Ẹmi Jehofa Ń Darí Awọn Eniyan Rẹ̀
“Ẹmi rẹ dara; ǹjẹ́ ki ó ṣamọna mi ni ilẹ iduroṣanṣan.”—ORIN DAFIDI 143:10, NW.
1, 2. Ki ni o le fa idaamu fun awọn iranṣẹ Jehofa aduroṣinṣin?
‘MO NIMỌLARA isorikọ gan-an ni! Nibo ni mo ti le ri itunu diẹ? Ọlọrun ha ti pa mi tì ni bi?’ Iwọ ha ti figbakanri nimọlara lọna yẹn bi? Bi iwọ ba ṣe bẹẹ, kìí ṣe iwọ nikan. Bi o tilẹ jẹ pe awọn iranṣẹ Jehofa aduroṣinṣin ń gbé ninu paradise tẹmi ti ń gbilẹ̀, wọn maa ń dojukọ awọn iṣoro ti ń pọnniloju, idanwo, ati awọn ìdẹwò ti o wọpọ fun araye ni awọn igba miiran.—1 Korinti 10:13.
2 Boya awọn idanwo pipẹtiti kan tabi okunfa masunmawo titobi rọgba yí ọ ká. Iwọ le maa ṣọ̀fọ̀ lori ikú ololufẹ kan o si le nimọlara idanikanwa gan-an. Tabi ọkàn rẹ le ni idaamu nipa aisan ọ̀rẹ́ timọtimọ kan. Iru awọn ipo ayika bẹẹ le maa jà ọ́ lólè ayọ ati alaafia wọn sì tilẹ lè maa halẹmọ igbagbọ rẹ. Ki ni iwọ nilati ṣe?
Beere Lọwọ Ọlọrun fun Ẹmi Rẹ̀
3. Bi ohun kan ba ń jà ọ́ lólè iru awọn animọ bii alaafia ati ayọ, ki ni yoo bọgbọnmu lati ṣe?
3 Bi ohun kan ba ń jà ọ lólè alaafia, ayọ, tabi awọn animọ bii ti Ọlọrun miiran, yoo jẹ ohun ọlọgbọn lati gbadura fun ẹmi mimọ, tabi ipá agbekankan ṣiṣẹ Ọlọrun. Eeṣe? Nitori pe ẹmi Jehofa ń mú awọn èso rere ti ń ran Kristian kan lọwọ lati koju awọn iṣoro, idanwo, ati awọn ìdẹwò jade. Lẹhin ti o kilọ lodisi “awọn iṣẹ́ ti ara,” aposteli Paulu kọwe pe: “Ṣugbọn eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa-pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa-tutu, ati ikora-ẹni-nijaanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni.”—Galatia 5:19-23.
4. Nigba ti awọn adanwo tabi ìdẹwò diẹ bá dojukọni, eeṣe ti yoo fi jẹ ohun ti o tọ́ lati ṣe pato ninu adura ẹni?
4 Nitori iru idanwo ti iwọ ń dojukọ, iwọ le mọ pe o wà ninu ewu pipadanu iwa-tutu tabi ọkàn-tútù rẹ. Nigba naa ṣe pato nipa gbigbadura si Jehofa Ọlọrun fun eso ẹmi ti iwa-tutu. Ti o ba dojukọ awọn idẹwo kan, ni pataki ni iwọ nilo eso ikora-ẹni-nijaanu. Niti tootọ, yoo tun ṣe wẹku lati gbadura fun iranlọwọ atọrunwa ni pipana ìdẹwo naa, fun idasilẹ kuro lọwọ Satani, ati fun ọgbọ́n ti a nilo lati foriti adanwo naa.—Matteu 6:13; Jakọbu 1:5, 6.
5. Bi ipo-ayika ba jẹ́ eyi ti ń danilaamu gan-an debi pe iwọ kò mọ eso ti ẹmi ti o yẹ lati gbadura fun, ki ni o le ṣe?
5 Bi o ti wu ki o ri, ni awọn igba miiran, ipo-ayika le jẹ eyi ti ń danilaamu tabi dojuru debi pe iwọ kì yoo mọ ewo ninu awọn eso ẹmi ni o nilo. Niti tootọ, ayọ, alaafia, iwa-tutu, ati gbogbo awọn animọ bii ti Ọlọrun miiran ni a le fi sinu ewu. Ki ni nigba naa?, Eeṣe ti o kò beere lọwọ Ọlọrun fun ẹmi mimọ funraarẹ ki o sì jẹ́ ki ó mu kí awọn eso ti o nilo gbilẹ ninu ọ̀ràn tirẹ? Awọn eso ti o ṣe pataki le jẹ́ ifẹ tabi ayọ tabi alaafia tabi akopọ awọn eso ti ẹmi. Tun gbadura pe ki Ọlọrun ràn ọ́ lọwọ lati jọ̀wọ́ araarẹ fun idari ẹmi rẹ̀, nitori oun ń lò ó lati dari awọn eniyan rẹ̀.
Jehofa Muratan Lati Ṣeranlọwọ
6. Bawo ni Jesu ṣe tẹ aini naa lati gbadura laisinmi mọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lọkan?
6 Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin Jesu Kristi beere fun itọni lori adura, ni apakan oun rọ̀ wọn lati gbadura fun ẹmi Ọlọrun. Jesu kọ́kọ́ lo apejuwe kan ti a ṣe lati sun wọn lati gbadura laisinmi. Oun wi pe: “Ta ni ninu yin ti yoo ni ọ̀rẹ́ kan, ti yoo si tọ̀ ọ́ lọ laaarin ọganjọ, ti yoo si wi fun un pe, Ọ̀rẹ́, wín mi ni ìṣù akara mẹta: Nitori ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò bọ̀ sọdọ mi, emi kò si ni nǹkan ti emi óò gbé kalẹ niwaju rẹ̀; ti oun o si gbé inu ile dahun wi fun un pe, Má yọ mi lẹnu: a ti sé ilẹkun ná, awọn ọmọ mi si ń bẹ lori ẹní pẹlu mi; emi kò le dide fifun ọ? Mo wi fun yin, bi oun kò tilẹ, fẹẹ dide ki o fifun un, nitori tii ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nitori àwíìyánnu [“itẹpẹlẹmọ alaiṣojo,” NW] rẹ̀ yoo dide, yoo si fun un pọ̀ tó bi o ti ń fẹ́.”—Luku 11:5-8.
7. Ki ni ijẹpataki ọ̀rọ̀ Jesu ni Luku 11:11-13, idaniloju wo ni wọn sì fun wa nipa Ọlọrun ati ẹmi rẹ̀?
7 Jehofa muratan lati ran olukuluku awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ ti wọn ti ṣe iyasimimọ lọwọ, o si ń tẹtisilẹ si awọn ẹbẹ wọn. Ṣugbọn bi iru ẹni bẹẹ ba ‘ń baa lọ ni bibeere,’ gẹgẹ bi Jesu ti rọni, eyi tọkasi ifẹ-ọkan atinuwa o si jẹ́ ìfihàn jade igbagbọ. (Luku 11:9, 10) Kristi fi kun un pe: “Ta nii ṣe baba ninu yin ti ọmọ rẹ̀ yoo beere akara lọdọ rẹ̀, ti ó jẹ́ fun un ni okuta? Tabi bi o beere ẹja, ti o jẹ́ fun un ni ejo dipo ẹja? Tabi bi o si beere ẹyin, ti o jẹ́ fun un ni àkeekè? Ǹjẹ́ bi ẹyin tii ṣe eniyan buburu ba mọ bi a tii fi ẹ̀bùn didara fun awọn ọmọ yin: meloomeloo ni Baba yin ti ń bẹ ni ọ̀run yoo fi ẹmi mimọ rẹ̀ fun awọn ti o ń beere lọdọ rẹ̀?” (Luku 11:11-13) Bi obi ori ilẹ̀-ayé kan, bi o tilẹ jẹ́ ẹni buburu lọna kan ṣáá nitori iwa ẹṣẹ ti a jogun, bá ń fun ọmọ rẹ̀ ni ohun ti o dara, dajudaju Baba wa ọ̀run yoo maa baa lọ lati fi ẹmi mimọ rẹ̀ fun eyikeyii ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin ti o ba fi irẹlẹ beere fun un.
8. Bawo ni Orin Dafidi 143:10 ṣe kan Dafidi, Jesu, ati awọn iranṣẹ Ọlọrun ti ode-oni?
8 Lati janfaani lati inu ẹmi Ọlọrun, a gbọdọ muratan lati tẹle idari rẹ̀ gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe. Oun gbadura pe: “Kọ́ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ ni Ọlọrun mi: jẹ́ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ni ilẹ ti o tẹ́jú, [“òdodo,” NW].” (Orin Dafidi 143:10) Dafidi, ẹni ti Saulu ọba Israeli ti fi òfin lé kuro ni ilu, fẹ́ ki ẹmi Ọlọrun lati dari oun ki oun baa le ni idaniloju pe ipa-ọna oun jẹ ododo. Bi akoko ti ń lọ Abiatari wá pẹlu èwù-efodi alufaa ti a fi ń wadii ifẹ-inu Ọlọrun daju. Gẹgẹ bi alufaa aṣoju Ọlọrun, Abiatari fun Dafidi ni itọni nipa ọ̀nà ti yoo tọ̀ lati le tẹ́ Jehofa lọrun. (1 Samueli 22:17–23:12; 30:6-8) Bii Dafidi, ẹmi Jehofa dari Jesu, eyi si ti jẹ́ otitọ bakan-naa niti awọn ẹni-ami-ororo ọmọ-ẹhin Kristi gẹgẹ bi agbo kan. Ni 1918 si 1919, wọn wà ninu ipo ìyàsọ́tọ̀ kan niwaju awujọ eniyan, awọn onisin ọ̀tá wọn si lero pe awọn le pa wọn run. Awọn ẹni-ami-ororo naa gbadura fun ọ̀nà abajade kuro ninu ipo aigbeṣẹ wọn, ati ni 1919, Ọlọrun dahun awọn adura wọn, o gbà wọn, o si tun fun wọn lokun ninu iṣẹ-isin rẹ̀. (Orin Dafidi 143:7-9) Dajudaju, ẹmi Jehofa ń ṣeranwọ o si ń darí awọn eniyan rẹ̀ nigba naa, bi o ti ń ṣe titi di oni yii.
Bi Ẹmi Naa Ṣe Ń Ṣeranlọwọ
9. (a) Bawo ni ẹmi mimọ ṣe ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi “oluranlọwọ”? (b) Bawo ni a ṣe mọ̀ pe ẹmi mimọ kìí ṣe eniyan? (Wo akiyesi ẹsẹ-iwe.)
9 Jesu Kristi pe ẹmi mimọ ni “olùtùnú [“oluranlọwọ,” NW].” Fun apẹẹrẹ, o wi fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Emi ó si beere lọwọ Baba, oun ó si fun yin ni olutunu miiran, ki o le maa ba yin gbé titi laelae, ani ẹmi otitọ nì; ẹni ti araye kò le gbà, nitori ti kò ri i, bẹẹ ni kò sì mọ̀ ọ́n: ṣugbọn ẹyin mọ̀ ọ́n; nitori ti o ń baa yin gbé, yoo si wà ninu yin.” Lara awọn ohun miiran, “oluranlọwọ” yẹn yoo jẹ olukọni, nitori Kristi ṣeleri pe: “Ṣugbọn [oluranlọwọ] naa, ẹmi mimọ, ẹni ti Baba yoo rán ni orukọ mi, oun ni yoo kọ yin ni ohun gbogbo, yoo si rán yin leti ohun gbogbo ti mo ti sọ fun yin.” Ẹmi naa yoo tun ṣe ẹlẹ́rìí nipa Kristi, oun si fi dá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ loju pe: “Anfaani ni yoo jẹ́ fun yin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, [oluranlọwọ] ki yoo tọ̀ yin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi ó rán an si yin.”—Johannu 14:16, 17, 26; 15:26; 16:7.a
10. Ni awọn ọ̀nà wo ni ẹmi mimọ gba fi araarẹ hàn bi oluranlọwọ?
10 Lati ọ̀run, Jesu tú ẹmi mimọ ti o ṣeleri naa jade sori awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni ọjọ Pentekosti ni 33 C.E. (Iṣe 1:4, 5; 2:1-11) Gẹgẹ bi oluranlọwọ kan, ẹmi naa fun wọn ni òye ti a mú pọ sii nipa ifẹ-inu ati ète Ọlọrun o si ṣí awọn Ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ rẹ̀ payá fun wọn. (1 Korinti 2:10-16; Kolosse 1:9, 10; Heberu 9:8-10) Oluranlọwọ yẹn tun fun awọn ọmọ-ẹhin Jesu lagbara lati jẹ́ ẹlẹ́rìí ni gbogbo ayé. (Luku 24:49; Iṣe 1:8; Efesu 3:5, 6) Lonii, ẹmi mimọ le ran Kristian kan ti ó ya araarẹ si mimọ lọwọ lati dagba ni ìmọ̀ bi oun ba yọọda araarẹ fun awọn ipese tẹmi ti Ọlọrun ṣe nipasẹ “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa.” (Matteu 24:45-47) Ẹmi Ọlọrun le pese iranlọwọ nipa fifunni ni igboya ati okun ti a nilo lati ṣe ẹlẹ́rìí gẹgẹ bi ọ̀kan ninu awọn iranṣẹ Jehofa. (Matteu 10:19, 20; Iṣe 4:29-31) Bi o ti wu ki o ri, ẹmi mimọ tun ń ran awọn eniyan Ọlọrun lọwọ ni awọn ọ̀nà miiran.
‘Pẹlu Irora Ti A Kò Le Fi Ẹnu Sọ’
11. Bi adanwo kan ba dabi eyi ti ń bonimọlẹ, ki ni Kristian kan nilati ṣe?
11 Bi adanwo kan ti o dabi eyi ti ń bonimọlẹ bá rọgba yí Kristian kan ká, ki ni oun nilati ṣe? Họwu, gbadura fun ẹmi mimọ, si jẹ́ ki ó ṣe iṣẹ rẹ̀! “Ẹmi pẹlu sì ń ran ailera wa lọwọ,” ni Paulu wi, “nitori a kò mọ bi a tii gbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn ẹmi tikaraarẹ ń fi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹbẹ fun wa. Ẹni ti o si ń wá inu ọkàn wò, ó mọ ohun ti inu ẹmi, nitori ti ó ń bẹbẹ fun awọn eniyan mimọ gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun.”—Romu 8:26, 27.
12, 13. (a) Bawo ni Romu 8:26, 27 ṣe kan awọn adura ti a gbà ninu awọn ipo ti ń danniwo ni pataki? (b) Ki ni Paulu ati awọn alabaakẹgbẹ rẹ̀ ṣe nigba ti wọn wà labẹ ikimọlẹ ti o rekọja ààlà ni agbegbe Asia?
12 Awọn eniyan mimọ ti ẹmi Ọlọrun ń bẹbẹ fun ni awọn ẹni-ami-ororo ọmọlẹhin Jesu, pẹlu ireti ti ọ̀run. Ṣugbọn yala iwọ ni ipe ti ọ̀run tabi ireti ti ilẹ̀-ayé, gẹgẹ bii Kristian kan iwọ lè ni iranlọwọ ẹmi mimọ Ọlọrun. Ni awọn igba miiran Jehofa maa ń funni ni idahun taarata si adura pàtó kan. Bi o ti wu ki o ri, ni awọn igba miiran, iwọ le ni idaamu debi pe o kò le sọ awọn imọlara rẹ jade ti o si lè jẹ pe iwọ lè bẹ Jehofa kiki pẹlu irora ti a kò sọ jade. Niti tootọ, iwọ lè ma mọ ohun ti o dara julọ fun ọ ti o sì tilẹ le beere fun ohun ti kò tọna ayafi ti o bá gbadura fun ẹmi mimọ. Ọlọrun mọ pe iwọ ń fẹ ki ifẹ-inu rẹ̀ di ṣiṣe, oun si mọ̀ ohun ti iwọ nilo niti gidi. Siwaju sii, nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, oun ń mu ki a ṣakọsilẹ ọpọlọpọ awọn adura sinu Ọ̀rọ̀ rẹ̀, awọn wọnyi sì ni i ṣe pẹlu awọn ipo ti ń danniwo. (2 Timoteu 3:16, 17; 2 Peteru 1:21) Nipa bayii, Jehofa le wo awọn ero-ọkan kan ti a sọ jade ninu iru awọn adura ti a misi bẹẹ gẹgẹ bi awọn ọ̀rọ̀ ti iwọ yoo nifẹsi lati sọ gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn iranṣẹ rẹ̀, oun sì le dahun awọn adura naa fun ọ.
13 Paulu ati awọn alabaakẹgbẹ rẹ̀ le ṣai tíì mọ ohun ti wọn yoo gbadura fun nigba ti wọn ń niriiri ipọnju ni agbegbe Asia. Niwọn bi wọn ti ‘wà labẹ ikimọlẹ dójú ààlà ti o rekọja okun wọn, wọn nimọlara ninu araawọn pe wọn ti gba idajọ iku.’ Ṣugbọn wọn beere fun adura ẹbẹ awọn yooku wọn si gbẹkẹle Ọlọrun, ẹni ti o le jí oku dide, oun si gbà wọn silẹ. (2 Korinti 1:8-11) Ẹ wo bi o ti tunininu tó pe Jehofa Ọlọrun ń gbọ́ o si ń ṣiṣẹ lori adura awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ!
14. Rere wo ni ó lè yọrisi bi Jehofa ba faayegba adanwo kan lati maa baa lọ fun igba diẹ?
14 Awọn idanwo sábà maa ń rọgba yi awọn eniyan Ọlọrun ká gẹgẹ bi eto-ajọ kan. Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi lakọọkọ, a ṣe inunibini si wọn lakooko Ogun Agbaye I. Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò ni òye ti o dá ṣaka nipa ipo wọn ti wọn kò si tipa bayii mọ ohun ti wọn yoo gbadura fun ni pato, Ọ̀rọ̀ Jehofa ni ninu awọn adura alasọtẹlẹ ti oun dahun fun wọn. (Orin Dafidi 69, 102, 126; Isaiah, ori 12) Ṣugbọn ki ni bi Jehofa ba faayegba idanwo kan lati maa baa lọ fun igba diẹ? Eyi le yọrisi ijẹrii kan, o le sun awọn kan lati ri otitọ, ki o si fun awọn Kristian ni anfaani lati fi ifẹ ará hàn nipa gbigbadura fun tabi ni ọ̀nà miiran ríran awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti wọn ń jìyà lọwọ. (Johannu 13:34, 35; 2 Korinti 1:11) Ranti pe Jehofa ń dari awọn eniyan rẹ̀ nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, o ń ṣe ohun ti o dara julọ fun wọn, o si sábà maa ń yanju awọn ọ̀ràn ni ọ̀nà kan ti yoo bọla fún ti yoo si sọ orukọ mimọ rẹ̀ di mímọ́.—Eksodu 9:16; Matteu 6:9.
Ẹ Maṣe Mú Ẹmi Mimọ Binu
15. Awọn Kristian le gbẹkẹle ẹmi Jehofa lati ṣe oun wo fun wọn?
15 Nitori naa, bi iwọ ba jẹ́ iranṣẹ Jehofa, gbadura fun ẹmi mimọ lakooko idanwo ati ni awọn igba miiran. Nigba naa rii daju pe o tẹle itọsọna rẹ̀, nitori Paulu kọwe pe: “Ẹ má sì ṣe mú ẹmi mimọ Ọlọrun binu, ẹni ti a fi ṣe edidi yin de ọjọ idande.” (Efesu 4:30) Ẹmi Ọlọrun ti jẹ́ o si jẹ́ èdídí, tabi ‘ẹ̀rí ohun ti ń bọ̀ sibẹ’ fun awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti wọn jẹ́ oluṣotitọ—iyẹn ni pe, iwalaaye alaileeku ti ọ̀run. (2 Korinti 1:22; Romu 8:15; 1 Korinti 15:50-57; Ìfihàn 2:10) Ati awọn Kristian ẹni-ami-ororo ati awọn ti wọn ni ireti ori ilẹ̀-ayé le gbẹkẹle ẹmi Jehofa lati ṣe pupọ fun wọn. Ó lè dari wọn ninu igbesi-aye iṣotitọ ki o si ràn wọ́n lọwọ lati yẹra fun awọn iṣẹ ẹṣẹ ti o maa ń ṣamọna si ainitẹwọgba Ọlọrun, ipadanu ẹmi mimọ rẹ̀, ati ikuna lati jere ìyè ayeraye.—Galatia 5:19-21.
16, 17. Bawo ni Kristian kan ṣe lè mú ẹmi naa binu?
16 Bawo ni Kristian kan, boya ni mimọọmọ tabi laimọọmọ, ṣe le mú ẹmi mimọ binu? Ó dara, Jehofa ń lo ẹmi rẹ̀ lati mu iṣọkan dagba ati lati yan awọn ọkunrin ti wọn ṣee gbẹkẹle sipo ninu ijọ. Nitori naa, bi mẹmba ijọ ba nilati kùn lodisi awọn alagba ti a yansipo, ki o tan òfófó abanijẹ kalẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ, oun kì yoo tẹlẹ idari ẹmi Ọlọrun sipa alaafia ati iṣọkan. Lapapọ, oun yoo maa mú ẹmi naa binu.—1 Korinti 1:10; 3:1-4, 16, 17; 1 Tessalonika 5:12, 13; Juda 16.
17 Ni kikọwe si awọn Kristian ni Efesu, Paulu kilọ lodisi awọn ìtẹ̀sí siha aiṣootọ, ibinu ti a fagun, ole jija, awọn ọrọ aitọ, ifẹ lilagbara lọna ti kò dara fun agbere, iwa atiniloju, iṣẹfẹ àlùfààṣá. Bi Kristian kan ba jọwọ araarẹ lati tẹ̀ síhà iru awọn nǹkan bẹẹ, oun ń tàpá si awọn itọni Bibeli ti a fi ẹmi misi. (Efesu 4:17-29; 5:1-5) Bẹẹni, ati de iwọn kan oun yoo tipa bẹẹ mú ẹmi Ọlọrun binu.
18. Ki ni o le ṣẹlẹ si Kristian eyikeyii ti o bẹrẹ sii kọ eti ikún si itọni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti a fi ẹmi misi?
18 Niti tootọ, Kristian eyikeyii ti o ba bẹrẹ sii kọ etí-ikún si itọni Ọ̀rọ̀ Jehofa ti a fi ẹmi misi le bẹrẹ sii mu awọn iṣesi tabi akopọ animọ pataki kan ti o lè yọrisi ẹṣẹ amọọmọda ati ipadanu ojurere Ọlọrun dagba. Bi o tilẹ jẹ oun pe lè ṣai maa fi ẹṣẹ danrawo nisinsinyi, oun le maa dorikọ ìhà yẹn. Iru Kristian kan bẹẹ ti o ń lodisi idari ẹmi naa yoo maa kó ẹdun-ọkan bá a. Oun yoo tun maa tipa bayii ṣàtakò sí ti yoo si maa kó ẹdun-ọkan ba Jehofa, Orisun ẹmi mimọ. Olufẹ Ọlọrun kan kì yoo fẹ́ lati ṣe iyẹn lae!
Ẹ Maa Baa Lọ Ni Gbigbadura fun Ẹmi Mimọ
19. Eeṣe ti awọn eniyan Jehofa ni pataki fi nilo ẹmi rẹ̀ lonii?
19 Bi iwọ ba jẹ́ iranṣẹ Jehofa, maa baa niṣo ní gbigbadura fun ẹmi mimọ rẹ̀. Ni pataki ní “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyi, pẹlu awọn igba lilekoko wọn ti o ṣoro lati balo, ni awọn Kristian nilo iranlọwọ ẹmi Ọlọrun. (2 Timoteu 3:1-5) Eṣu ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀, ti a lé kuro ni ọ̀run ti wọn si wa ni agbegbe ayé nisinsinyi, wà ninu rukerudo oniwaipa lodisi eto-ajọ Jehofa. Fun idi yii, nisinsinyi ju igbakigbari lọ, awọn eniyan Ọlọrun nilo ẹmi mimọ rẹ̀ lati dari, tabi ṣamọna, wọn ki o si jẹ́ ki wọn lè farada inira ati inunibini.—Ìfihàn 12:7-12.
20, 21. Eeṣe ti a fi nilati tẹle itọsọna Ọ̀rọ̀, ẹmi, ati eto-ajọ Jehofa?
20 Maa fi imọriri hàn fun iranlọwọ ti Jehofa Ọlọrun pese nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀ nigba gbogbo. Tẹle idari Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a fi ẹmi misi, Bibeli. Fọwọsowọpọ lẹkun-un-rẹrẹ pẹlu eto-ajọ ori ilẹ̀-ayé tí ẹmi Ọlọrun ń dari. Maṣe fayegba araarẹ lati yàbàrà lọ sori ipa-ọna kan ti kò bá iwe mimọ mu ti yoo jasi mimu ẹmi mimọ binu, nitori eyi le jalẹ si ifasẹhin rẹ̀ ati nipa bẹẹ ìjábá nipa tẹmi.—Orin Dafidi 51:11.
21 Jíjẹ́ ẹni ti ẹmi Jehofa ń darí ni ọ̀nà kanṣoṣo naa lati tẹ́ ẹ lọrun ki a si ni igbesi-aye alalaafia, alayọ. Ranti, pẹlu, pé Jesu pe ẹmi mimọ ni “oluranlọwọ,” tabi “olutunu.” (Johannu 14:16, akiyesi ẹsẹ-iwe) Nipasẹ rẹ̀, Ọlọrun ń tu awọn Kristian ninu o si ń fokun fun wọn lati koju awọn adanwo wọn. (2 Korinti 1:3, 4) Ẹmi naa ń fun awọn eniyan Jehofa lagbara lati waasu ihinrere naa o si ń ràn wọn lọwọ lati pe awọn koko inu Iwe Mimọ ti wọn nilo lati funni ni ijẹrii ti o dara wa si iranti. (Luku 12:11, 12; Johannu 14:25, 26; Iṣe 1:4-8; 5:32) Nipasẹ adura ati idari ẹmi naa, awọn Kristian le fi ọgbọ́n atọrunwa dojukọ awọn idanwo igbagbọ. Nitori naa, ninu gbogbo ipoayika igbesi-aye, wọn ń baa lọ ni gbigbadura fun ẹmi mimọ Ọlọrun. Gẹgẹ bi abajade rẹ̀, ẹmi Jehofa ń dari awọn eniyan rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bi o tilẹ jẹ pe a ṣakawe “oluranlọwọ” bi eniyan, ẹmi mimọ kìí ṣe eniyan, nitori ọ̀rọ̀ arọpo orukọ Griki kan fun awọn ohun kòṣakọ-kòṣabo (ti a pe ni “ó”) ni a lò fun ẹmi mimọ. Ọ̀rọ̀ arọpo orukọ Heberu ti ń tọka si abo bakan-naa ni a mulo lati ṣakawe ọgbọ́n bi eniyan. (Owe 1:20-33; 8:1-36) Pẹlupẹlu, ẹmi mimọ ni a “tú jade,” eyi ti a kò le ṣe pẹlu eniyan.—Iṣe 2:33.
Ki Ni Idahun Rẹ?
◻ Eeṣe ti a fi nilati gbadura fun ẹmi mimọ Jehofa?
◻ Bawo ni ẹmi mimọ ṣe jẹ́ oluranlọwọ?
◻ Ki ni o tumọsi lati mú ẹmi binu, bawo ni a si ṣe le yẹra fun ṣiṣe bẹẹ?
◻ Eeṣe ti a fi nilati maa baa lọ ni gbigbadura fun ẹmi mimọ ati ni titẹle idari rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹgẹ bí baba onifẹẹ kan ti ń fi awọn ohun daradara fun ọmọ rẹ̀, bẹẹ ni Jehofa ṣe ń fi ẹmi mimọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti wọn bá gbadura fun un
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Iwọ ha mọ bi ẹmi Ọlọrun ṣe ń jirẹẹbẹ fun awọn Kristian ti wọn kún fun adura bi?