Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
DECEMBER 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 7-9
“Jèhófà Bù Kún Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn Tí Ẹnikẹ́ni Kò Lè Kà”
it-1 997 ¶1
Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn
Èyí lè mú ká béèrè pé: Tó bá jẹ́ pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà làwọn tí Ọlọ́run máa gbà là, tí wọ́n á sì wà lórí ilẹ̀ ayé, báwo ni wọ́n ṣe wá ‘dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà’? (Ifi 7:9) Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “dúró” láti tọ́ka sí rírí ojú rere ẹnì kan tàbí kéèyàn wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà. (Sm 1:5; 5:5; Owe 22:29, AT; Lk 1:19) Kódà, orí tó ṣáájú nínú ìwé Ìfihàn sọ pé ṣe ni “àwọn ọba ayé, àwọn aláṣẹ, àwọn ọ̀gágun, àwọn ọlọ́rọ̀, àwọn alágbára, gbogbo ẹrú àti gbogbo àwọn tó wà lómìnira” ń wá bí wọ́n á ṣe fi ara wọn “pa mọ́ kúrò lójú Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ àti kúrò lọ́wọ́ ìbínú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, torí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn ti dé, ta ló sì lè dúró?” (Ifi 6:15-17; fi wé Lk 21:36.) Torí náà, “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” làwọn tó yèbọ́ lọ́jọ́ ìbínú ńlá náà, tí wọ́n sì “dúró” gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ti rí ojú rere Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.
it-2 1127 ¶4
Ìpọ́njú
Ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti èèyàn. Nínú ìran náà, wọ́n sọ fún un pé: “Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà.” (Ifi 7:13, 14) Ti pé àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà “wá látinú ìpọ́njú ńlá náà” fi hàn pé wọ́n là á já. Ọ̀rọ̀ tó fara jọ èyí wà nínú ìwé Ìṣe 7:9, 10, tó sọ pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú [Jósẹ́fù], ó gbà á nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.” Bí Ọlọ́run ṣe gba Jósẹ́fù nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀ fi hàn pé ó fara da gbogbo ohun tó kojú. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún la gbogbo ìpọ́njú náà já.
it-1 996-997
Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn
Bá A Ṣe Dá Wọn Mọ̀. Ohun kan tó jẹ́ ká dá “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà mọ̀ ni àlàyé tí Ìfihàn orí 7 ṣe nípa wọn àtàwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó tan mọ́ ọn. Ìfihàn 7:15-17 sọ pé Ọlọ́run “fi àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n,” ó sì ń “darí wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè,” àti pé Ọlọ́run “nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.” Nínú Ìfihàn 21:2-4, a rí àwọn ọ̀rọ̀ tó tún fara jọ èyí. Bí àpẹẹrẹ, ó ní: ‘Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé,’ ó tún “nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn,” àti pé “ikú ò ní sí mọ́.” Ó dájú pé àwọn tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé ni ìran yìí ń tọ́ka sí, kì í ṣe àwọn tó máa wà lọ́run níbi tí ‘Jerúsálẹ́mù Tuntun ti ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀.’
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 12
Ábádónì
Ta ni Ábádónì tó jẹ́ áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà?
Ìfihàn 9:11 pe orúkọ “áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” náà ní “Ábádónì.” Ọ̀rọ̀ yìí lédè Gíríìkì ni Ápólíónì tó túmọ̀ sí “Apanirun.” Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, wọ́n ronú pé àwọn èèyàn bí Olú Ọba Vespasian, Muhammad, títí kan Napoleon ni Ábádónì ń ṣàpẹẹrẹ, wọn tiẹ̀ ronú pé ìránṣẹ́ èṣù ni áńgẹ́lì náà máa jẹ́. Àmọ́ ó yẹ ká fi ohun tí Ìfihàn 20:1-3 sọ sọ́kàn, pé áńgẹ́lì náà ní “kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé aṣojú Ọlọ́run láti ọ̀run ló jẹ́ kì í ṣe ti Èṣù. Yàtọ̀ síyẹn, áńgẹ́lì náà mú Sátánì, ó dè é, ó sì jù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Nígbà tí ìwé The Interpreter’s Bible ń sọ̀rọ̀ nípa Ìfihàn 9:11, ó ní: “Ábádónì kì í ṣe ìránṣẹ́ èṣù, àmọ́ ó jẹ́ ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run lò láti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run.”
Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ náà ʼavad·dohnʹ ní ìtumọ̀ tó jọra pẹ̀lú Ṣìọ́ọ̀lù àti Ikú. Nínú Ìfihàn 1:18, Jésù Kristi sọ pé: “Mo wà láàyè títí láé àti láéláé, mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Isà Òkú.” Lúùkù 8:31 tiẹ̀ jẹ́ kó hàn gbangba pé ó lágbára láti ju ẹnikẹ́ni sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Hébérù 2:14 náà sì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù lágbára láti mú ìparun wá, kódà ó lágbára láti pa Sátánì run. Ó tiẹ̀ sọ pé Jésù náà wá ní ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara “kó lè tipasẹ̀ ikú rẹ̀ pa ẹni tó lè fa ikú run, ìyẹn Èṣù.” Ìfihàn 19:11-16 náà tún fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí Apanirun àti Amúdàájọ́ṣẹ.—Wo ÁPÓLÍÓNÌ.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 10-12
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 880-881
Àkájọ Ìwé
Ohun Tó Ṣàpẹẹrẹ. Àwọn ìgbà kan wà tí Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “àkájọ ìwé” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ìsíkíẹ́lì rí àkájọ ìwé kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ síwájú àtẹ̀yìn rẹ̀, Sekaráyà náà sì rí irú àkájọ ìwé bẹ́ẹ̀. Ojú kan ni wọ́n sábà máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí nínú àkájọ ìwé, àmọ́ bí wọ́n ṣe kọ̀rọ̀ síwájú àtẹ̀yìn ìwé náà ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí bí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe lágbára tó àti pé ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó wà nínú rẹ̀ kì í ṣọ̀rọ̀ ṣeréṣeré rárá. (Isk 2:9–3:3; Sek 5:1-4) Nínú ìran tó wà nínú Ìfihàn, ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ mú àkájọ ìwé kan dání sọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, wọ́n sì fi èdìdì méje dì í pinpin, èyí ni ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ títí tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run fi ṣí i. (Ifi 5:1, 12; 6:1, 12-14) Nígbà tó yá nínú ìran yẹn, áńgẹ́lì kan fún Jòhánù ní àkájọ ìwé kan, ó sì pàṣẹ fún un pé kó jẹ ẹ́. Ìwé náà dùn lẹ́nu Jòhánù, àmọ́ ó korò ní ikùn rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tó sì jẹ́ pé wọn ò fi èdìdì di àkájọ ìwé náà, á jẹ́ pé èèyàn lè mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Ó “dùn” mọ́ Jòhánù láti rí ọ̀rọ̀ gbankọgbì tó wà nínú rẹ̀, àmọ́ ó korò ní ti pé, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n pàṣẹ fún un pé kó kéde kò rọrùn rárá. (Ifi 10:1-11) Ohun tó fara jọ èyí náà ṣẹlẹ̀ sí Ìsíkíẹ́lì torí pé “orin arò, ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ àti ìpohùnréré ẹkún” ló wà nínú àkájọ ìwé tóun náà fẹ́ kéde rẹ̀.—Isk 2:10.
it-2 187 ¶7-9
Ìrora Ìrọbí
Nínú ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú Ìfihàn, ó rí obìnrin kan ní ọ̀run tí ‘ìrora àti ìnira mú kó máa ké jáde bó ṣe ń rọbí.’ Ó sì rí i tó bí “ọmọ kan, ọkùnrin ni, ẹni tó máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” Láìka gbogbo ìsapá dírágónì náà láti pa ọmọ náà jẹ, ṣe la “já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.” (Ifi 12:1, 2, 4-6) Bá a ṣe já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ọmọ náà gẹ́gẹ́ bíi tirẹ̀, ó sì jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ láyé àtijọ́ pé ká gbé ọmọ tuntun kan lọ sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ kó lè tẹ́wọ́ gbà á. (Wo ỌMỌ BÍBÍ.) Ó ṣe kedere nígbà náà pé “obìnrin” náà ní láti jẹ́ “ìyàwó” Ọlọ́run, ìyẹn “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” “ìyá” Kristi àtàwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí.—Ga 4:26; Heb 2:11, 12, 17.
Kò sí àní-àní pé ẹni pípé ni “obìnrin” Ọlọ́run yìí jẹ́, kò sì lè ní ìrora nípa tara. Torí náà, ìrora ìrọbí náà ń ṣàpẹẹrẹ pé “obìnrin” náà máa mọ̀ pé àsìkò tóun fẹ́ bímọ ti tó; á sì máa fojú sọ́nà pé òun máa bímọ láìpẹ́.—Ifi 12:2.
Ta ni ‘ọmọkùnrin’ náà máa jẹ́? Òun ló máa “fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” Sáàmù 2:6-9 náà sọ tẹ́lẹ̀ pé ohun tí Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe nìyẹn. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Kristi sáyé, tó kú, tó sì jíǹde ni Jòhánù rí ìran yìí. Torí náà, ó jọ pé ìràn yìí ń tọ́ka sí ìbí Ìjọba Mèsáyà tí Jésù Kristi, ọmọ Ọlọ́run máa ṣàkóso. Torí nígbà tí Ọlọ́run jí i dìde, ó “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, látìgbà yẹn, ó ń dúró de ìgbà tí a máa fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.”—Heb 10:12, 13; Sm 110:1; Ifi 12:10.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 17-19
“Ogun Tó Máa Fòpin sí Gbogbo Ogun”
it-1 1146 ¶1
Ẹṣin
Nínú ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo ń gun ẹṣin funfun kan, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn náà gun ẹṣin funfun sì ń tẹ̀ lé e. Ìran tí Jòhánù rí yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé ogun òdodo ni Kristi fẹ́ bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run jà àti pé Jèhófà Bàbá rẹ̀ àti Ọlọ́run rẹ̀ ló ń ṣojú fún. (Ifi 19:11, 14) Ṣáájú ìyẹn, Jòhánù rí àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tó ṣàpẹẹrẹ ìgbà tí Jésù gba agbára ìṣàkóso àtàwọn àjálù tó tẹ̀ lé e.—Ifi 6:2-8.
DECEMBER 30–JANUARY 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 20-22
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 249 ¶2
Ìyè
Ó ṣe kedere nínú òfin tí Ọlọ́run fún Ádámù pé tí Ádámù bá ṣègbọràn, kò ní kú. (Jẹ 2:17) Torí náà, tó bá dọjọ́ iwájú tí Ọlọ́run bá sọ ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn di asán, kò ní sí ohun táá máa fa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú fáwọn tó bá jẹ́ onígbọràn mọ́, títí láé ni wọ́n máa wà láàyè. (1Kọ 15:26) Lẹ́yìn tí ìṣàkóso Kristi tí ìwé Ìfihàn sọ pé ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bá dópin ni Ọlọ́run máa sọ ikú di asán. Bíbélì sọ pé àwọn tó máa di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi máa ‘pa dà wà láàyè, wọ́n á sì jọba pẹ̀lú Kristi fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.’ Àwọn wo wá ni “àwọn òkú yòókù” tí Bíbélì sọ pé kò ní wà láàyè “títí dìgbà tí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún náà parí”? Àwọn yìí ni àwọn tó máa wà láàyè lẹ́yìn tí ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso náà bá parí, ìyẹn ṣáájú kí wọ́n tó tú Sátánì sílẹ̀ látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ kó lè mú ìdánwò ìkẹyìn wá fáráyé. Nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá máa parí, gbogbo àwọn tó wà láyé á ti di pípé bí Ádámù àti Éfà ṣe wà kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀, àwọn náà máa pé láìní àbùkù kankan. Àwọn tó bá wá yege ìdánwò ìkẹyìn lẹ́yìn tí wọ́n bá tú Sátánì sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ ló máa gbádùn ìyè títí láé àti láéláé.—Ifi 20:4-10.
it-2 189-190
Adágún Iná
Inú ìwé Ìfihàn nìkan ni ọ̀rọ̀ yìí ti fara hàn, ó sì ṣe kedere pé ṣe ló ṣàpẹẹrẹ ohun kan. Bíbélì sọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà ṣàpẹẹrẹ nígbà tó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà.”—Ifi 20:14; 21:8
Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà nínú ìwé Ìfihàn tún jẹ́ kó hàn gbangba pé ṣe ló wulẹ̀ ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé a ju ikú sínú adágún iná náà. (Ifi 19:20; 20:14) Kò sí àní-àní pé ikú kì í ṣe ohun tá a lè fi iná gidi kan sun. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ pé a ju Èṣù tó jẹ́ ẹni ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí sínú adágún iná náà. Torí pé ẹni ẹ̀mí ni Èṣù, kò sí bí iná gidi kan ṣe lè ṣèpalára fún un.—Ifi 20:10; fi wé Ẹk 3:2 àti Ond 13:20.
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé adágún iná náà ṣàpẹẹrẹ “ikú kejì,” tí Ìfihàn 20:14 sì sọ pé a ju “ikú àti Isà Òkú” sínú rẹ̀, á jẹ́ pé adágún iná náà ò lè ṣàpẹẹrẹ ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù (Ro 5:12), kò sì lè ṣàpẹẹrẹ Isà Òkú. Torí náà, ó dájú pé ikú míì ni adágún iná náà ń ṣàpẹẹrẹ, àwọn tó bá sì kú ikú yìí kò ní lájíǹde mọ́. Ìdí ni pé kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé adágún iná náà yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, bí ikú tí Ádámù fà àti Isà Òkú ṣe yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn. (Ifi 20:13) Fún ìdí yìí, àwọn tí orúkọ wọn ò bá sí nínú “ìwé ìyè,” ìyẹn àwọn ẹni burúkú tí kò ṣe tán láti fara mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run la máa jù sínú adágún iná náà tó túmọ̀ sí ìparun ayérayé tàbí ikú kejì.—Ifi 20:15.
Bíbélì Kíkà