Ìgbẹ́jọ́ Tó Burú Jù Lọ Láyé
ṢÀṢÀ ni ẹjọ́ tí wọ́n dá nílé ẹjọ́ láyé ìgbàanì tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ tóyẹn. Ìwé mẹ́rin tá à ń pè ní ìwé Ìhìn Rere nínú Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe fàṣẹ ọba mú Jésù Kristi, bí wọ́n ṣe ṣẹjọ́ rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe pa á. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí bí wọ́n ṣe ṣe ẹjọ́ yìí? Ìdí kan ni pé Jésù ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe ìrántí ikú òun, èyí ló sì mú kí ẹjọ́ tó yọrí sí ikú yẹn ṣe pàtàkì gan-an, ìdí míì ni pé, ó yẹ kéèyàn mọ̀ bóyá àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Jésù jẹ́ òótọ́, ìdí míì tún ni pé, ó yẹ ká mọ̀ nítorí pé ikú ìrúbọ tí Jésù fínnúfíndọ̀ kú ṣe pàtàkì gan-an fún wa àti fún ọjọ́ ọ̀la wa.—Lúùkù 22:19; Jòhánù 6:40.
Abẹ́ àkóso Róòmù ni ìlú Palẹ́sínì wà lákòókò tí wọ́n ń ṣẹjọ́ Jésù. Àwọn ará Róòmù fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù láyè láti máa fi òfin àwọn Júù ṣèdájọ́ àwọn Júù, àmọ́ ó hàn kedere pé, wọn kò fún wọn láṣẹ láti pa àwọn ọ̀daràn. Nítorí náà, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Jésù ló mú un, àmọ́ àwọn ará Róòmù ló pa á. Iṣẹ́ ìwàásù Jésù dójú ti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ìgbà yẹn débi pé, àwọn kan lára wọn pinnu pé ó yẹ kí Jésù kú. Àmọ́, wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé ó yẹ kó kú lóòótọ́, pé ikú rẹ̀ bófin mu. Lẹ́yìn àyẹ̀wò fínnífínní tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú iṣẹ́ òfin ṣe nípa ìsapá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn láti pa Jésù, ó ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tí wọn ṣe, ó ní, “èyí ni ìgbẹ́jọ́ tó burú jù lọ láyé.”a
Gbogbo Ohun Tí Wọ́n Ṣe Kò Bófin Mu
Àwọn èèyàn pe Òfin tí Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní “ètò òfin tó tóbi jù lọ tó sì tíì mọ́gbọ́n dání jù lọ tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa.” Àmọ́, nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Jésù, àwọn rábì tí wọ́n ń ṣòfin fún ohun gbogbo ti fi ọ̀pọ̀ òfin tí kò sí nínú Bíbélì kún òfin Mósè, ọ̀pọ̀ lára rẹ̀ ni wọ́n kọ sínú Ìwé Támọ́dì nígbà tó yá. (Wo àpótí náà, “Àwọn Òfin Júù ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní,” lójú ìwé 20.) Ǹjẹ́ ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe ìgbẹ́jọ́ Jésù bá àwọn òfin tó wà nínú Bíbélì àti àwọn òfin tí kò sí nínú Bíbélì mu?
Ṣé Ẹlẹ́rìí méjì sọ ohun tó bára mu níwájú ilé ẹjọ́ pé Jésù hùwà ọ̀daràn ni wọ́n ṣe fàṣẹ ọba mú un ni? Kí ìfàṣẹ ọba múni náà tó lè bófin mu, ó ní láti rí bẹ́ẹ̀. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní ilẹ̀ Palẹ́sìnì, Júù kan tó gbà pé ẹnì kan ti rú òfin ní láti mú ẹ̀sùn náà wá sílé ẹjọ́ láwọn ọjọ́ tí wọ́n máa ń wá síbẹ̀. Ilé ẹjọ́ kò ní fẹ̀sùn kanni, ìwádìí lásán ni wọ́n máa ń ṣe láti mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n mú wá síwájú wọn. Àwọn ẹlẹ́rìí tó mú ẹ̀sùn wá nìkan ni wọ́n lè sọ pé ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn. Ó dìgbà tí wọ́n bá rí Ẹlẹ́rìí méjì ó kéré tán tí ọ̀rọ̀ wọn bára mu pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà kí wọ́n tó lè gbọ́ ẹjọ́ náà. Ẹ̀rí táwọn yẹn bá mú wá ló máa mú kí wọ́n sọ pé ẹni náà jẹ̀bi, tí wọ́n á sì lọ fi àṣẹ ọba mú un. Wọn kò fàyè gba ẹ̀rí tí ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo mú wá. (Diutarónómì 19:15) Àmọ́ nínú ọ̀ràn Jésù, ńṣe làwọn aláṣẹ Júù wá “ọ̀nà tí ó gbẹ́ṣẹ́” kí wọ́n lè pa Jésù. Wọ́n fi sí àtìmọ́lé nígbà tí wọ́n rí àkókò “tí ó dára,” ìyẹn ní alẹ́, nígbà tí kò sí “ogunlọ́gọ̀ nítòsí.”—Lúùkù 22:2, 5, 6, 53.
Kò sí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n fi kan Jésù kí wọ́n tó mú un. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi Jésù sí àtìmọ́lé ni àwọn àlùfáà àti Sànhẹ́dírìn, ìyẹn ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù, ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá àwọn ẹlẹ́rìí tó máa fẹ̀sùn kàn án. (Mátíù 26:59) Wọn kò rí ẹlẹ́rìí méjì tí ọ̀rọ̀ wọn bára mu. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ilé ẹjọ́ kọ́ ló yẹ kó máa wá àwọn ẹlẹ́rìí kiri o! Ọ̀gbẹ́ni A. Taylor Innes, tó jẹ́ amòfin àti òǹṣèwé sọ pé, “láti ṣẹjọ́ ẹnì kan, ní pàtàkì láti pa á, láìsí ẹ̀sùn kan nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ tó yẹ kẹ́ni náà wá jẹ́jọ́ lé lórí fi hàn pé ẹ̀tanú ló fa irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀.”
Àwọn èèyànkéèyàn tó fi Jésù sí àtìmọ́lé mú un lọ sílé Ánásì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà nígbà kan rí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi í ní ìbéèrè. (Lúùkù 22:54; Jòhánù 18:12, 13) Ohun tí Ánásì ṣe rú òfin tó sọ pé, ojú mọmọ ló yẹ kí wọ́n bójú tó ẹ̀sùn tí wọ́n lè torí rẹ̀ pààyàn, pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ alẹ́. Síwájú sí i, ilé ẹjọ́ ló ti yẹ kí wọ́n ti wádìí òótọ́ lẹ́nu ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn, kì í ṣe ní ilé ẹnì kan. Nígbà tí Jésù kíyè sí i pé, ìwádìí tí Ánásì ń ṣe kò bófin mu, ó dá a lóhùn pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Bi àwọn tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn. Wò ó! Àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí mo sọ.” (Jòhánù 18:21) Àwọn ẹlẹ́rìí ló yẹ kí Ánásì bi ní ìbéèrè kì í ṣe ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn. Ó yẹ kí ohun tí Jésù sọ yìí mú kí adájọ́ tó nífẹ̀ẹ́ òdodo bọ̀wọ̀ fún òfin, àmọ́ ìdájọ́ òdodo kọ́ ló jẹ Ánásì lógún.
Ìdáhùn Jésù mú kí òṣìṣẹ́ ọba kan gbá a lójú, ìyẹn nìkan kọ́ sì ni ìwà ipá tí wọ́n hù sí Jésù lálẹ́ ọjọ́ yẹn. (Lúùkù 22:63; Jòhánù 18:22) Òfin tó wà nínú ìwé Númérì orí 35, nínú Bíbélì nípa ìlú ààbò, sọ pé, wọn kò gbọ́dọ̀ fi ìyà jẹ ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà títí wọ́n máa fi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ló jẹ̀bi. Nítorí ìdí èyí, kò yẹ kí wọ́n fìyà jẹ Jésù.
Lẹ́yìn náà, àwọn tó mú Jésù mú un lọ sí ilé Káyáfà tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà lákòókò yẹn, wọ́n sì ń bá ìgbẹ́jọ́ alẹ́ tí kò bófin mú náà nìṣó. (Lúùkù 22:54; Jòhánù 18:24) Níbẹ̀, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ fojú pa àwọn ìlànà òfin rẹ́, àwọn àlùfáà ń “wá ẹ̀rí èké lòdì sí Jésù láti fi ikú pa á,” àmọ́ kò sí ẹlẹ́rìí méjì tí ọ̀rọ̀ wọn bára mu pé nǹkan báyìí ni Jésù sọ. (Mátíù 26:59; Máàkù 14:56-59) Nítorí náà, àlùfáà àgbà dọ́gbọ́n, ó fẹ́ kí Jésù sọ̀rọ̀ kan kí wọ́n lè gbá a mú pé ọ̀daràn ni. Ó bi í pé: “Ṣé ìwọ kò sọ ohun kan ní ìfèsìpadà ni? Kí ni ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jẹ́rìí lòdì sí ọ?” (Máàkù 14:60) Ọgbọ́nkọ́gbọ́n yìí kò bá òfin mu rárá. Ọ̀gbẹ́ni Innes tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sọ pé, “Kò bá ìdájọ́ òdodo mu rárá, bó bá jẹ́ nítorí kí èèyàn lè rí ọ̀rọ̀ gbá mú nínú ìdáhùn ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ló mú kéèyàn bi ẹni náà ní ìbéèrè.”
Níkẹyìn, àwọn èèyàn yìí gbá ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ mú. Nígbà tí Jésù fẹ́ dáhùn ìbéèrè wọn pé: “Ṣé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ẹni Ìbùkún?” Ó ní: “Èmi ni; ẹ ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tí yóò sì máa bọ̀ nínú àwọsánmà ọ̀run.” Àwọn àlùfáà ka ohun tí Jésù sọ yìí sí ọ̀rọ̀ òdì, “gbogbo wọ́n [sì] dá a lẹ́bi pé ó yẹ fún ikú.”—Máàkù 14:61-64.b
Òfin Mósè sọ pé, gbangba ló yẹ kí wọ́n ti ṣe ìgbẹ́jọ́. (Diutarónómì 16:18; Rúùtù 4:1) Àmọ́, ìkọ̀kọ̀ ni wọ́n ti gbọ́ ẹjọ́ Jésù. Kò sí ẹnì kankan tó fẹ́ gbèjà Jésù tàbí tí wọ́n yọ̀ǹda fún láti gbèjà rẹ̀. Wọn kò ṣe àyẹ̀wò ohun tí Jésù sọ pé òun ni Mèsáyà bóyá bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Wọn kò fàyè gba Jésù láti mú àwọn ẹlẹ́rìí wá pé òun kò jẹ̀bi. Ìbò èrú làwọn adájọ́ dì nígbà tí wọ́n ń pinnu bóyá ó jẹ̀bi tàbí kò jẹ̀bi.
Níwájú Pílátù
Nítorí pé àwọn Júù kò láṣẹ láti pa Jésù, wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Pọ́ńtíù Pílátù, gómìnà tó ń ṣojú fún Róòmù. Ohun tí Pílátù kọ́kọ́ béèrè ni pé: “Ẹ̀sùn wo ni ẹ mú wá lòdì sí ọkùnrin yìí?” Nígbà tí wọ́n rí i pé Pílátù kò ka ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì táwọn fi kan Jésù sí, ńṣe ni wọ́n ń fẹ́ kó pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù láì wádìí ọ̀rọ̀. Wọ́n sọ pé: “Bí ọkùnrin yìí kì í bá ṣe olùṣe búburú, a kì bá ti fà á lé ọ lọ́wọ́.” (Jòhánù 18:29, 30) Pílátù da ọ̀rọ̀ wọn nù, èyí sì mú kó di dandan fún àwọn Júù láti wá ẹ̀sùn míì jáde pé: “A rí ọkùnrin yìí tí ń dojú orílẹ̀-èdè wa dé, tí ó sì ń ka sísan owó orí fún Késárì léèwọ̀, tí ó sì ń sọ pé òun fúnra òun ni Kristi ọba.” (Lúùkù 23:2) Bí wọ́n ṣe pa ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì tì nìyẹn o, tí wọ́n sì yí i sí ẹ̀sùn ìṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba.
Irọ́ ni ẹ̀sùn pé “ó ka sísan owó orí . . . léèwọ̀,” àwọn tó sì fẹ̀sùn yìí kan Jésù mọ̀ pé kì í ṣe òótọ́. Ohun tí Jésù fi kọ́ni yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀sùn yẹn. (Mátíù 22:15-22) Ní ti ẹ̀sùn pé Jésù sọ ara rẹ̀ di ọba, Pílátù rí i pé ọkùnrin tó wà ní iwájú òun yìí kì í ṣe ewu fún ilẹ̀ Róòmù. Ó ní: “Èmi kò rí àléébù kankan nínú rẹ̀.” (Jòhánù 18:38) Títí wọ́n sì fi parí ìgbẹ́jọ́ náà ni Pílátù ń sọ gbólóhùn yìí lásọtúnsọ.
Pílátù kọ́kọ́ gbìyànjú láti dá Jésù sílẹ̀, nípa lílo àǹfààní ohun tí wọ́n máa ń ṣe lákòókò Ìrékọjá, ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ń dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀. Àmọ́, ohun tí Pílátù ní lọ́kàn kọ́ ló ṣẹlẹ̀ nítorí pé Bárábà tó jẹ̀bi ìdìtẹ̀ sí ìjọba àti ìpànìyàn ló dá sílẹ̀ nígbẹ̀yìn.—Lúùkù 23:18, 19; Jòhánù 18:39, 40.
Ńṣe ni ìgbìyànjú míì tí gómìnà tó ń ṣojú fún Róòmù yìí ṣe láti dá Jésù sílẹ̀ yọrí sí fífara mọ́ èrò àwọn èèyànkéèyàn náà. Ó ní kí wọ́n na Jésù lọ́rẹ́, kí wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ àlùkò fún un, kí wọ́n dé e ládé ẹ̀gún, kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì fi ṣe yẹ̀yẹ́. Lẹ́yìn náà, ó tún sọ fún àwọn èèyàn náà pé Jésù kò jẹ̀bi. Òun tí Pílátù ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: ‘Ṣé ohun tá a ṣe yìí kò tíì tẹ ẹ̀yin àlùfáà lọ́rùn ni?’ Ó ṣeé ṣe kó rò pé, ó yẹ kó tẹ́ wọn lọ́rùn tí àwọn ará Róòmù bá na ẹnì kan lọ́rẹ́, kí wọ́n sì gbà pé kò yẹ káwọn gbẹ̀san mọ́ tàbí kí ìyẹn mú kí wọ́n káàánú ẹni náà. (Lúùkù 23:22) Síbẹ̀, ìyẹn kò tẹ́ wọn lọ́rùn.
“Pílátù ń bá a nìṣó ní wíwá ọ̀nà láti tú [Jésù] sílẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, pé: ‘Bí ìwọ bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì. Olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá ń fi ara rẹ̀ jẹ ọba ń sọ̀rọ̀ lòdì sí Késárì.’” (Jòhánù 19:12) Tìbéríù ni Késárì lákòókò yẹn, olú ọba yìí máa ń pa ẹnikẹ́ni tó bá kà sí aláìdúróṣinṣin, títí kan àwọn òṣìṣẹ́ ọba tó wà nípò gíga pàápàá, àwọn èèyàn sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Pílátù ti múnú bí àwọn Júù, nítorí náà, kó fẹ́ wàhálà míì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sì sọ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ẹ̀sùn àìdúróṣinṣin. Ọ̀rọ̀ ogunlọ́gọ̀ náà fi hàn pé wọ́n fẹ́ ba ti Pílátù jẹ́, ìyẹn sì mú kí ẹ̀rù bà á. Ó juwọ́ sílẹ̀ nítorí wọ́n halẹ̀ mọ́ ọn, ó sì ní kí wọ́n lọ kan Jésù tí kò jẹ̀bi mọ́gi.—Jòhánù 19:16.
Àtúnyẹ̀wò Ẹ̀rí Náà
Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń ṣàlàyé ọ̀ràn òfin ti ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ìgbẹ́jọ́ Jésù nínú ìwé Ìhìn Rere. Wọ́n sì ti sọ pé, ẹjọ́ náà kò bá ìdájọ́ òdodo mu rárá. Amòfin kan sọ pé, “Pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ irú ẹjọ́ yìí tí wọ́n sì parí rẹ̀ tí wọ́n sì kéde ìdájọ́ láàárín òru sí àárọ̀ ọjọ́ kejì kò bá àwọn òfin àtàwọn ìlànà àwọn Hébérù mu rárá, bákan náà, kò bá ìdájọ́ òdodo mu.” Ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú òfin sọ pé: “Gbogbo ìgbẹ́jọ́ náà látòkè délẹ̀ ni kò bófin mu, kò sì bá ẹ̀tọ́ mu, èyí sì túmọ̀ sí pé, ilé ẹjọ́ yìí ṣìkà pa Jésù ni.”
Jésù kò jẹ̀bi. Àmọ́, ó mọ̀ pé ikú òun ṣe pàtàkì kí àwọn aráyé tí wọ́n jẹ́ onígbọràn lè rí ìgbàlà. (Mátíù 20:28) Ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo débi pé, ó gbà láti fara mọ́ àìṣẹ̀tọ́ tó burú jù lọ. Nítorí àwa ẹlẹ́ṣẹ̀ ló fi ṣe bẹ́ẹ̀. Kò yẹ ká gbàgbé èyí láé.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣàìdáa nítorí pé wọ́n ti lo ohun tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere nípa ikú Jésù láti mú káwọn èèyàn kórìíra àwọn Júù, àmọ́ kìí ṣe ohun táwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere ní lọ́kàn nìyẹn, nítorí pé Júù làwọn fúnra wọn.
b Ọ̀rọ̀ òdì ni lílo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò lọ́wọ̀ tàbí kí ẹnì kan sọ pé òun ní agbára tàbí àṣẹ tó jẹ́ ti Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Àwọn tó sì fẹ̀sùn kan Jésù kò lẹ́rìí kankan tí wọ́n lè fi tì í lẹ́yìn pé Jésù ṣe àwọn nǹkan yìí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Òfin Júù ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní
Àwọn ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan tó bẹ̀rẹ̀ Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣàkọ́sílẹ̀ àwọn òfin àtẹnudẹ́nu àwọn Júù táwọn èèyàn gbà pé wọ́n ti wà tipẹ́, ará wọn ni àwọn ìlànà tó wà nísàlẹ̀ yìí:
▪ Nínú àwọn ẹjọ́ tí wọ́n lè torí rẹ̀ pààyàn, àwọn ẹ̀rí tó wà pé ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn kò jẹ̀bi ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń gbé yẹ̀ wò
▪ Àwọn adájọ́ ní láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti gba ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà sílẹ̀
▪ Àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ gbe ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ni, wọn kò gbọ́dọ̀ ta kò ó
▪ Wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́rìí mọ bí ipa tí wọ́n ń kó ti ṣe pàtàkì tó
▪ Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn ẹlẹ́rìí, kì í ṣe níṣojú ẹlẹ́rìí míì
▪ Nínú ohun táwọn ẹlẹ́rìí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ, ọjọ́, ibi tí nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀, aago tó ṣẹlẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ gbọ́dọ̀ bára mu
▪ Ojúmọmọ ni wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́ àwọn ẹjọ́ tí wọ́n lè tìtorí rẹ̀ pààyàn, kí wọ́n sì parí wọn ní ojúmọmọ
▪ Wọn kò gbọ́dọ̀ gbọ́ àwọn ẹjọ́ tí wọ́n lè torí rẹ̀ pààyàn ní alẹ́ ọjọ́ Sábáàtì ku ọ̀la tàbí ọjọ́ tí ayẹyẹ kan ku ọ̀la
▪ Ọjọ́ kan náà ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ kí wọ́n sì parí ẹjọ́ tí wọ́n lè tìtorí rẹ̀ pààyàn, ìyẹn bí ẹjọ́ náà bá gbe ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà, tí kò bá gbè é nìkan ló máa parí lọ́jọ́ kejì nígbà tí adájọ́ máa kéde ìdájọ́, tí wọ́n á sì ṣe ohun tó yẹ fún ẹni náà
▪ Ó kéré tán, adájọ́ mẹ́tàlélógún [23] ló gbọ́dọ̀ gbọ́ ẹjọ́ tí wọ́n lè torí rẹ̀ pààyàn
▪ Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni àwọn adájọ́ máa dìbò, bóyá láti dá ẹni náà sílẹ̀ tàbí láti dá a lẹ́bi, orí ẹni tó kéré jù ni ìbò náà ti máa bẹ̀rẹ̀, àwọn akọ̀wé òfin á máa ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn tó gbà pé kí wọ́n dá ẹni náà sílẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àwọn tí kò gbà
▪ Wọ́n máa dá ẹnì kan láre, tí àwọn adájọ́ tí wọ́n sọ pé ẹni náà jàre bá fi ẹyọ kan pọ̀ ju iye àwọn adájọ́ tí wọ́n sọ pé ẹni náà jẹ̀bi, àmọ́ wọ́n máa dá ẹnì kan lẹ́bi tí iye àwọn adájọ́ tí wọ́n sọ pé ẹni náà jẹ̀bi bá fi méjì pọ̀ ju iye àwọn adájọ́ tí wọ́n sọ pé ẹni náà jàre, ṣùgbọ́n tó bá ṣẹlẹ̀ pé iye àwọn adájọ́ tí wọ́n sọ pé ẹnì kan jẹ̀bi bá fi ẹyọ kan pọ̀ ju iye àwọn adájọ́ tó sọ pé ẹni náà jàre, wọ́n á máa fi adájọ́ méjì míì kún un títí dìgbà tí wọ́n á fi lè ṣe ìpinnu tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀
▪ Bí gbogbo àwọn adájọ́ bá fẹnu kò pé ẹni kan jẹ̀bi láìsí adájọ́ kan ṣoṣo tó ta ko ìdájọ́ náà, irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, “ìyẹn [sì] fi hàn pé ọ̀tẹ̀ ló wà nídìí rẹ̀”
Àwọn Nǹkan Tí Kò Bófin Mu Nínú Ìgbẹ́jọ́ Jésù
▪ Ilé ẹjọ́ kò gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn ẹlẹ́rìí tó lè jẹ́rìí gbe Jésù
▪ Kò sí èyíkéyìí lára àwọn adájọ́ yẹn tó gbìyànjú láti gbèjà Jésù, ọ̀tá rẹ̀ ni gbogbo wọn
▪ Àwọn àlùfáà wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tó máa rojọ́ mọ́ Jésù kí wọ́n lè pa á
▪ Ilé àwọn kan ni wọ́n ti gbẹ́jọ́ náà lóru
▪ Ọjọ́ kan náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n sì parí ìgbẹ́jọ́ náà, ìyẹn sì jẹ́ alẹ́ ọjọ́ tí ayẹyẹ kan ku ọ̀la
▪ Wọn kò fi ẹ̀sùn kankan kan Jésù kí wọ́n tó fàṣẹ ọba mú un
▪ Wọn kò ṣèwádìí “ọ̀rọ̀ òdì” tí wọ́n sọ pé Jésù sọ pé òun ni Mèsáyà
▪ Wọ́n yí ẹ̀sùn náà pa dà nígbà tí wọ́n gbé ẹjọ́ náà dé ọ̀dọ̀ Pílátù
▪ Irọ́ làwọn ẹ̀sùn náà
▪ Pílátù rí i pé Jésù kò jẹ̀bi, síbẹ̀ ó ní kí wọ́n pa á
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Máa Jíhìn fún Ẹ̀jẹ̀ Ẹni Tí Wọ́n Fẹ̀sùn Kàn
Ìkìlọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí ni wọ́n máa ń ṣe nílé ẹjọ́ àwọn Júù fún àwọn ẹlẹ́rìí nípa bí ìwàláàyè ti ṣeyebíye tó, kí wọ́n tó jẹ́rìí sí ọ̀ràn ẹjọ́ tí wọ́n lè tìtorí rẹ̀ pààyàn:
“Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí ẹ gbà pé ó ṣẹlẹ̀ ni ẹ fẹ́ sọ àti èyí tí ẹ gbọ́ tàbí èyí tí ẹni tí ọ̀ràn ṣojú rẹ̀ sọ fún ẹlòmíì, tàbí ẹ lè rò pé, ‘Ẹni tí mo gbọ́rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀ kò lè purọ́.’ Tàbí, ẹ lè má mọ̀ pé a ṣì máa béèrè onírúurú ìbéèrè lọ́wọ́ yín tí a sì máa ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yín. A fẹ́ kẹ́ mọ̀ pé òfin tó ń darí àwọn ọ̀ràn ẹjọ́ nípa àwọn ohun ìní yàtọ̀ sí ti àwọn ọ̀ràn ẹjọ́ tí wọ́n lè tìtorí rẹ̀ pààyàn. Ní ti ẹjọ́ nípa àwọn ohun ìní, ẹnì kan lè san owó, táá sì gba ara rẹ̀ sílẹ̀. ‘Nínú ọ̀ràn ẹjọ́ tí wọ́n lè tìtorí rẹ̀ pààyàn, tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún ẹnì kan nítorí ẹ̀sùn èké táwọn ẹlẹ́rìí kan mú wá, àwọn ẹlẹ́rìí èké náà ló máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tó kú náà àti ti àwọn ọmọ tó yẹ kí ẹni náà bí.’”—Ìwé Támọ́dì Àwọn Ará Bábílónì, Sànhẹ́dírìn, 37a.
Bí wọ́n bá dájọ́ ikú fún ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà, àwọn ẹlẹ́rìí ló máa pa á.—Léfítíkù 24:14; Diutarónómì 17:6, 7.