jésù. Ó sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Gbólóhùn yìí mú kí àwọn ìbéèrè kan jẹ yọ. Ṣé dandan ni kí Jésù jẹ adúrú ìyà yẹn kó sì kú ni? Kí nìdí tó fi yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún irú ìyà yẹn? Báwo làwa tá a jẹ́ “ọ̀rẹ́ rẹ̀” tá a sì tún jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe lè fìwà jọ ọ́?
Kí Nìdí Tó Fi Pọn Dandan Pé Kí Jésù Jìyà Kó sì Kú?
5. Báwo ni Jésù ṣe mọ irú àwọn àdánwò tó ń dúró dè é?
5 Jésù mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sóun gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tí Ọlọ́run sọ pé ó ń bọ̀. Ó mọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìyà tó máa jẹ Mèsáyà àti bó ṣe máa kú. (Aísáyà 53:3-7, 12; Dáníẹ́lì 9:26) Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tó mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn le nítorí àdánwò tó ń dúró dè é. (Máàkù 8:31; 9:31) Nígbà tí wọ́n ń lọ síbi àjọyọ̀ Ìrékọjá tó ṣe kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù, ó sojú abẹ níkòó fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “A ó sì fa Ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá a lẹ́bi ikú, wọn yóò sì fà á lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, wọn yóò sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọn yóò sì tutọ́ sí i lára, wọn yóò sì nà án lọ́rẹ́, wọn yóò sì pa á.” (Máàkù 10:33, 34) Kì í ṣe ohun tí ò ní ṣẹlẹ̀ ló ń sọ. Bá a ti ṣe rí i, lóòótọ́ ni wọ́n fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n nà án lọ́rẹ́, wọ́n sì pà á.
6. Kí nìdí tí Jésù fi ní láti jìyà kó sì kú?
6 Kí wá nìdí tí Jésù fi ní láti jìyà kó sì kú? Ìdí pàtàkì bíi mélòó kan ni. Àkọ́kọ́, bí Jésù bá dúró ṣinṣin jálẹ̀, ó máa fi ara rẹ̀ hán gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fira rẹ̀ hàn bí alátìlẹyìn Jèhófà nínú ọ̀ràn ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Rántí pé Sátánì fẹ̀sùn èké kan ẹ̀dá èèyàn pé torí ohun tí wọ́n ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ni wọ́n ṣe ń sìn ín. (Jóòbù 2:1-5) Bí Jésù ṣe jẹ́ “onígbọràn títí dé ikú . . . lórí òpó igi oró,” ó jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sí òótọ́ olóókan nínú ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan ìran èèyàn. (Fílípì 2:8; Òwe 27:11) Èkejì, ìyà tí Jésù bá jẹ àti ikú tó bá kú ló máa ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. (Aísáyà 53:5, 10; Dáníẹ́lì 9:24) Jésù “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,” èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti lè ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. (Mátíù 20:28) Ẹ̀kẹta, bí Jésù ṣe fara da oríṣiríṣi ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ àti gbogbo ìnira tó bá a fi hàn pé “a ti dán [an] wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa.” Nípa báyìí, ó di Àlùfáà Àgbà tó ní ìyọ́nú tó sì “lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.”—Hébérù 2:17, 18; 4:15.
Kí Nìdí Tí Jésù Fi Fínnúfíndọ̀ Yọ̀ǹda Ẹ̀mí Rẹ̀?
7. Báwo ni nǹkan tí Jésù fi sílẹ̀ kó tó wá sáyé ṣe ṣe pàtàkì tó?
7 Kí ohun tí Jésù fínnúfíndọ̀ ṣe bàa lè yéni dáadáa, jẹ́ ká wò ó lọ́nà yìí ná: Ọkùnrin wo ló máa filé àtọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ tó sì máa rìnrìn àjò lọ sílùú òkèèrè bó bá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lara àwọn aráàlú náà ò ní gba tòun, tó mọ̀ pé ńṣe ni wọ́n á máa kan òun lábùkù tí wọ́n á sì jẹ òun níyà tí wọ́n á sì pa òun níkẹyìn? Wá wo ohun tí Jésù ṣe o. Kó tó wá sáyé, àyè pàtàkì ni Bàbá rẹ̀ fi í sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Síbẹ̀ Jésù fínnúfíndọ̀ fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ lọ́rùn ó sì wá di èèyàn lórí ilẹ̀ ayé níbí. Ó mọ̀ pé èyí tó pọ̀ nínú ọmọ aráyé ni ò ní fẹ́ràn òun, pé wọ́n á kan òun lábùkù lọ́nà tó búrú jáì, wọ́n á fojú òun gbolẹ̀ lọ́nà ìkà, wọ́n á jẹ òun ní palaba ìyà, wọ́n á sì fikú oró pa òun. (Fílípì 2:5-7) Kí ló mú kí Jésù múra tán láti wá la irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kọjá?
8, 9. Kí ló mú kí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀?
8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jésù ní fún Bàbá rẹ̀ ló mú kó lè yọ̀ǹda ara rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ìfaradà Jésù jẹ́ ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀, Jèhófà. Ìfẹ́ yẹn ló mú kí orúkọ Bàbá rẹ̀ àti àbùkù tó lè bá orúkọ náà jẹ ẹ́ lógún gan-an. (Mátíù 6:9; Jòhánù 17:1-6, 26) Ohun tó ṣe pàtàkì sí i jù ni bó ṣe máa mú gbogbo ẹ̀gàn táyé ti kó bá orúkọ Bàbá rẹ̀ kúrò. Torí náà, lójú Jésù, àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti jìyà nítorí òdodo, torí ó mọ̀ pé bí òun bá jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀, ó nípa tó máa kó láti mú kí orúkọ alẹ́wàlógo Bàbá rẹ̀ di mímọ́.—1 Kíróníkà 29:13.
9 Ohun mìíràn wà tó mú kí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, nǹkan ọ̀hún ni ìfẹ́ tó ní fún ẹ̀dá èèyàn. Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé ló sì ti ní irú ìfẹ́ yẹn sí aráyé. Tipẹ́tipẹ́ kí Jésù tó wá sáyé ni Bíbélì ti sọ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá èèyàn ṣe rí lọ́kàn rẹ̀, pé: “Àwọn ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:30, 31) Ó fi ìfẹ́ yìí hàn nígbà tó wà láyé. Bá a ṣe rí i ní orí mẹ́tà tó ṣáájú orí yìí, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jésù gbà fìfẹ́ hàn sí aráyé lápapọ̀ àti ní pàtàkì sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tó di Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Jòhánù 10:11) Ká sòótọ́, kò sọ́nà míì tó jùyẹn tó lè gbà fi ìfẹ́ tó ní fún wa hàn. Ṣé àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nírú ọ̀nà yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, kódà ohun tó pa láṣẹ fún wa láti ṣe nìyẹn.
“Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Ara Yín Lẹ́nì Kìíní-kejì . . . bí Mo Ti Nífẹ̀ẹ́ Yín”
10, 11. Àṣẹ tuntun wo ni Jésù fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí ló túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣègbọràn sí i?
10 Kí Jésù tó kú lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn tó sún mọ́ ọn jù lọ, pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Kí nìdí tí gbólóhùn náà “Kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́ni kìíní-kejì” fi jẹ́ “àṣẹ tuntun”? Ó ti wà nínú Òfin Mósè tẹ́lẹ̀ pé: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Ṣùgbọ́n àṣẹ tuntun yìí ń béèrè ju kéèyàn kàn nífẹ̀ẹ́ lásán lọ, ó ń béèrè pé ká nífẹ̀ẹ́ tó máa jẹ́ ká lè fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ torí àwọn ẹlòmíì. Jésù fúnra rẹ̀ sọ èyí lọ́nà tó ṣe kedere, pé: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:12, 13) Ohun tí àṣẹ tuntun náà túmọ̀ sí ni pé: “Nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ, ṣùgbọ́n kó ju bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ lọ.” Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ àti bó ṣe kú nítorí wa jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nípa irú ìfẹ́ yẹn.
11 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣègbọràn sí àṣẹ tuntun yìí? Rántí ohun tí Jésù sọ, pé: “Nípa èyí [ìyẹn, ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ] ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ ló máa fi wá hàn bíi Kristẹni tòótọ́. A lè fi ìfẹ́ yìí wé báàjì àyà. Àwọn tó bá ń lọ sí àpéjọ ọdọọdún ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi báàjì sáyà. Káàdì yìí ló jẹ́ àmì ìdánimọ̀ fẹ́ni tó fi sáyà, ó máa jẹ́ ká mọ orúkọ ẹni náà àti orúkọ ìjọ tó ti wá. Ìfẹ́ tó lè mú ká fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ nítorí àwọn míì ni “báàjì” tó ń fi wá hàn bí ojúlówó Kristẹni tòótọ́. Lédè míì, ìfẹ́ tá a ní síra wa gbọ́dọ̀ hàn débi tó fi máa ṣeé rí tàbí kó rí bíi báàjì, tó máa jẹ́ káwọn tó ń wò wá mọ̀ pé lóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá. Ó tọ́ kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ tí mo ní, èyí tó dà bíi “báàjì” ìdánimọ̀ mi, hàn kedere nínú ìgbésí ayé mi?’
Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Ní Ìfẹ́ Onífara-Ẹni-Rúbọ?
12, 13. (a) Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ara wa mú ká ṣe fún wọn? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti ní ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ?
12 Níwọ̀n bá a ti ń tọ Jésù lẹ́yìn, ó di dandan pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. Ó túmọ̀ sí pé tinútinú la fi gbọ́dọ̀ máa múra tán láti yááfì nǹkan kan nítorí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Báwo ló ṣe yẹ ká múra tán láti yááfì nǹkan tó nítorí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? Bíbélì dáhùn, ó ní: “Nípa èyí ni àwa fi wá mọ ìfẹ́, nítorí ẹni yẹn fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa; a sì wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fi ọkàn wa lélẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa.” (1 Jòhánù 3:16) Bíi ti Jésù, àwa náà gbọ́dọ̀ múra tán láti kú nítorí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, bó bá jẹ́ pé ohun tó gbà nìyẹn. Nígbà inúnibíni, ó sàn ká fi ẹ̀mí ara wa dí i dípò tá a ó fi da àwọn ará wa, èyí tó lè fi ẹ̀mí wọn sínú ewu. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ibi tí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tàbí ìjà ìran ti ń wáyé là ń gbé, a lè fi ẹ̀mí tiwa wewu láti lè dáàbò àwọn ará wa, láìwo ti ẹ̀yà tàbí ìran yòówù tí wọ́n ti wá. Bí ogun bá dé, ó sàn ká ṣẹ̀wọ̀n tàbí ká tiẹ̀ kú ju pé ká bá wọn gbé ohun ìjà láti fi pa ẹnikẹ́ni, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ká pa àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.—Jòhánù 17:14, 16; 1 Jòhánù 3:10-12.
13 Mímúra tán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ nítorí àwọn ará wa nìkan kọ́ ni ọ̀nà tá a lè gbà fi ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ hàn sí wọn. Ó ṣe tán, díẹ̀ lára wa ló tíì bá ara rẹ̀ nírú ipò tó ǹ béèrè pé ká fi ẹ̀mí wa rúbọ nítorí àwọn ará wa. Àmọ́ bá a bá nífẹ̀ẹ́ wọn débi tá a fi lè fẹ̀mí wa lélẹ̀ nítorí wọn, ǹjẹ́ kò yẹ ká yááfì àwọn nǹkan kéékèèké míì, ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nísinsìnyí? Ojúlówó ìfẹ́ túmọ̀ sí pé ká fi àwọn àǹfààní tàbí ìtura kan du ara wa nítorí àwọn ẹlòmíì. Kódà láwọn ìgbà tó ṣòroó ṣe, ó yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún ju tiwa lọ ká sì fi àníyàn tiwọn ṣíwájú tiwa. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Ọ̀nà pàtàkì míì wo la lè gbà fi ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ hàn?
Nínú Ìjọ àti Nínú Ìdílé
14. (a) (a) Àwọn nǹkan wo ló máa ń pọn dandan pé káwọn alàgbà yááfì? (b) Kí lèrò rẹ nípa àwọn alàgbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ yín?
14 Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn alàgbà ń yááfì kí wọ́n tó lè máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo.” (1 Pétérù 5:2, 3) Láfikún sí bíbójútó ìdílé tiwọn fúnra wọn, wọ́n tún máa ń lo àkókò lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ tàbí lópin ọ̀sẹ̀ láti bójú tó ọ̀ràn ìjọ, irú bíi mímúra ìpàdé sílẹ̀, ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn àti bíbójútó ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà ló tún máa ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn kan lára wọn ń ṣiṣẹ́ kára láwọn àpéjọ, àwọn kan wà lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tàbí Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀yin alàgbà ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ńṣe lẹ̀ ń fi ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ hàn bẹ́ẹ̀ ṣe ń múra tán láti lo àkókò yín, agbára yín àti ohun ìní yín láti fi ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo. (2 Kọ́ríńtì 12:15) Yàtọ̀ sí Jèhófà tó mọrírì bẹ́ ẹ ṣe ń sapá, àwọn ará ìjọ tẹ́ ẹ̀ ń bójú tó pẹ̀lú mọrírì iṣẹ́ yín.—Fílípì 2:29; Hébérù 6:10.
15. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun táwọn aya àwọn alàgbà fi ń du ara wọn? (b) Báwo lo ṣe rí ọ̀rọ̀ àwọn aya tó ń ti ọkọ wọn lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń bẹ ìjọ yín wò sí?
15 Ìyàwó àwọn alàgbà ńkọ́, ǹjẹ́ àwọn obìnrin adúró-tọkọ wọ̀nyí tiẹ̀ ń fi ohunkóhun du ara wọn kí ọkọ wọn bàa lè máa bójú tó agbo? Ó dájú pé bí ọkọ kan tó jẹ́ alàgbà bá lo àkókò tó yẹ kó lò pẹ̀lú aya rẹ̀ fún ọ̀ràn ìjọ, ìrúbọ kan nìyẹn jẹ́ látọ̀dọ̀ aya náà. Ìwọ tún wo bí ìyàwó àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ṣe máa ń fi ohun púpọ̀ du ara wọn bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé ọkọ wọn látinú ìjọ kan sí òmíràn àti láti àyíká kan sí òmíràn. Pé èèyàn ń sun inú ilé ara rẹ̀ ò sí nínú ọ̀rọ̀ tiwọn, orí bẹ́ẹ̀dì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì máa ń sùn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó tọ́ ká gbóríyìn fún irú àwọn aya wọ̀nyí torí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní, ìyẹn àwọn aya tí wọ́n fi ìrọ̀rùn ìjọ ṣáájú tara wọn, tí wọn kì í sì í rojú láti lo ara wọn fáwọn ẹlòmíì.—Fílípì 2:3, 4.
16. Kí làwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni fi máa ń du ara wọn nítorí àwọn ọmọ wọn?
16 Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìfẹ́ máa sún wa láti fi àwọn nǹkan kan du ara wa nítorí àwọn tó wà nínú ìdílé wa? Ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ̀yin òbí fi ń du ara yín kẹ́ ẹ tó lè máa fún àwọn ọmọ yín ní àwọn ohun tí wọ́n nílò àti kẹ́ ẹ tó lè tọ́ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ó lè jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ fi máa ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn kẹ́ ẹ tó lè rí oúnjẹ táwọn ọmọ yín máa jẹ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti aṣọ àti ibùgbé tí ẹ ní láti pèsè fún wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé báwọn ọmọ yín bá ti ní ohun tí wọ́n ń fẹ́, àbùṣe bùṣe, tiyín kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sí yín mọ́. Ẹ sì tún máa ń sapá gan-an láti kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́, láti mú wọn lọ sí ìpàdé àti láti bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (Diutarónómì 6:6, 7) Bí ìfẹ́ ṣe ń mú kẹ́ ẹ máa fi àwọn nǹkan kan du ara yín nítorí ìdílé yín yìí ń múnú Ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀ dùn, ó sì lè yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun fáwọn ọmọ yín.—Òwe 22:6; Éfésù 3:14, 15.
17. Báwo làwọn Kristẹni ọkọ ṣe lè fìwà jọ Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò mọ tara ẹ̀ nìkan?
17 Ẹ̀yin ọkọ, báwo lẹ ṣe lè fìwà jọ Jésù nínú jíjẹ́ kí ìfẹ́ máa sún yín láti máa fi àwọn nǹkan kan du ara yín nítorí ìdílé yín? Bíbélì dáhùn, ó ní: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:25) Bá a ti ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Jésù fẹ́ràn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ débi tó fi kú nítorí wọn. Kristẹni ọkọ gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bó ṣe máa ń fi nǹkan du ara rẹ̀, nípa bí kò ṣe “ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:3) Ńṣe ni irú ọkọ bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ máa fi tinútinú ṣe ohun tí aya rẹ̀ fẹ́, kó sì jẹ́ kí aya rẹ̀ mọ̀ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ òun lógún. Kò gbọ́dọ̀ máa jẹ́ pé ohun tóun bá ṣáà ti fẹ́ ṣáá ló gbọ́dọ̀ di ṣíṣe, kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ múra tán láti máa ro ti aya rẹ̀ mọ́ tiẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ohun tí aya rẹ̀ bá fẹ́ ò bá ti ta ko Ìwé Mímọ́. Ọkọ tí ìfẹ́ bá ń sún láti máa fi àwọn nǹkan du ara rẹ̀ máa ń jèrè ojú rere Jèhófà, taya tọmọ rẹ̀ sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fún un.
Kí Lo Máa Ṣe?
18. Kí ló yẹ ká tìtorí rẹ̀ máa ṣègbọràn sí àṣẹ tuntun yẹn pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́ni kìíní-kejì?
18 Kì í ṣe ohun tó rọrùn láti ṣègbọràn sí àṣẹ tuntun náà pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́ni kìíní-kejì, ṣùgbọ́n ohun pàtàkì kan wà tó yẹ ká tìtorí rẹ̀ máa ṣe é. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn . . . , ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Níwọ̀n bí Jésù ti kú fún wa, ǹjẹ́ kó yẹ káwa náà lo ìgbésí ayé wa fún un? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ tí Jésù ní.
19, 20. Ẹ̀bùn iyebíye wo ni Jèhófà fún wa, kí la sì lè ṣe tó máa fi hàn pé a gbà á?
19 Jésù ò sọ àsọdùn nígbà tó sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Bí Jésù ṣe múra tán láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa ni ọ̀nà gíga jù lọ tó gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa. Síbẹ̀ ẹnì kan wà tó tún fi ìfẹ́ tó lágbára ju ti Jésù lọ hàn sí wa. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi tó fi fi Ọmọ rẹ̀ rà wá padà ká bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Éfésù 1:7) Ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìràpadà yẹn, àmọ́ kò fipá mú wa láti gba ẹ̀bùn náà.
20 Ọwọ́ wa ló kù sí bá a bá máa gba ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí. Báwo la ṣe máa gbà á? Nípa “lílo ìgbàgbọ́” nínú Ọmọ rẹ̀ ni. Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán o. Ó gbọ́dọ̀ máa hàn nínú bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa. (Jákọ́bù 2:26) À ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù nípa títọ̀ ọ́ lẹ́yìn lójoojúmọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á jẹ́ ká rí ìbùkún rẹpẹtẹ láyé tá a wà yìí àti lọ́jọ́ iwájú, bí a ó ṣe rí i nínú àlàyé orí tó kẹ́yìn ìwé yìí.
a Lọ́jọ́ yẹn nìkan ṣoṣo, ẹ̀ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n tutọ́ sí Jésù lára, àwọn aṣáájú ìsìn ló kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wá ṣe tiwọn. (Mátíù 26:59-68; 27:27-30) Kódà gbogbo bí wọ́n ṣe fàbùkù kàn án tó yìí kò mú kó bọ́hùn, ó fara dà á, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Ojú mi ni èmi kò fi pa mọ́ fún àwọn ohun tí ń tẹ́ni lógo àti itọ́.”—Aísáyà 50:6.