-
“Èso Ti Ẹ̀mí” Ń Fi Ògo Fún Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2011 | April 15
-
-
3. (a) Bá a bá ń fi “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù, báwo nìyẹn ṣe máa fi ògo fún Ọlọ́run? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Àwọn ànímọ́ tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí ló ń jẹ́ ka mọ àkópọ̀ ìwà Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Orísun ẹ̀mí náà. (Kól. 3:9, 10) Jésù sọ ìdí tó gbawájú jù lọ tí àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ sapá láti fara wé Ọlọ́run nígbà tó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀.”a (Jòh. 15:8) Bá a bá ṣe ń fi “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù, bẹ́ẹ̀ ni àbájáde rẹ̀ á túbọ̀ máa fara hàn kedere nínú ọ̀nà tá a gbà ń sọ̀rọ̀ àti nínú ìwà wa; ìyẹn á sì tún máa fi ògo fún Ọlọ́run wa. (Mát. 5:16) Àwọn ọ̀nà wo ni èso ti ẹ̀mí gbà yàtọ̀ sí àwọn ìwà tá à ń rí nínú ayé Sátánì? Báwo la ṣe lè máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù? Kí nìdí tó fi lè dà bí ohun tó ṣòro fún wa láti fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù? A máa gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò bá a bá ṣe ń jíròrò apá mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú èso ti ẹ̀mí, ìyẹn ni ìfẹ́, ìdùnnú àti àlàáfíà.
-
-
“Èso Ti Ẹ̀mí” Ń Fi Ògo Fún Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2011 | April 15
-
-
a Lára èso tí Jésù mẹ́nu kàn ni “èso ti ẹ̀mí” àti “èso ètè” tí àwa Kristẹni fi ń rúbọ sí Ọlọ́run nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.—Héb. 13:15.
-