Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
AUGUST 22-28
it-1 ojú ìwé 857-858
Ìmọ̀tẹ́lẹ̀, Ìyàntẹ́lẹ̀
Ṣẹ́ Ọlọ́run ti kádàrá pé Júdásì máa da Jésù kí àsọtẹ́lẹ̀ lè ní ìmúṣẹ?
Bí Júdásì Ísíkáríótù ṣe da Jésù jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ní ìmúṣẹ, ó sì tún jẹ́ ká rí i pé Jèhófà àti Jésù lágbára láti mọ ohun to máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Sm 41:9; 55:12, 13; 109:8; Iṣe 1:16-20) Síbẹ̀, a ò lè sọ pé Ọlọ́run ti kádàrá rẹ̀ pé bó ṣe máa rí fún Júdásì nìyẹn. Lóòótọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé àwọn kan tó sún mọ́ Jésù máa dà á, àmọ́ kò sọ ẹni náà pàtó. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìlànà Bíbélì jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kọ́ ló kádàrá ohun tí Júdásì ṣe. Ọ̀kan lára ìlànà yẹn sọ pé: “Má ṣe fi ìkánjú gbé ọwọ́ lé ọkùnrin èyíkéyìí láé; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe jẹ́ alájọpín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn; pa ara rẹ mọ́ ní oníwàmímọ́.” (1Ti 5:22; fi wé 3:6.) Ká lè mọ̀ pé Jésù fẹ́ láti fọgbọ́n yan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ méjìlá, ó fi gbogbo òru gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ kó tó ṣèpinnu. (Lk 6:12-16) Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló kádàrá Júdásì pé ọ̀dàlẹ̀ ló máa jẹ́, á jẹ́ pé ọ̀tọ̀ ni ohun tó fẹ́ ká ṣe, ọ̀tọ̀ ni ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe. Ohun míì tó tún lè túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run lọ́wọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tá a bá dá.
Torí náà, ó ṣe kedere pé kò sí àmì pé Júdásì máa dalẹ̀ nígbà tí wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì. Àmọ́ nígbà tó yá, ó fàyè gbà á kí ‘gbòǹgbò onímájèlé rú yọ’ lọ́kàn rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́gbin. Bó ṣe di pé ó kọ ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nìyẹn, tó sì fàyè gba Èṣù láti máa darí rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jalè, ó sì di ọ̀dàlẹ̀. (Heb 12:14, 15; Jo 13:2; Iṣe 1:24, 25; Jak 1:14, 15; wo JUDAS No. 4.) Nígbà tó ṣe, Jésù wá rí i pé ọkàn Júdásì ti yà bàrà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Èyí ló mú kí Jésù mọ̀ pé Júdásì ló máa da òun àti ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.—Jo 13:10, 11.
Òótọ́ ni pé nínú Jòhánù 6:64, àkókò kan wà táwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kò gba ẹ̀kọ́ rẹ̀ gbọ́, ẹsẹ Bíbélì yẹn kà pé “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ [“láti ìbẹ̀rẹ̀,” JB] Jésù mọ àwọn tí kò gbà gbọ́ àti ẹni tí yóò dà á.” Wọ́n tún lo ọ̀rọ̀ náà “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” (Gr., ar·kheʹ) nínú 2 Pétérù 3:4 láti tọ́ka sí ìgbà ìṣẹ̀dá, ó sì tún lè tọ́ka sí àkókò míì. (Lk 1:2; Jo 15:27) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe bà lé àwọn Kèfèrí, ó ní “gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” Ó ṣe kedere pé “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” tí Pétérù sọ níbí yìí kì í ṣe àkókò tó di ọmọlẹ́yìn Kristi, kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tọ́ka sí àkókò pàtàkì kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn fún ìdí pàtàkì kan. (Iṣe 11:15; 2:1-4) Torí náà, ó gbàfiyèsí pé ìwé kàn tó ń jẹ́ Lange’s Commentary on the Holy Scriptures (p. 227) sọ kókó pàtàkì yìí nípa Jòhánù 6:64, ó ní: “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ . . . kò túmọ̀ sí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ gbogbo nǹkan, . . . bákan náà ni kò túmọ̀ sí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ bí [Jésù] ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, . . . tàbí bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jọ, kò sì túmọ̀ sí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà, . . . kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí ìgbà tí ìwà àìnígbàgbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í hàn lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ [èyí tó mú kí àwọn kan lára wọn kọsẹ̀]. Ìyẹn la fi lè sọ pé ó mọ ẹni tó máa dalẹ̀ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.”—Ọ̀gbẹ́ni P. Schaff, ló túmọ̀ rẹ̀ tó sì ṣàkójọ rẹ̀ lọ́dún 1976; fi wé 1Jo 3:8, 11, 12.
AUGUST 29–SEPTEMBER 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 110-118
“Kí Ni Èmi Yóò San Pa Dà Fún Jèhófà?”
w87 3/15 24 ¶5
Ọlọ́run Alayọ, Awọn Eniyan Alayọ!
◆ 116:3—Kí ni “àwọn ìjàrá ikú”?
Ó dabi ẹnipe iku ti dè onipsalm naa pinpin pẹlu okùn ti ko ṣee ja ti o fi jẹ pe àjàbọ́ kò ṣeeṣe. Awọn okùn ti a de pinpin yika apa ati ẹsẹ nfa awọn irora rironi, tabi awọn irora mimuna, ẹda-itumọ Greek Septuagint tumọ ọrọ Hebrew naa fun “awọn okùn” “gẹgẹ bi awọn irora mimuna.” Fun idi yii, nigba ti Jesu Kristi ku oun wa ninu idimu pinpin arọnilọwọ-rọnilẹsẹ, tabi awọn irora mimuna, ti iku. Nitori naa, nigba ti Jehofah ji Jesu dide, oun “ti tú irora iku.”—Ìṣe 2:24.