Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ Jésù fi wu àwọn ọmọ ogun Róòmù?
Àwọn ọmọ ogun mẹ́rin tó kan Jésù mọ́gi pín ẹ̀wù rẹ̀ láàárín ara wọn. Àmọ́, ìwé Jòhánù 19:23 sọ pé: “Ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ [Jésù] kò ní ojú rírán, ó jẹ́ híhun láti òkè jálẹ̀jálẹ̀ gígùn rẹ̀.” Àwọn ọmọ ogun náà gbà láàárín ara wọn pé káwọn má ṣe ya ẹ̀wù náà, àmọ́ káwọn ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè mọ ẹni tó máa ni ín. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe ẹ̀wù yẹn?
Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi owú tàbí ọ̀gbọ̀ ṣe tó máa ń balẹ̀ dé orúnkún tàbí ọrùn ẹsẹ̀. Ẹ̀wù ńlá méjì tó dọ́gba níbùú àti lóròó ni wọ́n sábà máa ń rán mọ́ra ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àti ní apá òkè. Wọ́n máa ń fi ihò tápá máa wọ̀ sílẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì, wọ́n sì máa ń fi ihò tí orí máa wọ̀ sílẹ̀ ní òkè ẹ̀wù náà.
Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àwọn ẹ̀wù tó jẹ́ olówó ńlá náà nìyẹn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé Jesus and His World ṣe sọ, “ẹ̀wù gígùn kan tí wọ́n ṣẹ́ po sí méjì ni wọ́n máa ń lò, wọ́n á wá yọ ihò tí orí máa wọ̀ sí i ní àárín,” wọ́n á sì rán an pọ̀. Wọ́n ní láti rán irú ẹ̀wù yìí pọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì.
Àgbègbè Palẹ́sìnì nìkan ni wọ́n ti máa ń ṣe irú ẹ̀wù tí kì í lójú rírán tí Jésù wọ̀ yìí. Ọwọ́ ni wọ́n máa fi ń hun àwọn òwú tí wọ́n pín sí ọ̀nà méjì pọ̀, oríṣi òwú àkọ́kọ́ máa ń wà nídùúró gbọọrọ-gbọọrọ, wọ́n á wá hun oríṣi òwú kejì mọ́ ọn yí ká nídùbúlẹ̀. Ẹni tó ń hun ẹ̀wù náà á máa ju ohun èlò tó fi ń hun ẹ̀wù náà síwá sẹ́yìn, ìyẹn ló sì máa ń gbé oríṣi òwú tó wà nídùbúlẹ̀ yẹn lọ síwá sẹ́yìn bí ìgbà téèyàn ń hun ẹ̀wù òfì. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà hun ẹ̀wù yìí máa ń “jẹ́ kó dà bíi àgbá tó rí roboto.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun iyebíye ni ẹni tó bá ní irú ẹ̀wù tí kò lójú rírán yìí ní nígbà yẹn, abájọ tó fi wu àwọn ọmọ ogun náà.
Ṣáwọn èèyàn máa ń sin oyin ní Ísírẹ́lì àtijọ́?
Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé òun máa mú wọn dé “ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:8) Ó dà bíi pé oúnjẹ táwọn kòkòrò tó n jẹ́ oyin máa ń mú jáde ni Ìwé Mímọ́ sábà máa ń tọ́ka sí lọ́pọ̀ ìgbà tó bá sọ̀rọ̀ nípa oyin. Bíbélì ò sọ bóyá àwọn kan ní Ísírẹ́lì àtijọ́ máa ń sin oyin. Àmọ́, ohun táwọn olùṣèwádìí kan rí láìpẹ́ yìí ní Àfonífojì Bet She’an tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń gbé ní Ísírẹ́lì láyé àtijọ́ “máa ń ṣòwò oyin sísìn ní aládàá ńlá.”
Àwọn olùṣèwádìí láti Hebrew University of Jerusalem’s Institute of Archaeology rí ibì kan nílùú Tel Rehov táwọn kan ti máa ń sin oyin ní ọ̀rúndún kẹwàá sí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn sì jẹ́ àwọn àkókò tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jọba nílùú Ísírẹ́lì. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí táwọn olùṣèwádìí máa rí àwọn ilé oyin ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Wọ́n sọ pé ilé tí wọ́n kọ́ tí wọ́n máa ń kó àgbá tí wọ́n fi ń sin oyin sí gba ọgọ́rùn-ún [100] kan àgbá oyin tí wọ́n tò tẹ̀ léra wọn, tí wọ́n sì tún gbé ó kéré tán àgbá oyin mẹ́ta-mẹ́ta lé orí ara wọn.
Àwọn olùṣèwádìí tí wọ́n wá láti Hebrew University of Jerusalem sọ pé, “amọ̀ tí wọn ò tíì finá sun ni wọ́n fi ṣe àgbá oyin kọ̀ọ̀kan . . . àgbá náà ga tó nǹkan bí ẹsẹ bàtà méjì àtààbọ̀, ó sì fẹ̀ díẹ̀ ju ẹsẹ̀ bàtà kàn lọ. . . . Àwọn tó mọ̀ nípa oyin sísìn àtàwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n lọ ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ fojú bù ú pé oyin táá máa jáde lọ́dọọdún nínú àwọn ilé oyin yìí á fẹ́rẹ̀ẹ́ kún àgbá méjì àtààbọ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ibi tí wọ́n ti ń sin oyin nílùú Tel Rehov
[Credit Line]
Látọwọ́: Institute of Archaeology/Hebrew University © Tel Rehov Excavations