ORÍ 5
“A Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Alákòóso”
Àwọn àpọ́sítélì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún gbogbo Kristẹni tòótọ́
Ó dá lórí Ìṣe 5:12–6:7
1-3. (a) Kí ló gbé àwọn àpọ́sítélì déwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, kí ló sì ṣe pàtàkì jù sí wọn? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun táwọn àpọ́sítélì náà ṣe?
INÚ ń bí àwọn adájọ́ Sàhẹ́ndìrìn gan-an! Àwọn àpọ́sítélì Jésù ń jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ gíga yìí. Kí ló gbé wọn délé ẹjọ́? Jósẹ́fù Káyáfà tó jẹ́ àlùfáà àgbà tó sì tún jẹ́ alága Sàhẹ́ndìrìn fìkanra sọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ká mọ ohun tó gbé wọn débẹ̀, ó ní: “A kìlọ̀ fún yín gidigidi pé kí ẹ má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ yìí.” Alága ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn tó ń bínú yìí ò fẹ́ fẹnu ẹ̀ pe orúkọ Jésù. Ó ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé, “síbẹ̀, ẹ wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù, ẹ sì pinnu láti mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sórí wa.” (Ìṣe 5:28) Ohun tó ń sọ ni pé: Táwọn àpọ́sítélì yẹn ò bá yéé wàásù, wọ́n á jẹ palaba ìyà!
2 Kí làwọn àpọ́sítélì yìí máa wá ṣe báyìí? Jésù ló ní kí wọ́n máa wàásù, Ọlọ́run ló sì fún un láṣẹ. (Mát. 28:18-20) Ṣáwọn àpọ́sítélì yìí ò wá ní wàásù mọ́ torí pé àwọn èèyàn ń halẹ̀ mọ́ wọn ni? Ṣé wọ́n á fìgboyà kojú àdánwò yìí, kí wọ́n sì máa wàásù nìṣó? Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé: Ṣé èèyàn ni wọ́n máa ṣègbọràn sí àbí Ọlọ́run? Àpọ́sítélì Pétérù ò fọ̀rọ̀ falẹ̀, kíá ló ṣojú fáwọn àpọ́sítélì yòókù láti sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣe kedere, ó sì fi hàn pé ó nígboyà.
3 Ó yẹ káwa Kristẹni tòótọ́ mohun táwọn àpọ́sítélì yẹn ṣe nígbà tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn halẹ̀ mọ́ wọn. Ọlọ́run pàṣẹ pé káwa náà máa wàásù, àwọn èèyàn sì lè ta ko àwa náà lẹ́nu iṣẹ́ yìí. (Mát. 10:22) Táwọn alátakò bá fẹ́ dí wa lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, kí la máa ṣe? Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun táwọn àpọ́sítélì yìí ṣe àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi wá ń jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn.a
“Áńgẹ́lì Jèhófà Ṣí Àwọn Ilẹ̀kùn” (Ìṣe 5:12-21a)
4, 5. Kí nìdí tí Káyáfà àtàwọn Sadusí fi ‘bínú gidigidi’?
4 Rántí pé nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ fún Pétérù àti Jòhánù pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, wọ́n fèsì pé: “A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:20) Lẹ́yìn tí Pétérù àti Jòhánù kúrò níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, àwọn àtàwọn àpọ́sítélì tó kù ń bá a lọ láti máa wàásù nínú tẹ́ńpìlì. Àwọn àpọ́sítélì yẹn ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, wọ́n ń mú àwọn aláìsàn lára dá, wọ́n sì ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ibì kan táwọn Júù máa ń pé jọ sí ni wọ́n wà, ìyẹn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé kan tí wọ́n ń pè ní “Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Sólómọ́nì,” lápá ìlà oòrùn tẹ́ńpìlì. Kódà, ó ṣeé ṣe kí òjìji Pétérù mú àwọn kan lára dá! Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n wò sàn ló tẹ́tí sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí èyí, “àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa ń dara pọ̀ mọ́ wọn, iye wọn sì pọ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.”—Ìṣe 5:12-15.
5 Nígbà tí Káyáfà àtàwọn Sadusí tí wọ́n jọ wà nínú ẹ̀ya ẹ̀sìn kan náà rí ohun táwọn àpọ́sítélì yẹn ń ṣe “inú bí wọn gidigidi,” wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. (Ìṣe 5:17, 18) Kí nìdí táwọn Sadusí yẹn fi ń bínú? Ìdí ni pé àwọn àpọ́sítélì ń kọ́ àwọn èèyàn pé Jésù ti jíǹde, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn Sadusí ò gbà pé àjíǹde wà. Àwọn àpọ́sítélì tún ń kọ́ni pé ó dìgbà téèyàn bá gba Jésù gbọ́ kó tó lè rí ìgbàlà, àmọ́ àwọn Sadusí ń bẹ̀rù pé ìjọba Róòmù lè fìyà jẹ àwọn táwọn èèyàn bá sọ Jésù di Aṣáájú. (Jòh. 11:48) Abájọ táwọn Sadusí fi fẹ́ pa àwọn àpọ́sítélì lẹ́nu mọ́!
6. Àwọn wo ló máa ń wà nídìí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí sì nìdí tí kò fi yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu?
6 Bákan náà lónìí, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ló sábà máa ń wà nídìí inúnibíni táwọn èèyàn ń ṣe sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n máa ń lo àṣẹ wọn láti mú káwọn ìjọba àtàwọn ilé iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró. Ṣó yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu? Rárá o. Ìdí ni pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ń tú àṣírí ohun táwọn ẹlẹ́sìn èké ń kọ́ àwọn èèyàn. Táwọn tó dìídì fẹ́ mọ òótọ́ bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa ń gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Jòh. 8:32) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ń mú káwọn olórí ẹ̀sìn kórìíra wa, kí wọ́n sì máa ṣe inúnibíni sí wa.
7, 8. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì gbọ́ ohun tí áńgẹ́lì yẹn sọ, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
7 Nígbà táwọn àpọ́sítélì wà lẹ́wọ̀n, tí wọ́n ń dúró de ìgbẹ́jọ́, wọ́n lè ti máa ronú pé ṣe kì í ṣe pé àwọn ọ̀tá máa pa àwọn báyìí? (Mát. 24:9) Àmọ́, ohun kan tí wọ́n ò ronú ẹ̀ rárá ṣẹlẹ̀ lóru. “Áńgẹ́lì Jèhófà ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà.”b (Ìṣe 5:19) Áńgẹ́lì yẹn wá sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn, ó ní: “Ẹ lọ dúró sínú tẹ́ńpìlì, kí ẹ sì máa sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn èèyàn.” (Ìṣe 5:20) Ó dájú pé àṣẹ tí áńgẹ́lì yẹn pa fi àwọn àpọ́sítélì náà lọ́kàn balẹ̀ pé ohun tó tọ́ làwọn ń ṣe. Ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì yẹn sọ sì ti ní láti fún wọn lókun pé kò sóhun tó lè mú káwọn yí ìpinnu àwọn pa dà. Ìgbàgbọ́ àwọn àpọ́sítélì ti wá lágbára sí i, wọ́n sì túbọ̀ nígboyà, torí náà wọ́n “wọ tẹ́ńpìlì ní àfẹ̀mọ́jú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni.”—Ìṣe 5:21.
8 Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara ẹ̀ pé, ‘Ṣé màá lè ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà kí n lè máa bá a lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tírú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀ sí mi?’ Tá a bá mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí, ọkàn wa máa balẹ̀ èyí á sì mú ká túbọ̀ máa “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run.”—Ìṣe 28:23; Ifi 14:6, 7.
“A Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Alákòóso Dípò Èèyàn” (Ìṣe 5:21b-33)
9-11. Kí làwọn àpọ́sítélì ṣe nígbà tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ní kí wọ́n má wàásù mọ́, báwo nìyẹn sì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ fáwa Kristẹni tòótọ́?
9 Káyáfà àtàwọn adájọ́ tó kù nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti múra tán láti fìyà jẹ àwọn àpọ́sítélì. Àwọn adájọ́ ní káwọn ọmọ ogun lọ kó àwọn àpọ́sítélì wá láì mọ̀ pé ohun kan ti ṣẹlẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Wo bó ṣe máa ya àwọn ọmọ ogun yẹn lẹ́nu tó nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ti jáde, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bá ẹ̀wọ̀n náà ní títì pa, tí ‘àwọn ẹ̀ṣọ́ sì dúró lẹ́nu àwọn ilẹ̀kùn.’ (Ìṣe 5:23) Kò pẹ́ tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì fi gbọ́ pé àwọn àpọ́sítélì ti pa dà sínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n ń wàásù nípa Jésù Kristi, iṣẹ́ tí wọ́n torí ẹ̀ fi wọ́n sẹ́wọ̀n! Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, olórí ẹ̀ṣọ́ yẹn àtàwọn ọmọ ogun lọ sí tẹ́ńpìlì láti lọ tún àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà kó, wọ́n sì mú wọn lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn.
10 Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, inú ń bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn gan-an wọ́n sì sọ pé káwọn àpọ́sítélì má wàásù mọ́. Kí làwọn àpọ́sítélì wá ṣe? Pétérù ló ṣojú fún àwọn tó kù, ó sì fìgboyà sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.” (Ìṣe 5:29) Ohun táwọn àpọ́sítélì yẹn ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa tó sì yẹ káwa Kristẹni tòótọ́ máa tẹ̀ lé. Nígbàkigbà táwọn aláṣẹ bá ní ká ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́, wọ́n ti kọjá àyè wọn nìyẹn. Torí náà, tí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” bá tiẹ̀ ṣòfin pé ká má wàásù mọ́, a ò ní yéé wàásù ìhìn rere, torí pé Ọlọ́run ló ní ká máa ṣe iṣẹ́ náà. (Róòmù 13:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa dọ́gbọ́n lóríṣiríṣi ká lè máa jẹ́rìí kúnnákúnná nìṣó nípa Ìjọba Ọlọ́run.
11 Nígbà táwọn adájọ́ yẹn gbọ́ báwọn àpọ́sítélì yẹn ṣe fìgboyà fún wọn lésì, inú bí wọn gan-an. Wọ́n pinnu pé ńṣe làwọ́n máa “pa wọ́n dà nù.” (Ìṣe 5:33) Ó wá dà bíi pé ikú ló kàn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ń fìtara wàásù tí wọ́n sì nígboyà yẹn. Ìyẹn mà lágbára o! Àmọ́, ọ̀nà àrà ni Ọlọ́run máa gbà ràn wọ́n lọ́wọ́!
“Ẹ Ò Ní Lè Bì Wọ́n Ṣubú” (Ìṣe 5:34-42)
12, 13. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Gàmálíẹ́lì fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ adájọ́, kí sì ni wọ́n ṣe? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dá sọ́rọ̀ àwa èèyàn rẹ̀ lóde òní, kí ló sì dá wa lójú bí Jèhófà bá tiẹ̀ fàyè gba pé ká “jìyà nítorí òdodo”?
12 Gàmálíẹ́lì, tó jẹ́ “olùkọ́ Òfin tí gbogbo èèyàn kà sí,” dá sọ̀rọ̀ náà.c Ó dájú pé àwọn adájọ́ tó kù bọ̀wọ̀ fún amòfin àgbà yìí gan-an, torí pé wọ́n fetí sọ́rọ̀ ẹ̀. Ó tiẹ̀ “pàṣẹ pé kí wọ́n mú àwọn [àpọ́sítélì] náà lọ síta fúngbà díẹ̀.” (Ìṣe 5:34) Gàmálíẹ́lì sọ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn kan tí wọ́n kó ọmọ ẹ̀yin jọ, àmọ́ tí gbogbo wọn tú ká lẹ́yìn táwọn aṣáájú wọn kú. Ó wá rọ ìgbìmọ̀ yẹn pé kí wọ́n fara balẹ̀, kí wọ́n sì ṣe sùúrù fáwọn àpọ́sítélì náà, torí pé kò tíì pẹ́ tí Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wọn kú. Ohun tí Gàmálíẹ́lì sọ yí wọn lérò pa dà, ó ní: “Ẹ má tojú bọ ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí, ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Torí tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ èèyàn ni ète tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ ò ní lè bì wọ́n ṣubú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ́ kàn rí i pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run jà ni.” (Ìṣe 5:38, 39) Àwọn adájọ́ yẹn fetí sí ìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì. Àmọ́, wọ́n ṣì na àwọn àpọ́sítélì náà lẹ́gba, wọ́n wá pàṣẹ fún wọn pé “kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́.”—Ìṣe 5:40.
13 Bíi tìgbà yẹn, Jèhófà lè mú káwọn èèyàn tó wà nípò gíga bíi Gàmálíẹ́lì gbèjà àwọn èèyàn ẹ̀ lóde òní. (Òwe 21:1) Jèhófà lè fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn aláṣẹ tó jẹ́ alágbára, àwọn adájọ́ tàbí àwọn aṣòfin láti ṣohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Neh. 2:4-8) Àmọ́, tó bá fàyè gba pé ká “jìyà nítorí òdodo,” ohun méjì kan dá wa lójú. (1 Pét. 3:14) Àkọ́kọ́ ni pé Ọlọ́run máa fún wa lágbára láti fara dà á. (1 Kọ́r. 10:13) Ìkejì ni pé àwọn alátakò ‘ò ní lè bì iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú.’—Àìsá. 54:17.
14, 15. (a) Kí làwọn àpọ́sítélì ṣe nígbà tí wọ́n nà wọ́n, kí sì nìdí? (b) Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà máa ń fara da inúnibíni tayọ̀tayọ̀.
14 Ṣé bí wọ́n ṣe na àwọn àpọ́sítélì yìí mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, tàbí kí wọ́n sọ pé àwọn ò ní wàásù mọ́? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n “jáde kúrò níwájú Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n ń yọ̀.” (Ìṣe 5:41) Kí nìdí tí wọ́n fi “ń yọ̀”? Ó dájú pé kì í ṣe ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n ló mú kí wọ́n máa yọ̀. Ohun tó mú kí wọ́n máa yọ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ń jìyà ni pé wọ́n mọ̀ pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti pé àwọn ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ Àwòkọ́ṣe àwọn.—Mát. 5:11, 12.
15 Bíi tàwọn arákùnrin wa ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, a máa ń fara dà á tayọ̀tayọ̀ nígbà tá a bá ń jìyà nítorí ìhìn rere. (1 Pét. 4:12-14) Kì í ṣe pé ó ń dùn mọ́ wa kí wọ́n máa halẹ̀ mọ́ wa, kí wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa tàbí kí wọ́n fi wá sẹ́wọ̀n. Àmọ́, inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Henryk Dornik, ọ̀pọ̀ ọdún ló fi fara da ìyà tó pọ̀ gan-an lábẹ́ ìjọba bóofẹ́bóokọ̀. Ó rántí pé, lóṣù August ọdún 1944, àwọn aláṣẹ yẹn fi òun àti àbúrò ẹ̀ ọkùnrin sínú àgọ́ ìfìyàjẹni. Àwọn alátakò yẹn sọ pé: “Ẹ ò lè yí wọn lérò pa dà láti ṣe nǹkan kan. Ó tẹ́ wọn lọ́rùn pé kí wọ́n kú.” Arákùnrin Dornik sọ pé: “Kì í ṣe pé ó wù mí pé kí n kú, àmọ́ inú mi máa ń dùn tí mo bá jẹ́ onìgboyà tí mo sì fara da ìyà nítorí pé mo fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.”—Jém. 1:2-4.
16. Báwo làwọn àpọ́sítélì ṣe fi hàn pé wọ́n ti pinnu láti jẹ́rìí kúnnákúnná, báwo làwa náà sì ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?
16 Àwọn àpọ́sítélì ò fàkókò ṣòfò rárá, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n ń fìgboyà ‘kéde ìhìn rere nípa Kristi lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé.’d (Ìṣe 5:42) Àwọn àpọ́sítélì náà ń fìtara wàásù, wọ́n sì ń jẹ́rìí kúnnákúnná. Kíyè sí i pé ńṣe ni wọ́n lọ ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn nínú ilé wọn bí Jésù Kristi ṣe sọ pé kí wọ́n ṣe. (Mát. 10:7, 11-14) Ó dájú pé èyí ló mú kí wọ́n lè fi ẹ̀kọ́ wọn kún Jerúsálẹ́mù. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé bíi tàwọn àpọ́sítélì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣe ń wàásù. Bá a ṣe ń dé gbogbo ilé tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa fi hàn pé àwa náà fẹ́ ṣiṣẹ́ ìwàásù yìí kúnnákúnná, kí gbogbo èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere. Ṣé Jèhófà sì ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tá à ń ṣe? Ó dájú pé ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Àìmọye èèyàn ló ti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ pé ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ wàásù nílé wọn ni wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere.
Àwọn Ọkùnrin Tó Kúnjú Ìwọ̀n “Bójú Tó Ọ̀ràn Tó Pọn Dandan” (Ìṣe 6:1-6)
17-19. Ọ̀rọ̀ wo ló fẹ́ ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn ará jẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kí làwọn àpọ́sítélì sì ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà?
17 Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ táwọn àpọ́sítélì ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Kí ni nǹkan náà? Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ló jẹ́ àlejò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i kí wọ́n tó pa dà sílé. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù wá fowó ṣètìlẹyìn tinútinú kí wọ́n lè ra oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì táwọn àlejò yìí nílò. (Ìṣe 2:44-46; 4:34-37) Àmọ́ ohun kan wá ṣẹlẹ̀ tó gba pé kí wọ́n fọgbọ́n bojú tó. “Àwọn tó ń pín [oúnjẹ] lójoojúmọ́ ń gbójú fo àwọn opó” tó jẹ́ Gíríìkì. (Ìṣe 6:1) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn kò gbójú fo àwọn opó tó ń sọ èdè Hébérù. Ó jọ pé kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ láàárín wọn. Ìyapa sì nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń dá sílẹ̀.
18 Àwọn àpọ́sítélì ló para pọ̀ di ìgbìmọ̀ olùdarí, àwọn ló sì ń bójú tó àwọn ìjọ tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Torí náà, wọ́n mọ̀ pé kò yẹ káwọn “fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ [kí wọ́n] máa pín oúnjẹ.” (Ìṣe 6:2) Kí wọ́n lè yanjú ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n wá àwọn ọkùnrin méje “tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n,” káwọn àpọ́sítélì lè yàn wọ́n láti máa bójú tó “ọ̀ràn tó pọn dandan yìí.” (Ìṣe 6:3) Àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ló lè ṣe iṣẹ́ yìí, torí ó jọ pé iṣẹ́ yẹn kọjá pé kí wọ́n kàn fún àwọn èèyàn lóúnjẹ, ó tún kan pé kí wọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ owó, kí wọ́n ra àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, kí wọ́n sì fara balẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Orúkọ Gíríìkì ni gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn náà ń jẹ́, ó sì ṣeé ṣe kínú àwọn opó tí wọ́n gbójú fò dá yẹn dùn sí èyí. Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì ti gbàdúrà lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n yan àwọn ọkùnrin méje náà láti bójú tó “ọ̀ràn tó pọn dandan” yìí.e
19 Ṣé bí wọ́n ṣe yan àwọn ọkùnrin méje yẹn pé kí wọ́n máa bójú tó oúnjẹ wá túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ìwàásù ò sí lára iṣẹ́ wọn? Rárá o! Lára àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn ni Sítéfánù, ẹni tó ṣì máa fi ìtara àti ìgboyà wàásù ìhìn rere náà. (Ìṣe 6:8-10) Bákan náà, Fílípì tá a wá mọ̀ sí “ajíhìnrere” wà lára àwọn méje tí wọ́n yàn. (Ìṣe 21:8) Ó ṣe kedere pé àwọn ọkùnrin méje náà ń bá a lọ láti máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
20. Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà táwọn àpọ́sítélì tẹ̀ lé?
20 Àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì làwa èèyàn Jèhófà náà ń tẹ̀ lé lóde òní. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n máa ń yàn láti jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ gbọ́dọ̀ ní ọgbọ́n Ọlọ́run, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa hùwà tó fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí wọn. Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣètò bí wọ́n ṣe ń yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè, kí wọ́n lè di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.f (1 Tím. 3:1-9, 12, 13) Ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run fi darí àwọn tó kọ Bíbélì, ìlànà Bíbélì la sì fi ń yan àwọn arákùnrin tó ń sìn nínú ìjọ, torí náà a lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló yàn wọ́n. Àwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára yìí máa ń bójú tó ọ̀pọ̀ nǹkan tó pọn dandan. Bí àpẹẹrẹ, táwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ bá nílò ìrànlọ́wọ́, àwọn alàgbà máa ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Jém. 1:27) Àwọn alàgbà kan wà lára àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn kan máa ń ṣètò àpéjọ àgbègbè, àwọn míì sì wà lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì tí kì í ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tàbí kíkọ́ni ní tààràtà. Gbogbo àwọn ọkùnrin tá a yàn yìí gbọ́dọ̀ mọ bí wọ́n á ṣe máa ṣe ojúṣe wọn nínú ìjọ àtàwọn iṣẹ́ míì nínú ètò Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́, kò sì yẹ kí ọ̀kan pa èkejì lára.—1 Kọ́r. 9:16.
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Gbilẹ̀ Nìṣó” (Ìṣe 6:7)
21, 22. Kí ló fi hàn pé Jèhófà bù kún ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà?
21 Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà ò tú ká nígbà táwọn èèyàn ṣe inúnibíni sí wọ́n, ìṣòro tó wáyé láàárín wọn ò sì fa ìyapa. Ó hàn gbangba pé Jèhófà bù kún wọn, torí Bíbélì sọ pé: “Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbilẹ̀ nìṣó, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń pọ̀ sí i gidigidi ní Jerúsálẹ́mù; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ náà.” (Ìṣe 6:7) Yàtọ̀ sí èyí, ọ̀pọ̀ ìròyìn nípa bí ìhìn rere ṣe tẹ̀ síwájú ló wà nínú ìwé Ìṣe. (Ìṣe 9:31; 12:24; 16:5; 19:20; 28:31) Lóde òní pẹ̀lú, ǹjẹ́ inú wa kì í dùn tá a bá gbọ́ ìròyìn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ síwájú láwọn apá ibòmíì láyé?
22 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tínú ń bí gan-an ṣì ń bá a nìṣó láti ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àmọ́, inúnibíni tó le ju ìyẹn lọ máa tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Sítéfánù sì ni wọ́n dájú sọ lọ́tẹ̀ yìí, báa ṣe máa rí i nínú orí tó kàn.
a Wo àpótí náà, “Sàhẹ́ndìrìn—Ilé Ẹjọ́ Gíga Àwọn Júù.”
b Ibi àkọ́kọ́ nìyí lára àwọn ibi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún (20) tí ìwé Ìṣe ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì ní tààràtà. Ìṣe 1:10 ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa wọn lọ́nà tí kò ṣe tààràtà nígbà tó sọ pé “ọkùnrin méjì tó wọ aṣọ funfun.”
c Wo àpótí náà, “Èèyàn Pàtàkì Ni Gàmálíẹ́lì Láàárín Àwọn Rábì.”
d Wo àpótí náà, “Ìwàásù ‘Láti Ilé dé Ilé.’”
e Àwọn ọkùnrin yẹn ti ní láti ní àwọn ìwà àti ìṣe tí Bíbélì sọ pé ó yẹ káwọn alàgbà ní, torí pé “ọ̀ràn tó pọn dandan” ni wọ́n fẹ́ bójú tó, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú un. Àmọ́ o, Ìwé Mímọ́ ò sọ ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ọkùnrin láti jẹ́ alàgbà tàbí alábòójútó nínú ìjọ.
f Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọn ló máa ń yan àwọn alàgbà. (Ìṣe 14:23; 1 Tím. 5:22; Títù 1:5) Lóde òní, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń yan àwọn alábòójútó àyíká, àwọn alábòójútó àyíká ló sì máa ń yan àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.