ORÍ 26
“Kò sí Ìkankan Lára Yín Tó Máa Ṣègbé”
Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó lágbára òun sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn nígbà tí ọkọ̀ tó wọ̀ rì
Ó dá lórí Ìṣe 27:1–28:10
1, 2. Ìrìn àjò wo ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ rìn, àwọn nǹkan wo ló sì ṣeé ṣe kó máa rò lọ́kàn?
PỌ́Ọ̀LÙ ń ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ, torí pé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn máa ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù lọ́jọ́ iwájú. Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Késárì ni wàá sì lọ.” Pọ́ọ̀lù ti lo ọdún méjì ní àhámọ́ báyìí, torí náà ìrìn àjò tó jìn tí wọ́n fẹ́ rìn lọ sí Róòmù máa mú kára tù ú díẹ̀. (Ìṣe 25:12) Bó tiẹ̀ jẹ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń wọ ọkọ̀ òkun tó bá ń rìnrìn àjò, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìrìn àjò náà máa ń tura. Yàtọ̀ síyẹ̀n, ọkàn Pọ́ọ̀lù lè má balẹ̀ bó ṣe mọ̀ pé òun fẹ́ lọ jẹ́jọ́ níwájú Késárì, oríṣiríṣi nǹkan ló sì ṣeé ṣe kó máa rò lọ́kàn.
2 Ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ̀mí Pọ́ọ̀lù ti wà nínú “ewu lójú òkun.” Bí àpẹẹrẹ, ìgbà mẹ́ta ló wọkọ̀ tó rì, kódà ọ̀sán kan àti òru kan ló lò lórí agbami òkun. (2 Kọ́r. 11:25, 26) Bákan náà, ìrìn àjò yìí yàtọ̀ sí èyí tó ti ń rìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì nígbà tí wọn ò tíì fi í sẹ́wọ̀n. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Pọ́ọ̀lù ti wà lẹ́wọ̀n, ó sì máa rìnrìn àjò ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) kìlómítà láti Kesaríà lọ sí Róòmù. Ṣó máa lè rin ìrìn àjò yìí láìséwu? Tó bá tiẹ̀ débẹ̀ láyọ̀, ṣé ó mọ̀ bóyá wọ́n máa dájọ́ ikú fóun? Ẹ má gbàgbé pé ìjọba tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn ló máa gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀.
3. Kí ni Pọ́ọ̀lù pinnu pé òun máa ṣe, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń rónu nípa ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ sí i, ṣé o rò pé Pọ́ọ̀lù wá sọ̀rètí nù tàbí kó wá máa bẹ̀rù torí ohun tó lè ṣẹlẹ̀? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀! Ó mọ̀ pé òun máa láwọn ìṣòro kan, àmọ́ kò mọ ọ̀nà tó máa gbà wá. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kò sí àǹfààní kankan nínú kóun máa ṣàníyàn nípa ìṣòro tóun ò lè yanjú, ó sì mọ̀ pé tóun bá ṣàníyàn jù, òun lè má láyọ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun. (Mát. 6:27, 34) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kóun wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn alákòóso. (Ìṣe 9:15) Pọ́ọ̀lù ti pinnu pé kò sí ohun tó máa dí òun lọ́wọ́ kóun má ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fóun. Ṣé kì í ṣe ìpinnu tiwa náà nìyẹn? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìrìn àjò ojú òkun tó gbàfiyèsí tí Pọ́ọ̀lù rìn, ká sì wo ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a lè rí kọ́ látibẹ̀.
“Ẹ̀fúùfù . . . Dojú Kọ Wá” (Ìṣe 27:1-7a)
4. Irú ọkọ̀ òkun wo ni Pọ́ọ̀lù wọ̀ níbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀, àwọn wo ló sì wà pẹ̀lú rẹ̀?
4 Wọ́n ní kí ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Júlíọ́sì máa bójú tó Pọ́ọ̀lù àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n míì, ọ̀gágun náà sì pinnu láti wọ ọkọ̀ òkun àwọn oníṣòwò tó gúnlẹ̀ sí Kesaríà. Èbúté Adiramítíúmù tó wà ní ìwọ̀ oòrùn etíkun Éṣíà Kékeré lọkọ̀ náà ti wá, ìyẹn ní òdìkejì ìlú Mítílénè ní erékùṣù Lesbos. Ọkọ̀ òkun yìí máa ń lọ láti àríwá sí ìwọ̀ oòrùn, ó máa ń dúró já ẹrù ó sì tún máa ń kó àwọn ẹrù míì. Wọn ò ṣe àwọn ọkọ̀ òkun yìí láti máa kó èrò, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n. (Wo àpótí náà, “Ọkọ̀ Òkun Táwọn Oníṣòwò Máa Ń Wọ̀.”) Ó dájú pé ọkàn Pọ́ọ̀lù máa balẹ̀ pé òun nìkan kọ́ ni Kristẹni láàárín àwọn ọ̀daràn yẹn. Ó kéré tán, àwọn arákùnrin méjì wà pẹ̀lú ẹ̀, ìyẹn Àrísítákọ́sì àti Lúùkù. Kódà, Lúùkù ló kọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. A ò mọ̀ bóyá àwọn arákùnrin adúróṣinṣin yìí ló san owó ọkọ̀ wọn tàbí ńṣe ni wọ́n wọkọ̀ náà lọ́fẹ̀ẹ́ torí pé ìránṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ni wọ́n.—Ìṣe 27:1, 2.
5. Àwọn wo ni Pọ́ọ̀lù rí ní Sídónì, ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa?
5 Lẹ́yìn ọjọ́ kan tí wọ́n ti wà lójú òkun, tí wọ́n sì ti rin nǹkan bí àádọ́fà (110) kìlómítà sí apá àríwá, ọkọ̀ òkun náà gúnlẹ̀ sí Sídónì tó wà létíkun Síríà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ọmọ ìlú Róòmù, tí wọn ò sì tíì dá a lẹ́bi ni ò jẹ́ kí Júlíọ́sì hùwà sí i bí wọ́n ṣe máa ṣe sáwọn ọ̀daràn. (Ìṣe 22:27, 28; 26:31, 32) Júlíọ́sì jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀ lọ wo àwọn ará. Ẹ ò rí i pé inú àwọn ará yẹn á dùn gan-an láti tọ́jú àpọ́sítélì yìí lẹ́yìn tó ti pẹ́ lẹ́wọ̀n! Ṣéwọ náà lè ronú nípa ohun tó o lè ṣe láti fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ará? Tó o bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará, ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa rí.—Ìṣe 27:3.
6-8. Àwọn ìlú wo ni Pọ́ọ̀lù lọ lẹ́yìn tó kúrò ní Sídónì, àǹfààní wo ló sì jọ pé Pọ́ọ̀lù ní láti wàásù?
6 Ọkọ̀ òkun náà gbéra kúrò ní Sídónì, ó ń tọ etíkun náà lọ títí tó fi kọjá ìlú Sìlíṣíà tó wà nítòsí Tásù tó jẹ́ ìlú Pọ́ọ̀lù. Lúùkù ò sọ pé ọkọ̀ náà dúró níbòmíì, àmọ́ ó sọ ohun kan tó fi hàn pé wọ́n wà nínú ewu, ó ní: “Ẹ̀fúùfù . . . dojú kọ wá.” (Ìṣe 27:4, 5) Síbẹ̀, pẹ̀lú bí nǹkan ò ṣe rọrùn fún Pọ́ọ̀lù, a lè fojú inú wo bó ṣe ń lo gbogbo àǹfààní tó ní láti wàásù ìhìn rere. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù wàásù fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn míì tó wà nínú ọkọ̀, títí kan àwọn òṣìṣẹ́, àwọn ọmọ ogun àtàwọn tó pàdé láwọn èbúté tọ́kọ̀ ń gúnlẹ̀ sí. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó yẹ káwa náà máa lo àwọn àǹfààní tá a bá ní láti wàásù ìhìn rere.
7 Nígbà tó yá, ọkọ̀ náà dé èbúté Máírà tó wà ní gúúsù etíkun Éṣíà Kékeré. Ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó kù ti wọ ọkọ̀ òkun míì tó máa gbé wọn dé ibi tí wọ́n ń lọ gangan, ìyẹn ìlú Róòmù. (Ìṣe 27:6) Láyé ìgbà yẹn, àwọn ará Róòmù máa ń ra ọ̀pọ̀ ọkà lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, ìlú Máírà sì lọkọ̀ òkun táwọn ará Íjíbítì fi ń kó ọkà náà máa ń gúnlẹ̀ sí. Júlíọ́sì wá irú ọkọ̀ òkun bẹ́ẹ̀, ó sì ní káwọn ọmọ ogun àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n wọ ọkọ̀ náà. Ó dájú pé ọkọ̀ òkun yìí tóbi ju èyí tí wọ́n kọ́kọ́ wọ̀ lọ. Ó kó wíìtì tó pọ̀ gan-an pẹ̀lú àwọn èrò bí àwọn òṣìṣẹ́, àwọn ọmọ ogun, àwọn ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn èèyàn míì tó ń lọ sí Róòmù. Iye wọn sì jẹ́ igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (276). Ní báyìí tí wọ́n ti wọ ọkọ̀ òkun míì, Pọ́ọ̀lù tún rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó lè wàásù fún, ó sì dájú pé ó lo àǹfààní yìí dáadáa.
8 Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dúró ní ìlú Kínídọ́sì tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré. Tí ojú ọjọ́ bá dáa, kò lè gba ọkọ̀ òkun ju ìrìn ọjọ́ kan lọ. Àmọ́ Lúùkù sọ pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí a ti rọra ń tukọ̀ bọ̀, a dé Kínídọ́sì tipátipá.” (Ìṣe 27:7a) Kò rọrùn rárá láti tukọ̀ torí ẹ̀fúùfù tó lágbára yẹn. (Wo àpótí náà, “Ẹ̀fúùfù Líle Lórí Òkun Mẹditaréníà.”) Ronú nípa bó ṣe máa nira tó fáwọn èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ òkun náà, bí wọ́n ṣe ń tukọ̀ gba àárín omi òkun tó ń ru gùdù àti ẹ̀fúùfù tó lágbára gan-an.
“Ìjì Líle Náà Ń Fi Agbára Gbá Wa Síwá-Sẹ́yìn” (Ìṣe 27:7b-26)
9, 10. Àwọn ìṣòro wo ló dojú kọ wọ́n lágbègbè Kírétè?
9 Ọ̀gá àwọn atukọ̀ náà pinnu pé àwọn á máa bá ìrìn àjò lọ lápá ìwọ̀ oòrùn láti Kínídọ́sì, àmọ́ Lúùkù tọ́rọ̀ náà ṣojú ẹ̀ sọ pé “ẹ̀fúùfù kò jẹ́ kí a lọ tààrà.” (Ìṣe 27:7b) Bí ọkọ̀ òkun náà ṣe kúrò ní èbúté, ẹ̀fúùfù tó lágbára fẹ́ wá láti apá àríwá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọkọ̀ náà lọ sí apá gúúsù lọ́nà tó yára. Àmọ́ wọ́n gba tòsí erékùṣù Kírétè kó lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù tó le yẹn, bí erékùṣù Sápírọ́sì ṣe dáàbò bò wọ́n nígbà kan rí. Nígbà tọ́kọ̀ náà kọjá ibi òkìtì tó wà ní Sálímónè lápá ìlà oòrùn Kírétè, ẹ̀fúùfù náà rọlẹ̀ díẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọkọ̀ náà ti dé apá gúúsù erékùṣù yẹn níbi tí ẹ̀fúùfù ò ti fi bẹ́ẹ̀ lágbára. Ẹ ò rí i pé ọkàn àwọn èrò inú ọkọ̀ yẹn máa kọ́kọ́ balẹ̀ bí wọ́n ṣe bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù náà! Àmọ́, ẹ̀rù ṣì ń bà wọ́n torí pé ìgbà òtútù ti sún mọ́lé, kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn lórí òkun.
10 Lúùkù wá sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí gan-an, ó ní: “Bí a ṣe ń tukọ̀ lọ ní etíkun [Kírétè] tipátipá, a dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Èbúté Rere.” Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti wà nítòsí ilẹ̀, tí wọ́n sì ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù tó lágbára yẹn, ó ṣì ṣòro fún wọn láti tukọ̀ náà. Níkẹyìn, wọ́n ríbì kan tí ọkọ̀ náà lè gúnlẹ̀ sí, èyí tí wọ́n sọ pé ó wà lágbègbè kan ní etíkun náà. Báwo ni wọ́n ṣe pẹ́ tó níbẹ̀? Lúùkù sọ pé wọ́n lo “àkókò púpọ̀” létíkun yẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gbọ́dọ̀ pẹ́ níbẹ̀ torí ó máa ń léwu gan-an láti tukọ̀ láwọn oṣù September àti October.—Ìṣe 27:8, 9.
11. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn tó wà nínú ọkọ̀, síbẹ̀ kí ni wọ́n ṣe?
11 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé Pọ́ọ̀lù ti máa ń rìnrìn àjò gba orí òkun Mẹditaréníà kọjá làwọn èrò inú ọkọ̀ ṣe ní kó gba àwọn nímọ̀ràn. Ó wá sọ pé kí wọ́n má ṣe tẹ̀ síwájú nínú ìrìn àjò náà. Ó sọ fún wọn pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa yọrí sí “òfò àti àdánù ńlá,” kódà ẹ̀mí lè ṣòfò. Àmọ́, atukọ̀ àti ẹni tó ni ọkọ̀ fẹ́ máa bá ìrìn àjò náà lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé wọ́n fẹ́ tètè dé ibi tí kò séwu rárá ni wọ́n ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n ṣe yí Júlíọ́sì lérò pa dà nìyẹn, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn sì gbà pé kí wọ́n gbìyànjú láti dé Fóníìsì, ìyẹn èbúté kan tó ṣì wà níwájú. Ó jọ pé èbúté yẹn tóbi, ó sì máa dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ òtútù. Torí náà, nígbà tí atẹ́gùn tó dà bíi pé á jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti tukọ̀ rọra fẹ́ wá láti apá gúúsù, wọ́n ṣíkọ̀.—Ìṣe 27:10-13.
12. Ewu wo ni ọkọ̀ náà kó sí nígbà tí wọ́n kúrò ní Kírétè, kí làwọn tó ń tukọ̀ náà sì ṣe kí jàǹbá má bàa ṣẹlẹ̀?
12 Bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò náà lọ ni “ìjì líle” kan bá bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, wọ́n rí ibì kan tó wà lẹ́yìn “erékùṣù kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Káúdà,” wọ́n sì dúró síbẹ̀ fúngbà díẹ̀. Erékùṣù náà wà ní nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́rin (65) sí Èbúté Rere. Síbẹ̀, ọkọ̀ náà ṣì wà nínú ewu torí ìjì ṣì lè gbé e lọ sí apá gúúsù kó sì lọ forí sọ iyanrìn tó gbára jọ nítòsí etíkun ilẹ̀ Áfíríkà. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀, wọ́n gbé ọkọ̀ ojú omi kékeré tí wọ́n so mọ́ ọkọ̀ náà wọnú ẹ̀. Kò rọrùn fún wọn láti gbé ọkọ̀ ojú omi kékeré náà torí ó jọ pé omi ti kún inú ẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbìyànjú láti fi okùn tàbí ẹ̀wọ̀n de àwọn igi tó wà lábẹ́ ọkọ̀ okùn náà, kó lè le dáadáa. Wọ́n wá fa ìgbòkun ọkọ̀ náà sílẹ̀, ìyẹn aṣọ tí ẹ̀fúùfù máa ń fẹ́ sí kí ọkọ̀ lè máa lọ geerege, wọ́n sì gbìyànjú gan-an láti tu ọkọ̀ náà gba inú ìjì tó lágbára yẹn kọjá. Ẹ ò rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa dẹ́rù bà wọ́n gan-an! Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n dá yìí, kò sí ìyàtọ̀, torí pé ṣe ni ‘ìjì líle náà ń fi agbára gbá wọn síwá-sẹ́yìn.’ Ní ọjọ́ kẹta wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ẹrù inú ọkọ̀ náà dà sínú òkun, kí ọkọ̀ náà lè léfòó.—Ìṣe 27:14-19.
13. Báwo ni nǹkan ṣe rí nínú ọkọ̀ tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ láàárín ìgbà tí ìjì fi jà?
13 Ó dájú pé ẹ̀rù máa ba gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà gan-an. Àmọ́, ọkàn Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ò ní kú. Ìdí ni pé Olúwa ti mú kó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé ó máa wàásù ní Róòmù. Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì kan tún fìdí ìlérí náà múlẹ̀. (Ìṣe 19:21; 23:11) Síbẹ̀, ìjì líle náà ò dáwọ́ dúró fún odindi ọ̀sẹ̀ méjì tọ̀sántòru. Àwọn tó ń tukọ̀ náà kò ríran láti mọ ibi tọ́kọ̀ náà wà àti ibi tó forí lé torí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá àti ojú ọjọ́ tó ṣú dùdù tó bo oòrùn àti ìràwọ̀. Ká sòótọ́, ẹnu wọn á kọ oúnjẹ! Torí bí òtútù ṣe ń mú wọn, bẹ́ẹ̀ ni òjò ń rọ̀, tí èébì ń gbé wọn, tẹ́rù sì ń bà wọ́n.
14, 15. (a) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn tí wọ́n jọ wọkọ̀ sọ̀rọ̀, kí nìdí tó fi mẹ́nu kan ìkìlọ̀ tó fún wọn ṣáájú? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ?
14 Pọ́ọ̀lù dìde, ó wá rán wọn létí pé òun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀. Àmọ́ kò fọ̀rọ̀ gún wọn lára, kó wá máa sọ pé ‘kò tán, ṣebí mo sọ fún yín.’ Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ti jẹ́ káwọn èrò náà fojú ara wọn rí i pé ó yẹ káwọn ti gbàmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù. Ó sọ fún wọn pé: “Ní báyìí, mo rọ̀ yín pé kí ẹ mọ́kàn le, torí kò sí ìkankan lára yín tó máa ṣègbé, àyàfi ọkọ̀ òkun yìí.” (Ìṣe 27:21, 22) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn máa tù wọ́n lára gan-an! Inú Pọ́ọ̀lù náà á sì dùn pé ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ní kóun sọ fáwọn èrò inú ọkọ̀ náà. Èyí jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa rántí pé gbogbo èèyàn ló ṣeyebíye lójú Jèhófà. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Jèhófà . . . kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká sa gbogbo ipá wa ká lè wàásù ọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó! Ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn wà nínú ewu, wọ́n sì ṣeyebíye lójú Jèhófà.
15 Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ti máa wàásù fáwọn èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ náà nípa bóun ṣe ń “retí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe.” (Ìṣe 26:6; Kól. 1:5) Ní báyìí tí ọkọ̀ wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rì, Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò ní kú, ó sì tún sọ ìdí tó fi dá òun lójú. Ó sọ pé: “Ní òru yìí, áńgẹ́lì Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀ . . . , dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sọ pé: ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Wàá dúró níwájú Késárì, sì wò ó! Ọlọ́run ti fún ọ ní gbogbo àwọn tí ẹ jọ wà nínú ọkọ.’ ” Pọ́ọ̀lù wá rọ̀ wọ́n pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin èèyàn, ẹ mọ́kàn le, torí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé bó ṣe sọ fún mi ló máa rí. Àmọ́ ṣá o, ọkọ̀ wa máa lọ fàyà sọlẹ̀ sí èbúté ní erékùṣù kan.”—Ìṣe 27:23-26.
“Gbogbo Wa Dórí Ilẹ̀ Láìséwu” (Ìṣe 27:27-44)
16, 17. (a) Ìgbà wo ní Pọ́ọ̀lù gbàdúrà, kí ló sì yọrí sí? (b) Báwo lọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣe ṣẹ?
16 Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n ti wà lórí omi, tẹ́rù ń bà wọ́n, tí ìjì líle náà sì ti ń gbé ọkọ̀ wọn fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti àádọ́rin (870) kìlómítà, àwọn atukọ̀ náà rí ohun kan tó fi hàn pé wọ́n ti ń sún mọ́ èbúté. Wọ́n wá ju ìdákọ̀ró sínú omi láti ẹ̀yìn ọkọ̀ náà, kí ọkọ̀ náà má bàa tún lọ síbòmíì, kí wọ́n sì lè darí ẹ̀ sí etíkun. Lẹ́yìn náà, àwọn atukọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa sá lọ, àmọ́ àwọn ọmọ ogun ò gbà kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun àtàwọn ọmọ ogun náà pé: “Láìjẹ́ pé àwọn èèyàn yìí dúró sínú ọkọ̀ òkun yìí, ẹ ò lè yè bọ́ o.” Ní báyìí tí ìgbì òkun ò gbé ọkọ̀ náà mọ́, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹun, ó fi dá wọn lójú pé kò séwu mọ́, ó sì “dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn.” (Ìṣe 27:31, 35) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbàdúrà yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún Lúùkù, Àrísítákọ́sì àtàwọn Kristẹni lóde òní. Tó o bá ń gbàdúrà níwájú àwọn èèyàn, ṣé àdúrà ẹ máa ń tù wọ́n nínú, ṣó sì máa ń fún wọn lókun?
17 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù gbàdúrà tán, ‘gbogbo wọn mọ́kàn le, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun.’ (Ìṣe 27:36) Wọ́n kó gbogbo ẹrù èso wíìtì tó wà nínú ọkọ̀ náà dà sínú òkun kó lè fúyẹ́ sí i, kó sì lè túbọ̀ léfòó lórí omi bó ṣe ń sún mọ́ etíkun. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ náà gé àwọn ìdákọ̀ró kúrò, wọ́n tú àwọn okùn tí wọ́n fi so àwọn àjẹ̀ tó máa ń wà lẹ́yìn ọkọ̀ òkun, wọ́n sì ta ìgbòkun iwájú ọkọ̀ sínú afẹ́fẹ́ kó lè túbọ̀ rọrùn fún wọn láti wa ọkọ̀ náà gúnlẹ̀. Nígbà tó yá iwájú ọkọ̀ náà fẹnu gúnlẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ iyanrìn tàbí ẹrẹ̀ ló fẹnu sọ. Lẹ́yìn náà, ìgbì bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ ìdí ọkọ̀ náà. Àwọn ọmọ ogun kan fẹ́ pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kí wọ́n má bàa sá lọ, àmọ́ Júlíọ́sì ò gbà fún wọn. Ó wá sọ pé kí gbogbo wọn lúwẹ̀ẹ́ lọ sórí ilẹ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, gbogbo àwọn èèyàn náà tí iye wọn jẹ́ igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (276) ló yè é. Bíbélì sọ pé, ‘gbogbo wọn dórí ilẹ̀ láìséwu.’ Àmọ́, ibo ni wọ́n gúnlẹ̀ sí?—Ìṣe 27:44.
“Inú Rere Àrà Ọ̀tọ̀” (Ìṣe 28:1-10)
18-20. Báwo làwọn ará Málítà ṣe fi “inú rere àrà ọ̀tọ̀” hàn, iṣẹ́ ìyanu wo ni Ọlọ́run sì fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe?
18 Erékùṣù Málítà tó wà ní gúúsù Sísílì ni gbogbo àwọn tó la ìṣẹ̀lẹ̀ yìí já gúnlẹ̀ sí. (Wo àpótí náà, “Ibo Ni Málítà Wà?”) Àwọn èèyàn tó ń sọ èdè àjèjì tí wọ́n ń gbé ní erékùṣù náà fi “inú rere àrà ọ̀tọ̀” hàn sí wọn. (Ìṣe 28:2) Wọ́n dá iná fún àwọn àlejò tó gúnlẹ̀ sí èbúté yẹn kí wọ́n lè yáná, torí pé gbogbo ara wọn ló tutù tí wọ́n sì ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Iná yìí jẹ́ kí ara wọn móoru bí òjò ṣe ń rọ̀ tí òtútù sì ń mú. Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ ìyanu kan ṣẹlẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń yáná.
19 Pọ́ọ̀lù fẹ́ ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́, torí náà ó ṣa igi díẹ̀ tó máa kó sínú iná. Ohun tó ń ṣe lọ́wọ́ nìyẹn tí ejò paramọ́lẹ̀ kan fi jáde wá. Ejò náà ṣán an, ó sì wé mọ́ ọn lọ́wọ́. Àwọn ará Málítà rò pé àwọn òòṣà wọn ló jẹ́ kí ejò náà ṣán Pọ́ọ̀lù láti fìyà jẹ ẹ́.a
20 Àwọn aráàlú tó rí i pé ejò ṣán Pọ́ọ̀lù rò pé ‘ara ẹ̀ máa wú.’ Ìwé ìwádìí kan sọ pé “ọ̀rọ̀ ìṣègùn” ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò níbí yìí nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Kò sì yani lẹ́nu pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ló wá sọ́kàn “Lúùkù oníṣègùn tó jẹ́ olùfẹ́.” (Ìṣe 28:6; Kól. 4:14) Bó ti wù kó rí, Pọ́ọ̀lù gbọn ejò olóró náà dà nù, kò sì pá a lára.
21. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Lúùkù ṣàlàyé tó fi hàn pé àkọsílẹ̀ rẹ̀ péye? (b) Iṣẹ́ ìyanu wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe, kí nìyẹn sì mú káwọn ara Málítà ṣe?
21 Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Púbílọ́sì ń gbé lágbègbè Málítà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù ní erékùṣù yẹn. Lúùkù pè é ní “olórí erékùṣù náà,” àwọn awalẹ̀pìtàn sì ti rí orúkọ oyè yìí níbi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílùú Málítà. Púbílọ́sì gba Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò lálejò fún ọjọ́ mẹ́ta. Àmọ́, ara bàbá Púbílọ́sì ò yá. Lúùkù tún ṣàlàyé irú àìsàn tó ń ṣe ọkùnrin náà lọ́nà tó péye. Ó sọ pé, ó “wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, ibà àti ìgbẹ́ ọ̀rìn ń yọ ọ́ lẹ́nu.” Pọ́ọ̀lù wá gbàdúrà fún un, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì mú un lára dá. Iṣẹ́ ìyanu yìí ya àwọn èèyàn ìlú náà lẹ́nu gan-an, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn aláìsàn míì wá sọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù kó lè wò wọ́n sàn. Wọ́n tún mú ẹ̀bùn wá fún òun àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò, kí wọ́n lè ní àwọn nǹkan tí wọ́n nílò lójú ọ̀nà.—Ìṣe 28:7-10.
22. (a) Kí ni ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ tó fi hàn pé ó mọyì ohun tí Lúùkù kọ nípa bí wọ́n ṣe rìnrìn àjò lọ sí Róòmù? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí tó kàn?
22 Òótọ́ ni gbogbo ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò nípa ìrìn àjò tí Pọ́ọ̀lù rìn lórí òkun, àkọsílẹ̀ náà sì péye. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé: “Àkọsílẹ̀ Lúùkù nípa ìrìn àjò tí Pọ́ọ̀lù rìn . . . dá yàtọ̀ torí pé àlàyé tó ṣe ló kún rẹ́rẹ́ jù lọ nínú Bíbélì. Àwọn ohun tó sọ nípa àwọn atukọ̀ ojú òkun ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe pàtó. Bákan náà, ohun tó sọ nípa bí nǹkan ṣe rí ní òkun Mẹditaréníà ti ìlà oòrùn péye,” torí náà ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ló ń ṣàkọ́sílẹ̀ gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Lúùkù ṣe ń rìnrìn àjò pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù ló ń kọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa tún rí ohun tó pọ̀ kọ sílẹ̀ nínú ìrìn àjò wọn tó kàn. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù tí wọ́n bá dé Róòmù? Ẹ jẹ́ ká wo orí tó kàn.
a Báwọn èèyàn yẹn ṣe mọ̀ pé paramọ́lẹ̀ ni ejò yẹn fi hàn pé ejò paramọ́lẹ̀ wà ní erékùṣù Málítà nígbà yẹn. Àmọ́ kò sí ejò paramọ́lẹ̀ ní erékùṣù náà mọ́ báyìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bójú ọjọ́ ṣe ń yí pa dà bọ́dún ṣe ń gorí ọdún ló fà á. Tàbí kó jẹ́ torí pé àwọn èèyàn ń pọ̀ sí i ní erékùṣù náà.