Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Fílípì Batisí Ìjòyè Òṣìṣẹ́ Ará Etiópíà kan
BÍ Ó ti ń lọ lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ará Etiópíà kan ń fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ̀. Ó ń kàwé sókè—àṣà tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn arìnrìn àjò ọ̀rúndún kìíní. Ọkùnrin tí a ń sọ yìí jẹ́ ìjòyè òṣìṣẹ́ “tí ó wà ní ipò agbára lábẹ́ Káńdésì ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà.”a Ó “ń bójú tó gbogbo ìṣúra rẹ̀”—ìyẹn ni pé, ó jẹ́ mínísítà ìnáwó. Ìjòyè òṣìṣẹ́ yìí ń kà láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ó ba lè jèrè ìmọ̀.—Ìṣe 8:27, 28.
Ajíhìnrere Fílípì wà nítòsí. Áńgẹ́lì kán ti darí rẹ̀ sí agbègbè yìí, a sì sọ fun nísinsìnyí pé: “Sún mọ́ ọn kí o sì da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí.” (Ìṣe 8:26, 29) A lè fojú inú wo Fílípì tí ó ń bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Ta ni ọkùnrin yìí? Kí ni ó ń kà? Èé ṣe tí a fi daríì mi sí i?’
Bí Fílípì ti ń sáré lẹ́gbẹ̀ẹ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà, ó gbọ́ tí ará Etiópíà náà ń ka ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn kan a mú un wá fún pípa, àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn kan tí kò lè fọhùn níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun kò la ẹnu rẹ̀. Nígbà ìtẹ́lógo rẹ̀ a mú ìdájọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ta ni yóò sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀? Nítorí a mú ìwàláàyè rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 8:32, 33.
Lọ́gán Fílípì lóye àyọkà náà. Ó jẹ́ láti inú àkọsílẹ̀ Aísáyà. (Aísáyà 53:7, 8) Ohun ti ará Etiópíà náà ń kà gbà á lọ́kàn. Fílípì bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nípa bíbéèrè pé: “Ní ti gàsíkíá ìwọ́ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ará Etiópíà náà fèsì pé: “Ní ti gidi, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kán fi mí mọ̀nà?” Lẹ́yìn náà, ó pàrọwà fún Fílípì láti dára pọ̀ mọ́ òun nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.—Ìṣe 8:30, 31.
“Kí Ni Ó Dí Mi Lọ́wọ́ Dídi Ẹni Tí A Batisí?”
Ará Etiópíà náà sọ fún Fílípì pé: “Mo bẹ̀ ọ́, Ta ni wòlíì náà wí èyí nípa rẹ̀? Nípa ara rẹ̀ ni tàbí nípa ọkùnrin mìíràn?” (Ìṣe 8:34) Àìlóye ará Etiópíà náà kò yani lẹ́nu, nítorí ìtumọ̀ “àgùntàn,” tàbí “ìránṣẹ́,” ti inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti jẹ́ àdììtú fún ìgbà pípẹ́. (Aísáyà 53:11) Ẹ wo bí èyí yóò ti ṣe kedere tó nígbà tí Fílípì polongo “ìhìn rere nípa Jésù” fún ará Etiópíà náà! Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ará Etiópíà náà sọ pé: “Wò ó! Ìwọ́jọpọ̀ omi; kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” Nítorí náà, Fílípì batisí rẹ̀ lọ́gán.—Ìṣe 8:35-38.
Èyí ha jẹ́ ìgbésẹ̀ oníwàǹwára bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ará Etiópíà náà jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù kan.b Nítorí náà, òún ti jẹ́ olùjọsìn Jèhófà tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ nípa Ìwé Mímọ́, àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Mèsáyà. Ṣùgbọ́n, ìmọ̀ rẹ̀ kò pé. Nísinsìnyí tí òún ti gba ìsọfúnni ṣíṣe kókó yìí nípa ipa iṣẹ́ Jésù Kristi, ará Etiópíà náà lóye ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ṣe tán láti pa á mọ́. Batisí bá a mu wẹ́kú.—Mátíù 28:18-20; Pétérù Kìíní 3:21.
Lẹ́yìn ìgbà náà, “ẹ̀mi Jèhófà ṣamọ̀nà Fílípì lọ kíákíá.” Ó kọjá lọ sẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn. Ará Etiópíà náà “ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ ó ń yọ̀.”—Ìṣe 8:39, 40.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n fún Wa
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní, ojúṣe wa ni láti ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ti ṣàṣeyọrí ní sísọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò tàbí ní àwọn àyíká ipò tí kò jẹ́ bí àṣà míràn. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba, lọ́dọọdún, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà Ọlọ́run nípa ṣíṣe batisí.
Àmọ́ ṣáá o, a kò gbọdọ̀ kánjú ti àwọn ẹni tuntun sí ṣíṣe batisí. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ gba ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi. (Jòhánù 17:3) Lẹ́yìn náà, wọ́n gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, ní kíkọ ìwà àìtọ́ sílẹ̀ àti yíyí padà láti lè bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. (Ìṣe 3:19) Èyí ń gba àkókò, pàápàá tí èrò àti ìwà àìtọ́ bá ti ta gbòǹgbò jinlẹ̀. Nígbà tí ó yẹ kí àwọn ẹni tuntún ṣírò ohun tí jíjẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn yóò náni, ìbùkún tabua ń wá láti inú wíwọnú ipò ìbátan oníyàsímímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. (Fi wé Lúùkù 9:23; 14:25-33.) Àwọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ń fi tìtaratìtara darí irú àwọn ẹni tuntun bẹ́ẹ̀ sínú ètò àjọ tí Ọlọ́run ń lò láti mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ. (Mátíù 24:45-47) Gẹ́gẹ́ bí ará Etiópíà náà, àwọn wọ̀nyí yóò yọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n sì pa á mọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Káńdésì” kì í ṣe orúkọ ṣùgbọ́n oyè (ó fara jọ “Fáráò” àti “Késárì”) tí a lò fún àwọn ọbabìnrin Etiópíà tí wọ́n jẹ tẹ̀ léra.
b Àwọn aláwọ̀ṣe jẹ́ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n yàn láti rọ̀ mọ́ Òfin Mósè.—Léfítíkù 24:22.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Èé Ṣe Tí A Fi Pè É Ní Ìwẹ̀fà?
Jálẹ̀ ìròyìn Ìṣe orí 8, a tọ́ka sí ará Etiópíà náà gẹ́gẹ́ bí “ìwẹ̀fà.” Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí Òfin Mósè kò ti fàyè gba ọkùnrin tí a ti tẹ̀ lọ́dàá láti wá sínú ìjọ, ó dájú pé ọkùnrin yìí kì í ṣe ìwẹ̀fà ní ti gidi. (Diutarónómì 23:1) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “ìwẹ̀fà” lè tọ́ka sí ẹnì kan tí ó wà ní ipò gíga. Nípa báyìí, ará Etiópíà náà jẹ́ ìjòyè òṣìṣẹ́ lábẹ́ ọbabìnrin Etiópíà.