ORÍ 4
‘Àwọn Èèyàn Tí Ò Kàwé àti Gbáàtúù’
Àwọn àpọ́sítélì fìgboyà wàásù, Jèhófà sì mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí
Ó dá lórí Ìṣe 3:1–5:11
1, 2. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Pétérù àti Jòhánù ṣe nítòsí ẹnu ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì?
OÒRÙN ń tàn sórí àwọn èèyàn lọ́sàn-án ọjọ́ kan. Àwọn Júù olùfọkànsìn àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í dé sí tẹ́ńpìlì. ‘Àkókò àdúrà’ ò sì ní pẹ́ tó.a (Ìṣe 2:46; 3:1) Pétérù àti Jòhánù gba àárín àwọn èrò rẹpẹtẹ yìí kọjá lọ sítòsí ẹnu ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń pè ní Ẹlẹ́wà. Báwọn èèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́tùn lósì, tí ìró ẹsẹ̀ ń dún ní gbogbo àgbègbè tẹ́ńpìlì náà, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin alágbe kan tó yarọ látìgbà tí wọ́n ti bí i ń tọrọ bárà.—Ìṣe 3:2; 4:22.
2 Bí Pétérù àti Jòhánù ṣe ń sún mọ́ alágbe náà, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó sábà máa ń sọ nígbà tó bá ń tọrọ owó. Àwọn àpọ́sítélì náà dúró, wọ́n wo apá ibi tí ọkùnrin náà wà, ó sì rò pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ fún òun lówó. Pétérù wá sọ fún un pé: “Mi ò ní fàdákà àti wúrà, àmọ́ ohun tí mo ní ni màá fún ọ. Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì, máa rìn!” Wo bí ẹnu ṣe máa ya gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà tí Pétérù fa ọkùnrin náà sókè, tó sì dìde dúró fún ìgbà àkọ́kọ́ látọjọ́ tí wọ́n ti bí i! (Ìṣe 3:6, 7) Tún ronú nípa bí ọkùnrin náà á ṣe máa wo ẹsẹ̀ rẹ̀, táá sì máa bi ara ẹ̀ pé àbí ẹsẹ̀ òun tó rọ tẹ́lẹ̀ náà kọ́ lòun bẹ̀rẹ̀ sí í gbé níkọ̀ọ̀kan yìí? Abájọ tó fi ń fò kiri tó sì ń gbóhùn sókè bó ṣe ń yin Ọlọ́run!
3. Ẹ̀bùn pàtàkì wo ni ọkùnrin tó yarọ tẹ́lẹ̀ àti ọ̀pọ̀ èèyàn náà lè rí gbà?
3 Inú ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà níbẹ̀ dùn gan-an, wọ́n sì rọ́ lọ bá Pétérù àti Jòhánù ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Sólómọ́nì. Jésù ti dúró síbẹ̀ rí láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà táwọn èèyàn náà débẹ̀, Pétérù ṣàlàyé ìdí pàtàkì táwọn fi ṣe iṣẹ́ ìyanu náà. (Jòh. 10:23) Ó nawọ́ ẹ̀bùn kan tó ju fàdákà tàbí wúrà lọ sí ọ̀pọ̀ èèyàn náà àti ọkùnrin tó yarọ tẹ́lẹ̀ yìí. Ẹ̀bùn yìí kọjá pé wọ́n kàn wo èèyàn sàn. Ó jẹ́ àǹfààní láti ronú pìwà dà, ká pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́, kí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, ẹni tí Jèhófà fi ṣe “Olórí Aṣojú ìyè.”—Ìṣe 3:15.
4. (a) Wàhálà wo ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Pétérù àti Jòhánù ṣiṣẹ́ ìyanu? (b) Àwọn ìbéèrè méjì wo la máa dáhùn?
4 Ọjọ́ ńlá mà lọjọ́ yẹn o! Ẹni tó yarọ tẹ́lẹ̀ rí ìwòsàn gbà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. Ọ̀pọ̀ àwọn míì sì láǹfààní láti gba ìwòsàn tẹ̀mí kí wọ́n lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Ọlọ́run. (Kól. 1:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà ló bẹ̀rẹ̀ wàhálà tó wáyé láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi àtàwọn aláṣẹ tí wọn ò ní fẹ́ kí wọ́n tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 1:8) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù àti Jòhánù “ò kàwé àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù,” kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà jẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ èèyàn náà, kí la sì lè rí kọ́ látinú ìwà àti ìṣe wọn?b (Ìṣe 4:13) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pétérù, Jòhánù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù tí wọ́n bá ṣenúnibíni sí wa?
Kì Í Ṣe “Agbára Wa” (Ìṣe 3:11-26)
5. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Pétérù gbà bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀?
5 Pétérù àti Jòhánù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn èèyàn náà ló sọ pé kí wọ́n pa Jésù, síbẹ̀ wọ́n bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀. (Máàkù 15:8-15; Ìṣe 3:13-15) Ronú nípa bí Pétérù ṣe fìgboyà sọ fún wọn pé orúkọ Jésù lòun fi wo ọkùnrin náà sàn. Kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé wọ́n lọ́wọ́ sí ikú Kristi. Àmọ́, kò di àwọn èèyàn náà sínú, torí ó mọ̀ pé ‘àìmọ̀kan ló mú kí wọ́n ṣe é.’ (Ìṣe 3:17) Ó bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọmọ ìyá, ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn lọ́nà tó fi máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Tí wọ́n bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú Kristi, “àsìkò ìtura” máa wá látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Ìṣe 3:19) Ó yẹ káwa náà jẹ́ onígboyà bá a ṣe ń kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, ká má sì máa bomi la Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, kò yẹ ká jẹ́ oníjàgídíjàgan, ẹni tó le koko, tàbí alárìíwísí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa wo gbogbo àwọn tá à ń wàásù fún bí ẹni tó máa tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bákan náà bíi ti Pétérù, ó yẹ ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn lọ́nà tó fi máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.
6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Pétérù àti Jòhánù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí wọn ò sì jọra wọn lójú?
6 Àwọn àpọ́sítélì náà ò jọra wọn lójú. Wọn ò ṣe bíi pé agbára àwọn làwọn fi mú ọkùnrin náà lára dá. Pétérù sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń wò wá bíi pé agbára wa ló tó bẹ́ẹ̀, àbí torí pé ìfọkànsin Ọlọ́run tí a ní la fi mú kí ọkùnrin yìí máa rìn?” (Ìṣe 3:12) Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì tó kù mọ̀ pé Ọlọ́run ló fún wọn lágbára tí wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, kì í ṣe agbára àwọn. Torí pé wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọ́n gbà pé Jèhófà àti Jésù ni ọpẹ́ àti ìyìn yẹ.
7, 8. (a) Ẹ̀bùn wo la lè fún àwọn èèyàn? (b) Báwo ni ìlérí nípa ‘ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ ṣe ń ṣẹ lónìí?
7 Ó yẹ káwa náà máa fi hàn pé a ò jọra wa lójú bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ohun kan ni pé ẹ̀mí Ọlọ́run kì í fún àwọn Kristẹni òde òní lágbára láti woni sàn lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, a lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi kí wọ́n sì gba irú ẹ̀bùn tí Pétérù fáwọn èèyàn, ìyẹn àǹfààní láti rí ìdáríjì gbà kí Jèhófà sì mára tù wọ́n. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba ẹ̀bùn yìí lọ́dọọdún, tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi.
8 Dájúdájú, a ti wà ní àkókò tí Pétérù pè ní “àkókò ìmúbọ̀sípò gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ látẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà àtijọ́.” Ẹ̀rí fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ṣẹ, torí Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lókè ọ̀run látọdún 1914. (Ìṣe 3:21; Sm. 110:1-3; Dán. 4:16, 17) Kété lẹ́yìn náà, Kristi bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò láyé. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní láti wọnú párádísè tẹ̀mí, kí wọ́n sì fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ti bọ́ ìwà àtijọ́ tó ń sọni dìbàjẹ́ sílẹ̀, wọ́n sì ti “gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Éfé. 4:22-24) Bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ran Pétérù àti Jòhánù lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú ọkùnrin arọ tó ń tọrọ bárà yẹn lára dá, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń ràn wá lọ́wọ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lè yọrí sí rere. Bíi ti Pétérù, a gbọ́dọ̀ máa fìgboyà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lọ́nà tó dáa. Tá a bá sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé agbára Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe kì í ṣe agbára wa.
‘A Ò Lè Ṣàì Sọ̀rọ̀’ (Ìṣe 4:1-22)
9-11. (a) Kí làwọn alákòóso àwọn Júù ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Pétérù àti Jòhánù ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? (b) Kí làwọn àpọ́sítélì pinnu láti ṣe?
9 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ìyẹn bí Pétérù ṣe fi ìgboyà wàásù àti bí ọkùnrin tó yarọ tẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń pariwo tó sì ń fò sókè fa ìdàrúdàpọ̀. Èyí mú kí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì, tí wọ́n yàn sípò láti máa bójú tó ètò ààbò ní gbogbo àgbègbè tẹ́ńpìlì àtàwọn olórí àlùfáà rọ́ wá síbẹ̀ láti wá wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn ọkùnrin wọ̀nyí jẹ́ Sadusí, ìyẹn ẹ̀yà ẹ̀sìn Júù kan tó ní ọ̀rọ̀ àti agbára, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará Róòmù láti pa àlàáfíà ìlú mọ́. Wọn ò fára mọ́ òfin àtẹnudẹ́nu àwọn Farisí, wọn ò sì gbà gbọ́ pé àjíǹde wà.c Ẹ wo bí inú ṣe máa bí wọn tó nígbà tí wọ́n rí Pétérù àti Jòhánù nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n ń fìgboyà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù ti jíǹde!
10 Àwọn alátakò tí inú ń bí yìí ju Pétérù àti Jòhánù sínú ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì fà wọ́n lọ síwájú ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù lọ́jọ́ kejì. Àwọn Júù tó jẹ́ ọlọ́lá àti alágbára yìí gbà pé Pétérù àti Jòhánù “ò kàwé àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù,” èyí jẹ́ nítorí pé wọn ò kẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbà pé wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì. Síbẹ̀, bí ọ̀rọ̀ ṣe dá lẹ́nu wọn mú kẹ́nu ya àwọn alákòóso yẹn. Kí ló mú kí Pétérù àti Jòhánù lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó wọni lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Ohun kan ni pé “wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù.” (Ìṣe 4:13) Àṣẹ tó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Jésù Ọ̀gá wọn fi ń kọ́ni, kì í ṣe bíi tàwọn akọ̀wé òfin.—Mát. 7:28, 29.
11 Ilé ẹjọ́ náà pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́. Láàárín àwọn Júù nígbà yẹn, ohun tí ilé ẹjọ́ bá sọ làṣẹ. Kò tíì pẹ́ púpọ̀ sígbà yẹn tí ilé ẹjọ́ yìí dá Jésù lẹ́bi pé “ikú ló tọ́ sí i.” (Mát. 26:59-66) Síbẹ̀, ẹ̀rù ò ba Pétérù àti Jòhánù. Wọ́n dúró síwájú àwọn ọlọ́rọ̀, ọ̀mọ̀wé, àtàwọn ọlọ́lá yìí, wọ́n sì fìgboyà sọ pé: “Ẹ̀yin náà ẹ sọ, tó bá tọ́ lójú Ọlọ́run pé ká fetí sí yín dípò ká fetí sí Ọlọ́run. Àmọ́ ní tiwa, a ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.”—Ìṣe 4:19, 20.
12. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti nígboyà kí ohun tá a gbà gbọ́ sì dá wa lójú?
12 Ṣé ìwọ náà lè nígboyà bíi ti Pétérù àti Jòhánù? Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o láǹfààní láti wàásù fáwọn ọlọ́rọ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé, tàbí àwọn tó lẹ́nu láwùjọ? Táwọn aráalé ẹ, àwọn ọmọléèwé ẹ, tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ohun tó o gbà gbọ́ ńkọ́? Ṣẹ́rù ò ní bà ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó o lè ṣe wà. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè fìgboyà àti ọ̀wọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (Mát. 10:11-18) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ṣèlérí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun á máa bá a nìṣó láti wà pẹ̀lú wọn “ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Jésù ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti kọ́ wa ní ọ̀nà tá a lè gbà sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a gbà gbọ́. (Mát. 24:45-47; 1 Pét. 3:15) Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa àwọn ìtọ́ni tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé ìjọ, irú bí ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni àti àlàyé Bíbélì tí wọ́n máa ń ṣe nínú àwọn àpilẹ̀kọ bí “Ohun Tí Bíbélì Sọ” lórí ìkànnì jw.org. Ṣé o máa ń lọ sípàdé ìjọ déédéé, ṣé o sì máa ń ka àwọn àpilẹ̀kọ náà? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ nígboyà, ohun tó o gbà gbọ́ á sì túbọ̀ dá ẹ lójú. Àti pé, bíi tàwọn àpọ́sítélì, o ò ní í jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye tó o ti kọ́.
Wọ́n “Gbé Ohùn Wọn Sókè sí Ọlọ́run” (Ìṣe 4:23-31)
13, 14. Bí wọ́n bá ń ṣàtakò sí wa, kí ló yẹ ká ṣe, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
13 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n tú Pétérù àti Jòhánù sílẹ̀, ni wọ́n lọ bá àwọn tó kù nínú ìjọ. Gbogbo wọn jọ “gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run,” wọ́n sì gbàdúrà pé kó fún àwọn nígboyà láti máa wàásù. (Ìṣe 4:24) Pétérù mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbára lé òye ara ẹ̀ tó bá kan pé ká ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí Pétérù fi ìdánilójú sọ fún Jésù pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó dájú pé èmi ò ní kọsẹ̀ láé!” Síbẹ̀, bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, kò pẹ́ tí ìbẹ̀rù èèyàn mú kí Pétérù sẹ́ ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ àti olùkọ́ rẹ̀. Àmọ́ o, Pétérù kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe rẹ̀.—Mát. 26:33, 34, 69-75.
14 Bó o ṣe ń jẹ́rìí nípa Kristi, máa rántí pé agbára rẹ nìkan ò lè mú kó o ṣàṣeyọrí. Táwọn alátakò bá gbìyànjú láti mú kó o ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí tàbí tí wọn ò fẹ́ kó o má wàásù mọ́, àpẹẹrẹ Pétérù àti Jòhánù ni kó o tẹ̀ lé. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ lókun. Jẹ́ kí ìjọ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Sọ àwọn ìṣòro tó ò ń dojú kọ fún àwọn alàgbà àtàwọn míì tó dàgbà dénú nínú ìjọ. Àdúrà táwọn míì bá gbà lè fún ẹ lókun tó o nílò.—Éfé. 6:18; Jém. 5:16.
15. Tẹ́nì kan bá ti fìgbà kan rí jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kí nìdí tí kò fi yẹ kó rẹ̀wẹ̀sì?
15 Ṣé o ti dojú kọ àwọn ìṣòro kan rí, tíyẹn sì mú kó o má wàásù mọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má rẹ̀wẹ̀sì. Rántí pé, ìgbà kan wà táwọn àpọ́sítélì ò wàásù mọ́ lẹ́yìn tí Jésù kú, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi pa dà sẹ́nu iṣẹ́ náà. (Mát. 26:56; 28:10, 16-20) Dípò tí wàá fi jẹ́ káwọn àṣìṣe tó o ti ṣe kọjá kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, o ò ṣe ronú nípa ohun tó o kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀, kó o sì lo ẹ̀kọ́ náà láti gbé àwọn míì ró?
16, 17. Kí la lè rí kọ́ nínú àdúrà táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gbà ní Jerúsálẹ́mù?
16 Kí ló yẹ ká máa gbàdúrà fún táwọn aláṣẹ bá ń ni wá lára? Kíyè sí i pé àwọn àpọ́sítélì ò sọ pé kí Ọlọ́run má ṣe jẹ́ káwọn dojú kọ àdánwò. Wọn rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Tí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ẹ̀yin náà.” (Jòh. 15:20) Ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ adúróṣinṣin náà bẹ Jèhófà pé kó “fiyè sí” ìhàlẹ̀ àwọn tó ń ta kò wọ́n. (Ìṣe 4:29) Ó dájú pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yé àwọn àpọ́sítélì yẹn dáadáa, wọ́n mọ̀ pé ńṣe làwọn ń dojú kọ inúnibíni káwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lè ṣẹ. Wọ́n mọ̀ pé ohun yòówù káwọn alákòóso èèyàn lásánlàsàn máa sọ, ìfẹ́ Ọlọ́run máa “ṣẹ ní ayé,” bí Jésù ṣe sọ nígbà tó ń kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà.—Mát. 6:9, 10.
17 Káwọn ọmọ ẹ̀yìn lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà.” Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wọn? Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, “ibi tí wọ́n kóra jọ sí mì tìtì, gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣe 4:29-31) Kò sóhun tó lè ní kí ìfẹ́ Ọlọ́run má ṣẹ. (Àìsá. 55:11) Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé kò sóhun tá a lè ṣe, táwọn tó ń ṣàtakò sì burú bí ẹkùn tí ò ṣeé gbéná wò lójú, tá a bá ké pe Ọlọ́run, ó dá wa lójú pé ó máa fún wa lókun ká lè máa bá a nìṣó láti fìgboyà sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
“Èèyàn Kọ́” La Máa Jíhìn fún “Ọlọ́run Ni” (Ìṣe 4:32–5:11)
18. Ọ̀nà wo làwọn ará tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbà ran ara wọn lọ́wọ́?
18 Kò pẹ́ táwọn ará tó wà nínú ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù fi lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000).d Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun yẹn ti wá, wọ́n “ṣọ̀kan ní inú àti ọkàn.” Wọ́n ní inú kan náà àti èrò kan náà. (Ìṣe 4:32; 1 Kọ́r. 1:10) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ò kàn gbàdúrà pé kí Jèhófà bù kún àwọn nìkan. Àmọ́, wọ́n ń ran ara wọn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọ́n bá sì rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń pèsè ohun táwọn ara wọn nílò nípa tára. (1 Jòh. 3:16-18) Àpẹẹrẹ kan ni ti ọmọ ẹ̀yìn náà Jósẹ́fù, táwọn àpọ́sítélì tún ń pè ní Bánábà. Ó ta ilẹ̀ rẹ̀, ó sì kó gbogbo owó náà sílẹ̀ kí wọ́n lè fi bójú tó àwọn tó wá sí Jerúsálẹ́mù láti ọ̀nà tó jìn, kí wọ́n lè pẹ́ níbẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ẹ̀sìn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́.
19. Kí nìdí tí Jèhófà fi pa Ananáyà àti Sàfírà?
19 Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Ananáyà àti Sàfírà wà lára àwọn tó ta ohun ìní wọn, wọ́n sì fowó náà ṣètìlẹ́yìn. Wọ́n dọ́gbọ́n bíi pé gbogbo owó náà ni wọ́n fi ṣètìlẹ́yìn, àmọ́ wọ́n “yọ lára owó náà pa mọ́.” (Ìṣe 5:2) Torí ohun tí wọ́n ṣe yìí, Jèhófà pa wọ́n. Kì í ṣe torí pé owó tí wọ́n kó wá ò tó ló fi ṣe bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé èrò ọkàn wọn ò dáa, wọ́n sì hùwà ẹ̀tàn. ‘Èèyàn kọ́ ni wọ́n parọ́ fún, Ọlọ́run ni.’ (Ìṣe 5:4) Bíi tàwọn alágàbàgebè tí Jésù dá lẹ́bi, Ananáyà àti Sàfírà ò ro bí wọ́n ṣe máa múnú Ọlọ́run dùn, ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wọn ni bí wọ́n ṣe máa gbayì lójú àwọn èèyàn.—Mát. 6:1-3.
20. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ fún Jèhófà ní nǹkan?
20 Bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ olóòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní náà jẹ́ ọ̀làwọ́, a máa ń fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. A kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti fi àkókò tàbí owó rẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Jèhófà ò tiẹ̀ fẹ́ ká máa fipá sin òun. (2 Kọ́r. 9:7) Tá a bá sì fún Jèhófà ní ohunkóhun, kì í ṣe bó ṣe pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì lójú ẹ̀, bí kò ṣe ohun tó mú ká ṣe bẹ́ẹ̀. (Máàkù 12:41-44) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká fìwà jọ Ananáyà àti Sàfírà, kó má lọ jẹ́ pé torí a fẹ́ gbayì lójú àwọn èèyàn la ṣe ń sin Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi ti Pétérù, Jòhánù àti Bánábà, ká máa sin Jèhófà nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, a sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa dénú.—Mát. 22:37-40.
a Àwọn èèyàn máa ń gbàdúrà ní tẹ́ńpìlì nígbà ẹbọ àárọ̀ àti nígbà ẹbọ ìrọ̀lẹ́. “Wákàtí kẹsàn-án,” tàbí nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán ni wọ́n máa ń rú ẹbọ ìrọ̀lẹ́.
b Wo àwọn àpótí náà, “Pétérù—Apẹja Tó Di Àpọ́sítélì Onítara” àti “Jòhánù—Àpọ́sítélì Tí Jésù Fẹ́ràn.”
c Wo àpótí náà, “Àlùfáà Àgbà Àtàwọn Olórí Àlùfáà.”
d Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) péré làwọn Farisí tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sì ṣeé ṣe káwọn Sadusí tó wà níbẹ̀ má tóyẹn. Èyí lè jẹ́ ká rí ìdí míì tí inú wọn ò fi dùn sí ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn fi ń kọ́ni nípa Jésù.