ORÍ 10
“Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Gbilẹ̀”
Áńgẹ́lì tú Pétérù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ìhìn rere sì ń gbilẹ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni
Ó dá lórí Ìṣe 12:1-25
1-4. Ipò tó nira wo ni Pétérù dojú kọ, báwo ló sì ṣe máa rí lára ẹ ká ní ìwọ ni Pétérù?
WỌ́N tilẹ̀kùn onírin mọ́ Pétérù gbàgà. Pétérù wà láàárín àwọn ọmọ ogun Róòmù méjì tí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ so ọwọ́ rẹ̀ mọ́ tiwọn, wọ́n sì lọ tì í mọ́lé. Ó wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ó sì ṣeé ṣe kó tó bí ọjọ́ mélòó kan tó lò níbẹ̀ tó ń retí ohun tí wọ́n máa ṣe fún un. Kò sí ohun míì tó rí ju ògiri ẹ̀wọ̀n, àwọn àgádágodo, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n.
2 Pétérù gbọ́ ìròyìn burúkú kan. Ọba Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kìíní ti pinnu láti pa á.a Kódà, wọ́n ti pinnu láti mú un wá síwájú àwọn èèyàn lẹ́yìn Ìrékọjá, kí wọ́n lè fi ikú ẹ̀ dá àwọn èèyàn náà lára yá. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré o. Torí kò tíì pẹ́ tí aláṣẹ kan náà yìí pa Jémíìsì tóun náà jẹ́ àpọ́sítélì.
3 Ronú nípa ipò tí Pétérù máa wà lálẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ pa á. Kí ló lè máa rò nínú àtìmọ́lé tó ṣókùnkùn tí wọ́n fi sí? Ṣé ó rántí ohun tí Jésù sọ lọ́dún kan ṣáájú ìgbà yẹn pé, lọ́jọ́ kan wọ́n máa dè é, wọ́n á sì mú un lọ síbi tí kò fẹ́, kí wọ́n lè pa á? (Jòh. 21:18, 19) Ó ṣeé ṣe kí Pétérù máa ronú pé àkókò náà ló ti tó yẹn.
4 Ká ní ìwọ ni Pétérù báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ọ̀pọ̀ ló máa rò pé kò sọ́nà àbáyọ kankan mọ́. Àmọ́, ṣé ìṣòro kan lè dé bá ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi tó jẹ́ olóòótọ́, tí kò sì ní sọ́nà àbáyọ? Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tí Pétérù àtàwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ ṣe nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
“Ìjọ Ń Gbàdúrà Kíkankíkan” (Ìṣe 12:1-5)
5, 6. (a) Kí nìdí tí Ọba Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kìíní fi ń ni ìjọ Kristẹni lára, báwo ló sì ṣe ṣe é? (b) Kí nìdí tí ikú Jémíìsì fi jẹ́ àdánwò ńlá fún ìjọ?
5 Bá a ṣe sọ nínú orí tó ṣáájú nínú ìwé yìí, ìdùnnú ńlá ló jẹ́ fún ìjọ Kristẹni bí Kèfèrí náà Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀ ṣe di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ báwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn tí kì í ṣe Júù ṣe ń jọ́sìn pa pọ̀ ní fàlàlà ti ní láti ya àwọn Júù tí kì í ṣe onígbàgbọ́ lẹ́nu.
6 Olóṣèlú tó gbọ́n féfé ni Hẹ́rọ́dù, ó sì rí èyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan tó fi lè rí ojú rere àwọn Júù, torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ni àwọn Kristẹni lára. Ó ti ní láti gbọ́ pé àpọ́sítélì Jémíìsì sún mọ́ Jésù Kristi dáadáa. Torí náà, Hẹ́rọ́dù “fi idà pa Jémíìsì arákùnrin Jòhánù.” (Ìṣe 12:2) Ẹ ò rí i pé àdánwò ńlá nìyẹn jẹ́ fún ìjọ! Jémíìsì wà lára àwọn mẹ́ta tó rí Jésù nígbà ìyípadà ológo àti nígbà tó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu kan táwọn àpọ́sítélì yòókù kò rí. (Mát. 17:1, 2; Máàkù 5:37-42) Jésù pe Jémíìsì àti arákùnrin rẹ̀ Jòhánù ní “Àwọn Ọmọ Ààrá” nítorí ìtara wọn tó múná. (Máàkù 3:17) Àdánù ńlá ni ikú àpọ́sítélì onígboyà tó jẹ́ adúróṣinṣin, táwọn ará sì fẹ́ràn yìí jẹ́ fún ìjọ.
7, 8. Kí ni ìjọ ń ṣe nígbà tí Pétérù wà lẹ́wọ̀n?
7 Ikú Jémíìsì múnú àwọn Júù dùn gan-an bí Ágírípà ṣe fẹ́ kó rí. Ìyẹn ló ki ọba yìí láyà láti tún mú Pétérù. Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, ó fàṣẹ mú Pétérù. Ó ṣeé ṣe kí Ágírípà rántí pé ọgbà ẹ̀wọ̀n ò tu irun kankan lára àwọn àpọ́sítélì mọ́, bá a ṣe rí i ní Orí 5 ìwé yìí. Lọ́tẹ̀ yìí, torí pé Hẹ́rọ́dù ò fẹ́ kí Pétérù bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́, ó ní kí wọ́n kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́, kó sì wà láàárín ẹ̀ṣọ́ méjì tí wọ́n dúró tì í gbágbáágbá. Àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rìndínlógún (16) ló ń ṣọ́ ọ, tí wọ́n ń gba iṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn látàárọ̀ ṣúlẹ̀ títí di ọjọ́ kejì, kí àpọ́sítélì yìí má bàa bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Tó bá fi lè lọ pẹ́rẹ́n, àwọn ló máa gba ikú ẹ̀ kú. Nírú ipò tó nira yìí, kí làwọn Kristẹni tó kù máa ṣe?
8 Ìjọ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ìṣe 12:5 sọ pé: “Nítorí náà, wọ́n fi Pétérù sínú ẹ̀wọ̀n, àmọ́ ìjọ ń gbàdúrà kíkankíkan sí Ọlọ́run nítorí rẹ̀.” Dájúdájú, àdúrà àtọkànwá ni wọ́n gbà nítorí arákùnrin wọn olùfẹ́ ọ̀wọ́n yìí. Wọn ò jẹ́ kí ikú Jémíìsì mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí wọ́n rò pé àdúrà ò já mọ́ nǹkan kan. Ojú pàtàkì ni Jèhófà fi máa ń wo àdúrà, ó sì máa ń dáhùn àwọn àdúrà tó bá bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Héb. 13:18, 19; Jém. 5:16) Ẹ̀kọ́ tó yẹ káwa Kristẹni fi sọ́kàn lèyí jẹ́.
9. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni tó gbàdúrà nítorí Pétérù?
9 Ṣé o mọ àwọn ará wa kan tí wọ́n ń fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro? Ó lè jẹ́ inúnibíni, bóyá àwọn aláṣẹ sọ pé kí wọ́n má wàásù mọ́, tàbí kó jẹ́ pé àjálù ló ṣẹlẹ̀ sí wọn. Á dáa tó o bá lè máa gbàdúrà àtọkànwá fún wọn. O tún lè mọ̀ àwọn kan tí wọ́n ń fara da àwọn ìṣòro tó yàtọ̀, ó lè jẹ́ ìṣòro ìdílé, ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àwọn ìṣòro kan tó fẹ́ paná ìgbàgbọ́ wọn. Tó o bá ronú jinlẹ̀ kó o tó gbàdúrà, wàá lè rántí àwọn bíi mélòó kan tó o lè dárúkọ wọn bó o ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Ó dájú pé tó o bá wà nínú ìṣòro, wàá fẹ́ káwọn ará gbàdúrà nítorí tiẹ̀ náà.
“Máa Tẹ̀ Lé Mi” (Ìṣe 12:6-11)
10, 11. Ṣàlàyé bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe mú Pétérù kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
10 Ṣé ẹ̀rù ń ba Pétérù bó ṣe mọ̀ pé wọ́n fẹ́ pa òun? A ò lè sọ, àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ńṣe ló sùn lọ fọnfọn láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ méjì tó wà lójúfò. Ó dá ọkùnrin olóòótọ́ yìí lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kejì, Jèhófà ò ní gbàgbé òun. (Róòmù 14:7, 8) Kò dájú pé Pétérù ronú kan iṣẹ́ ìyanu tó máa tó ṣẹlẹ̀. Lójijì, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan mọ́lẹ̀ yòò nínú ẹ̀wọ̀n tó wà. Áńgẹ́lì kan ló wọlé, ó dájú pé àwọn ẹ̀ṣọ́ náà ò rí i, ó sì jí Pétérù pé kó dìde kíákíá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é lágbára gan-an, wẹ́rẹ́ báyìí ni wọ́n já bọ́!
11 Áńgẹ́lì náà fún Pétérù láwọn ìtọ́ni tó ṣe ṣókí, ó sọ fún un pé: “Dìde kíákíá! . . . Wọ aṣọ rẹ, kí o sì wọ bàtà rẹ. . . . Gbé aṣọ àwọ̀lékè rẹ wọ̀.” Kíákíá ni Pétérù ṣe ohun tó ní kó ṣe. Níkẹyìn, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi,” Pétérù sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, wọ́n sì rọra gba àárín àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà níta lọ síbi ilẹ̀kùn onírin. Báwo ni wọ́n ṣe máa kọjá níbẹ̀? Bí irú ìbéèrè yìí bá tiẹ̀ wá sí Pétérù lọ́kàn, kò dájú pé ó rò ó lọ títí. Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ilẹ̀kùn onírin náà, ńṣe ló “fúnra rẹ̀ ṣí fún wọn.” Kí wọ́n tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n ti gba ẹnu ìlẹ̀kùn onírin yìí jáde sí ojú ọ̀nà kan, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kò rí áńgẹ́lì náà mọ́. Nígbà tó ku Pétérù nìkan, ó wá rí i pé òótọ́ ni gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, kì í ṣe ìran. Pétérù ti dòmìnira!—Ìṣe 12:7-11.
12. Tá a bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe gba Pétérù, báwo nìyẹn ṣe lè tù wá nínú?
12 Ó tù wá nínú gan-an bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ní agbára tó ju gbogbo agbára lọ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ là. Ọba táwọn alákòóso tó lágbára jù lọ láyé ń tì lẹ́yìn ló fi Pétérù sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, wẹ́rẹ́ ni Pétérù kúrò lẹ́wọ̀n náà! Lóòótọ́, ìgbà gbogbo kọ́ ni Jèhófà máa ń gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ là lọ́nà ìyanu. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún Jémíìsì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò tún ṣe bẹ́ẹ̀ fún Pétérù lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìyẹn nígbà tí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ikú àpọ́sítélì yìí wá nímùúṣẹ. Lónìí, àwa Kristẹni ò retí pé kí Jèhófà máa gbà wá là lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, a mọ̀ pé Jèhófà ò tíì yí pa dà. (Mál. 3:6) Ó máa tó lo Ọmọ rẹ̀ láti dá àìmọye èèyàn nídè kúrò lọ́wọ́ ikú, tó dà bí ọgbà ẹ̀wọ̀n téèyàn ò lè jáde nínú ẹ̀. (Jòh. 5:28, 29) Tá a bá ń ronú lórí ìlérí yìí, ó máa fún wa lókùn gan-an tá a bá wà nínú ìṣòro.
“Wọ́n Rí I, Ẹnu sì Yà Wọ́n” (Ìṣe 12:12-17)
13-15. (a) Báwo ló ṣe rí lára ìjọ tó wà nílé Màríà nígbà tí Pétérù dé? (b) Kí lohun tó kàn nínú ìwé Ìṣe báyìí, kí ló sì dájú pé Pétérù ń bá a nìṣó láti ṣe fáwọn ará?
13 Pétérù dúró sójú ọ̀nà tó ṣókùnkùn yẹn, ó ń ronú ohun tó fẹ́ ṣe. Wẹ́rẹ́ lohun kan sọ sí i lọ́kàn. Ó rántí pé arábìnrin kan tó ń jẹ́ Màríà ń gbé nítòsí ibẹ̀. Ó dájú pé opó ni obìnrin yìí, ó sì jọ pé ó lówó lọ́wọ́, torí pé ó nílé tó tóbi tí ìjọ ti ń ṣèpàdé. Òun ni ìyá Jòhánù Máàkù tí ìwé Ìṣe mẹ́nu kàn fún ìgbà àkọ́kọ́ níbí yìí. Nígbà tó yá, Máàkù ọmọ rẹ̀ wá dà bí ọmọ fún Pétérù. (1 Pét. 5:13) Lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn ará ìjọ náà ló wà nílé Màríà, tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ti ṣú. Kò sí àníàní pé ńṣe ni gbogbo wọn ń gbàdúrà pé kí wọ́n tú Pétérù sílẹ̀, àmọ́ wọn ò mọ bí Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà wọn!
14 Pétérù kan ilẹ̀kùn àbáwọlé tó já sínú àgbàlá láti ìta ilé náà. Ìránṣẹ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ródà wá sẹ́nu ọ̀nà. (Orúkọ Gíríìkì ni Ródà, ohun tó túmọ̀ sí ni òdòdó tó rẹwà.) Ẹnu ya Ródà gan-an nígbà tó gbóhùn Pétérù! Inú ẹ̀ dùn débi pé kàkà kó ṣílẹ̀kùn fún Pétérù, ńṣe ló fi sílẹ̀ lórí ìdúró, ó sì sá pa dà lọ sínú ilé kó lè sọ fún ìjọ pé Pétérù ló wà lẹ́nu ọ̀nà. Àmọ́ wọn ò gbà á gbọ́, ńṣe ni wọ́n sọ pé orí ẹ̀ ti yí, síbẹ̀ ọmọbìnrin yìí ò jẹ́ kó sú òun. Ó ṣáà ń tẹnu mọ́ ọn pé òótọ́ lòun ń sọ. Nígbà tó yá, àwọn kan gbà pé ó ṣeé ṣe kó gbọ́ nǹkan lóòótọ́, àmọ́ wọ́n ní ó lè jẹ́ ohùn áńgẹ́lì tó ń ṣojú fún Pétérù ló gbọ́. (Ìṣe 12:12-15) Ní gbogbo àkókò yìí, Pétérù ṣáà ń kanlẹ̀kùn títí tí wọ́n fi wá ṣílẹ̀kùn fún un.
15 Nígbà tí wọ́n ṣílẹ̀kùn, “wọ́n rí i, ẹnu sì yà wọ́n”! (Ìṣe 12:16) Inú àwọn èèyàn náà dùn débi pé ńṣe ni Pétérù ní láti rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n dákẹ́ kó lè sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí fún wọ́n. Ó ní kí wọ́n sọ fún àpọ́sítélì Jémíìsì àtàwọn ará tó kù, lẹ́yìn náà ó kúrò níbẹ̀ káwọn ọmọ ogun Hẹ́rọ́dù tó wá a kàn. Pétérù lọ síbi tí kò léwu kó lè máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó níbẹ̀. Yàtọ̀ sígbà tí Pétérù dá sí bí wọ́n ṣe yanjú ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ ní Ìṣe orí 15, kò tún síbi tí ìwé Ìṣe ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti ìrìn àjò tó rìn lọ̀rọ̀ kàn báyìí nínú ìwé Ìṣe. Àmọ́, ó dájú pé Pétérù ń fún ìgbàgbọ́ àwọn ará lókun ní gbogbo ibi tó lọ. Nígbà tó sì fi àwùjọ tó wà nílé Màríà sílẹ̀, kò sí àní-àní pé inú wọn dùn gan-an.
16. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere tó máa múnú wa dùn lọ́jọ́ iwájú?
16 Nígbà míì, Jèhófà máa ń ṣe nǹkan àrà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ò retí láti múnú wọn dùn. Bọ́rọ̀ àwọn ará tó ń gbàdúrà nítorí Pétérù ṣe rí gan-an nìyẹn lálẹ́ ọjọ́ náà. Bó sì ṣe máa ń rí lára wa náà nìyẹn tí Jèhófà bá rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí wá lónìí. (Òwe 10:22) Lọ́jọ́ iwájú, a máa rí báwọn ìlérí Jèhófà ṣe máa ṣẹ kárí ayé. Àwọn ohun àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ kọjá ohun tá a lè ronú kàn báyìí. Tá a bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan rere la máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú.
“Áńgẹ́lì Jèhófà Kọ Lù Ú” (Ìṣe 12:18-25)
17, 18. Kí ló mú káwọn èèyàn pe Hẹ́rọ́dù ní “ọlọ́run”?
17 Bí Pétérù ṣe lọ ya Hẹ́rọ́dù lẹ́nu, ó sì ká a lára. Lójú ẹsẹ̀, Hẹ́rọ́dù pàṣẹ pé kí wọ́n lọ wá a wá, ó sì ní kí wọ́n lọ gbọ́ tẹnu àwọn ẹ̀ṣọ́ náà. Wọ́n kó wọn lọ láti “fìyà jẹ wọ́n,” ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n pa wọ́n. (Ìṣe 12:19) Hẹ́rọ́dù Ágírípà ò lójú àánú rárá. Ṣé ọkùnrin òǹrorò yìí jìyà ohun tó ṣe yìí?
18 Ó ṣeé ṣe kójú ti Ágírípà torí pé kò rí Pétérù pa, àmọ́ kò pẹ́ tó fi láǹfààní láti tún máa gbé ara rẹ̀ ga. Ohun kan ló ṣẹlẹ̀ tó mú káwọn kan lára àwọn ọ̀tá rẹ̀ wá túbá fún un, kò sì sí àníàní pé ó máa fẹ́ sọ̀rọ̀ níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù ń múra ọ̀rọ̀ tó fẹ́ sọ sílẹ̀, Lúùkù sọ pé: “Hẹ́rọ́dù gbé aṣọ ìgúnwà wọ̀.” Òpìtàn Júù náà, Josephus sọ pé fàdákà ni wọ́n fi ṣe aṣọ tí Hẹ́rọ́dù wọ̀, débi pé tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn sí i lára, ńṣe ló ń tàn yanran tó sì wá dà bí òrìṣà. Ọkùnrin olóṣèlú tó jẹ́ agbéraga yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Làwọn èrò náà bá ń pariwo, wọ́n sì ń kígbé pé: “Ohùn ọlọ́run ni, kì í ṣe ti èèyàn!”—Ìṣe 12:20-22.
19, 20. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi fìyà jẹ Hẹ́rọ́dù? (b) Báwo ni àkọsílẹ̀ nípa ikú tó pa Hẹ́rọ́dù Ágírípà ṣe tù wá nínú?
19 Ọlọ́run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gba irú ìyìn bẹ́ẹ̀, ó sì ń wo Hẹ́rọ́dù! Tí Hẹ́rọ́dù bá fẹ́, ó lè yọ ara rẹ̀ nínú ewu. Ńṣe ló yẹ kó pa àwọn èèyàn náà lẹ́nu mọ́ tàbí kó sọ pé kí wọ́n má ṣe fògo fóun. Àmọ́, ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe ṣẹ mọ́ ọn lára pé: “Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun.” (Òwe 16:18) “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, áńgẹ́lì Jèhófà kọ lù ú,” ó mú kí ọkùnrin agbéraga yìí kú ikú ẹ̀sín. “Ìdin jẹ ẹ́, ó sì kú.” (Ìṣe 12:23) Bákan náà, Òpìtàn Júù náà Josephus sọ pé a kọ lu Àgírípà lójijì, ó tún fi kún un pé, ọba náà gbà pé ohun tó fa ikú tó fẹ́ pa òun yìí ni pé òun gba ògo tí kò tọ́ sí òun. Josephus sọ pé ó tó ọjọ́ márùn-ún tí Ágírípà fi jẹ̀rora kó tó kú.b
20 Nígbà míì, ó lè dà bíi pé àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tí ò dáa láì sẹ́ni tó máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò. Kò yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu torí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòh. 5:19) Síbẹ̀, ó máa ń dun àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà míì tó bá dà bíi pé àwọn èèyàn burúkú yẹn ò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìdí nìyẹn táwọn àkọsílẹ̀ bí èyí fi máa ń tuni nínú. Wọ́n máa ń jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ń dá àwọn ẹni ibi lẹ́jọ́, ìyẹn sì máa ń jẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ rántí pé ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. (Sm. 33:5) Bó pẹ́ bó yá, ó dájú pé Ọlọ́run máa dá gbogbo ẹjọ́ lọ́nà tó tọ́.
21. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló wà nínú ìwé Ìṣe orí 12, kí sì nìdí tó fi fi wá lọ́kàn balẹ̀?
21 Ọ̀rọ̀ ìṣírí tó parí ìwé Ìṣe orí 12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń gbilẹ̀, ó sì ń tàn kálẹ̀.” (Ìṣe 12:24) Èyí jẹ́ ká rí i pé iṣẹ́ ìwàásù ń tẹ̀ síwájú nígbà yẹn. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn, Jèhófà ṣì ń bù kún iṣẹ́ yìí. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe bí àpọ́sítélì kan ṣe kú àti bí èkejì ṣe bọ́ lọ́wọ́ ikú nìkan ló wà nínú ìwé Ìṣe orí 12. Orí yìí tún jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà ṣe kí Sátánì má bàa pa ìjọ Kristẹni run tàbí dá iṣẹ́ ìwàásù táwọn Kristẹni ń fìtara ṣe nígbà yẹn dúró. Gbogbo àtakò Sátánì nígbà yẹn ló já sásán, bó sì ṣe máa rí nìyẹn fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ dí iṣẹ́ ìwàásù náà lọ́wọ́, kò ní ṣàṣeyọrí. (Àìsá. 54:17) Àmọ́, ní tàwọn tó ń sin Jèhófà, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé Jésù Kristi, iṣẹ́ wọn ò ní já sásán. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Ká sòótọ́, àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ la ní láti máa wàásù “ọ̀rọ̀ Jèhófà” lónìí!
a Wo àpótí náà, “Ọba Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kìíní.”
b Dókítà kan tó tún jẹ́ òǹkọ̀wé sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé aràn tó máa ń ba ìfun jẹ́ ló fa àrùn tí Josephus àti Lúùkù sọ pé ó pa Hẹ́rọ́dù. Àwọn èèyàn máa ń pọ irú aràn bẹ́ẹ̀ jáde, ó sì lè rìn jáde lára ẹni tó ń ṣàìsàn lẹ́yìn tó bá kú. Ìwé kan sọ pé: “Torí pé oníṣègùn ni Lúùkù, ó ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hẹ́rọ́dù lọ́nà tó ṣe kedere, ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé ikú oró ni Hẹ́rọ́dù kú.”