Níbo Ni Àwọn Òkú Wà?
ÀWỌN Yoruba ní Ìwọ̀-Oòrùn Africa máa ń sọ pé: “Ayé lọjà; ọ̀run nilé wa.” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsìn ní ń sọ èrò yìí jáde ní àsọtúnsọ. Ó gbé èrò náà jáde pé ilẹ̀-ayé dàbí ọjà, tí a ń bẹ̀wò fún ìgbà díẹ̀ tí a óò sì túká. Ní ìbámu pẹ̀lú èrò-ìgbàgbọ́ yìí, nígbà ikú ọ̀run ni a ń lọ, ilé wa níti gidi.
Bibeli kọ́ni pé àwọn kan ń lọ sí ọ̀run. Jesu Kristi sọ fún àwọn aposteli rẹ̀ olùṣòtítọ́ pé: “Ninu ilé Baba mi ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ. . . . Mo ń bá ọ̀nà mi lọ lati pèsè ibi kan sílẹ̀ fún yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ tí mo sì pèsè ibi kan sílẹ̀ fún yín, emi tún ń bọ̀ wá emi yoo sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi dájúdájú, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹlu lè wà níbẹ̀.”—Johannu 14:2, 3 NW.
Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu kò túmọ̀sí pé gbogbo ènìyàn rere ni ó ń lọ sí ọ̀run tàbí pé ọ̀run jẹ́ ilé aráyé. A mú àwọn kan lọ sí ọ̀run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìṣàkóso lé ilẹ̀-ayé lórí. Jehofa Ọlọrun mọ̀ pé àwọn àkóso ẹ̀dá ènìyàn kò lè bójútó àlámọ̀rí lórí ilẹ̀-ayé lọ́nà tí yóò kẹ́sẹjárí láé. Nítorí náà, ó ṣètò fún àkóso, tàbí Ìjọba ti ọ̀run, tí yóò gba àkóso ayé nígbẹ̀yìn gbẹ́yín tí yóò sì yí i padà sí Paradise tí òun ti pète pé kí ó jẹ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Matteu 6:9, 10) Jesu ni yóò jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọrun. (Danieli 7:13, 14) A óò yan àwọn mìíràn láti inú ìran ènìyàn láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀. Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn tí yóò lọ sí ọ̀run yóò jẹ́ “ìjọba kan ati àlùfáà fún Ọlọrun wa, wọn yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀-ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:10, NW.
Àwọn Wo Ni Ń Lọ sí Ọ̀run?
Ní gbígbé ẹrù-iṣẹ́ bàǹtà-banta tí àwọn olùṣàkóso ti ọ̀run wọ̀nyí yóò ní yẹ̀wò, kò yanilẹ́nu pé wọ́n níláti kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun àbéèrè-fún tí ó pọndandan. Àwọn wọnnì tí ń lọ sí ọ̀run gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye nípa Jehofa wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí i. (Johannu 17:3; Romu 6:17, 18) A béèrè pé kí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu Kristi. (Johannu 3:16) Síbẹ̀, ó ní nínú ju ìyẹn lọ. Ọlọrun gbọ́dọ̀ pè wọ́n kí ó sì yàn wọ́n nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀. (2 Timoteu 1:9, 10; 1 Peteru 2:9) Síwájú síi, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ Kristian tí a ti batisí tí ó sì ti di ‘àtúnbí,’ tí a bí nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun. (Johannu 1:12, 13; 3:3-6) Wọ́n níláti pa ìwàtítọ́ wọn mọ́ sí Ọlọrun títí dé ojú ikú.—2 Timoteu 2:11-13; Ìṣípayá 2:10.
Àìlóǹkà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ayé rí tí wọ́n sì ti kú kò kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun àbéèrè-fún wọ̀nyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ní àǹfààní díẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun òtítọ́ náà. Àwọn mìíràn kò ka Bibeli rí ohun tí wọ́n sì mọ̀ nípa Jesu Kristi kò tó nǹkan tàbí kí wọ́n má tilẹ̀ mọ̀ rárá nípa rẹ̀! Kódà láàárín àwọn Kristian tòótọ́ tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé lónìí, àwọn díẹ̀ ni Ọlọrun yàn fún ìyè ti ọ̀run.
Nítorí náà ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, iye àwọn wọnnì tí ń lọ sí ọ̀run yóò kéré ní ìfiwéra. Jesu tọ́kasí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gẹgẹ bí “agbo kékeré.” (Luku 12:32, NW) Lẹ́yìn náà, a ṣí i payá fún aposteli Johannu pé àwọn wọnnì “tí a ti rà lati ilẹ̀-ayé wá” láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run yóò jẹ́ 144,000. (Ìṣípayá 14:1, 3; 20:6, NW) Bí a bá fi wéra pẹ̀lú ọ̀pọ̀ billion àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé lórí ilẹ̀-ayé rí, iye yẹn kéré níti tòótọ́.
Àwọn Wọnnì Tí Kì Yóò Lọ sí Ọ̀run
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn wọnnì tí kì yóò lọ sí ọ̀run? Wọ́n ha ń jìyà ní ibi ìdálóró ayérayé kan, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìsìn kan ti fi kọ́ni bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́, nítorí pé Jehofa jẹ́ Ọlọrun ìfẹ́. Àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ kìí ju àwọn ọmọ wọn sínú iná, bẹ́ẹ̀ sì ni Jehofa kìí dá àwọn ènìyàn lóró ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀.—1 Johannu 4:8.
Ìfojúsọ́nà tí ó wà fún àwọn tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn wọnnì tí wọ́n ti kú ni àjíǹde sórí paradise ilẹ̀-ayé. Bibeli sọ pé Jehofa dá ilẹ̀-ayé “kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Isaiah 45:18) Onipsalmu náà polongo pé: “Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Oluwa; ṣùgbọ́n ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Orin Dafidi 115:16) Ilẹ̀-ayé ni yóò jẹ́ ilé wíwàpẹ́títí fún aráyé, kìí ṣe ọ̀run.
Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé: “Wákàtí naa ń bọ̀ ninu èyí tí gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ [ti Jesu, “Ọmọkùnrin ènìyàn”] wọn yoo sì jáde wá.” (Johannu 5:27-29, NW) Kristian aposteli Paulu tẹnumọ́ ọn pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.” (Iṣe 24:15, NW) Lórí òpó-igi ìdálóró, nípasẹ̀ àjíǹde sórí paradise ilẹ̀-ayé Jesu ṣèlérí ìyè fún olubi kan tí ó ronúpìwàdà.—Luku 23:43.
Ṣùgbọ́n, ipò wo ni àwọn òkú tí a óò jí dìde sí ìyè lórí ilẹ̀-ayé wà ní lọ́wọ́lọ́wọ́? Ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu ṣèrànwọ́ láti dáhùn ìbéèrè yìí. Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti kú. Ṣáájú kí Jesu tó lọ jí i dìde, Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé: “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣugbọn mo ń rìnrìn-àjò lọ sí ibẹ̀ lati jí i kúrò lójú oorun.” (Johannu 11:11, NW) Nípa báyìí Jesu fi ikú wé oorun, oorun ìjìkà láìsí lílá ààlá.
Sísùn Nínú Ikú
Àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ mìíràn bá èrò sísùn nínú ikú yìí mu. Wọn kò kọ́ni pé ẹ̀dá ènìyàn ní ọkàn àìleèkú tí ń kọjá lọ si ilẹ̀ ọba ẹ̀mí nígbà ikú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bibeli sọ pé: “Àwọn òkú kò mọ ohun kan . . . Ìfẹ́ wọn pẹ̀lú, àti ìríra wọn, àti ìlara wọn, ó parun nísinsìnyí; . . . Kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà-òkú níbi tí ìwọ ń rè.” (Oniwasu 9:5, 6, 10) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, onípsalmu náà polongo pé ènìyàn “padà sí erùpẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.”—Orin Dafidi 146:4.
Àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ wọ̀nyí mú un ṣe kedere pé àwọn tí wọ́n ń sùn nínú ikú kò lè rí wa tàbí gbọ́ wa. Kò ṣeéṣe fún wọn láti mú ìbùkún tàbí àjálù wá. Wọn kò sí ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe pé wọ́n ń gbé ní àwùjọ àwọn babańlá. Wọ́n jẹ́ aláìlẹ́mìí, wọn kò sí níbì kankan.
Nígbà tí ó bá tó àkókò lójú Ọlọrun, àwọn wọnnì tí wọ́n ti sùn nínú ikú nísinsìnyí tí wọ́n sì wà nínú agbára ìrántí rẹ̀ ni a óò jí dìde sí ìyè nínú paradise ilẹ̀-ayé kan. Yóò jẹ́ ayé kan tí a fọ̀ mọ́ kúrò nínú ìsọdèérí, wàhálà, àti àwọn ìṣòro tí aráyé ń nírìírí wọn báyìí. Ẹ wo bí ìyẹn yóò ti jẹ́ àkókò onídùnnú tó! Nínú Paradise yẹn wọn yóò ní ìfojúsọ́nà fún wíwàláàyè títíláé, nítorí Orin Dafidi 37:29 mú un dá wa lójú pé: “Olódodo ni yóò jogun ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
MO JÁWỌ́ NÍNÚ JÍJỌ́SÌN ÀWỌN ÒKÚ
“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń ran bàbá mí lọ́wọ́ lákòókò àwọn ìrúbọ rẹ̀ déédéé sí bàbá rẹ̀ tí ó ti kú. Nígbà kan tí bàbá mí kọ́fẹpadà láti inú àìsàn lílekoko kan, bàbá onífá sọ fún un pé kí ó fi ewúrẹ́ kan, iṣu, obì, àti ọtí ṣèrúbọ sí bàbá rẹ̀ tí ó ti kú ní ìmọrírì fún ìkọ́fẹpadà rẹ̀. Ó tún fún bàbá mi nímọ̀ràn pé kí ó tu àwọn babańlá rẹ̀ tí ó ti kú lójú láti báa lé àìsàn àti àjálù mìíràn jìnnà.
“Ìyá mi ra àwọn ohun tí a béèrè fún ìrúbọ náà, tí a óò ṣe níbi sàréè bàbá mi àgbà. Sàréè náà wà ní ẹ̀gbẹ́ ilé wa gan-an, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀.
“Àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, àti àwọn aládùúgbò ni a pè láti wá bá wa ṣe ìrúbọ náà. Bàbá mi, tí ó wà-sórí wà-sọ́rùn láti lè bá ayẹyẹ náà mu, jókòó sórí àga kan tí ó dojúkọ ojúbọ náà níbi tí a to agbárí àwọn ewúrẹ́ tí a ti fi ṣèrúbọ sí. Iṣẹ́ tèmi ni láti bu ọtí láti inú ìgò sínú tọ́ḿbìlà kékeré kan, èyí tí mo gbé fún bàbá mi. Lẹ́yìn náà, ó ta á sílẹ̀ ní ṣíṣe ìrúbọ. Bàbá mi pe orúkọ bàbá rẹ̀ nígbà mẹ́ta ó sì gbàdúrà sí i fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ àjálù ọjọ́-ọ̀la.
“A fi obì ṣe ìrúbọ, a sì pa àgbò kan, a sè é, gbogbo àwọn tí wọ́n pésẹ̀ sì jẹ ẹ́. Èmi náà jẹ níbẹ̀ mo sì jó sí orin àti ìlù tí wọ́n ń lù. Bàbá mi jó bíi kòkòrò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbà ti ń dé sí i. Ó ń gbàdúrà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan sí àwọn babańlá rẹ̀ láti bùkún fún gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀, nígbà tí àwọn ènìyàn náà, tí ó fi mọ́ èmi alára, ń dáhùn pé Ise, tí ó túmọ̀ sí ‘Bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí.’ Mo tẹjúmọ́ bàbá mi pẹ̀lú ọkàn-ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìyàlẹ́nu pẹ̀lú ìyánhànhàn fún ọjọ́ náà tí n óò dàgbà tó láti lè ṣe ìrúbọ sí àwọn babańlá tí ó ti kú.
“Láìka ọ̀pọ̀ ìrúbọ tí a ṣe sí, àlàáfíà kò sí nínú ìdílé náà. Nígbà tí ó jẹ́ pé ìyá mí ní àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n wà láàyè, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta tí ó bí tí ó wàláàyè fún ìgbà pípẹ́; gbogbo wọ́n kú ní rèwerèwe. Nígbà tí ìyá mi lóyún mìíràn, bàbá mi ṣe ìrúbọ híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ kí ó baà lè bí ọmọ náà láyọ̀.
“Ìyá bí ọmọbìnrin mìíràn. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà ọmọ náà dùbúlẹ̀ àìsàn ó sì kù. Bàbá mi kàn sí onífá, tí ó sọ pé ọ̀tá kan ní ó fa ikú náà. Onífá náà wí pé kí ‘ọkàn’ ọmọ náà baà lè jà padà, a ó nílò igi tí ń jó kan, ìgò ọtí kan, àti ọmọjá kan láti fi ṣèrúbọ. A óò gbé igi tí ń jó náà sórí sàréè, ọtí náà ni a óò wọ́n káàkiri orí sàréè náà, ajá kékeré náà ni a ó sì sìn lóòyẹ̀ sẹ́bàá sàréè náà. Èyí ní a lérò pé yóò jí ọkàn ọmọbìnrin tí ó ti kú náà láti lè gbẹ̀san ikú rẹ̀.
“Mo gbé igo ọtí àti igi tí ń jó náà lọ sẹ́bàá sàréè náà, bàbá mi sì gbé ọmọjá náà, èyí tí ó sin gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tí onífá fún un. Gbogbo wa gbàgbọ́ pé láàárín ọjọ́ méje ọkàn ọmọbìnrin tí ó ti kú náà yóò pa ẹni náà tí ó fa ikú àìtọ́jọ́ rẹ̀ run. Oṣù méjì kọjá, síbẹ̀ a kò gbọ́ ìròyìn ikú kankan ní àdúgbò. Mo nímọ̀lára ìjákulẹ̀.
“Ẹni ọdún 18 ni mi nígbà náà. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà mo ṣe alábàápàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n fihàn mí láti inú Ìwé Mímọ́ pé àwọn òkú kò lè ṣe ohun rere tàbí búburú sí àwọn alààyè. Bí ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe ń fìdímúlẹ̀ nínú ọkàn-àyà mi, mo sọ fún bàbá mi pé n kò ní máa bá a lọ rúbọ sí àwọn òkú mọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná ó bínú sí mi fún kíkọ òun sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ ọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣàkíyèsí pé n kò ṣetán láti jáwọ́ nínú ìgbàgbọ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí, kò tako ìjọsìn mi sí Jehofa.
“Ní April 18, 1948, mo fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ mi hàn nípasẹ̀ batisí nínú omi. Láti ìgbà náà wá, mo tí ń bá a nìṣó láti máa fi ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ ṣiṣẹ́sin Jehofa, ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di òmìnira kúrò nínú ìjọsìn àwọn babańlá tí ó ti kú, tí wọn kò lè ràn wá lọ́wọ́ tàbí pa wá lára.”—A kọ ọ́ ránṣẹ́ láti ọwọ́ J. B. Omiegbe, Benin City, Nigeria.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìdùnnú ńláǹlà yóò wà nígbà tí a bá jí àwọn òkú dìde sórí paradise ilẹ̀-ayé