Ǹjẹ́ Mo Ti Fi Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Ara Mi?
ORÍṢIRÍṢI èrò làwọn tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní nípa nǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run jẹ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tàwọn ènìyàn ní gbogbo gbòò. Síbẹ̀, kò sí ìdí tó fi yẹ kó rú wọn lójú bẹ́ẹ̀. Yékéyéké ni Bíbélì ṣàlàyé ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́. Kàkà tí ì bá fi jẹ́ ẹnì kan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ti máa ń sọ, ó jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ tí ó lágbára tí Ọlọ́run máa ń lò láti fi mú kí ìfẹ́ rẹ̀ di ṣíṣe.—Sáàmù 104:30; Ìṣe 2:33; 4:31; 2 Pétérù 1:21.
Níwọ̀n bí ẹ̀mí mímọ́ tí ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ṣíṣàṣeparí àwọn ètè Ọlọ́run, ó yẹ ká jẹ́ kí ìgbésí ayé wa wà níbàámu pẹ̀lú rẹ̀. Ó yẹ ká fi í ṣe olùrànlọ́wọ́ tiwa fúnra wa.
Èé Ṣe Táa Fi Nílò Olùrànlọ́wọ́?
Bí Jésù ti ń fojú sọ́nà de ìgbà tó máa kúrò láyé, ó mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé.” Ó sì tún sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ń sọ òtítọ́ fún yín pé, fún àǹfààní yín ni mo fi ń lọ. Nítorí bí èmi kò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà kì yóò wá sọ́dọ̀ yín lọ́nàkọnà; ṣùgbọ́n bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, èmi yóò rán an sí yín dájúdájú.”—Jòhánù 14:16, 17; 16:7.
Jésù gbé iṣẹ́ ńlá kan lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tó pàṣẹ fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. “ (Mátíù 28:19, 20) Èyí kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn rárá, nítorí lójú àtakò ni wọ́n ti máa ṣàṣeparí rẹ̀.—Mátíù 10:22, 23.
Bí àtakò yóò ti máa wá látòde, bẹ́ẹ̀ náà ni àìgbọ́ra-ẹni-yé díẹ̀díẹ̀ nínú ìjọ yóò tún máa dá kún-un. Ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, láti máa ṣọ́ àwọn tí ń fa ìpínyà àti àwọn àyè fún ìkọ̀sẹ̀ lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ sì yẹra fún wọn.” (Róòmù 16:17, 18) Ipò yìí á túbọ̀ wá burú sí i tí àwọn àpọ́sítélì bá ti wá kú. Pọ́ọ̀lù ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.”—Ìṣe 20:29, 30.
Wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti lè borí àwọn ìdènà yìí. Ọlọ́run pèsè rẹ̀ fún wọn nípasẹ̀ Jésù. Lẹ́yìn tó jíǹde, nǹkan bí ọgọ́fà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “kún fún ẹ̀mí mímọ́” ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa.—Ìṣe 1:15; 2:4.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ tí a tú jáde lákòókò yẹn ni olùrànlọ́wọ́ tí Jésù ṣèlérí. Ó dájú pé báyìí, wọ́n túbọ̀ ní òye kíkún sí i nípa nǹkan tí Jésù ń sọ nígbà tó ní: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” (Jòhánù 14:26) Ó tún pè é ní ‘olùrànlọ́wọ́, ẹ̀mí òtítọ́ náà.’—Jòhánù 15:26.
Báwo Ni Ẹ̀mí Náà Ṣe Jẹ́ Olùrànlọ́wọ́?
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ẹ̀mí náà máa gbà ṣiṣẹ́ bí olùrànlọ́wọ́. Àkọ́kọ́, Jésù ṣèlérí pé yóò rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun létí àwọn nǹkan tí òun ti sọ fún wọn. Ohun tó ní lọ́kàn nípa sísọ báyìí ju wíwulẹ̀ mú ọ̀rọ̀ wá sí ìrántí wọn lọ. Ńṣe ni ẹ̀mí náà yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó ti kọ́ wọn àti ìjẹ́pàtàkì wọn. (Jòhánù 16:12-14) Ní kúkúrú, ẹ̀mí náà yóò mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ní òye kíkún nípa òtítọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá fún nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, nítorí ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 2:10) Kí àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù tó lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ìmọ̀ pípéye, òye tiwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ jinlẹ̀.
Èkejì, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà kí wọ́n sì máa gbà á déédéé. Bí wọn kò bá mọ ohun tó yẹ kí wọ́n gbàdúrà fún nígbà míì, ẹ̀mí náà lè bẹ̀bẹ̀ fún wọn tàbí kó ràn wọ́n lọ́wọ́. “Lọ́nà kan náà, ẹ̀mí pẹ̀lú dara pọ̀ mọ́ ìrànlọ́wọ́ fún àìlera wa; nítorí ìṣòro ohun tí àwa ì bá máa gbàdúrà fún bí ó ti yẹ kí a ṣe ni àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde.”—Róòmù 8:26.
Ìkẹta, ẹ̀mí náà yóò ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́wọ́ nínú gbígbèjà òtítọ́ ní gbangba. Ó kìlọ̀ fún wọn pé: “Wọn yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́, wọn yóò sì nà yín lọ́rẹ́ nínú àwọn sínágọ́gù wọn. Họ́wù, wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n bá fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ; nítorí a ó fi ohun tí ẹ ó sọ fún yín ní wákàtí yẹn; nítorí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí Baba yín ni ó ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.”—Mátíù 10:17-20.
Ẹ̀mí mímọ́ náà yóò tún ṣèrànwọ́ ní fífi ìjọ Kristẹni hàn yàtọ̀, yóò sì sún àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ láti ṣe àwọn ìpinnu ara ẹni tó mọ́gbọ́n dání. Ẹ jẹ́ ká jíròrò apá méjèèjì yìí nínú kókó ẹ̀kọ́ yìí ní kíkún sí i ká sì rí ìjẹ́pàtàkì wọn fún wa lónìí.
Yóò Jẹ́ Àmì Ìdánimọ̀
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn Júù fi sìn lábẹ́ Òfin Mósè gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí pé wọ́n kọ Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, láìpẹ́, àwọn náà yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀, ó ní: “Ṣé ẹ kò tíì kà nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì ni èyí tí ó ti di olórí òkúta igun ilé. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ohun ìyanu ní ojú wa’? Ìdí nìyí tí mo fi wí fún yín pé, a ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mátíù 21:42, 43) Gbàrà tí ìjọ Kristẹni di èyí tí a dá sílẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi di ‘orílẹ̀-èdè tí ń mú èso rẹ̀ jáde.’ Látìgbà náà lọ, ìjọ yìí ni Ọlọ́run ń lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó gbà fi ń báni sọ̀rọ̀. Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ nípa ṣíṣí tí ojú rere Ọlọ́run ti ṣípò padà sọ́dọ̀ ìjọ yìí, Ọlọ́run pèsè àmì tí kò ní àṣìmọ̀ tí wọn yóò fi mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti lè sọ̀rọ̀ ní àwọn èdè tí wọn kò kọ́ rí, èyí tó mú kí ẹnu ya àwọn òǹwòran kí wọ́n sì béèrè pé: “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí olúkúlùkù wa ń gbọ́ èdè tirẹ̀ nínú èyí tí a bí wa sí?” (Ìṣe 2:7, 8) Agbára láti lè sọ̀rọ̀ ní àwọn èdè àjèjì, tòun ti “ọ̀pọ̀ àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì [tó] bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì,” mú kí nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ènìyàn mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń ṣiṣẹ́ ní tòótọ́.—Ìṣe 2:41, 43.
Bákan náà, bí wọ́n ti ń fi “èso ti ẹ̀mí” bí ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn, ó wá hàn kedere pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Gálátíà 5:22, 23) Ká sòótọ́, ìfẹ́ ló fi ìjọ Kristẹni tòótọ́ hàn lọ́nà tó tayọ jù lọ. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35.
Àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni ti ìjímìjí fara mọ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run wọ́n sì lo àǹfààní ìrànlọ́wọ́ tó pèsè. Bí àwọn Kristẹni lónìí ti mọ̀ pé Ọlọ́run kò tún jí òkú dìde kí ó sì tún ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi ti ọ̀rúndún kìíní mọ́, wọ́n ń jẹ́ kí èso ẹ̀mí Ọlọ́run fi àwọn hàn yàtọ̀ pé ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ni àwọ́n jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 13:8.
Olùrànlọ́wọ́ Nínú Ṣíṣe Ìpinnu Ara Ẹni
Ìpèsè ẹ̀mí mímọ́ ni Bíbélì jẹ́. Nítorí náà, báa bá jẹ́ kí Bíbélì tọ́ wa, ńṣe ló máa dà bí ẹni pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń kọ́ wa. (2 Tímótì 3:16, 17) Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ṣùgbọ́n ṣé a máa ń gbà á láyè?
Tó bá di ọ̀ràn yíyan irú iṣẹ́ tí a fẹ́ ṣe ńkọ́? Ẹ̀mí mímọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi irú ojú tí Jèhófà fi wo iṣẹ́ táa fẹ́ ṣe wò ó. Iṣẹ́ táa fẹ́ ṣe gbọ́dọ̀ wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì, ì bá sì dáa kó jẹ́ èyí tó máa lè jẹ́ ká lépa góńgó ìṣàkóso Ọlọ́run. Ní tòótọ́, owó oṣù, ipò ọlá, àti iyì tó wà nídìí iṣẹ́ kan kọ́ ni pàtàkì. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bóyá ó pèsè àwọn ohun tó pọn dandan táa nílò fún ìgbésí ayé, kó sì fún wa ní àyè tó tó láti ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.
Kò sóhun tó burú nínú fífẹ́ láti gbádùn ìgbésí ayé. (Oníwàásù 2:24; 11:9) Nítorí náà, Kristẹni kan tó lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì lè ṣe eré ìnàjú láti rí ìtura àti ìgbádùn. Ṣùgbọ́n ó yẹ kó yan irú eré ìnàjú tó gbé èso ti ẹ̀mí yọ, kì í ṣe irú àwọn tó jẹ́ pé “iṣẹ́ ti ara” ni wọ́n ń fi hàn. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Wàyí o, àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.” A tún gbọ́dọ̀ yàgò fún dídi “olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”—Gálátíà 5:16-26.
Bákan náà ló rí pẹ̀lú ọ̀ràn yíyan ọ̀rẹ́. Ó bọ́gbọ́n mu pé bí ipò tẹ̀mí wọ́n ṣe dúró déédéé sí ló yẹ ká fi yàn wọ́n, kì í ṣe ìrísí wọn tàbí bí wọ́n ṣe ní nǹkan ìní tó. Kò sí àní-àní pé ọkùnrin náà, Dáfídì, jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ pé ó jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [òun] lọ́rùn.” (Ìṣe 13:22) Láìfi ti bí ìrísí rẹ̀ ti rí pè, Ọlọ́run yan Dáfídì láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì, níbàámu pẹ̀lú ìlànà náà pé: “Kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀rẹ́ ló ti tú ká nítorí pé orí ìrísí ara tàbí nǹkan ìní ni wọ́n gbé e kà. Ọ̀rẹ́ táa bá gbé karí ọrọ̀ tí kò dáni lójú lè dojú dé lójijì. (Òwe 14:20) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ẹ̀mí mí sí gbà wá nímọ̀ràn pé, nígbà táa bá ń yan ọ̀rẹ́, àwọn tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti sin Jèhófà ni kí a yàn. Ó sọ fún wa pé kí á pọkàn pọ̀ sórí fífúnni dípò gbígbà nítorí pé fífúnni ló ń múni láyọ̀ jù lọ. (Ìṣe 20:35) Àkókò àti ìfẹ́ni wà lára àwọn nǹkan tó níye lórí jù lọ táa lè fún àwọn ọ̀rẹ́ wa.
Bíbélì pèsè ìmọ̀ràn tí ẹ̀mí mí sí fún Kristẹni kan tó ń wá ẹni tó máa fẹ́. Lẹ́nu kan ṣá, àfi bíi pé ó ní: ‘Má wo kìkìdá ojú àti bí ìdúró ẹ̀ ṣe rí. Ẹsẹ̀ rẹ̀ ni kóo wò.’ Ẹsẹ̀ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, lọ́nà ti pé: Ṣé ó ń lo àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ Jèhófà nípa wíwàásù ìhìn rere, lédè mìíràn, ṣé wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́wà lójú Jèhófà? Ṣé ó wọ àwọn ẹsẹ̀ náà ní bàtà ìhìn òtítọ́ àti ti ìhìn rere àlááfíà? A kà á pé: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o, ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, ẹni tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́, ẹni tí ń sọ fún Síónì pé: ‘Ọlọ́run rẹ ti di ọba!’”—Aísáyà 52:7; Éfésù 6:15.
Bí a ti ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” a nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:1) Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ti iṣẹ́ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lẹ́yìn lọ́nà tó lágbára, títí kan jíjẹ́ olùrànlọ́wọ́ tiwọn fúnra wọn. Fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tó jẹ́ ìpèsè ẹ̀mí mímọ́, ni ọ̀nà pàtàkì tí àwa pẹ̀lú fi lè fi ẹ̀mí mímọ́ ṣe olùrànlọ́wọ́ tiwa fúnra wa. Ṣé a ti ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]