Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu
A Fà á Lé Wọn Lọwọ Wọn Si Mu un Lọ
NIGBATI Pilatu, ẹni ti a sun nipasẹ ìwà jẹ́jẹ́ Jesu ti a ti daloro, gbiyanju lẹẹkansii lati tú u silẹ, ibinu awọn olori alufa wa peleke sii. Wọn ti pinnu lati maṣe jẹ ki ohunkohun ṣedilọwọ fun ète buruku wọn. Nitorinaa wọn tun bẹrẹsii hóyèè lẹẹkansii: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”
Pilatu fi irira dahunpada pe: “Ẹ mú un funra yin ki ẹ si kaǹ án mọ́gi.” Ni odikeji si ohun ti wọn fi itẹnumọ sọ ni iṣaaju, awọn Júù le ni aṣẹ lati fiya iku jẹ awọn ọdaran fun awọn ẹṣẹ nipa isin ti iwuwo wọn pọ dé ààyè kan. Lẹhinnaa, fun igba karun-un o kere tan, Pilatu sọ nigbangba pe Jesu kò mọwọ́mẹsẹ̀, ni wiwipe: “Emi ko ri ariwisi eyikeyii ninu rẹ.”
Awọn Júù, ni ririi pe awọn ẹ̀sùn oṣelu wọn ti kuna lati mu eso jade, yipada si ẹ̀sùn ọrọ-odi nipa isin tí wọn ti lo ni ọpọlọpọ wakati ṣaaju nibi ìgbẹ́jọ́ Jesu niwaju awọn Sanhendrin. Wọn wipe, “Awa ni ofin kan, ati ni ibamu pẹlu ofin naa oun yẹ si iku, nitoripe oun ṣe araarẹ ni ọmọkunrin Ọlọrun.”
Ẹ̀sùn yi jẹ titun si Pilatu, o si mu ki o kun fun ibẹru sii. Nisinsinyi oun mọdaju pe Jesu kii ṣe eniyan lasan, ani gẹgẹ bi àlá aya rẹ ati bi agbara ihuwa pipẹtẹri Jesu ti fihan. Ṣugbọn “ọmọkunrin Ọlọrun” kẹ̀? Pilatu mọ pe Jesu wa lati Galili. Sibẹ, o ha le ṣeeṣe pe oun ti walaaye ṣaaju bi? Ni mimu un pada sinu aafin lẹẹkansi, Pilatu beere pe: “Nibo ni iwọ ti wa?”
Jesu wa ni idakẹjẹẹ. Ṣaaju isinsinyi oun ti sọ fun Pilatu pe ọba ni oun, ṣugbọn ijọba oun kiise apakan aye yii. Nisinsinyi alaye eyikeyii siwaju si ki yoo ṣeranwọ fun ète wiwulo kankan. Bi o ti wu ki o ri, ọ̀wọ̀ ara ẹni Pilatu ni a tàbùkù si nipa kikọ lati dahun, ibinu rẹ̀ si ru si Jesu pelu awọn ọrọ naa: “Iwọ ko ha ni sọrọ si mi bi? Iwọ ko ha mọ pe emi ni ọla-aṣẹ lati tu ọ silẹ mo si ni ọla-aṣẹ lati kan ọ mọgi?”
Jesu fesipada tirẹlẹtirẹlẹ pe: “Iwọ ki yoo ni ọla-aṣẹ eyikeyii rara lodisi mi ayafi bi a ba ti yọnda fifun ọ lati oke wa.” Oun ntọkasi ọla-aṣẹ ti Ọlọrun yọnda fifun awọn oluṣakoso ẹda-eniyan lati bojuto awọn àlámọ̀rí ori ilẹ-aye. Jesu fikun un pe: “Idi niyi ti ọkunrin naa ti o fa mi le ọ lọwọ fi ni ẹṣẹ giga ju.” Nitootọ, Kaifa alufaa agba naa ati awọn abaniṣebi rẹ̀ ati Judasi Iskariotu ru ẹrù ìjíhìn wiwuwo ju ti Pilatu fun iwa ti ko ba idajọ-ododo mu ti a hù si Jesu.
Nigbati Jesu tubọ wú u lórí ti o si kun fun ibẹru pe Ó le ni ipilẹṣẹ ti ọrun, Pilatu sọ awọn isapa rẹ lati tú U silẹ dọtun. Bi o ti wu ki o ri, awọn Júù fi irira kọ̀ fun Pilatu. Wọn tun ẹ̀sùn oṣelu wọn, sọ ni hihalẹ lọna arekereke pe: “Bi iwọ ba tu ọkunrin yii silẹ, iwọ kii ṣe ọrẹ Kesari. Olukuluku ẹni ti o nsọ ara rẹ di ọba sọrọ lodisi Kesari.”
Laika awọn akoba ńláǹlà naa si, Pilatu mu Jesu jade lẹẹkansi “Ẹ woo! Ọba yin!” ni oun tun fọranlọ wọn lẹẹkansii.
“Mu un lọ! Mu un lọ! Kàn án mọgi!” ni idahun ti o jade wa.
“Njẹ ki emi ki o kan ọba yin mọgi bi?” Pilatu beere pẹlu ìgbékútà.
Awọn Júù ti nimọlara ainitẹlọrun labẹ iṣakoso awọn ara Romu. Nitootọ, wọn fi tẹ̀gàtẹ̀gàn koriira ijọbalenilori Romu! Sibẹ, pẹlu àgàbàgebè awọn olori alufa wipe: “Awa ko ni ọba kan bikoṣe Kesari.”
Nitori ibẹru ipo oṣelu ati ifusi rẹ, Pilatu juwọsilẹ labẹ awọn ibeere dandangbọn aláìsimi, ti nhalẹ̀ mọ́ni lati ọdọ awọn Júù. Oun fa Jesu le wọn lọwọ. Awọn ọmọ-ogun bọ aṣọ elese-aluko lọrun Jesu wọn si fi ẹwu àwọ̀lékè rẹ wọ̀ọ́. Gẹgẹbi wọn ti ńmú Jesu lọ lati kan an mọgi, a mu ki o ru igi idaloro ti oun funrarẹ.
Ṣugbọn nisinsinyi o ti di ìyálẹ̀ta ọjọ Friday, Nisan 14; boya ọjọ́kanrí ti nsunmọ. Jesu kò foju ba oorun lati kutukutu owurọ ọjọ Thursday, oun si ti jiya iriri onirora kan tẹ̀lé omiran. O yeni pe, okun rẹ tan laipẹ labẹ ẹru igi naa. Nitorinaa ẹnikan ti nkọja lọ, Simoni kan bayii ara Kirene ni Africa, ni a fipá mu wọnú iṣẹ-isin lati bá a rùú. Gẹgẹbi wọn ti nrin lọ, ọpọ iye awọn eniyan tẹle wọn, ti o ni-ninu ọpọlọpọ obinrin ti wọn nlu ara wọn ninu ẹdun-ọkan ti wọn si ńpohùnréré ẹkun Jesu.
Ni yiyijusi awọn obinrin naa Jesu wipe: “Ẹyin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ dakẹ sisunkun fun mi. Kaka bẹẹ, ẹ sunkun fun ara yin ati fun awọn ọmọ yin; nitoripe, woo! awọn ọjọ nbọ ninu eyi ti awọn eniyan yoo wipe, ‘Alayọ ni awọn obinrin ti wọn yàgàn, ati awọn ile-ọlẹ ti ko bimọ ati ọmu ti ko fi ọyàn fun ọmọ mu!’ Nigbanaa ni wọn o bẹrẹsi wi fun awọn oke-nla pe, ‘Ṣubu lu wa!’ ati fun awọn oke-kekere, ‘Bòwá mọ́lẹ̀!’ Nitoripe bi wọn ba ṣe awọn nkan wọnyi nigbati igi jẹ tutu, kinni yoo waye nigbati o ba gbẹ?”
Jesu ntọkasi igi orilẹ-ede Júù, tí ọ̀rinrin iwalaaye ṣi nbẹ ninu rẹ nitori wiwanibẹ Jesu ati wíwà awọn aṣẹku ti wọn nigbagbọ ninu rẹ̀. Ṣugbọn nigbati a ba mu awọn wọnyi jade kuro ninu orilẹ-ede naa, kiki igi kan ti o ti kú nipa tẹmi ni yoo ṣẹ́kù, bẹẹni, eto-ajọ ti orilẹ-ede kan ti o ti gbẹ. Óò iru idi fun sisunkun wo ni yoo wa nigbati awọn ọmọ-ogun Romu, ti wọn nṣiṣẹsin gẹgẹbi awọn tẹ́tù Ọlọrun, ba pa orilẹ-ede Júù run dahoro! Johanu 19:6-17; 18:31; Luku 23:24-31; Matiu 27:31, 32; Maaku 15:20, 21, NW.
◆ Ẹ̀sùn wo lodisi Jesu ni awọn aṣaju isin fikan an nigbati awọn ẹ̀sùn oṣelu wọn kuna lati mu eso jade?
◆ Eeṣe ti o fi dabi ẹnipe Pilatu kun fun ibẹru sii?
◆ Tani o ru ẹrù ẹṣẹ titobiju fun ohun ti o ṣẹlẹ si Jesu?
◆ Bawo ni awọn alufa ṣe mu ki Pilatu fa Jesu le wọn lọwọ fun ìyà-ikú?
◆ Kinni Jesu sọ fun awọn obinrin ti wọn nsunkun fun un, kinni o si ni lọkan nipa titọkasi igi naa gẹgẹbi eyi ti o “tutu” ati lẹhinnaa gẹgẹbi eyi ti o “gbẹ”?