Má Ṣe Dá Sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Tàbí Ogun
“Ẹ san . . . àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—MÁTÍÙ 22:21.
1. Báwo la ṣe lè máa pa àṣẹ Ọlọ́run àti ti ìjọba mọ́?
BÍBÉLÌ kọ́ wa pé ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ, àmọ́ ó tún sọ fún wa pé ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. (Ìṣe 5:29; Títù 3:1) Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe é? Jésù sọ ìlànà kan táá jẹ́ ká mọ ẹni tá a gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí. Ó sọ pé ká san “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”[1] (Wo àfikún àlàyé.) (Mátíù 22:21) À ń san “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì” tá a bá ń pa òfin ìjọba mọ́, tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn aṣojú ìjọba, tá a sì ń san owó orí. (Róòmù 13:7) Àmọ́, táwọn aláṣẹ bá ní ká ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́, àá sọ fún wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé a kò ní ṣe é.
2. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òṣèlú?
2 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà san “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run” ni pé ká má máa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. A kì í dá sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú òṣèlú. (Aísáyà 2:4) Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà ti fàyè gba ìjọba èèyàn láti máa ṣàkóso, a kì í ta kò wọ́n. Bákan náà, a kì í dá sí ayẹyẹ orílẹ̀-èdè tàbí ohunkóhun tó máa gbé orílẹ̀-èdè wa lárugẹ. (Róòmù 13:1, 2) A kì í gbìyànjú láti dojú ìjọba dé tàbí dìtẹ̀ sí ìjọba, a kì í kó sáwọn olóṣèlú lórí torí kí wọ́n lè ṣohun tá a fẹ́, a kì í dìbò, a kì í sì í di olóṣèlú.
3. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun?
3 Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tí Ọlọ́run fi sọ pé a ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Ọ̀kan lára ìdí náà ni pé àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé, Jésù kì í sì í ṣe “apá kan ayé.” Kò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. (Jòhánù 6:15; 17:16) Ìdí míì ni pé Ìjọba Ọlọ́run là ń fojú sọ́nà fún. Torí pé a kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, a ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ẹnu wa sì gbà á láti sọ fáwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro èèyàn. Ìsìn èké ń dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, èyí sì máa ń fa ìyapa láàárín àwọn èèyàn. Àmọ́ torí pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun, a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa kárí ayé.—1 Pétérù 2:17.
4. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé ó máa túbọ̀ ṣòro fún wa láti wà láìdá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu báyìí pé a ò ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun?
4 Wọ́n lè má fúngun mọ́ wa pé ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú lórílẹ̀-èdè tá à ń gbé. Àmọ́ bí òpin ètò Sátánì yìí ṣe ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ láá túbọ̀ máa ṣòro fún wa láti wà láìdá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Lónìí, ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn ti di “aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan” àti “olùwarùnkì,” wọ́n á sì túbọ̀ máa yapa sí i. (2 Tímótì 3:3, 4) Láwọn orílẹ̀-èdè kan, nǹkan ti yí pa dà lágbo òṣèlú, torí náà wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ àwọn ará wa pé kí wọ́n lọ́wọ́ sí òṣèlú àti ogun. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká pinnu báyìí pé a ò ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun kódà tí wọ́n bá fipá mú wa láti lọ́wọ́ sí i. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin tá a lè ṣe láti múra sílẹ̀.
OJÚ TÍ JÈHÓFÀ FI Ń WO ÌJỌBA ÈÈYÀN NI KÓ O MÁA FI WÒ Ó
5. Kí lèrò Jèhófà nípa ìjọba èèyàn?
5 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà múra sílẹ̀ ká má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun ni pé ká máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìjọba èèyàn wò ó. Jèhófà ò fún àwa èèyàn láṣẹ pé ká máa ṣàkóso lórí ara wa. (Jeremáyà 10:23) Lójú Jèhófà, ọmọ ìyá kan náà ni gbogbo wa. Àmọ́ torí pé àwọn aláṣẹ máa ń gbé orílẹ̀-èdè wọn lárugẹ, wọ́n ti kẹ̀yìn àwọn èèyàn síra. Kódà bí àwọn alákòóso bá tiẹ̀ ń ṣe ipa tiwọn, wọn ò lè mú gbogbo ìṣòro aráyé kúrò. Bákan náà, wọ́n ti sọ ara wọn di ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run.—Ka Sáàmù 2:2, 7-9.
Pinnu pé o ò ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun kódà nígbà tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀
6. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn aláṣẹ ìjọba?
6 Ọlọ́run fàyè gba ìjọba èèyàn láti ṣàkóso torí pé wọ́n lè pa àlááfíà mọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. Èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. (Róòmù 13:3, 4) Ọlọ́run tiẹ̀ sọ fún wa pé ká máa gbàdúrà kí àwọn aláṣẹ ìjọba lè jẹ́ ká jọ́sìn Jèhófà láìsí wàhálà kankan. (1 Tímótì 2:1, 2) Táwọn kan bá fẹ́ dí iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́wọ́, a lè ní káwọn aláṣẹ ràn wá lọ́wọ́. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe gan-an nìyẹn. (Ìṣe 25:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé Sátánì ló ń darí ìjọba èèyàn, kò sọ pé òun ló ń darí àwọn aláṣẹ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Lúùkù 4:5, 6) Torí náà, kò yẹ ká máa sọ pé Èṣù ló ń darí ẹnì kan pàtó tó wà nípò àṣẹ. Bíbélì sọ pé a kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnì kankan ní búburú.—Títù 3:1, 2.
7. Kí ni kò yẹ ká máa ṣe?
7 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni pé ká má ṣe gbè sẹ́yìn àwọn olóṣèlú tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú kankan, bí wọ́n bá tiẹ̀ ń sọ ohun tá a rò pé ó máa ṣe wá láǹfààní. Èyí lè má fìgbà gbogbo rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, ká ní àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba orílẹ̀-èdè kan tó ti fa ọ̀pọ̀ ìnira fáwọn èèyàn títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó dájú pé o ò ní dá sí irú ẹ̀, àmọ́ ṣó o máa fọwọ́ sí ohun tí wọ́n ṣe yẹn, tí wàá sì máa gbàdúrà pé kí wọ́n ṣàṣeyọrí? (Éfésù 2:2) Tá ò bá fẹ́ dá sí tọ̀tún-tòsì lóòótọ́, a ò ní gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni ká wá máa sọ pé ẹgbẹ́ kan dáa ju ẹgbẹ́ míì lọ. Ìwà wa àti ohun tá à ń sọ ló sì máa fi hàn bóyá à ń gbè sẹ́yìn wọn tàbí a ò gbè sẹ́yìn wọn.
Ẹ JẸ́ “ONÍṢỌ̀Ọ́RA” KÍ Ẹ SÌ JẸ́ “ỌLỌ́RÙN-MÍMỌ́”
8. Tí kò bá rọrùn láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun, báwo la ṣe lè jẹ́ “oníṣọ̀ọ́ra” àti “ọlọ́rùn-mímọ́”?
8 Ọ̀nà kejì tá ò fi ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun ni pé ká jẹ́ ‘oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ ká jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.’ (Ka Mátíù 10:16, 17.) Bá a ṣe lè jẹ́ “oníṣọ̀ọ́ra” ni pé ká máa ronú nípa ìṣòro tó lè yọjú lójijì. A sì lè jẹ́ “ọlọ́rùn-mímọ́” tá ò bá sẹ́ ìgbàgbọ́ bí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ bá wáyé. Ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tó lè wáyé àti ohun tá a lè ṣe ká má bàa sẹ́ ìgbàgbọ́.
9. Kí ló yẹ ká máa ṣọ́ra fún tá a bá ń sọ̀rọ̀?
9 Ọ̀rọ̀ ẹnu wa. A gbọ́dọ̀ wà lójúfò táwọn èèyàn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun, a ò ní sọ pé a fara mọ́ ohun tí ẹgbẹ́ òṣèlú kan ṣe tàbí pé a ò fara mọ́ ọn. Dípò ká máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọba èèyàn ṣe fẹ́ yanjú ìṣòro aráyé, á dáa ká kúkú fi bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa yanjú ìṣòro náà hàn wọ́n nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, táwọn èèyàn bá fẹ́ mọ èrò wa nípa ọ̀rọ̀ ìṣẹ́yún tàbí bí ọkùnrin ṣe ń fẹ́ ọkùnrin tí obìnrin sì ń fẹ́ obìnrin, ṣe ni ká sọ ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, ká sì sọ bí àwa náà ṣe ń fi í sílò nínú ìgbésí ayé wa. Bí ẹnì kan bá sọ pé ó yẹ kí ìjọba fagi lé àwọn òfin kan tàbí kí wọ́n ṣàtúnṣe sí i, a ò ní sọ pé ó dáa tàbí kò dáa, a ò sì ní gbìyànjú láti yí onítọ̀hún lérò pa dà.
Fi ohun tó o gbọ́ wé “àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro” tó wà nínú Bíbélì
10. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun tá a bá gbọ́ ohun táwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde?
10 Ilé iṣẹ́ ìròyìn. Nígbà míì, àwọn ìròyìn kan lè gbè sẹ́yìn àwọn kan. Èyí sì sábà máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé ìjọba ló ń sọ ohun táwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn máa gbé jáde. Táwọn oníròyìn tàbí àwọn akọ̀ròyìn bá ń gbè sápá kan, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, ká má bàa bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ó lójú oníròyìn tí mo máa ń fẹ́ tẹ́tí sí torí mo gba ohun tó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú?’ Tó ò bá fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, yẹra fún kíka àwọn ìwé tó ń gbè sẹ́yìn àwọn olóṣèlú kan, má sì máa tẹ́tí sírú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, wá ìròyìn tí ò gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni. Kó o sì wá fi ohun tó o gbọ́ wé “àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro” tó wà nínú Bíbélì.—2 Tímótì 1:13, Bíbélì Mímọ́.
11. Bí àwọn ohun ìní wa bá gbà wá lọ́kàn jù, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó ṣòro fún wa láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun?
11 Ìfẹ́ ohun ìní tara. Bí owó àtàwọn ohun ìní wa bá ti gbà wá lọ́kàn jù, ìyẹn lè mú kó ṣòro fún wa láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Lẹ́yìn ọdún 1970, ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè Màláwì ló fi gbogbo ohun tí wọ́n ní sílẹ̀ torí wọ́n kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kan. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ó ṣòro fáwọn kan láti fi ìgbésí ayé tó ti mọ́ wọn lára sílẹ̀. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ruth sọ pé, “Àwa àtàwọn kan la jọ fi ìlú sílẹ̀, àmọ́ nígbà tó ṣe, àwọn kan lára wa dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà, wọ́n sì pa dà sílé torí pé wọn ò lè fara mọ́ bí ipò nǹkan ṣe rí ní àgọ́ tá a wà náà.” Àmọ́, ohun tó yàtọ̀ pátápátá síyẹn lèyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe. Wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun kódà bí ìyẹn bá tiẹ̀ máa mú kí nǹkan nira fún wọn tàbí kí wọ́n pàdánù gbogbo ohun ìní wọn.—Hébérù 10:34.
12, 13. (a) Kí lèrò Jèhófà nípa àwa èèyàn? (b) Báwo la ṣe máa mọ̀ tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi orílẹ̀-èdè wa yangàn?
12 Ìyangàn. Àwọn èèyàn sábà máa ń fọ́nnu nípa ẹ̀yà wọn, ìlú wọn, orílẹ̀-èdè wọn, tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa fi yangàn pàápàá. Àmọ́ lójú Jèhófà, kò sẹ́ni tó sàn ju ẹnì kan lọ, orílẹ̀-èdè kan ò sì sàn ju òmíì. Bákan náà ni gbogbo wa rí lójú Jèhófà. Lóòótọ́, ànímọ́ tá a ní ò jọra, àmọ́ bí àwọn ànímọ́ tá a ní ṣe yàtọ̀ síra yẹn gan-an ni kì í jẹ́ káyé tètè súni. Kì í ṣe pé Jèhófà fẹ́ ká pa àṣà ìbílẹ̀ wa tì. Àmọ́, kò fẹ́ ká máa ronú pé a dáa ju àwọn ẹlòmíì lọ.—Róòmù 10:12.
13 Kò yẹ ká máa fi orílẹ̀-èdè wa yangàn débi pé àá wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó dáa ju àwọn tó kù lọ. Tó bá jẹ́ nǹkan tá à ń ṣe nìyẹn, ó máa ṣòro fún wa láti wà láìdá sí tọ̀tún-tòsì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn. Àwọn Hébérù kan ń ṣe ojúṣàájú sáwọn opó tó jẹ́ Gíríìkì. (Ìṣe 6:1) Àmọ́, báwo la ṣe máa mọ̀ tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í nírú ìwà bẹ́ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan tí kì í ṣe ọmọ ìlú wa bá gbà wá nímọ̀ràn, ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la máa sọ fún un pé, ‘Àwa ti gbọ́n ju gbogbo ìyẹn lọ níbí,’ ká sì fọwọ́ rọ́ ohun tó sọ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ìmọ̀ràn pàtàkì yìí: ‘Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.’—Fílípì 2:3.
JÈHÓFÀ MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
14. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́, àpẹẹrẹ wo la sì rí nínú Bíbélì tó fi hàn pé àdúrà máa ń ràn wá lọ́wọ́?
14 Ohun kẹta tá a lè ṣe tá ò fi ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun ni pé ká gbára lé Jèhófà. Gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ní sùúrù àti ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu. Àwọn ànímọ́ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ táwọn aláṣẹ bá ṣe ohun kan tí kò tọ́ tàbí tí wọ́n bá rẹ́ ọ jẹ. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o lè fòye mọ àwọn ohun tó lè mú kó ṣòro fún ẹ láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Sọ fún un pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ohun tó tọ́ nígbà ìṣòro. (Jákọ́bù 1:5) Wọ́n lè rán ẹ lọ sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n fìyà jẹ ọ́ torí pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà kó o lè ṣàlàyé ìdí tó ò fi lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á.—Ka Ìṣe 4:27-31.
Há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí, irú bí àwọn tó máa jẹ́ kó o lè máa fojú inú yàwòrán ayé tuntun àtàwọn tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun
15. Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun? (Tún wo àpótí náà “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Ìgbàgbọ́ Wọn Lókun.”)
15 Jèhófà fún wa ní Bíbélì kó lè máa fún wá lókun nípa tẹ̀mí. Máa ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Há àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sórí torí bó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò ní Bíbélì lọ́wọ́, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ló máa kù ẹ́ kù. Bíbélì tún lè mú kí ìrètí tó o ní nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú túbọ̀ dájú. Ìrètí tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ lágbára tá a bá máa fara da inúnibíni. (Róòmù 8:25) Mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣàlàyé àwọn ohun tó ò ń fojú sọ́nà fún nínú ayé tuntun, kó o wá máa wo ara rẹ níbẹ̀.
KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN OLÓÒÓTỌ́ ÌRÁNṢẸ́ JÈHÓFÀ
16, 17. Kí la lè rí kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí kò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
16 Ohun kẹrin tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun ni pé ká máa ronú nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́. Nínú Bíbélì, a rí àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó lo ìgboyà, tí wọ́n sì fọgbọ́n ṣe àwọn ìpinnu tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Ronú nípa bí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣe kọ̀ láti jọ́sìn ère tó dúró fún ìjọba ìlú Bábílónì tí wọ́n ní kí wọ́n forí balẹ̀ fún. (Ka Dáníẹ́lì 3:16-18.) Ìtàn Bíbélì yìí ti fún ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí nígboyà láti ṣàlàyé ìdí tí wọn fi kọ̀ láti kí àsíá orílẹ̀-èdè wọn. Jésù ò lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí àwọn ọ̀rọ̀ míì tó lè dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. Ó mọ̀ pé àpẹẹrẹ rere tóun bá fi lélẹ̀ máa ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—Jòhánù 16:33.
17 Lóde òní, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ni kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Wọ́n ti fìyà jẹ àwọn kan lára wọn, wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa wọ́n torí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Àpẹẹrẹ wọn lè fún àwa náà nígboyà. Arákùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Tọ́kì sọ pé: “Ọmọdé ni Arákùnrin Franz Reiter nígbà tí wọ́n pa á torí pé ó kọ̀ láti wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hitler. Lẹ́tà tó kọ sí ìyá rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn fi hàn pé ó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Èmi náà á sì fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ tí n bá kojú irú àdánwò bẹ́ẹ̀.”[2]—Wo àfikún àlàyé.
18, 19. (a) Báwo làwọn ará inú ìjọ rẹ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun? (b) Kí lo pinnu pé wàá ṣe?
18 Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ rẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Tó o bá ń kojú àdánwò, jẹ́ kí àwọn alàgbà ìjọ rẹ mọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n á fún ẹ nímọ̀ràn tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ látinú Bíbélì. Bákan náà, táwọn míì nínú ìjọ bá mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, wọ́n á fún ẹ níṣìírí kó o má bàa juwọ́ sílẹ̀. Sọ pé kí wọ́n rántí rẹ nínú àdúrà wọn. Àmọ́, ó yẹ káwa náà máa ti àwọn arákùnrin wa lẹ́yìn ká sì máa gbàdúrà fún wọn. (Mátíù 7:12) O lè rí orúkọ àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n nínú àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lórí ìkànnì jw.org, ìyẹn “Jehovah’s Witnesses Imprisoned for Their Faith—By Location,” wàá rí i lábẹ́ NEWSROOM > LEGAL DEVELOPMENTS. Yan díẹ̀ lára àwọn orúkọ tó wà níbẹ̀, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn ará yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ adúróṣinṣin sí i.—Éfésù 6:19, 20.
19 Bí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń sún mọ́lé, a lè retí pé kí àwọn aláṣẹ túbọ̀ fúngun mọ́ wa láti lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká pinnu pé a ò ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun.
^ [1] (ìpínrọ̀ 1) Ọ̀rọ̀ àwọn alákòóso ni Jésù ń sọ nígbà tó dárúkọ Késárì. Nígbà yẹn, Késárì ló ń ṣàkóso, òun sì ni aláṣẹ tó ga jù lọ.
^ [2] (ìpínrọ̀ 17) Wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 662 àti àpótí náà “Ikú Rẹ̀ Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga” orí 14 nínú ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!