Máa Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Nínú Àdúrà Onífẹ̀ẹ́ Tó Gbà
“Baba, . . . ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo.”—JÒH. 17:1.
1, 2. Ṣàlàyé ohun tí Jésù ṣe fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni.
ILẸ̀ ti ń ṣú lọ ní Nísàn, ọjọ́ kẹrìnlá, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá tán ni. Àjọyọ̀ yìí ló máa ń rán wọn létí bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn baba ńlá wọn nídè kúrò lóko ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì. Àmọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ máa rí “ìdáǹdè àìnípẹ̀kun” tó ju ìyẹn lọ gbà. Ní ọjọ́ kejì, àwọn ọ̀tá máa pa Ọ̀gá wọn tí kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, Ọlọ́run máa sọ ìwà ìkà tí wọ́n hù yẹn di ìbùkún. Ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ máa mú kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Héb. 9:12-14.
2 Ká má bàa gbàgbé ohun tí Ọlọ́run fi ìfẹ́ pèsè fún wa yìí, Jésù ṣe ìfilọ́lẹ̀ ohun kan tó máa rọ́pò Ìrékọjá tó máa ń wáyé lọ́dọọdún. Báwo ni Jésù ṣe ṣe é? Ó bu búrẹ́dì aláìwú kan, ó fi í fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ló ṣe pẹ̀lú ife tí wáìnì pupa wà nínú rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.”—Lúùkù 22:19, 20.
3. (a) Ìyípadà pàtàkì wo ló wáyé lẹ́yìn ikú Jésù? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká béèrè nípa àdúrà tí Jésù gbà ní Jòhánù orí 17?
3 Òpin máa tó dé bá májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá. Májẹ̀mú tuntun láàárín Jèhófà àtàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tá a fi ẹ̀mí yàn ló máa wá rọ́pò rẹ̀. Jésù ò fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí dà bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ò sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan, àwọn èèyàn náà ò sì wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ kó ẹ̀gàn ńláǹlà bá orúkọ mímọ́ Ọlọ́run. (Jòh. 7:45-49; Ìṣe 23:6-9) Àmọ́, Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wà ní ìṣọ̀kan kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ní ìrẹ́pọ̀ láti fi ògo fún orúkọ Ọlọ́run. Torí náà, kí ni Jésù ṣe? Ó gba àdúrà kan tó tíì wọni lọ́kàn jù lọ, ó sí jẹ́ àǹfààní fún ẹnikẹ́ni láti kà á. (Jòh. 17:1-26; wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) Àwa tá à ń gbé lónìí wá lè béèrè pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run dáhùn àdúrà Jésù?” Ó tún yẹ ká bi ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé, “Ǹjẹ́ mò ń ṣe ohun tí Jésù sọ nínú àdúrà yẹn?”
ÀWỌN NǸKAN TÍ JÉSÙ KÀ SÍ PÀTÀKÌ
4, 5. (a) Kí la rí kọ́ nínú gbólóhùn tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn apá tó kan Jésù nínú àdúrà náà?
4 Jésù ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run títí tí ilẹ̀ fi ṣú. Lẹ́yìn náà ló wá bojú wo òkè tó sì gbàdúrà pé: “Baba, wákàtí náà ti dé; ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní ọlá àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara, pé, ní ti gbogbo iye àwọn tí ìwọ ti fi fún un, kí ó lè fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun. . . . Mo ti yìn ọ́ lógo ní ilẹ̀ ayé, ní píparí iṣẹ́ tí ìwọ ti fún mi láti ṣe. Nítorí náà, nísinsìnyí ìwọ, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.”—Jòh. 17:1-5.
5 Kíyè sí ohun tí Jésù kà sí pàtàkì nínú gbólóhùn tó fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀. Ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ ni bí orúkọ Baba rẹ̀ ọ̀run ṣe máa di èyí tá a ṣe lógo. Ohun tó kọ́kọ́ béèrè fún nínú àdúrà àwòṣe tó kọ́ wa náà nìyẹn. Ó ní: “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Lúùkù 11:2) Ọ̀rọ̀ tó kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni ohun kejì tó gbàdúrà fún. Ó bẹ Ọlọ́run pé kó “fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù béèrè ohun tó fẹ́ kí Ọlọ́run ṣe fún òun, ó sọ pé: “Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.” Ohun tí Jèhófà fi san Ọmọ rẹ̀ olóòótọ́ yìí lẹ́san kọjá ohun tó béèrè fún. Ọlọ́run fún un ní “orúkọ tí ó ta” ti gbogbo àwọn áńgẹ́lì “yọ.”—Héb. 1:4.
‘KÍ WỌ́N MỌ ỌLỌ́RUN TÒÓTỌ́ KAN ṢOṢO’
6. Kí àwọn àpọ́sítélì tó lè jogún ìyè ayérayé, kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe? Báwo la ṣe mọ̀ pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Jésù tún gbàdúrà nípa ohun tí àwa ẹlẹ́ṣẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe kọ́wọ́ wa tó lè tẹ ìyè àìnípẹ̀kun tó jẹ́ ẹ̀bùn tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. (Ka Jòhánù 17:3.) Ó sọ pé a gbọ́dọ̀ máa “gba ìmọ̀” Ọlọ́run àti Kristi “sínú.” Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀. Ọ̀nà pàtàkì míì tá a fi lè gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú ni pé ká máa lo ìmọ̀ tá a bá ní nípa Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa, ká sì gbádùn ayọ̀ téèyàn máa ń rí níbẹ̀. Ó dájú pé ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe nìyí, torí Jésù sọ síwájú sí i nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Àwọn àsọjáde tí ìwọ fi fún mi ni mo ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà wọ́n.” (Jòh. 17:8) Àmọ́, kí wọ́n tó lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun, wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò lórí àwọn àsọjáde Ọlọ́run kí wọ́n sì máa fi ohun tí wọ́n ti kọ́ sílò lójoojúmọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Ǹjẹ́ àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ yẹn ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. A mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé Ọlọ́run kọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ́nà tí kò ṣeé pa rẹ́, sára òkúta méjìlá tó jẹ́ ìpìlẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun ti ọ̀run.—Ìṣí. 21:14.
7. Kí ló túmọ̀ sí láti mọ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an?
7 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé nínú èdè Gíríìkì ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí ‘gbígba ìmọ̀ sínú’ lédè Yorùbá ni a tún lè túmọ̀ sí kéèyàn “máa ní ìmọ̀ sí i” tàbí kéèyàn “máa bá a nìṣó láti ní ìmọ̀.” Ìtumọ̀ méjèèjì yìí so kọ́ra, méjèèjì ló sì ṣe pàtàkì. Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Jòhánù 17:3 (NW) tiẹ̀ tún túmọ̀ rẹ̀ sí “mímọ̀ tí wọ́n bá ń mọ̀ ọ́.” Látàrí èyí, ‘gbígba ìmọ̀ sínú’ túmọ̀ sí pé kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ síwájú àti síwájú sí i títí tó fi máa ní àǹfààní láti “mọ” Ọlọ́run. Àmọ́, kéèyàn mọ Ẹni tó ga jù lọ láyé àti lọ́run yìí kọjá kéèyàn kàn mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Láti mọ̀ Jèhófà gba pé kéèyàn jẹ́ kí ìfẹ́ mú kí òun ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn ará. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run.” (1 Jòh. 4:8) Torí náà, kéèyàn máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run wà lára ohun tó túmọ̀ sí láti mọ orúkọ rẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 2:3-5.) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn tó mọ Jèhófà! Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Júdásì Ísíkáríótù jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè pàdánù àjọṣe tímọ́tímọ́ yìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sapá gidigidi kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run má bàa bà jẹ́. Nígbà tó bá yá, ọwọ́ wa máa tẹ ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ̀bùn tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ni èyí sì jẹ́.—Mát. 24:13.
“NÍ TÌTORÍ ORÚKỌ RẸ”
8, 9. Kí ló jẹ Jésù lógún jù lọ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wo ló dájú pé Jésù kò fara mọ́?
8 Ta ló jẹ́ ka àdúrà Jésù tó wà nínú Jòhánù orí 17, tí kò ní gbà pé òótọ́ ni Jésù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àti àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí? (Jòh. 17:20) Àmọ́, bá a ṣe máa rí ìgbàlà kọ́ ló jẹ Jésù lógún jù lọ o! Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ dá lé lórí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni bó ṣe máa sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ́ tí yóó sì máa yìn ín lógo. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an fún àwọn tó péjọ nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárétì, ó ka ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé Aísáyà tó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” Ó dájú pé nígbà tí Jésù ka ibí yìí, ó ti ní láti pe orúkọ Ọlọ́run ketekete.—Lúùkù 4:16-21.
9 Ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù, ọ̀pọ̀ ọdún kí Jésù tó wá sáyé ni àwọn olórí ẹ̀sìn ti kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n má ṣe lo orúkọ Ọlọ́run. Ó dájú pé Jésù kò fara mọ́ irú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu yẹn. Ó sọ fún àwọn alátakò rẹ̀ pé: “Mo wá ní orúkọ Baba mi, ṣùgbọ́n ẹ kò gbà mí; bí ẹlòmíràn bá dé ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ ó gba ẹni yẹn.” (Jòh. 5:43) Lẹ́yìn náà, nígbà tó ku ọjọ́ mélòó kan kí Jésù kú, ó sọ ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ nínú àdúrà. Ó ní: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” (Jòh. 12:28) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé jálẹ̀ àdúrà tá à ń jíròrò yìí, Jésù fi hàn pé orúkọ Baba òun jẹ òun lógún.
10, 11. (a) Báwo ni Jésù ṣe sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ̀? (b) Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ ní lọ́kàn bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ wọn?
10 Jésù gbàdúrà pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn ènìyàn tí ìwọ fi fún mi láti inú ayé. Tìrẹ ni wọ́n jẹ́, ìwọ sì fi wọ́n fún mi, wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Pẹ̀lúpẹ̀lù, èmi kò sí ní ayé mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n wà ní ayé, èmi sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn ní tìtorí orúkọ rẹ, èyí tí ìwọ ti fi fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́.”—Jòh. 17:6, 11.
11 Nígbà tí Jésù sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe pé ó kàn pe orúkọ náà lẹ́nu lásán. Jésù tún jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí orúkọ Ọlọ́run dúró fún, ìyẹn àwọn ànímọ́ àgbàyanu Ọlọ́run àti bó ṣe ń bá àwa èèyàn lò. (Ẹ́kís. 34:5-7) Kódà láti orí ìtẹ́ ògo tí Jésù wà lọ́run báyìí, ó ṣì ń ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀ ní gbogbo ayé. Kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ní lọ́kàn bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí? Wọ́n gbọ́dọ̀ ní in lọ́kàn pé àwọn máa sọ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i di ọmọ ẹ̀yìn kí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí tó dé. Ẹ wo bí orúkọ tí Jèhófà máa ṣe fún ara rẹ̀ lákòókò yẹn ṣe máa jẹ́ àgbàyanu tó, nígbà tó bá dá àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ tó jẹ́ adúróṣinṣin nídè!—Ìsík. 36:23.
“KÍ AYÉ LÈ GBÀ GBỌ́”
12. Àwọn nǹkan mẹ́ta wo ló pọn dandan pé ká ṣe ká bàa lè kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tá à ń ṣe?
12 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣiṣẹ́ takuntakun láti mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ìyẹn ṣe pàtàkì kí wọ́n bàa lè parí iṣẹ́ tí Jésù bẹ̀rẹ̀. Jésù gbàdúrà pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi jáde sínú ayé, èmi pẹ̀lú rán wọn jáde sínú ayé.” Jésù tẹnu mọ́ àwọn nǹkan mẹ́ta tó pọn dandan pé kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà. Ohun tó kọ́kọ́ ṣe ni pé ó gbàdúrà pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun má ṣe jẹ́ apá kan ayé aláìmọ́ tí Sátánì ń ṣàkóso lé lórí yìí. Èkejì, ó gbàdúrà pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jẹ́ mímọ́ bí wọ́n ṣe ń fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù. Ẹ̀kẹta, Jésù bẹ Jèhófà léraléra pé kó jẹ́ kí ìfẹ́ so àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun pọ̀ ṣọ̀kan bí ìfẹ́ ṣe so òun àti Baba òun pọ̀ ṣọ̀kan. Èyí gba pé ká yẹ ara wa wò. Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Jésù gbàdúrà fún yìí?’ Jésù gbà pé táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta yìí, ayé máa gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ni ó ‘rán òun jáde.’—Ka Jòhánù 17:15-21.
13. Báwo ni Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà Jésù ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni?
13 Téèyàn bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì, tí wọ́n kọ lẹ́yìn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin, á rí i pé Ọlọ́run dáhùn àdúrà Jésù. Ní ọ̀rúndún kìíní, bí Júù ṣe wà nínú ìjọ, bẹ́ẹ̀ làwọn Kèfèrí wà, olówó àti tálákà, ẹrú àtàwọn olówó wọn. Ẹ wo bó ṣe rọrùn tó fún àwọn ìyàtọ̀ yìí láti fa ìpínyà láàárín àwọn Kristẹni nígbà yẹn. Síbẹ̀, gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan débi pé ṣe ni wọ́n dà bí ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara èèyàn, tí Jésù sì jẹ́ orí wọn. (Éfé. 4:15, 16) Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìyanu nìyẹn jẹ́ nínú ayé Sátánì tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí! Ọpẹ́ ni fún Jèhófà tó lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára láti mú kó ṣeé ṣe.—1 Kọ́r. 3:5-7.
14. Báwo ni Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà Jésù lóde òní?
14 Ó bani nínú jẹ́ pé ìgbà táwọn àpọ́sítélì wà láyé nìkan ni ìṣọ̀kan àgbàyanu yìí mọ. Lẹ́yìn tí wọ́n kú, ńṣe làwọn apẹ̀yìndà gbòde, ìyẹn ló sì fà á tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì fi wà. (Iṣé 20:29, 30) Àmọ́, ní ọdún 1919, Jésù dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn nídè kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀sìn èké ó sì kó wọn jọ nínú “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:14) Kí ló ti jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe fún gbogbo aráyé? Ó ti lé ní mílíọ̀nù méje èèyàn látinú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” tí wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ wọn báyìí. Àwọn “àgùntàn mìíràn” tó dara pọ̀ mọ́ wọn yìí jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, wọ́n sì jọ ń sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan. (Jòh. 10:16; Ìṣí. 7:9) Ọ̀nà àrà ni Jèhófà gbà dáhùn àdúrà Jésù pé, “kí ayé lè ní ìmọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi jáde àti pé ìwọ [Jèhófà] nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti nífẹ̀ẹ́ mi.”—Jòh. 17:23.
ÌPARÍ TÓ MÚNI LỌ́KÀN YỌ̀
15. Ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jésù bẹ Ọlọ́run pé kó ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn?
15 Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ oṣù Nísàn 14, Jésù ti kọ́kọ́ ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ‘lógo,’ tàbí pé ó dá wọn lọ́lá ní ti pé ó bá wọn dá májẹ̀mú pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú òun nínú Ìjọba òun. (Lúùkù 22:28-30; Jòh. 17:22) Torí náà, ó gbàdúrà nípa gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó máa di ẹni àmì òróró pé: “Baba, ní ti ohun tí ìwọ ti fi fún mi, mo dàníyàn pé, níbi tí mo bá wà, kí àwọn náà lè wà pẹ̀lú mi, láti lè rí ògo mi tí ìwọ ti fi fún mi, nítorí pé ìwọ nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Jòh. 17:24) Dípò tí àwọn àgùntàn mìíràn Jésù á fi máa jowú, ńṣe ni inú wọn ń dùn, èyí sì tún jẹ́ ẹ̀rí pé ìṣọ̀kan wà láàárín gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà láyé lónìí.
16, 17. (a) Ní ìparí àdúrà tí Jésù gbà, kí ló pinnu pé òun máa ṣe? (b) Kí ló yẹ kí àwa náà pinnu láti ṣe?
16 Àwọn aṣáájú ìsìn ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà láyé mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti fara mọ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà ní àwọn èèyàn tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan tí wọ́n sì mọ Ọlọ́run ní tòótọ́. Bó ṣe rí lọ́jọ́ Jésù náà nìyẹn. Torí náà ló ṣe fi ọ̀rọ̀ tó ń múni lọ́kàn yọ̀ parí àdúrà rẹ̀. Ó ní: “Baba olódodo, ní tòótọ́, ayé kò tíì wá mọ̀ ọ́; ṣùgbọ́n mo ti wá mọ̀ ọ́, àwọn wọ̀nyí sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi jáde. Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀, kí ìfẹ́ tí ìwọ fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.”—Jòh. 17:25, 26.
17 Ta ló jẹ́ sọ pé Jésù kò ṣe ohun tó gbàdúrà lé lórí yìí? Gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ, ó ṣì ń mú ká máa sọ orúkọ Baba rẹ̀ àtohun tó ní lọ́kàn láti ṣe di mímọ̀ fáwọn èèyàn. Ǹjẹ́ ká máa ṣègbọràn sí àṣẹ Kristi, ká máa fi ìtara wàásù ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 10:42) Ǹjẹ́ ká tún máa ṣiṣẹ́ kára ká lè ṣe ara wa ní òṣùṣù ọwọ̀. Lọ́nà yìí, a ó lè máa ṣe ohun tí Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà, a ó sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fi ògo fún orúkọ Jèhófà. Èyí sì tún máa yọrí sí ayọ̀ ayérayé fún wa.