Báwo Lẹ̀mí Ọlọ́run Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Lónìí?
LÁTINÚ oyún lọkùnrin náà ti yarọ. Ojoojúmọ́ ló máa ń jókòó sẹ́nu ọ̀nà tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń pè ní Ẹlẹ́wà kó lè máa tọrọ báárà lọ́wọ́ àwọn tó ń wọ tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n, níjọ́ kan, wọ́n ta abirùn tó ń ṣagbe yìí lọ́rẹ tó ju owó ẹyọ wẹ́wẹ́ mélòó kan lọ. Wọ́n wò ó sàn!—Ìṣe 3:2-8.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù ló “gbé e dìde,” tó fi ṣẹlẹ̀ pé “àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun ọrùn ẹsẹ̀ rẹ̀ ni a mú le gírí,” àmọ́, wọn ò sọ pé àwọn làwọ́n mú un lára dá. Èé ṣe? Pétérù fúnra rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe kàyéfì lórí èyí, tàbí èé ṣe tí ẹ fi ń tẹjú mọ́ wa bí ẹni pé nípa agbára ara wa tàbí fífọkànsin Ọlọ́run ni a fi mú un rìn?” Láìṣe àní-àní, Pétérù àti Jòhánù mọ̀ pé kì í ṣe agbára àwọn làwọn fi ṣe é bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.—Ìṣe 3:7-16; 4:29-31.
Lásìkò yẹn, wọ́n máa ń ṣe irú “iṣẹ́ agbára” bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn ìjọ Kristẹni tuntun náà. (Hébérù 2:4) Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé lẹ́yìn tí ète tí a fi ṣe wọ́n ti ní ìmúṣẹ, “a óò mú wọn wá sí òpin.”a (1 Kọ́ríńtì 13:8) Nítorí náà, Ọlọ́run ò fọwọ́ sí i mọ́, ká máa ṣe ìmúláradá, ká máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, tàbí ká máa lé ẹ̀mí èṣù dà nù lára èèyàn nínú ìjọ Kristẹni tòótọ́.
Ṣùgbọ́n ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ò ṣiṣẹ́ mọ́ ni? Rárá o! Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀nà mìíràn yẹ̀ wò tí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ṣiṣẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní, tó sì ń ṣiṣẹ́ síbẹ̀ nígbà tiwa.
“Ẹ̀mí Òtítọ́”
Ọ̀nà kan tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń gbà ṣiṣẹ́ ni láti fúnni ní ìsọfúnni, láti lani lóye, láti ṣí òtítọ́ payá. Kí Jésù tó kú, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí èyíinì bá dé, ẹ̀mí òtítọ́ náà, yóò ṣamọ̀nà yín sínú òtítọ́ gbogbo.”—Jòhánù 16:12, 13.
“Ẹ̀mí òtítọ́ náà” tú jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa nígbà tí wọ́n fi ẹ̀mí mímọ́ batisí nǹkan bí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n péjọ sínú iyàrá lókè ilé kan ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 2:1-4) Àpọ́sítélì Pétérù wà lára àwọn tó péjọ síbi àjọ̀dún tí wọ́n ń ṣe lọ́dọọdún náà. Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé Pétérù, ó “dìde dúró,” ó sì ṣàlàyé àwọn òtítọ́ kan nípa Jésù. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣàlàyé kíkún nípa bí a ṣe “gbé Jésù ará Násárétì . . . ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:14, 22, 33) Ẹ̀mí Ọlọ́run tún ru Pétérù sókè láti fìgboyà wí fún àwọn Júù tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa àti Kristi.” (Ìṣe 2:36) Ní àbájáde iṣẹ́ tí ẹ̀mí mí sí Pétérù láti jẹ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún èèyàn ló “fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀,” wọ́n sì batisí wọn. Lọ́nà yìí, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà òtítọ́.—Ìṣe 2:37-41.
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún ṣiṣẹ́ bí olùkọ́ àti olùránnilétí. Jésù sọ pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.”—Jòhánù 14:26.
Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ṣiṣẹ́ bí olùkọ́? Ẹ̀mí Ọlọ́run ṣí ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn payá sí àwọn ohun tí wọ́n ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ lẹ́nu Jésù ṣùgbọ́n tí kò yé wọn dáadáa. Fún àpẹẹrẹ, àwọn àpọ́sítélì mọ̀ pé nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ Jésù, ó sọ fún ará Róòmù náà, Pọ́ńtíù Pílátù, tí í ṣe gómìnà Jùdíà pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù ń gòkè re ọ̀run ní ohun tó lé ní ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tó sọ bẹ́ẹ̀, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣì ní èrò tí kò tọ̀nà náà pé a óò gbé Ìjọba yẹn kalẹ̀ síhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 18:36; Ìṣe 1:6) Èyí mú kó hàn kedere pé àwọn àpọ́sítélì ò lóye ohun tí Jésù sọ yékéyéké àyàfi ẹ̀yìn ìgbà tí a tú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa.
Ẹ̀mí Ọlọ́run tún ṣiṣẹ́ bí olùránnilétí nípa rírán wọn létí onírúurú ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ wọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nípa ikú Kristi àti àjíǹde rẹ̀ ní ìtumọ̀ tuntun nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ ṣe fún wọn. (Mátíù 16:21; Jòhánù 12:16) Rírántí tí àwọn àpọ́sítélì rántí àwọn ohun tí Jésù fi kọ́ wọn ló mú kí wọ́n lè ṣàlàyé ìdúró tí wọ́n mú láìṣojo níwájú àwọn ọba, àwọn adájọ́, àti àwọn aṣáájú ìsìn.—Máàkù 13:9-11; Ìṣe 4:5-20.
Láfikún sí i, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣèrànwọ́ nípa dídarí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sí ìpínlẹ̀ tó méso jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. (Ìṣe 16:6-10) Ẹ̀mí Ọlọ́run tún ru àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sókè láti lọ́wọ́ nínú kíkọ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, sílẹ̀ fún àǹfààní gbogbo ìran ènìyàn. (2 Tímótì 3:16) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ṣiṣẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Kì í ṣe torí kó lè máa ṣiṣẹ́ ìyanu nìkan ló ṣe wà.
Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ìgbà Tiwa
Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn Kristẹni tòótọ́ nígbà tiwa. Ẹ̀rí èyí hàn sí àwùjọ kékeré kan ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Allegheny, Pennsylvania ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, nígbà tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń parí lọ. Àwọn tí ń fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ṣàfẹ́rí “òtítọ́.”—Jòhánù 8:32; 16:13.
Ọ̀kan lára wọn, tó ń jẹ́ Charles Taze Russell, sọ nípa bó ṣe ṣàfẹ́rí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ tó, ó wí pé: “Mo gbàdúrà . . . pé kí n lè mú ẹ̀tanú èyíkéyìí tó lè ṣèdíwọ́ fún mi kúrò lọ́kàn àti èrò inú mi, kí ẹ̀mí rẹ̀ sì lè fòye tó tọ́ yé mi.” Ọlọ́run dáhùn àdúrà tó fìrẹ̀lẹ̀ gbà yìí.
Bí Russell àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti ń fi taápọntaápọn ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, wọ́n wá lóye àwọn ohun mélòó kan. Russell ṣàlàyé pé: “A wá rí i pé tipẹ́tipẹ́ ni oríṣiríṣi ẹ̀ya ìsìn àti àwùjọ àwọn èèyàn ti ń ba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì jẹ́, wọ́n sì ń lú wọn mọ́ àwọn ohun tí kò yàtọ̀ sí ìméfò ẹ̀dá àti ìṣìnà.” Èyí wá yọrí sí ohun tó pè ní “fífi òtítọ́ síbi tí kò yẹ.” Láìṣe àní-àní, àwọn ẹ̀kọ́ kèfèrí tó ti wọnú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù tipẹ́tipẹ́ ti bo àwọn òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n Russell múra tán láti mọ òtítọ́, kó sì kéde rẹ̀.
Nínú ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence, Russell àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ fìgboyà bẹnu àtẹ́ lu àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké tí ń purọ́ nípa Ọlọ́run. Wọ́n lóye pé—lòdì sí èrò tí ọ̀pọ̀ àwọn onísìn ní—ọkàn lè kú, pé tí a bá kú, inú sàréè la ń lọ, àti pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo tó wà, òun kì í ṣe apá kan Mẹ́talọ́kan.
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ lè retí pé inú àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ò ní dùn bí wọ́n ṣe ń tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké yẹn. Nítorí pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ṣì ń fẹ́ láti wà nípò ńlá tí wọ́n wà, púpọ̀ wọn ló ṣètò bí àwọn èèyàn yóò ṣe máa gbékèé yíde nípa Russell. Ṣùgbọ́n òun àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ kò juwọ́ sílẹ̀. Wọ́n gbọ́kàn lé ẹ̀mí Ọlọ́run láti tọ́ wọn sọ́nà. Russell sọ pé: “Ìdánilójú tí Olúwa wa fún wa ni pé . . . ẹ̀mí mímọ́ Baba, tó fi ránṣẹ́ nítorí ti Jésù Olùdáǹdè wa, Alárinà àti Olórí wa, àti nítorí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ rẹ̀ ni yóò máa kọ́ wa.” Ó sì fún wọn nítọ̀ọ́ni lóòótọ́! Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì olóòótọ́ ọkàn yìí ò yé mu omi òtítọ́ mímọ́ gaara látinú Bíbélì, wọ́n sì ń pòkìkí rẹ̀ káyé.—Ìṣípayá 22:17.
Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí ètò àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tòde òní ti ń tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Bí ẹ̀mí Jèhófà ti ń la àwọn Ẹlẹ́rìí lóye nípa tẹ̀mí láìdáwọ́dúró, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń fínnúfíndọ̀ ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ láti lè wà níbàámu pẹ̀lú òye lọ́ọ́lọ́ọ́.—Òwe 4:18.
“Ẹ Ó . . . Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”
Jésù tọ́ka sí iṣẹ́ mìíràn tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yóò ṣe nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ìlérí tí Jésù ṣe láti fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní “agbára” àti “ẹ̀mí mímọ́” kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn ṣì wúlò lónìí.
Àwọn ènìyàn mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. (Wo àpótí) Láìṣe àní-àní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní ilẹ̀ àti ọ̀wọ́ àwọn erékùṣù tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ. Lábẹ́ gbogbo ipò táa lè finú rò, títí kan fífi ẹ̀mí wọn wewu ní àwọn àgbègbè tí ogun ti ń jà, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ní ṣíṣètìlẹyìn fún Ìjọba Ọlọ́run. Ìtara tí wọ́n ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ń fi ẹ̀rí tó lágbára hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ lónìí. Ó sì hàn gbangba pé Jèhófà Ọlọ́run ń bù kún ìsapá wọn.
Fún àpẹẹrẹ, lọ́dún tó kọjá, ó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí tí a lò nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kí ló wá jẹ́ àbájáde rẹ̀? Nǹkan bí 323,439 èèyàn ló fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run hàn nípa gbígbà láti ṣèrìbọmi. Ní àfikún sí i, 4,433,884 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni a bá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn ṣe nínú ilé wọn. Lápapọ̀, 24,607,741 ìwé ńlá, 631,162,309 ìwé ìròyìn, àti ìwé pẹlẹbẹ àti àwọn ìwé kékeré tí àròpọ̀ wọ́n jẹ́ 63,495,728 la fi sóde. Ẹ̀rí ńlá mà lèyí jẹ́ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́!
Bí Ẹ̀mí Ọlọ́run Ṣe Kàn Ọ́
Bí ẹnì kan bá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, tó mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu, tó sì fi ìgbàgbọ́ hàn nínú ìpèsè ìràpadà, ọ̀nà ṣí sílẹ̀ fún un wàyí láti mú ìdúró tó mọ́ tónítóní pẹ̀lú Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Ọlọ́run . . . fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sínú yín.”—1 Tẹsalóníkà 4:7, 8; 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
Níní ẹ̀mí Ọlọ́run ń yọrí sí ìbùkún púpọ̀. Irú ìbùkún wo? Lọ́nà kan, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí sọ pé: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, [àti] ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Nítorí náà, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lágbára láti súnni ṣe rere, láti mú kí èèyàn máa fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù.
Láfikún sí i, tóo bá ka Bíbélì, tóo sì fi ohun tí o ń kọ́ sílò, ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye, ìfòyemọ̀, àti ìrònújinlẹ̀. Sólómọ́nì Ọba rí “ọgbọ́n àti òye ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi àti fífẹ̀ ọkàn-àyà” nítorí pé ó wá ọ̀nà láti múnú Ọlọ́run dùn dípò ènìyàn. (1 Àwọn Ọba 4:29) Níwọ̀n bí Jèhófà ti fún Sólómọ́nì ní ẹ̀mí mímọ́, ó dájú pé kò ní ṣàìfún àwọn tó ń fẹ́ láti mú inú rẹ̀ dùn láyé ìsinyìí ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún máa ń ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti kọjúùjà sí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù, ètò àwọn nǹkan búburú yìí, àti èrò ibi tí ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀ ní. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Ẹ̀mí mímọ́ lè máà mú àwọn àdánwò àti ìdẹwò kúrò; ṣùgbọ́n ó lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti fara dà wọ́n. Nípa gbígbẹ́kẹ̀lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, a lè rí “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” gbà, tí a lè fi kojú ìṣòro tàbí wàhálà èyíkéyìí.—2 Kọ́ríńtì 4:7; 1 Kọ́ríńtì 10:13.
Tóo bá gbé gbogbo ẹ̀rí tó wà yẹ̀ wò, kò sí àní-àní pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ láyé ìsinyìí. Ẹ̀mí Jèhófà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun láti jẹ́rìí nípa àwọn ète rẹ̀ kíkọyọyọ. Ó ń bá a lọ láti máa fi ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí ń kọ mànà hàn, ó sì ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, èyí sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin ti Ẹlẹ́dàá wa. Inú wa dùn gan-an pé Ọlọ́run mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa fífún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nígbà tiwa yìí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Eṣe ti Awọn Ẹbun Yiyanilẹnu ti Ẹmi Fi Dopin?” nínú Ilé Ìṣọ́, April 1, 1972, ojú ìwé 215 sí 218.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Ohun Táwọn Mìíràn Ń Wí Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn ń háyà àwọn ògbóǹkangí olùgbaninímọ̀ràn láti tan àwọn ènìyàn wá sí ṣọ́ọ̀ṣì tàbí kí wọ́n máa ṣàríyànjiyàn lórí àwọn ọ̀ràn tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ìsinyìí, bí ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ àti ìṣẹ́yún, àwọn Ẹlẹ́rìí ò bá ayé tẹ̀ síbi tó ń tẹ̀ sí. Wọ́n ṣì ń lọ káàkiri Ayé létòlétò.”—Ìwé ìròyìn The Orange County Register ti Àgbègbè Orange, California, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
“Tó bá di ọ̀ràn títan ìgbàgbọ́ kálẹ̀, àwọn ìsìn tó ń fìtara ṣe é . . . bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kéré níye.”—Ìwé ìròyìn The Republic ti Columbus, Indiana, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
“Àwọn nìkan ni wọ́n ń mú ‘ìhìn rere’ lọ láti ilé dé ilé, tí wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.”—Ìwé ìròyìn Życie Literackie, Poland.
“Nínú ìpolongo ìwàásù títóbi jù lọ tí a tíì gbọ́ nípa rẹ̀ rí, kò síbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì jíṣẹ́ Jèhófà dé láyé.”—Ìwé ìròyìn News-Observer, Tamaqua, Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń là wá lóye nípa tẹ̀mí,
. . . ó ń gbé àwọn ìwà ẹ̀yẹ Kristẹni ga,
. . . ó sì ń tì wá lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù wa jákèjádò ayé