“Kí Ni Òtítọ́?”
ÌBÉÈRÈ yẹn ni Pọ́ńtù Pílátù tó jẹ́ gómìnà Róòmù béèrè lọ́wọ́ Jésù tẹ̀gàntẹ̀gàn. Jésù kò dá Pílátù lóhùn ìbéèrè náà nítorí pé Pílátù ò fẹ́ ìdáhùn kankan. Bóyá ojú tí Pílátù fi wo òtítọ́ ni pé ó jẹ́ ohun tó ṣòroó lóye.—Jòhánù 18:38.
Ìwà àìka òtítọ́ sóhun tó ṣe pàtàkì yìí wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn èèyàn lónìí, títí kan àwọn olórí ẹ̀sìn, àwọn ọ̀mọ̀wé àtàwọn òṣèlú. Wọ́n sọ pé kò sóhun kan pàtó tó ń jẹ́ òtítọ́, àgàgà tó bá kan irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù tàbí ọ̀rọ̀ ìjọsìn, wọ́n ní ohun tó bá wu kálukú ló lè ṣe àti pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí kò dúró sójú kan. Dájúdájú, ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé àwọn èèyàn lè fúnra wọn pinnu bóyá ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́. (Aísáyà 5:20, 21) Èyí sì tún ń mú káwọn èèyàn máa ka àwọn ìlànà táwọn ará àtijọ́ tẹ̀ lé àtàwọn ìwà rere tí wọ́n hù sóhun tí kò bóde mu mọ́.
Ó yẹ ká fiyè sí gbólóhùn tó mú kí Pílátù béèrè ìbéèrè yẹn. Jésù sọ pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Jésù kò gbà pé òtítọ́ jẹ́ ohun tó ṣòroó lóye. Ó ṣèlérí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32.
Ibo la ti lè rí òtítọ́ yẹn? Nígbà kan tí Jésù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Bíbélì, ìwé tí Ọlọ́run mí sí, jẹ́ ká mọ òtítọ́ tó ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé, tó sì tún jẹ́ ká ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.—2 Tímótì 3:15-17.
Pílátù pàdánù àǹfààní tó ní láti mọ òtítọ́ nítorí pé kò bìkítà nípa rẹ̀. Ìwọ náà ńkọ́? O lè ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa “òtítọ́” tí Jésù fi kọ́ni. Inú wọn yóò dùn láti ṣàlàyé rẹ̀ fún ọ.