Onínúnibíni Rí Ìmọ́lẹ̀ Ńlá
INÚ Sọ́ọ̀lù ń ru gùdù sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. Inúnibíni tí wọ́n ṣe sí wọn ní Jerúsálẹ́mù, títí kan bí wọ́n ṣe sọ Sítéfánù lókùúta pa, kò tíì tó lójú ẹ̀ rárá, ní báyìí, ó ń wá ọ̀nà láti mú kí inúnibíni náà gbóná sí i. “[Sọ́ọ̀lù], tí ó ṣì ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, lọ bá àlùfáà àgbà, ó sì béèrè fún àwọn lẹ́tà sí àwọn sínágọ́gù ní Damásíkù, kí ó lè mú ẹnikẹ́ni tí ó bá rí tí ó jẹ́ ti Ọ̀nà Náà wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè, àti ọkùnrin àti obìnrin.”— Ìṣe 9:1, 2.
Bí Sọ́ọ̀lù ṣe kọrí sọ́nà Damásíkù yẹn, yóò ti máa ronú nípa ọ̀nà tó lè rọrùn fún òun jù láti ṣe ohun tí òun fẹ́ lọ ṣe. Ó dájú pé àṣẹ tí àlùfáà àgbà fún un ti fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun yóò rí ìtìlẹ́yìn àwọn aṣáájú àwùjọ ńlá ti àwọn Júù tó wà ní ìlú yẹn. Sọ́ọ̀lù yóò sọ pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́.
Inú Sọ́ọ̀lù yóò túbọ̀ máa dùn ni, bó ṣe ń sún mọ́ ibi tó ń lọ. Ìrìn àjò rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù sí Damásíkù—ọ̀nà tó jìn tó nǹkan bíi kìlómítà okòólénígba, tó sì gba ìrìn ọjọ́ méje tàbí mẹ́jọ—ti ní láti jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu. Lójijì ní nǹkan bí ọwọ́ ọ̀sán ni ìmọ́lẹ̀ kan tí títàn rẹ̀ kọjá ti oòrùn yí Sọ́ọ̀lù ká, ló bá ṣubú lulẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn kan tó ń sọ fún un ní èdè Hébérù pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Láti máa bá a nìṣó ní títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́ mú kí ó nira fún ọ.” Sọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ta ni ọ́, Olúwa.” Èsì tó gbọ́ ni pé: “Èmi ni Jésù, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Nítorí fún ète yìí ni mo ṣe mú kí o rí mi, kí èmi lè yàn ọ́ ṣe ẹmẹ̀wà àti ẹlẹ́rìí àwọn ohun tí ìwọ ti rí àti àwọn ohun tí èmi yóò mú kí o rí nípa mi; nígbà tí èmi yóò dá ọ nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yìí àti kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, tí èmi ń rán ọ sí.” Sọ́ọ̀lù wá béèrè pé: “Kí ni kí n ṣe, Olúwa?” “Dìde, bá ọ̀nà rẹ lọ sí Damásíkù, ibẹ̀ sì ni wọn yóò ti sọ fún ọ nípa ohun gbogbo tí a ti yàn kalẹ̀ fún ọ láti ṣe.”—Ìṣe 9:3-6; 22:6-10; 26:13-17.
Àwọn tó ń rìnrìn àjò pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù gbọ́ ohùn kan, ṣùgbọ́n wọn ò rí ẹni tó ń sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lóye ohun tó sọ. Bí títàn ìmọ́lẹ̀ náà ṣe pọ̀ tó, kò jẹ́ kí Sọ́ọ̀lù ríran nígbà tó dìde, ńṣe ni wọ́n dì í lọ́wọ́ mú kúrò níbẹ̀. “Kò sì rí ohunkóhun fún ọjọ́ mẹ́ta, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò mu.”—Ìṣe 9:7-9; 22:11.
Ọjọ́ Mẹ́ta fún Ṣíṣe Àṣàrò
Júdásì, tó ń gbé ní ojú pópó tí a ń pè ní Títọ́, gba Sọ́ọ̀lù lálejò.a (Ìṣe 9:11) Ojú pópó yìí—tí a ń pè ní Darb al-Mustaqim ní èdè Lárúbáwá—ṣì jẹ́ ojú ọ̀nà kan ní Damásíkù títí di òní olónìí. Fojú inú wo ohun tí Sọ́ọ̀lù lè máa rò nígbà tó wà nílé Júdásì. Ìrírí tí Sọ́ọ̀lù ní yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì ti kó jìnnìjìnnì bá a. Àkókò wá wà fún un wàyí láti ronú lórí ohun tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn túmọ̀ sí.
Ohun tí onínúnibíni náà ti kà sí ẹ̀fẹ̀ lásán wá ń di òótọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Jésù Kristi Olúwa tí a kàn mọ́gi—tí àwọn aláṣẹ Júù gíga jù lọ ti dá lẹ́bi, ‘táwọn èèyàn tẹ́ńbẹ́lú tí wọ́n sì ń yẹra fún’—wà láàyè. Họ́wù, ó tiẹ̀ tún wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run nínú “ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́”! Jésù ni Mèsáyà náà. Òótọ́ ni ohun tí Sítéfánù àtàwọn yòókù sọ. (Aísáyà 53: 3; Ìṣe 7:56; 1 Tímótì 6:16) Àṣé àṣìṣe ńlá tiẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù ti ń ṣe, nítorí pé Jésù jẹ́ kí ó mọ̀ pé òun alára wà lára àwọn tí Sọ́ọ̀lù ń ṣe inúnibíni sí! Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tó hàn kedere wọ̀nyí, báwo ni Sọ́ọ̀lù ó ṣe máa “bá a nìṣó ní títàpá sí kẹ́sẹ́”? Kódà bópẹ́bóyá akọ màlúù kan tó jẹ́ olóríkunkun yóò ṣe ohun tí olówó rẹ̀ fẹ́. Nítorí náà, bí Sọ́ọ̀lù bá wá kọ̀ pé òun ò ní ṣe ohun tí Jésù fẹ́, ó wulẹ̀ ń ṣe ara rẹ̀ ni.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù ni Mèsáyà náà, ó dájú pé Ọlọ́run ò lè dá a lẹ́bi. Síbẹ̀ Jèhófà ti yọ̀ǹda rẹ̀ láti joró ikú tó burú jù lọ, ó sì tún jẹ́ kí ó wà lára àwọn tí Òfin sọ nípa wọn pé: “Ohun ègún Ọlọ́run ni ẹni tí a gbé kọ́.” (Diutarónómì 21:23) Jésù kú nígbà tí wọ́n gbé e kọ́ sórí igi oró. Ègún tí ó gbà kì í ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ fúnra rẹ̀, nítorí pé kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan, àmọ́ ó gbà á nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìran ènìyàn. Sọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé níkẹyìn pé: “Gbogbo àwọn tí ó gbára lé àwọn iṣẹ́ òfin wà lábẹ́ ègún; nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ègún ni fún olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ láti dúró nínú gbogbo ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé Òfin láti ṣe wọ́n.’ Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó hàn gbangba pé nípa òfin, kò sí ẹnì kankan tí a polongo ní olódodo lọ́dọ̀ Ọlọ́run . . . Kristi nípa rírà, tú wa sílẹ̀ kúrò lábẹ́ ègún Òfin nípa dídi ègún dípò wa, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹni ègún ni olúkúlùkù ènìyàn tí a gbé kọ́ sórí òpó igi.’”—Gálátíà 3:10-13.
Ẹbọ Jésù ní agbára láti rani padà. Nípa títẹ́wọ́ gba ẹbọ yẹn, Jèhófà kan Òfin náà àti ègún rẹ̀ mọ́gi lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù lóye kókó yẹn, ó wá ṣeé ṣe fún un láti fojú pàtàkì wo igi oró náà, ó kà á sí “ọgbọ́n Ọlọ́run,” tó sì jẹ́ pé “lójú àwọn Júù okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀” ni. (1 Kọ́ríńtì 1:18-25; Kólósè 2:14) Nítorí náà, tó bá jẹ́ pé kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin ni a ó ti rí ìgbàlà, tó jẹ́ pé nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run ń fi fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bíi Sọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ni, nígbà náà yóò ṣeé ṣe kí àǹfààní náà dé ọ̀dọ̀ àwọn tí kò sí lábẹ́ Òfin. Àwọn Kèfèrí sì ni Jésù fẹ́ rán Sọ́ọ̀lù sí.—Éfésù 3:3-7.
A ò lè sọ bí Sọ́ọ̀lù ṣe lóye èyí tó ní àkókò tó yí padà. Jésù ní láti bá a sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ pàápàá, ìyẹn nípa iṣẹ́ tó fẹ́ lọ jẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè. Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí Sọ́ọ̀lù tó kọ èyí sílẹ̀ lábẹ́ ìmísí àtọ̀runwá. (Ìṣe 22:17-21; Gálátíà 1:15-18; 2:1, 2) Àmọ́, ọjọ́ díẹ̀ péré ló kọjá kí Sọ́ọ̀lù tó rí àṣẹ gbà látọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ tuntun.
Ananíà Ṣèbẹ̀wò
Lẹ́yìn tí Jésù fara han Sọ́ọ̀lù, ó tún fara han Ananíà, ó sì wí fún un pé: “Lọ sí ojú pópó tí a ń pè ní Títọ́, àti pé nínú ilé Júdásì, wá ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù, láti Tásù. Nítorí, wò ó! ó ń gbàdúrà, nínú ìran, ó ti rí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ananíà tí ó wọlé wá, tí ó sì gbé ọwọ́ lé e kí ó lè tún máa ríran.”—Ìṣe 9:11, 12.
Mímọ̀ tí Ananíà mọ Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ ló jẹ́ ká lóye ìdí tí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù fi yà á lẹ́nu. Ó ní: “Olúwa, mo ti gbọ́ nípa ọkùnrin yìí láti ẹnu ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí ohun aṣeniléṣe tí ó ṣe sí àwọn ẹni mímọ́ rẹ ní Jerúsálẹ́mù ti pọ̀ tó. Ní báyìí, ó ti gba ọlá àṣẹ láti ọwọ́ àwọn olórí àlùfáà láti fi gbogbo àwọn tí ń ké pe orúkọ rẹ sínú àwọn ìdè.” Àmọ́, Jésù wí fún Ananíà pé: “Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, nítorí ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti gbé orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Ìṣe 9:13-15.
Pẹ̀lú ìfọkànbalẹ̀, Ananíà dorí kọ àdírẹ́sì ibi tí Jésù fún un. Bí Ananíà ṣe rí Sọ́ọ̀lù báyìí tó sì kí i, ló bá gbé ọwọ́ lé e lórí. Ohun tí àkọsílẹ̀ náà sọ ni pé “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ohun tí ó rí bí ìpẹ́ jábọ́ kúrò ní ojú [Sọ́ọ̀lù], ó sì tún ń ríran.” Sọ́ọ̀lù ti wá ṣe tán láti fetí sílẹ̀ báyìí. Ọ̀rọ̀ tí Ananíà sọ fìdí àwọn ohun tó ṣeé ṣe kí Sọ́ọ̀lù ti lóye nínú ọ̀rọ̀ Jésù múlẹ̀ pé: “Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa ti yàn ọ́ láti wá mọ ìfẹ́ rẹ̀ àti láti rí Ẹni olódodo náà àti láti gbọ́ ohùn ẹnu rẹ̀, nítorí pé ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún un sí gbogbo ènìyàn nípa àwọn ohun tí ìwọ ti rí, tí o sì ti gbọ́. Nísinsìnyí, èé ti ṣe tí ìwọ fi ń jáfara? Dìde, kí a batisí rẹ, kí o sì wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù nípa kíké tí o bá ń ké pe orúkọ rẹ̀.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Sọ́ọ̀lù “dìde, a sì batisí rẹ̀, ó jẹ oúnjẹ, ó sì jèrè okun.”—Ìṣe 9:17-19; 22:12-16.
Lẹ́yìn tí Ananíà olóòótọ́ parí iṣẹ́ rẹ̀, ó tán, a ò gbọ́ ohunkóhun nípa rẹ̀ mọ́. Àmọ́, gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Sọ́ọ̀lù lẹnu ń yà! Ẹni tí ń ṣe inúnibíni tẹ́lẹ̀, tó jẹ́ pé ó wá sí Damásíkù láti mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ni sínágọ́gù, ó sì ń fẹ̀rí hàn pé Jésù ni Kristi náà.—Ìṣe 9:20-22.
“Àpọ́sítélì fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
Ohun tí Sọ́ọ̀lù bá pàdé lójú ọ̀nà sí Damásíkù ni kò jẹ́ kí ó máa bá inúnibíni tó ń ṣe lọ mọ́. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ti wá mọ ẹni tí Mèsáyà náà jẹ́, ó lè wá darí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àti àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí Jésù. Mímọ̀ tí Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jésù ti fara han òun, pé ó ‘ti mú òun’ ó sì ti yanṣẹ́ fún òun gẹ́gẹ́ bí “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” ti ní láti ní ipa tó lágbára nínú yíyí ìgbésí ayé Sọ́ọ̀lù padà. (Fílípì 3:12; Róòmù 11:13) Nísinsìnyí, tó ti wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó ní àǹfààní àti ọlá àṣẹ tó jẹ́ pé yóò nípa lórí ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àti ìtàn ẹ̀sìn Kristẹni.
Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí awuyewuye dìde lórí bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ àpọ́sítélì, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ní ọlá àṣẹ náà nípa títọ́ka sí ìrírí rẹ̀ lójú ọ̀nà Damásíkù. Ó béèrè pé: “Èmi kì í ha ṣe àpọ́sítélì bí? Èmi kò ha ti rí Jésù Olúwa wa bí?” Lẹ́yìn tó mẹ́nu kan bí Jésù tó jí dìde ṣe fara han àwọn tó kù, Sọ́ọ̀lù (Pọ́ọ̀lù) sọ pé: “Ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.” (1 Kọ́ríńtì 9:1; 15:8) Ó dà bí ẹni pé ìran tí Sọ́ọ̀lù rí nípa ògo Jésù lókè ọ̀run ti jẹ́ kí ó ní àǹfààní dídi ẹni tí a bí tàbí tí a jí dìde sí ìyè tẹ̀mí ṣáájú àkókò tó yẹ́ kó ṣẹlẹ̀.
Sọ́ọ̀lù mọyì àǹfààní tó ní, ó sì tiraka láti kún ojú ìwọ̀n rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Èmi ni mo kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì, èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì, nítorí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n . . . inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọ́run] tí ó sì wà fún mi kò já sí asán, ṣùgbọ́n mo ṣe òpò púpọ̀ ju gbogbo [àpọ́sítélì yòókù lọ].”—1 Kọ́ríńtì 15: 9, 10.
Bóyá ìwọ náà ti ṣe bíi ti Sọ́ọ̀lù, tóo ri pé kí o tó lè rí ojú rere Ọlọ́run gbà, o ní láti tún èrò àtọjọ́mọ́jọ́ tóo ní nípa ìsìn rẹ ṣe. Ó dájú pé o kún fún ìmoore gan-an pé Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rí ìmọ́lẹ̀ náà, tó sì lóye ohun tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, kò lọ́tìkọ̀ láti ṣe é. Ó sì fi ìtara àti ìmúratán ṣe é ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀. Àpẹẹrẹ gíga lọ́lá lèyí mà jẹ́ lónìí o, fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ rí ojú rere Jèhófà!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan rò pé Júdásì ní láti jẹ́ aṣáájú àwùjọ àwọn Júù tó wà ládùúgbò náà tàbí kó jẹ́ pé ó ní ilé èrò kan tí àwọn Júù lè dé sí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ojú pópó tí a ń pè ní Títọ́ ní Damásíkù òde òní
[Credit Line]
Fọ́tò látọ̀dọ̀ ROLOC Color Slides