Ǹjẹ́ o Wà Lára Àwọn Tí Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́?
“Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi. Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́.”—JÒHÁNÙ 14:21.
1, 2. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí aráyé? (b) Kí ni Jésù dá sílẹ̀ ní alẹ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
JÈHÓFÀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn tó ṣẹ̀dá. Àní, ó nífẹ̀ẹ́ aráyé “tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Bí àkókò tá a máa ń ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ti ń sún mọ́ tòsí, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé Jèhófà “nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Jòhánù 4:10.
2 Ní òru Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá kóra jọ sí yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù láti ṣayẹyẹ Ìrékọjá, tó jẹ́ ìrántí ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. (Mátíù 26:17-20) Lẹ́yìn tí Jésù ṣe àjọyọ̀ àwọn Júù yìí tán, ó lé Júdásì Ísíkáríótù jáde, ó sì dá oúnjẹ alẹ́ ìrántí kan sílẹ̀, èyí tó máa di Ìṣe Ìrántí ikú Kristi fún àwọn Kristẹni.a Jésù lo búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tó túmọ̀ sí ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀, ó sì mú kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá yòókù jùmọ̀ jẹ oúnjẹ yìí. A rí kúlẹ̀kúlẹ̀ bó ṣe ṣe é nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́ta àkọ́kọ́, èyí tí Mátíù, Máàkù, àti Lúùkù kọ, àti nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó pè é ní “oúnjẹ alẹ́ Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 11:20; Mátíù 26:26-28; Máàkù 14:22-25; Lúùkù 22:19, 20.
3. Àwọn ọ̀nà pàtàkì wo ni àkọsílẹ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ nípa àwọn wákàtí tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú yàrá òkè fi yàtọ̀ sí ti àwọn tó kù?
3 Ó yẹ fún àfiyèsí pé àpọ́sítélì Jòhánù kò mẹ́nu kan lílo búrẹ́dì àti wáìnì, bóyá nítorí pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é lámọ̀dunjú ní àkókò tó kọ àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere tó kọ (ní nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Tiwa). (1 Kọ́ríńtì 11:23-26) Àmọ́, lábẹ́ ìmísí, Jòhánù nìkan ṣoṣo ló fúnni ní àwọn ìsọfúnni kan tó ṣe kókó nípa ohun tí Jésù sọ àti ohun tí ó ṣe kó tó dá Ìṣe Ìrántí ikú Rẹ̀ sílẹ̀ àti kété lẹ́yìn tó dá a sílẹ̀. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí gba odindi orí márùn-ún nínú ìwé Ìhìn Rere Jòhánù. Kedere-kèdèrè ni ìsọfúnni yìí jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run máa ń nífẹ̀ẹ́ sí. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìwé Jòhánù orí kẹtàlá sí ìkẹtàdínlógún.
Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Ìfẹ́ Títayọ Tí Jésù Ní
4. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe tẹnu mọ́ olórí kókó ìpàdé tí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí sílẹ̀? (b) Kí ni ìdí pàtàkì kan tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ Jésù?
4 Ìfẹ́ ni kókó pàtàkì tó wà nínú àwọn orí wọ̀nyí látòkèdélẹ̀, ìyẹn àwọn orí tí Jésù ti fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìmọ̀ràn ìdágbére. Àní, onírúurú ọ̀nà tá a gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” fara hàn ní ìgbà mọ́kànlélọ́gbọ̀n níbẹ̀. Kò síbi tá a tún ti mẹ́nu kan ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jésù ní fún Jèhófà, Baba rẹ̀, àti èyí tó ní fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó bá a ṣe mẹ́nu kàn án nínú àwọn orí wọ̀nyí. Inú gbogbo ìwé Ìhìn Rere tó sọ nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù la ti rí ìfẹ́ tí Jésù ní sí Jèhófà, àmọ́ Jòhánù nìkan ṣoṣo ló kọ ọ́ pé Jésù sọ ní kedere pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòhánù 14:31) Jésù tún sọ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti nífẹ̀ẹ́ mi, tí èmi sì nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi. Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Ọmọ rẹ̀ nítorí pé elétí ọmọ ni. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ ńlá lèyí jẹ́ fún gbogbo ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi!
5. Báwo ni Jésù ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
5 Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jésù ní fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ tí Jòhánù fi bẹ̀rẹ̀ àlàyé rẹ̀ nípa ìpàdé ìkẹyìn tí Jésù ṣe pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Jòhánù sọ pé: “Wàyí o, nítorí ó mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ ìrékọjá náà pé wákàtí òun ti dé fún òun láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba, bí Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé, ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòhánù 13:1) Ní alẹ́ mánigbàgbé yẹn, ó kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ kan tí wọn kò ní gbàgbé láé, nípa bí wọn ṣe ní láti máa fìfẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn. Ó wẹ ẹsẹ̀ wọn. Ohun tó yẹ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fẹ́ láti ṣe fún Jésù àtàwọn arákùnrin wọn nìyí, ṣùgbọ́n wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù ṣe iṣẹ́ rírẹlẹ̀ yìí, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí èmi, tí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nítorí mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòhánù 13:14, 15) Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ múra tán láti sin àwọn arákùnrin wọn, kí inú wọn sì máa dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 20:26, 27, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; Jòhánù 13:17.
Máa Pa Àṣẹ Tuntun Náà Mọ́
6, 7. (a) Kúlẹ̀kúlẹ̀ pàtàkì wo ni Jòhánù sọ nípa ìdásílẹ̀ Ìṣe Ìrántí náà? (b) Àṣẹ tuntun wo ni Jésù pa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí ló sì jẹ́ tuntun níbẹ̀?
6 Àkọsílẹ̀ tí Jòhánù kọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní yàrá òkè ní alẹ́ Nísàn 14 nìkan ṣoṣo ló dìídì mẹ́nu kan bí Júdásì Ísíkáríótù ṣe jáde lọ. (Jòhánù 13:21-30) Fífi gbogbo àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere wéra jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà tí ọ̀dàlẹ̀ yìí lọ tán ni Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ dá Ìṣe Ìrántí ikú Rẹ̀ sílẹ̀. Ó wá dìídì bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ sọ̀rọ̀ gan-an. Ó fún wọn ní ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìdágbére. Bí a ṣe ń múra láti lọ sí Ìṣe Ìrántí, ó yẹ kí a nífẹ̀ẹ́ jíjinlẹ̀ sí ohun tí Jésù sọ ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, pàápàá jù lọ nítorí pé a fẹ́ wà lára àwọn tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́.
7 Ìtọ́ni àkọ́kọ́ pàá tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ jẹ́ ìtọ́ni tuntun. Ó sọ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Kí ló jẹ́ tuntun nínú àṣẹ yìí? Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ ní alẹ́ yẹn, Jésù wá ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà yékéyéké, ó ní: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:12, 13) Òfin Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ‘kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn.’ (Léfítíkù 19:18) Àmọ́, àṣẹ tí Jésù pa kọjá ìyẹn. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n múra tán láti fi ẹ̀mí ara wọn rúbọ fún àwọn arákùnrin wọn.
8. (a) Kí ló wé mọ́ ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ? (b) Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn lóde òní?
8 Àkókò Ìṣe Ìrántí jẹ́ àkókò tó dára jù lọ láti yẹ ara wa wò, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìjọ, kí a lè rí i bóyá lóòótọ́ la ní ànímọ́ tí a fi ń dá Kristẹni tòótọ́ mọ̀ yìí—ìyẹn ni irú ìfẹ́ tí Kristi ní. Irú ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ lè túmọ̀ sí pé kí Kristẹni kan fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu dípò tí ì bá fi da arákùnrin rẹ̀, èyí sì ti rí bẹ́ẹ̀ láwọn àkókò kan. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń wé mọ́ mímúra tán láti fi ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí du ara wa kí a lè ran àwọn arákùnrin wa àtàwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nínú èyí. (2 Kọ́ríńtì 12:15; Fílípì 2:17) Àwọn èèyàn mọ̀ jákèjádò ayé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Wọ́n máa ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́, wọ́n sì ń là kàkà láti sọ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn.b—Gálátíà 6:10.
Àjọṣe Tó Ṣeyebíye
9. Bí a ò bá fẹ́ kí àjọṣe pàtàkì tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ bà jẹ́, kí la óò máa fayọ̀ ṣe?
9 Kò sí ohun tó lè ṣe pàtàkì lójú wa ju kí Jèhófà àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́ kí ìfẹ́ yìí tó lè nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ wa, a ní láti ṣe ohun kan. Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi. Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́, ṣe ni èmi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi yóò sì fi ara mi hàn fún un kedere.” (Jòhánù 14:21) Níwọ̀n bí a ti mọyì àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀, tayọ̀tayọ̀ la fi ń pa àwọn àṣẹ wọn mọ́. Èyí kan àṣẹ tuntun náà pé kí a ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ, ó sì tún kan ìtọ́ni tí Kristi fúnni lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ “láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná,” kí a máa sapá láti “sọ” àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà “di ọmọ ẹ̀yìn.”—Ìṣe 10:42; Mátíù 28:19, 20.
10. Àwọn àjọṣe pàtàkì wo ló wà fún àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn”?
10 Nígbà tó yá lálẹ́ ọjọ́ yẹn tí Jésù ń dáhùn ìbéèrè kan tí Júdásì (Tádéọ́sì) àpọ́sítélì olóòótọ́ nì gbé dìde, Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Baba mi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa yóò sì fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùjókòó wa.” (Jòhánù 14:22, 23) Kódà nígbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tá a pè láti wá bá Jésù jọba ní ọ̀run ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà àti pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 15:15; 16:27; 17:22; Hébérù 3:1; 1 Jòhánù 3:2, 24) Àmọ́, “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, tí wọ́n ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, tún ní àjọṣe pàtàkì pẹ̀lú Jésù Kristi, “olùṣọ́ àgùntàn” wọn, àti Jèhófà Ọlọ́run wọn, bí wọ́n bá sáà ti jẹ́ onígbọràn.—Jòhánù 10:16; Sáàmù 15:1-5; 25:14.
“Ẹ Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
11. Ìkìlọ̀ tó gbàrònú wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
11 Ní àkókò ìpàdé ìkẹyìn yìí tí Jésù ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, ó fún wọn ní ìkìlọ̀ kan tó gbàrònú pé: Bí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, ayé á kórìíra onítọ̀hún. Ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín. Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín sọ́kàn, pé, Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú; bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóò pa tiyín mọ́ pẹ̀lú.”—Jòhánù 15:18-20.
12. (a) Kí nìdí tí Jésù fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ayé yóò kórìíra wọn? (b) Kí ni ì bá dára kí gbogbo wa ronú lé lórí bí Ìṣe Ìrántí ti ń sún mọ́lé?
12 Jésù ṣèkìlọ̀ yìí kí àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá wọ̀nyí àti gbogbo Kristẹni tòótọ́ tó máa dé lẹ́yìn wọn má bàá rẹ̀wẹ̀sì, kí wọ́n sì juwọ́ sílẹ̀ nítorí pé ayé kórìíra wọn. Ó fi kún un pé: “Mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín kí a má bàa mú yín kọsẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò lé yín jáde kúrò nínú sínágọ́gù. Ní ti tòótọ́, wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa yín yóò lérò pé òun ti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n wọn yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí pé wọn kò mọ Baba tàbí èmi.” (Jòhánù 16:1-3) Ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì kan ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ ìṣe tá a lò fún ‘mú kọsẹ̀’ níhìn-ín túmọ̀ sí “láti mú kí ẹnì kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyè méjì nípa ẹnì kan, láti mú kó kẹ̀yìn sí ẹni tó yẹ kó fọkàn tán, kó kẹ̀yìn sí ẹni tó yẹ kó máa ṣègbọràn sí; láti mú kí ẹnì kan yapa.” Bí àkókò tí a ó ṣe Ìṣe Ìrántí ti ń sún mọ́lé, ì bá dára kí gbogbo wa ronú nípa ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ayé ọjọ́un àti ti àkókò tá a wà yìí, ká sì fara wé àpẹẹrẹ wọn, bí wọ́n ṣe dúró ṣinṣin nígbà àdánwò. Má ṣe jẹ́ kí àtakò tàbí inúnibíni mú kí o kọ Jèhófà àti Jésù sílẹ̀, àmọ́ pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé wọn kí o sì máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.
13. Kí ni Jésù béèrè nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú àdúrà kan tó gbà sí Baba rẹ̀?
13 Nínú àdúrà tí Jésù gbà kẹ́yìn kó tó kúrò ní yàrá òkè yẹn ní Jerúsálẹ́mù, ó sọ fún Baba rẹ̀ pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, ṣùgbọ́n ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé. Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14-16) Kí ó dá wa lójú pé ojú Jèhófà kò kúrò lára àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí, kí ó lè fún wọn lókun bí wọ́n ṣe ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé.—Aísáyà 40:29-31.
Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Baba àti Ti Ọmọ
14, 15. (a) Kí ni Jésù fi ara rẹ̀ wé, ní ìyàtọ̀ sí ‘àjàrà jíjẹrà’ wo? (b) Àwọn wo ni “ẹ̀ka” ti “àjàrà tòótọ́” náà?
14 Nínú ọ̀rọ̀ ìfinúkonú tí Jésù bá àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ ní alẹ́ Nísàn 14 yẹn, ó fi ara rẹ̀ wé “àjàrà tòótọ́,” ní ìyàtọ̀ sí ‘àjàrà jíjẹrà’ ti Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́. Ó sọ pé: “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni aroko.” (Jòhánù 15:1) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn, wòlíì Jeremáyà ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, pé: “Mo ti gbìn ọ́ bí ààyò àjàrà pupa . . . Báwo ni a ṣe yí ọ padà di ọ̀mùnú àjàrà ilẹ̀ òkèèrè tí ó jẹrà bàjẹ́ sí mi?” (Jeremáyà 2:21) Wòlíì Hóséà náà tún kọ̀wé pé: “Àjàrà jíjẹrà bàjẹ́ ni Ísírẹ́lì. Ó ń bá a lọ láti mú èso jáde fún ara rẹ̀ . . . Ọkàn-àyà wọ́n ti di alágàbàgebè.”—Hóséà 10:1, 2.
15 Dípò kí Ísírẹ́lì máa so èso tí ìjọsìn tòótọ́ ń so, ńṣe ló di apẹ̀yìndà, tó sì ń so èso fún ara rẹ̀. Ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ìpàdé àṣekágbá tí Jésù ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún àwọn aṣáájú Júù alágàbàgebè pé: “Mo . . . wí fún yín pé, A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mátíù 21:43) Orílẹ̀-èdè tuntun yẹn ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tó ní ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nínú, àwọn tá a fi wé “ẹ̀ka” ti “àjàrà tòótọ́” náà, ìyẹn Kristi Jésù.—Gálátíà 6:16; Jòhánù 15:5; Ìṣípayá 14:1, 3.
16. Kí ni Jésù rọ àwọn olóòótọ́ àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá láti ṣe, kí la sì lè sọ nípa àwọn olóòótọ́ ìyókù ẹni àmì òróró ní àkókò òpin yìí?
16 Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní yàrá òkè yẹn pé: “Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni ó ń mú kúrò, gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó ń wẹ̀ mọ́, kí ó lè so èso púpọ̀ sí i. Ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú yín. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fúnra rẹ̀ láìjẹ́ pé ó dúró nínú àjàrà, lọ́nà kan náà ni ẹ̀yin náà kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi.” (Jòhánù 15:2, 4) Ìtàn àwọn ènìyàn Jèhófà òde òní fi hàn pé àwọn olóòótọ́ ìyókù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù, tó jẹ́ Orí wọn. (Éfésù 5:23) Wọ́n yọ̀ǹda ara wọn fún ìfọ̀mọ́ àti ìyọ́mọ́. (Málákì 3:2, 3) Láti ọdún 1919 ni wọ́n ti ń so èso Ìjọba náà lọ́pọ̀ yanturu. Àkọ́kọ́ lára èso ìjọba náà ni àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” alábàákẹ́gbẹ́ wọn ti ń pọ̀ sí i látọdún 1935 wá.—Ìṣípayá 7:9; Aísáyà 60:4, 8-11.
17, 18. (a) Ọ̀rọ̀ wo ni Jésù sọ tó ń ran àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Jèhófà? (b) Báwo ni lílọ síbi Ìṣe Ìrántí náà yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́?
17 Gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ni ọ̀rọ̀ tí Jésù tún sọ bá wí, pé: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti nífẹ̀ẹ́ mi, tí èmi sì nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi. Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 15:8-10.
18 Gbogbo wa la fẹ́ wà nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí sì ń mú kí a jẹ́ Kristẹni tí ń so èso. À ń ṣe èyí nípa lílo gbogbo àǹfààní tá a ní láti wàásù “ìhìn rere Ìjọba” náà. (Mátíù 24:14) A tún ń sa gbogbo ipá wa láti fi “èso ti ẹ̀mí” hàn nínú ìgbésí ayé wa. (Gálátíà 5:22, 23) Lílọ sí ibi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi yóò fún wa lókun bá a ti ń sapá láti ṣe èyí, nítorí pé a óò rán wa létí ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Kristi ní sí wa.—2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.
19. Ìrànlọ́wọ́ mìíràn wo la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Lẹ́yìn tí Jésù dá Ìṣe Ìrántí náà sílẹ̀, ó ṣèlérí pé Baba òun yóò rán “olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́,” sí àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn òun. (Jòhánù 14:26) Bí ẹ̀mí yìí ṣe ń ran àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Jèhófà la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìṣirò Bíbélì, ní ọdún 2002, Nísàn 14 bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ Thursday, March 28. Ní alẹ́ yẹn, gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri àgbáyé yóò kóra jọ láti ṣe ìrántí ikú Jésù Kristi, Olúwa.
b Wo ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, orí 19 àti 32.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
• Ẹ̀kọ́ tó ṣeé mú lò wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa fífi ìfẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn?
• Àkókò Ìṣe Ìrántí jẹ́ àkókò tó bá a mu wẹ́kú láti yẹ ara ẹni wò lórí ọ̀ràn wo?
• Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ìkìlọ̀ Jésù nípa bí ayé yóò ṣe kórìíra wa, tí wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wa, mú wa kọsẹ̀?
• Ta ni “àjàrà tòótọ́” náà? Àwọn wo ni “ẹ̀ka,” kí la sì retí látọ̀dọ̀ wọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní mánigbàgbé ẹ̀kọ́ nípa fífi ìfẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ń ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn