Dídá Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo náà Mọ̀
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé láti ìgbà tí ẹ̀dá ènìyàn ti wà ni wọ́n ti ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run. Àwọn ọlọ́run àti abo ọlọ́run tí wọ́n ń sìn jákèjádò ayé ti pọ̀ débi pé ó ṣòro láti mọ iye wọn pàtó—àmọ́ wọ́n tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́.
Níwọ̀n bí a ti fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run kan wà, a wá béèrè nísinsìnyí pé, Èwo nínú àwọn ọlọ́run tí a ń sìn jákèjádò ilẹ̀ ayé, nísinsìnyí àti ní ìgbà àtijọ́ ni Ọlọ́run tòótọ́? Pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo tí ó ṣeé dá mọ̀ wà ni a sọ kedere nínú Bíbélì ní Jòhánù 17:3 pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”
Orúkọ Ìdánimọ̀ Kan
Yóò jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́n mu pé kí ọlọ́run èyíkéyìí tí ó ní àkópọ̀ ìwà ní orúkọ ti ara rẹ̀ láti fìyàtọ̀ sáàárín òun àti àwọn ọlọ́run mìíràn tí wọ́n ní orúkọ tiwọn. Yóò dára jù kí ó jẹ́ orúkọ tí ọlọ́run náà yàn fún ara rẹ̀, yàtọ̀ sí èyí tí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ fún un.
Àmọ́, òkodoro òtítọ́ kan tí ó rúni lójú wá jẹ yọ. Nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ìsìn tí ó ti fìdí múlẹ̀ dáadáa ni ó ní orúkọ tí wọ́n fi ń pe ọlọ́run wọn, àwọn Júù àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí ó lókìkí ní Kirisẹ́ńdọ̀mù ti kùnà láti ní orúkọ ìdánimọ̀ pàtó kan fún ọlọ́run tí wọ́n ń sìn. Dípò èyí, wọ́n yíjú sí àwọn orúkọ oyè bíi Olúwa, Ọlọ́run, Olódùmarè, àti Baba.
Òǹkọ̀wé David Clines kọ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí sínú ìwé Theology pé: “Nígbà kan láàárín ọ̀rúndún karùn-ún àti ìkejì ṣááju Sànmánì Tiwa, jàǹbá bíbaninínújẹ́ kan ṣẹlẹ̀ sí Ọlọ́run: orúkọ rẹ̀ sọnù. Kí a sọ ojú abẹ níkòó, àwọn Júù jáwọ́ nínú lílo Yahweh, tí ó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú gbólóhùn tọ́ka sí Yahweh bíi: Ọlọ́run, Olúwa, Orúkọ Náà, Ẹni Mímọ́, Atẹ́rẹrẹkáyé, àti Ibẹ̀ pàápàá. Kódà Adonai ni àwọn òǹkàwé ń pè ní àwọn ẹsẹ ti a kọ Yahweh sí nínú Bíbélì. Bí a ṣe wá wó Tẹ́ńpìlì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn ààtò ìsìn ọjọ́kan-lọ́gbọ̀n tí a ti ń lo orúkọ náà pàápàá kásẹ̀ nílẹ̀, kódà a ti gbàgbé bí a ṣe ń pe orúkọ náà.” Àmọ́, kò sí ẹnì kan tí ó lè sọ àkókò pàtó tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Júù dẹ́kun pípe orúkọ Ọlọ́run sókè ketekete tí wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù fún Ọlọ́run àti Olúwa Ọba Aláṣẹ rọ́pò rẹ̀.
Nígbà náà, ó dà bí ẹni pé ohun àkọ́kọ́ tí ó pọndandan fún ìwákiri èyíkéyìí láti dá “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà” mọ̀ yóò jẹ́ láti fi orúkọ rẹ̀ mọ̀ ọ́n. Irú ìwákiri bẹ́ẹ̀ kò ṣòro rárá, nítorí pé orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá náà, fara hàn kedere lọ́nà rírọrùn nínú Sáàmù 83:18 pé: “Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orúkọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.”—King James Version.
Ṣé Jèhófà Ni Àbí Yahweh?
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé orúkọ náà Jèhófà fara hàn nínú ìtumọ̀ King James Version àti àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn, àwọn kan yàn láti lo orúkọ náà Yahweh dípò Jèhófà. Orúkọ wo ló tọ̀nà?
Èdè Hébérù ní a fi kọ èyí tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì. Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, orúkọ àtọ̀runwá náà fara hàn ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] ìgbà, a sì fi kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin kọ ọ́—YHWH tàbí JHVH. Àwọn ọ̀rọ̀ oníkọ́ńsónáǹtì mẹ́rin ni a sábà máa ń pè ní Tetragrammaton, tàbí Tetragram, tí a fà yọ láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì tó túmọ̀ sí “lẹ́tà mẹ́rin.” Wàyí o, ìbéèrè wá dìde lórí bó ti yẹ kí a pe ọ̀rọ̀ náà nítorí pé kọ́ńsónáǹtì nìkan ni wọ́n fi ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù ìjímìjí, láìsí àwọn fáwẹ́ẹ̀lì níbẹ̀ láti tọ́ àwọn òǹkàwé sọ́nà. Nítorí náà, yálà pípè Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà di Yahweh tàbí Jèhófà wà lọ́wọ́ irú fáwẹ́ẹ̀lì tí òǹkàwé fi sí kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin náà. Lónìí, ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Hébérù ni wọ́n fara mọ́ Yahweh bí ọ̀nà tí ó tọ́ láti pè é.
Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ni a fọwọ́ sí jù fún ìṣedéédéé délẹ̀. Lọ́nà wo? Wọ́n ti tẹ́wọ́ gba pípe ọ̀rọ̀ náà Jèhófà ní èdè Yorùbá fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Ó yẹ kí àwọn tó tako pípè é lọ́nà yìí tún tako lílo àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti tẹ́wọ́ gbà bíi Jeremáyà àti Jésù pàápàá. Jeremáyà ní láti yí padà sí Yir·meyahʹ tàbí Yir·meyaʹhu, tí ó jẹ́ pípè ọ̀rọ̀ náà lédè Hébérù ní ìjímìjí, Jésù náà ní láti di Ye·shuʹaʽ (lédè Hébérù) tàbí I·e·sousʹ (lédè Gíríìkì). Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, títí kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbà pé ìṣedéédéé délẹ̀ ti mú ki a tẹ́wọ́ gba èdè Gẹ̀ẹ́sì tí gbogbogbòò ti mọ̀ náà, “Jehovah” [Jèhófà] àti èyí tó bá a dọ́gba wẹ́kú ní àwọn èdè mìíràn.
Ó Ha Já Mọ́ Nǹkan Kan Ní Gidi Bí?
Àwọn kan lè jiyàn pé yálà a fi orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè pè é tàbí a kò fi pè é, kò ṣe nǹkan kan, ó sì tẹ́ wọn lọ́rùn láti máa sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run kí wọ́n sì máa tọ́ka sí i bíi Baba tàbí kí wọ́n kàn pè é ní Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì wọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ orúkọ oyè ni, kì í ṣe orúkọ àti pé wọn kì í ṣe orúkọ ara ẹni tàbí èyí tí a lè fi dáni mọ̀. Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí a ń lò fún Ọlọ́run (ʼElo·himʹ, lédè Hébérù) ni a ń lò láti fi ṣàpèjúwe ọlọ́run èyíkéyìí—kódà ọlọ́run òrìṣà ti àwọn Filísínì tí ń jẹ́ Dágónì. (Àwọn Onídàájọ́ 16:23, 24) Nítorí náà, bí Hébérù kan bá wulẹ̀ sọ fún ará Filísínì pé òun ń sin “Ọlọ́run,” ìyẹn kò tí ì fi Ọlọ́run tòótọ́ tí òun ń sìn hàn yàtọ̀.
Ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú The Imperial Bible-Dictionary ti 1874, dùn mọ́ni nínú gan an ni, pé: “[Jèhófà] jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ gidi níbi gbogbo, ó dúró fún orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ nìkan ṣoṣo; ní ti Elohim, ó ní ànímọ́ ọ̀rọ̀ orúkọ gidi, ó sì sábà máa ń tọ́ka sí Atóbijù, àmọ́ gbogbo ìgbà kọ́ ni a máa ń lo orúkọ yẹn fún òun nìkan. . . . Hébérù lè sọ pé Elohim náà, Ọlọ́run tòótọ́ náà, ní ìlòdì sí àwọn ọlọ́run èké; ṣùgbọ́n kò lè sọ pé Jèhófà náà, nítorí pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Ó máa ń sọ ọ́ léraléra pé Ọlọ́run mi . . . ; àmọ́ kì í ṣe Jèhófà mi, nítorí nígbà tí ó bá sọ pé Ọlọ́run mi, Jèhófà ló ní lọ́kàn. Ó máa ń sọ pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì, àmọ́ kò jẹ́ sọ pé Jèhófà Ísírẹ́lì, nítorí pé kò sí Jèhófà mìíràn. Ó máa ń sọ pé Ọlọ́run alààyè, àmọ́ kò jẹ́ sọ pé Jèhófà alààyè, nítorí kò sí ọ̀nà mìíràn láti ronú nípa Jèhófà ju pé ó jẹ́ alààyè.”
Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Tòótọ́ Náà
Dájúdájú, mímọ orúkọ ẹnì kan lásán, kò túmọ̀ sí pé a mọ̀ ọ́n dáradára. Èyí tó pọ̀ jù nínú wa ló mọ orúkọ àwọn gbajúmọ̀ òṣèlú. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀ èdè mìíràn pàápàá lè ní àwọn orúkọ tí a mọ̀ dáradára. Àmọ́ wíwulẹ̀ mọ orúkọ wọn—kí a tilẹ̀ mọ̀ ọ́n pè dáadáa—kò túmọ̀ sí pé a mọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí fúnra wọn tàbí pé a mọ irú ènìyàn tí wọ́n jẹ́. Bákan náà, láti mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà, a gbọ́dọ̀ wá bí a óò ṣe mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ kí wọ́n sì jọ wá lójú.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, òtítọ́ ni pé àwọn ènìyàn kò lè rí Ọlọ́run tòótọ́ náà láé, ó ti fi inúrere mú kí a kọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àkópọ̀ ìwà rẹ̀ sílẹ̀ fún wa nínú Bíbélì. (Ẹ́kísódù 33:20; Jòhánù 1:18) A fi ìran àgbàlá Ọlọ́run Olódùmarè ní ọ̀run han àwọn wòlíì Hébérù kan lábẹ́ ìmísí. Ohun tí wọ́n júwe kò ṣàgbéyọ iyì, àgbàyanu ọlá ńlá àti agbára nìkan, ó tún sọ nípa ìparọ́rọ́ ọkàn-àyà, ìwàlétòlétò, ẹwà, àti adùn.—Ẹ́kísódù 24:9-11; Aísáyà 6:1; Ìsíkíẹ́lì 1:26-28; Dáníẹ́lì 7:9; Ìṣípayá 4:1-3.
Jèhófà Ọlọ́run to díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ rẹ̀ fífanimọ́ra lẹ́sẹẹsẹ fún Mósè, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sínú Ẹ́kísódù 34:6, 7 pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” Ìwọ kò ha gbà pé mímọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yìí yóò mú wa sún mọ́ ọn, yóò sì mú kí a fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan bí?
Nígbà tí ó jẹ́ pé kò sí ẹ̀dá ènìyàn kankan tí ó lè rí Jèhófà Ọlọ́run nínú ògo rẹ̀ dídányanran, a kọ ọ́ pé nígbà tí Jésù Kristi jẹ́ ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, ó fi irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run, Baba rẹ̀ ọ̀run, jẹ́ hàn ní ti gidi. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, Jésù sọ pé: “Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe. Nítorí ohun yòówù tí Ẹni yẹn ń ṣe, nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ ń ṣe pẹ̀lú lọ́nà kan náà.”—Jòhánù 5:19.
Ohun tí a lè rí fà yọ nínú èyí ni pé bí Jésù ṣe ní inú rere, ìyọ́nú, ìwàtútù, àti ọ̀yàyà títí kan ìfẹ́ àtọkànwá fún òdodo àti bí ó ṣe kórìíra ìwà ibi jẹ́ àwọn ànímọ́ tí Jésù kíyè sí lára Baba rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú rẹ̀ ni àgbàlá ọ̀run kí ó tó di ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí èyí, nígbà tí a bá wá fòye mọ ìtumọ̀ orúkọ náà Jèhófà ní tòótọ́, ó dájú pé a ní gbogbo ìdí láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ yẹn, kí a yìn ín, kí a gbé e ga, kí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀.
Mímọ Ọlọ́run tòótọ́ lọ́nà yìí jẹ́ ìgbéṣẹ̀ tí kì í dópin, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn kedere ní ọ̀nà tí a gbà kọ Jòhánù 17:3 nínú Ìwé Mímọ́ ni Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Níhìn-ín, lílo ẹ̀dà ọ̀rọ̀ ìṣe pípéye náà “láti mọ̀” ṣèrànwọ́ púpọ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ tí ń tọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bá a lọ ni a lò dípò ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo pọ́ńbélé tí ń tọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Nítorí náà, a kà á báyìí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” Dájúdájú, bíbá a lọ láti máa gba ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, sínú àti ti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, jẹ́ ìgbéṣẹ̀ tí kò gbọ́dọ̀ dópin.
A Fi Ọlọ́run Tòótọ́ Náà Hàn
Nítorí náà, a lè tètè dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí àwọn èké ọlọ́run. Òun ni Olódùmarè Ẹlẹ́dàá àgbáyé, títí kan pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé àti ìran ènìyàn tí ó wà lórí rẹ̀. Ó ní orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ kan, ìyẹn ni Jèhófà tàbí Yahweh. Òun kì í ṣe apá kan àdìpọ̀ ọlọ́run mẹ́ta tàbí Mẹ́talọ́kan tí kò ṣeé lóye. Ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó sì ń fẹ́ ohun tó dára jù lọ fún gbogbo ènìyàn tó jẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀. Àmọ́, ó tún jẹ́ Ọlọ́run àìṣègbè, tí kò ní fàyè gba àwọn tí wọ́n rin kinkin mọ́ bíba ayé jẹ́, tí wọ́n sì ń súnná sí ogun àti ìwà ipá.
Jèhófà ti fi ìmúratán rẹ̀ hàn láti mú ìwà ibi àti ìjìyà kúrò lórí ilẹ̀ ayé àti láti sọ ọ́ di párádísè níbi tí àwọn ènìyàn aláìlábòsí-ọkàn lè máa gbé nínú ayọ̀ títí láé. (Sáàmù 37:10, 11, 29, 34) Ọlọ́run Olódùmarè ti fi Ọmọ rẹ̀, Jésù, jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run, láìpẹ́ Jésù yóò mú ayé tuntun òdodo yẹn wá, yóò sì mú Párádísè padà bọ̀ sórí ilẹ̀ ayé wa.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.
Nísinsìnyí, a lérò pé yóò ti rọrùn fún ọ láti dáhùn ìbéèrè náà, Ọlọ́run ha wà ní ti gidi bí? kí o sì dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀ wàyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jésù Kristi fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà