Ojú-Ìwòye Kristian Nípa Ọlá-Àṣẹ
“Kò sí ọlá-àṣẹ kankan àyàfi lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.”—ROMU 13:1, NW.
1. Èéṣe tí a fi lè sọ pé Jehofa ni Ọlá-Àṣẹ Onípò Àjùlọ?
ỌLÁ-ÀṢẸ sopọ̀ mọ́ ipò jíjẹ́ Ẹlẹ́dàá. Ẹni Onípò Àjùlọ náà tí ó fi ìwàláàyè fún gbogbo ẹ̀dá, abẹ̀mí àti aláìlẹ́mìí, ni Jehofa Ọlọrun. Láìṣeéjáníkoro òun ni Aláṣẹ Onípò Àjùlọ. Àwọn Kristian tòótọ́ ṣàjọpín ìmọ̀lára àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí wọ́n polongo pé: “Oluwa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára: nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ ni wọ́n fi wà tí a sì dá wọn.”—Ìfihàn 4:11.
2. Báwo ni àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn ní ìjímìjí ṣe gbà ní ọ̀nà kan pé àwọn kò ní ẹ̀tọ́ tí ó bá ìwà ẹ̀dá mú láti jẹgàba lé ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lórí, kí sì ni Jesu sọ fún Pontiu Pilatu?
2 Òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn ní ìjímìjí gbìyànjú láti mú ọlá-àṣẹ wọn bófinmu nípa jíjẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ ọlọrun tàbí pé àwọn jẹ́ aṣojú ọlọrun kan jẹ́ mímọ̀ ọ́n sínú ara wọn pé kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó ní ẹ̀tọ́ àjogúnbá láti ṣàkóso lé àwọn ẹ̀dá ènìyàn mìíràn lórí.a (Jeremiah 10:23) Jehofa Ọlọrun ni orísun kanṣoṣo tí ó bófinmu fún ọlá-àṣẹ. Kristi sọ fún Pontiu Pilatu, gómìnà Romu ti Judea pé: “Iwọ kì bá ní ọlá-àṣẹ kankan rárá lòdì sí mi láìjẹ́ pé a ti yọ̀ǹda rẹ̀ fún ọ lati òkè wá.”—Johannu 19:11, NW.
“Kò Sí Ọlá-Àṣẹ Kankan Àyàfi Lati Ọ̀dọ̀ Ọlọrun”
3. Kí ni aposteli Paulu sọ nípa “awọn aláṣẹ onípò gíga,” àwọn ìbéèrè wo sì ni gbólóhùn ọ̀rọ̀ Jesu àti Paulu gbé dìde?
3 Aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn Kristian tí wọ́n ń gbé lábẹ́ ìjẹgàba Ilẹ̀-Ọba Romu pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ awọn aláṣẹ onípò gíga, nitori kò sí ọlá-àṣẹ kankan àyàfi lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun; awọn ọlá-àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí awọn ipò wọn aláàlà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.” (Romu 13:1, NW) Kí ni Jesu nílọ́kàn nígbà tí ó sọ pé ọlá-àṣẹ Pilatu ni a ti fifún un “lati òkè wá”? Àti pé ní ọ̀nà wo ni Paulu gbà rò pé àwọn ọlá-àṣẹ òṣèlú ti ọjọ́ rẹ̀ ni a gbé dúró sí ipò wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun? Wọ́n ha ní in lọ́kàn pé Jehofa ni ó yan ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso òṣèlú ayé yìí sí ipò wọn bí?
4. Kí ni Jesu àti Paulu pe Satani, ìjẹ́wọ́ Satani wo sì ni Jesu kò sẹ́?
4 Báwo ni èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí Jesu ti pe Satani ní “olùṣàkóso ayé yii,” tí aposteli Paulu sì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọlọrun ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii”? (Johannu 12:31; 16:11; 2 Korinti 4:4, NW) Síwájú síi, nígbà tí ó ń dán Jesu wò, Satani fi “ọlá-àṣẹ” lórí “gbogbo ilẹ̀-ọba ayé” lọ̀ ọ́, ní jíjẹ́wọ́ pé ọlá-àṣẹ yìí ni a ti fifún òun. Jesu kọ ìfilọni yìí, ṣùgbọ́n kò sẹ́ ẹ pé irú ọlá-àṣẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti Satani láti fifúnni.—Luku 4:5-8.
5. (a) Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lóye àwọn ọ̀rọ̀ Jesu àti Paulu nípa ọlá-àṣẹ ẹ̀dá ènìyàn? (b) Ní ọ̀nà wo ni àwọn ọlá-àṣẹ onípò gíga fi “dúró sí awọn ipò wọn aláàlà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun”?
5 Jehofa fi ipò ìṣàkóso lórí ayé yìí lé Satani lọ́wọ́ nípa yíyọ̀ọ̀da fún un láti wàláàyè lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ àti lẹ́yìn tí ó ti tan Adamu àti Efa jẹ tí ó sì ti mú kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí ipò ọba aláṣẹ Òun. (Genesisi 3:1-6; fiwé Eksodu 9:15, 16.) Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ Jesu àti ti Paulu gbọ́dọ̀ túmọ̀sí pé lẹ́yìn tí tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ní Edeni ti kọ ìṣàkóso Ọlọrun, tàbí àkóso Ọlọrun sílẹ̀, Jehofa fàyègba ẹ̀dá ènìyàn tí a sọdàjèjì láti dá àwọn ìṣètò ọlá-àṣẹ tí yóò yọ̀ọ̀da fún wọn láti gbé nínú ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí ó wà létòlétò sílẹ̀. Ní àwọn ìgbà mìíràn, Jehofa ti mú kí àwọn alákòóso tàbí àkóso kan kùnà nítorí àtilè mú ète rẹ̀ ṣẹ. (Danieli 2:19-21) Ó sì ti fàyègba àwọn mìíràn láti máa bá ìjọba nìṣó. A lè sọ nípa ti àwọn alákòóso tí Jehofa fàyègba wíwà wọn pé “a gbé [wọn] dúró sí awọn ipò wọn aláàlà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.”
Àwọn Kristian Ìjímìjí àti Àwọn Ọlá-Àṣẹ Romu
6. Ojú wo ni àwọn Kristian ìjímìjí fi wo àwọn ọlá-àṣẹ Romu, èésìtiṣe?
6 Àwọn Kristian ìjímìjí kò pawọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ya ìsìn Ju tí wọ́n di tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun tí wọ́n sì bá àwọn ọmọ ogun Romu tí wọ́n gba ilẹ̀ Israeli jà. Níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé àwọn ọlá-àṣẹ Romu, pẹ̀lú ètò ìgbékalẹ̀ òfin alákọsílẹ̀ wọn, rí i dájú pé gbogbo nǹkan wà létòlétò lórí ilẹ̀ àti lójú òkun; tí wọ́n gbẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn ojú ìṣàn omi àfọwọ́là, tí wọ́n la àwọn ọ̀nà, tí wọ́n sì kọ́ àwọn afárá wíwúlò; tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lápapọ̀ fún ire gbogbo ènìyàn, àwọn Kristian kà wọ́n sí ‘òjíṣẹ́ Ọlọrun [tàbí, “ìránṣẹ́,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé] sí wọn fún ire wọn,’ (Romu 13:3, 4, NW) Òfin àti àṣẹ ìtọ́ni ń pèsè àyíká ipò kan tí ó mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn Kristian láti wàásù ìhìnrere jákèjádò, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti pàṣẹ. (Matteu 28:19, 20) Pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn rere gbogbo, wọ́n lè san àwọn owó-orí tí àwọn Romu bù lé wọn, àní bí a bá tilẹ̀ lò díẹ̀ lára owó náà fún àwọn ète tí Ọlọrun kò tẹ́wọ́gbà.—Romu 13:5-7.
7, 8. (a) Kí ni fífarabalẹ̀ ka Romu 13:1-7 ṣípayá, kí sì ni àyíká ọ̀rọ̀ náà fihàn? (b) Lábẹ́ àwọn àyíká ipò wo ni àwọn ọlá-àṣẹ Romu kìí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “òjíṣẹ́ Ọlọrun,” àti pé nínú ọ̀ràn yìí ìṣarasíhùwà wo ni àwọn Kristian ìjímìjí mú dàgbà?
7 Fífarabalẹ̀ ka àwọn ẹsẹ̀ méje àkọ́kọ́ nínú Romu orí 13 (NW) ṣí i payá pé “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ti òṣèlú jẹ́ “òjíṣẹ́ Ọlọrun” láti yin àwọn wọnnì ti wọ́n bá ṣe rere àti láti fìyàjẹ àwọn wọnnì tí wọ́n bá ń ṣe ohun búburú. Àyíká ọ̀rọ̀ náà fihàn pé Ọlọrun ni ń pinnu ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú, kìí ṣe àwọn ọlá-àṣẹ onípò gíga náà. Nítorí náà, bí olú-ọba Romu tàbí ọlá-àṣẹ òṣèlú èyíkéyìí mìíràn bá béèrè àwọn nǹkan tí Ọlọrun kàléèwọ̀ tàbí, ní ìdàkejì, bí òun bá ka àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè fún léèwọ̀, kò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọrun mọ́. Jesu wí pé: “Ẹ fi ohun tíí ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” (Matteu 22:21) Bí Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Romu bá béèrè àwọn nǹkan tíí ṣe ti Ọlọrun, bí ìjọsìn tàbí ìwàláàyè ẹni, àwọn Kristian tòótọ́ ń tẹ̀lé ìmọ̀ràn aposteli náà pé: “Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.”—Iṣe 5:29, NW.
8 Kíkọ̀ tí àwọn Kristian ìjímìjí kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn olú-ọba àti ìbọ̀rìṣà, láti máṣe kọ àwọn ìpàdé Kristian wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì ṣíwọ́ wíwàásù ìhìnrere mú inúnibíni wá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó gbàgbọ́ pé aposteli Paulu ni a ṣekúpa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ìtọ́ni Olu-Ọba Nero. Àwọn olú-ọba mìíràn, ní pàtàkì Domitian, Marcus Aurelius, Septimius Severus, Decius, àti Diocletian, pẹ̀lú ṣenúnibíni sí àwọn Kristian ìjímìjí. Nígbà tí àwọn olú-ọba wọ̀nyí àti àwọn ọlá-àṣẹ tí ó jẹ́ ìsọ̀ǹgbè wọn ṣenúnibíni sí àwọn Kristian, ó dájú pé wọn kò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “òjíṣẹ́ Ọlọrun.”
9. (a) Kí ni ó ṣì jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀ nípa àwọn ọlá-àṣẹ òṣèlú, láti ọ̀dọ̀ tá sì ni ẹranko ẹhànnà ti òṣèlú náà ti gba agbára àti ọlá-àṣẹ? (b) Lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mu kí ni a lè sọ nípa ìtẹríba Kristian fún àwọn ọlá-àṣẹ onípò gíga?
9 Gbogbo èyí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àkàwé pé nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọlá-àṣẹ onípò giga ti òṣèlú ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà kan gẹ́gẹ́ bí “ìṣètò Ọlọrun” láti rí i dájú pé ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó wà létòlétò ń báa lọ, wọ́n ṣì jẹ́ apákan ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ayé èyí tí Satani jẹ́ ọlọrun fún. (1 Johannu 5:19) Wọ́n jẹ́ apákan ètò-àjọ òṣèlú kárí-ayé tí “ẹranko ẹhànnà” inú ìwé Ìfihàn 13:1, 2 (NW) ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Ẹranko yẹn gba agbára àti ọlá-àṣẹ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ “dragoni ńlá naa,” Satani Eṣu. (Ìfihàn 12:9) Nítorí náà, lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mú, ìtẹríba Kristian kan fún irú àwọn ọlá-àṣẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláàlà, kìí ṣe pátápátá.—Fiwé Danieli 3:16-18.
Ọ̀wọ̀ Yíyẹ fún Ọlá-Àṣẹ
10, 11. (a) Báwo ni Paulu ṣe fihàn pé a gbọ́dọ̀ ní ọ̀wọ̀ fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ nípò ọlá-àṣẹ? (b) Báwo àti lọ́nà wo ni a fi lè gbàdúrà “nípa awọn ọba ati gbogbo awọn wọnnì tí wọn wà ní ibi ipò gíga”?
10 Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò túmọ̀sí pé àwọn Kristian níláti mú ìṣarasíhùwà onímòójúkuku, àti ìṣàyàgbàǹgbà dàgbà sí àwọn ọlá-àṣẹ òṣèlú onípò gíga. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ọ̀wọ̀ kò yẹ fún ní pàtàkì níti ìgbésí-ayé wọn ní kọ́lọ́fín, tàbí ní gbangba. Síbẹ̀, nípasẹ̀ àpẹẹrẹ àti ìmọ̀ràn wọn, àwọn aposteli fihàn pé àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ipò ọlá-àṣẹ ní a gbọ́dọ̀ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá lò. Nígbà tí Paulu farahàn níwájú Ọba Herodu Agrippa Kejì tí ó fẹ́ ìbátan rẹ̀ obìnrin, ó báa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ yíyẹ.—Iṣe 26:2, 3, 25.
11 Paulu tilẹ̀ sọ pé ó jẹ́ ohun yíyẹ láti mẹ́nukan àwọn ọlá-àṣẹ ayé nínú àwọn àdúrà wa, ní pàtàkì nígbà tí a bá késí wọ́n láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó kan ìgbésí-ayé wa àti àwọn ìgbòkègbodò Kristian. Ó kọ̀wé pé: “Nitori naa mo gbani níyànjú, ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, àdúrà, ìbẹ̀bẹ̀fúnni, ọrẹ-ẹbọ ọpẹ́, nipa gbogbo onírúurú ènìyàn, nipa awọn ọba ati gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ní ibi ipò gíga; kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí-ayé píparọ́rọ́ ati dídákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹlu ìfọkànsin Ọlọrun kíkún ati ìwà àgbà. Èyí dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Olùgbàlà wa, Ọlọrun, ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́-inú rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọn sì wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.” (1 Timoteu 2:1-4, NW) Ìṣarasíhùwà wa tí ó fi ọ̀wọ̀ hàn fún irú àwọn ọlá-àṣẹ bẹ́ẹ̀ lè mú kí wọ́n yọ̀ọ̀da wa láti túbọ̀ máa fi òmìnira fàlàlà bá iṣẹ́ wa ti gbígbìyànjú láti gba “gbogbo onírúurú ènìyàn” là nìṣó.
12, 13. (a) Ìmọ̀ràn wíwàdéédéé wo ni Peteru fifúnni nípa ọlá-àṣẹ? (b) Báwo ni a ṣe lè sọ ‘ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú’ tí wọ́n dá ẹ̀tanú sílẹ̀ lòdìsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa di èyí tí kò gbéṣẹ́?
12 Aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Nitori Oluwa ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ṣẹ̀dá: yálà sábẹ́ ọba gẹ́gẹ́ bí onípò gíga tabi sábẹ́ awọn gómìnà gẹ́gẹ́ bí awọn tí oun rán lati fi ìyà jẹ awọn aṣebi ṣugbọn lati yin awọn olùṣe rere. Nitori bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́, pé nipa ṣíṣe rere kí ẹ̀yin lè dí ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan mọ́ awọn aláìlọ́gbọ́n-nínú lẹ́nu. Ẹ wà gẹ́gẹ́ bí awọn ẹni òmìnira, síbẹ̀ kí ẹ sì di òmìnira yín mú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí bojúbojú kan fún ìwà búburú, bíkòṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọrun. Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọrun, ẹ máa fi ọlá fún ọba.” (1 Peteru 2:13-17, NW) Ẹ wo bí ìmọ̀ràn yìí ti wàdéédéé tó! A jẹ Ọlọrun ní gbèsè ìtẹríba pátápátá gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀, a sì ń fún àwọn ọlá-àṣẹ òṣèlú tí a rán láti fìyàjẹ àwọn aṣebi ní ìtẹríba aláàlà àti ọlọ́wọ̀.
13 A ti ríi pé ọ̀pọ̀ àwọn ọlá-àṣẹ ti ayé ni wọ́n ní èrò àṣìrò tí kò báradé rárá nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Èyí máa ń sábà jẹ́ nítorí pé àwọn aláràn-án-kàn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn ènìyàn Ọlọrun máa ń fún wọn ní ìsọfúnni tí ó lòdì. Tàbí ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ nípa wa ni wọ́n rígbọ́ láti inú ìròyìn, tí wọn kìí ṣaláì múkan-mọ́kan nínú ohun tí wọ́n ń sọ. Ní àwọn ìgbà mìíràn a lè wó ẹ̀tanú yìí palẹ̀ nípa ìṣarasíhùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wa àti, níbi tí ó bá ti ṣeéṣe, nípa fífún àwọn ọlá-àṣẹ náà ní àwòrán títọ̀nà nípa iṣẹ́ àti èrò-ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìwé pẹlẹbẹ náà Jehovah’s Witnesses in the Twentieth Century pèsè àkópọ̀ àlàyé ṣókí fún àwọn ìjòyè òṣìṣẹ́ tí ọwọ́ wọn dí. Fún ìsọfúnni kíkún síi, a lè pèsè ìwé náà Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom fún wọn, irin-iṣẹ́ àtàtà kan tí ó yẹ kí ó ní àyè kan lórí pẹpẹ ìkówèésí ti àwọn ibi àkójọ ìwé kíkà ti àdúgbò àti ti orílẹ̀-èdè.
Ọlá-Àṣẹ Nínú Ilé Àwọn Kristian
14, 15. (a) Orí kí ni a gbé ọlá-àṣẹ láàárín agbo-ilé Kristian kan kà? (b) Kí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn aya Kristian sí àwọn ọkọ wọn, èésìtiṣe?
14 Kò ní sísọ mọ́ pé bí Ọlọrun bá béèrè pé kí àwọn Kristian fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fún àwọn ọlá-àṣẹ ti ayé, wọ́n tún níláti bọ̀wọ̀ fún ìṣètò ọlá-àṣẹ tí Ọlọrun fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú àwọn agbo-ilé Kristian bákan náà. Aposteli Paulu ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ àkópọ̀ àlàyé ṣókí nípa ìlànà ipò orí tí ń siṣẹ́ láàárín àwọn ènìyàn Jehofa. Ó kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé, Kristi ni orí olúkúlùkù ọkùnrin; orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀; àti orí Kristi sì ní Ọlọrun.” (1 Korinti 11:3, NW) Èyí ni ìlànà ti ìṣàkóso Ọlọrun, tàbí àkóso Ọlọrun. Kí ni ó wémọ́ ọn?
15 Nínú ilé ni ọ̀wọ̀ fún ìṣàkóso Ọlọrun ti ń bẹ̀rẹ̀. Aya Kristian kan tí kìí fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn fún ọlá-àṣẹ ọkọ rẹ̀—yálà òun jẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́—kò hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣàkóso Ọlọrun. Paulu gba àwọn Kristian nímọ̀ràn pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún ara yín lẹ́nìkínní kejì ninu ìbẹ̀rù Kristi. Kí awọn aya wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Oluwa, nitori pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti jẹ́ orí ìjọ, bí oun ti jẹ́ olùgbàlà ara yii. Níti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti wà ní ìtẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí awọn aya pẹlu wà fún awọn ọkọ wọn ninu ohun gbogbo.” (Efesu 5:21-24, NW) Bí ó ti jẹ́ pé àwọn Kristian ọkùnrin gbọ́dọ̀ tẹríba fún ipò orí Kristi, àwọn Kristian obìnrin gbọ́dọ̀ mọ ọgbọ́n tí ń bẹ nínú títẹríba fún ọlá-àṣẹ tí Ọlọrun fifún àwọn ọkọ wọn. Èyí yóò mú ìtẹ́lọ́rùn inú lọ́hùn-ún tí ó jinlẹ̀ wá, àti èyí tí ó ṣe pàtàkì jù, ìbùkún Jehofa.
16, 17. (a) Báwo ni àwọn ọmọ tí a tọ́ dàgbà nínú ilé Kristian ṣe lè ya araawọn sọ́tọ̀ gédégbé láàárín ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lónìí, ìsúnniṣe wo ni wọ́n sì ní? (b) Báwo ni Jesu ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọ̀dọ́ lónìí, kí sì ni a fún wọn ní ìṣírí láti ṣe?
16 Àwọn ọmọ tí ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun láyọ̀ láti fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fún àwọn òbí wọn. A ti sọtẹ́lẹ̀ nípa ìran àwọn ọ̀dọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn pé wọ́n yóò jẹ́ “aṣàìgbọ́ràn sí òbí.” (2 Timoteu 3:1, 2) Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ onímìísí ti Ọlọrun sọ fún àwọn ọmọ Kristian pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigidi nínú Oluwa.” (Kolosse 3:20) Ọ̀wọ̀ fún ọlá-àṣẹ àwọn òbí dùnmọ́ Jehofa nínú ó sì ń mú àwọn ìbùkún wá.
17 Èyí ni a ṣàkàwé rẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Jesu. Àkọsílẹ̀ Luku sọ pé: “Ó sì bá wọn [àwọn òbí rẹ̀] sọ̀kalẹ̀ lọ wọ́n sì wá sí Nasareti, ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn. . . . Jesu sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ninu ọgbọ́n ati ninu ìdàgbàsókè ti ara-ìyára ati ninu ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọrun ati ènìyàn.” (Luku 2:51, 52, NW) Jesu jẹ́ ọmọ ọdún 12 ní ìgbà náà, irú ọ̀rọ̀-ìṣe Griki náà tí a lò níhìn-ín sì tẹnumọ́ ọn pé ó “ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́” àwọn òbí rẹ̀. Nítorí náà ìtẹríba rẹ̀ kò dópin nígbà tí ó di ọ̀dọ́langba. Bí ẹ̀yin ọ̀dọ́ bá fẹ́ láti tẹ̀síwájú nínú ipò tẹ̀mí àti nínú níní ojúrere pẹ̀lú Jehofa àti àwọn ènìyàn olùfọkànsin Ọlọrun, ẹ óò fi ọ̀wọ̀ hàn fún ọlá-àṣẹ nínú àti lẹ́yìn-òde ilé yín.
Ọlá-Àṣẹ Láàárín Ìjọ
18. Ta ni Orí ìjọ Kristian, ta ni ó sì ti yan ọlá-àṣẹ lé lọ́wọ́?
18 Ní sísọ̀rọ̀ nípa àìní náà fún àṣẹ ìtọ́ni láàárín ìjọ Kristian, Paulu kọ̀wé pé: “Nitori Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun rúdurùdu, bíkòṣe ti àlàáfíà. . . . Ṣugbọn kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà bíbójúmu ati nipa ìṣètò [tàbí, “ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìtọ́ni,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé].” (1 Korinti 14:33, 40, NW) Fún ohun gbogbo láti lè wà nípa ìṣètò, Kristi, Orí ìjọ Kristian, ti yan ọlá-àṣẹ lé àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ lọ́wọ́. A kà pé: “Ó sì fúnni ní awọn kan gẹ́gẹ́ bí aposteli, awọn kan gẹ́gẹ́ bí wòlíì, awọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, awọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn ati olùkọ́, lati lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà awọn ẹni mímọ́, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ . . . Ṣugbọn ní sísọ òtítọ́, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè ninu ohun gbogbo sínú ẹni naa tí í ṣe orí, Kristi.”—Efesu 4:11, 12, 15, NW.
19. (a) Ta ni Kristi ti yànsípò lórí àwọn ohun ìní rẹ̀ ti orí ilẹ̀-ayé, ta ni ó sì ti fún ní àkànṣe ọlá-àṣẹ? (b) Fífi ọlá-àṣẹ fúnni wo ni ó wáyé nínú ìjọ Kristian, kí sì ni èyí béèrè fún lọ́wọ́ wa?
19 Ní àkókò òpin yìí, Kristi ti yan àpapọ̀ “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” sípò “lórí gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀,” tàbí àwọn ire Ìjọba lórí ilẹ̀-ayé. (Matteu 24:45-47, NW) Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, ẹrú yìí ni ẹgbẹ́ olùṣàkóso tí àwọn Kristian ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni-àmì-òróró ń ṣojú fún, àwọn ẹni tí Kristi ti fi ọlá-àṣẹ fún láti ṣe àwọn ìpinnu àti láti yan àwọn alábòójútó mìíràn. (Iṣe 6:2, 3; 15:2) Ní ìdàkejì, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fi ọlá-àṣẹ fún Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó àgbègbè àti àyíká, àti àwọn alàgbà láàárín ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó ju 73,000 lọ jákèjádò ilẹ̀-ayé. Gbogbo àwọn Kristian ọkùnrin olùfọkànsìn wọ̀nyí yẹ fún ìtìlẹ́yìn àti ọ̀wọ̀ wa.—1 Timoteu 5:17.
20. Àpẹẹrẹ wo ni ó fihàn pè inú Jehofa kò dùn sí àwọn wọnnì tí wọn kò bá ní ọ̀wọ̀ fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń bẹ nípò ọlá-àṣẹ?
20 Níti ọ̀wọ̀ tí a jẹ àwọn wọnnì tí ń bẹ nípò ọlá-àṣẹ láàárín ìjọ Kristian ní gbèsè rẹ̀, a lè ṣe ìfiwéra kan tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ sókè pẹ̀lú ìtẹríba tí a jẹ àwọn ọlá-àṣẹ ayé ní gbèsè rẹ̀. Nígbà tí ẹnìkan bá tẹ òfin ènìyàn kan tí Ọlọrun tẹ́wọ́gbà lójú, ìyà tí “awọn wọnnì tí ń ṣàkóso” bá fi jẹ ẹ́, níti tòótọ́ jẹ́ ìfihànjáde ìrunú Ọlọrun lọ́nà tí kò ṣe tààràtà “sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣèwàhù.” (Romu 13:3, 4, NW) Bí Jehofa bá bínú nígbà tí ẹnìkan bá rú òfin ènìyàn tí kò sì fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fún àwọn ọlá-àṣẹ ayé, ẹ wo bí kì yóò ti mú inú rẹ̀ dùn tó bí Kristian olùṣèyàsímímọ́ kan bá tẹ́ḿbẹ́lú àwọn ìlànà Bibeli tí ó sì fi àìlọ́wọ̀ hàn fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà ní ipò ọlá-àṣẹ!
21. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo ni àwa yóò láyọ̀ láti tẹ̀lé, kí sì ni a óò gbéyẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e?
21 Dípò kí a mú ìbínú Ọlọrun wá sórí araawa nípa mímú ìṣarasíhùwà ọlọ̀tẹ̀ àti adádúrólómìnira dàgbà, àwa yóò tẹ̀lé ìmọ̀ràn Paulu sí àwọn Kristian ní Filippi pé: “Nitori naa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ní ọ̀nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣugbọn nísinsìnyí pẹlu ìmúratán púpọ̀ sí i nígbà tí emi kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà tiyín yọrí pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì; nitori Ọlọrun ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ṣe ninu yín, nitori ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ baà lè ní ìfẹ́-inú kí ẹ sì gbéṣẹ́ṣe. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú ati ìjiyàn, kí ẹ lè wá jẹ́ aláìlẹ́bi ati ọlọ́wọ́mímọ́, awọn ọmọ Ọlọrun láìní àbààwọ́n kan ní àárín ìran oníwà wíwọ́ ati onímàgòmágó, láàárín awọn tí ẹ̀yin ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ ninu ayé.” (Filippi 2:12-15, NW) Láìdàbí ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó ti òde ìwòyí tí ó ti mú yánpọnyánrin ọlá-àṣẹ wá sórí araarẹ̀, àwọn ènìyàn Jehofa máa ń fi pẹ̀lú ìmúratán tẹríba fún ọlá-àṣẹ. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ kórè àǹfààní ńláǹlà, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lée.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú.
Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò
◻ Ta ni Ọlá-Àṣẹ Onípò Àjùlọ, èésìtiṣe tí ọlá-àṣẹ rẹ̀ fi bófinmu?
◻ Ní ọ̀nà wo ni àwọn ọlá-àṣẹ onípò gíga fi “dúró sí awọn ipò wọn aláàlà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun”?
◻ Nígbà wo ni àwọn ọlá-àṣẹ onípò gíga ṣíwọ́ láti máa jẹ́ “òjíṣẹ́ Ọlọrun”?
◻ Ìṣètò ọlá-àṣẹ wo ni ó wà láàárín àwọn ìdílé Kristian?
◻ Fífi ọlá-àṣẹ fúnni wo ni ó wà láàárín ìjọ Kristian?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jesu wí pé: “Ẹ fi ohun tíí ṣe ti Kesari fún Kesari”