Ìṣàbójútó Lọ́nà Ìṣètò Ìṣàkóso Ọlọ́run Ní Sànmánì Kristẹni
“Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere rẹ̀ . . . láti tún kó ohun gbogbo jọ pa pọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.”—ÉFÉSÙ 1:9, 10.
1, 2. (a) Báwo ni kíkó “àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run” jọ ṣe tẹ̀ síwájú, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe fi ẹ̀mí Mósè àti ti Èlíjà hàn láti 1914?
KÍKÓ “àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run” jọ yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nígbà tí a bí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Aísáyà 43:10; Pétérù Kíní 2:9, 10) Lẹ́yìn ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, iṣẹ́ ìkójọ náà lọ sílẹ̀ bí àwọn apẹ̀yìndà “èpò” tí Sátánì fún, ṣe bo àwọn ojúlówó Kristẹni (tí Jésù pè ní “àlìkámà”) mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí “ìgbà ìkẹyìn” ṣe ń sún mọ́lé, Ísírẹ́lì tòótọ́ ti Ọlọ́run wá sójú táyé lẹ́ẹ̀kan sí i, a sì yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní Jésù, ní 1919.a—Mátíù 13:24-30, 36-43; 24:45-47; Dáníẹ́lì 12:4.
2 Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe àwọn iṣẹ́ ńláǹlà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè àti Èlíjà ti ṣe.b (Ìṣípayá 11:5, 6) Láti 1919, wọ́n ti wàásù ìhìn rere nínú ayé oníkanra, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìgboyà bíi ti Èlíjà. (Mátíù 24:9-14) Láti 1922 ẹ̀wẹ̀, wọ́n ti polongo ìdájọ́ Jèhófà lórí aráyé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe mú ìyọnu àjàkálẹ̀ Ọlọ́run wá sórí Íjíbítì ìgbàanì. (Ìṣípayá 15:1; 16:2-17) Àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí jẹ́ apá pàtàkì nínú ẹgbẹ́ ayé tuntun ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Wà Lẹ́nu Iṣẹ́
3. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó fi hàn pé ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wà létòletò?
3 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí a fòróró yàn ti wà létòletò. Bí iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti ń pọ̀ sí i, ni a ń dá ìjọ àdúgbò sílẹ̀ sí i, tí a sì ń yan àwọn alàgbà sípò. (Títù 1:5) Lẹ́yìn ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn àpọ́sítélì 12 náà ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso tí ó lọ́lá àṣẹ. Nítorí èyí, wọ́n mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù láìbẹ̀rù. (Ìṣe 4:33, 35, 37; 5:18, 29) Wọ́n ṣètò ìpínkiri oúnjẹ fún àwọn aláìní, wọ́n sì rán Pétérù àti Jòhánù lọ sí Samáríà láti ṣiṣẹ́ lórí ìfẹ́ tí a ròyìn pé àwọn ará ibẹ̀ ń fi hàn. (Ìṣe 6:1-6; 8:6-8, 14-17) Bánábà mú Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ wọn láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé aṣenúnibíni tẹ́lẹ̀ rí yìí ti di ọmọlẹ́yìn Jésù báyìí. (Ìṣe 9:27; Gálátíà 1:18, 19) Lẹ́yìn tí Pétérù sì ti wàásù fún Kọ̀nílíù àti agbo ilé rẹ̀, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣàlàyé bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú ọ̀ràn yí fún àwọn àpọ́sítélì àti àwọn arákùnrin mìíràn tí ó wà ní Jùdíà.—Ìṣe 11:1-18.
4. Ìgbìdánwò wo ni a ṣe láti pa Pétérù, ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe dá ẹ̀mí rẹ̀ sí?
4 Nígbà tí ó ṣe, ẹgbẹ́ olùṣàkóso wá sábẹ́ àtakò líle koko. A ju Pétérù sẹ́wọ̀n, dídá tí ańgẹ́lì dá sí ọ̀ràn náà ni a sì fi gba ẹ̀mí rẹ̀ là. (Ìṣe 12:3-11) Nísinsìnyí, fún ìgbà àkọ́kọ́, ẹnì kan, yàtọ̀ sí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì 12 náà, fara hàn ní ipò yíyọrí ọlá ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí a tú Pétérù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó sọ fún àwùjọ tí ó pé jọ pọ̀ sí ilé ìyá Jòhánù Máàkù pé: “Ẹ ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún Jákọ́bù [iyèkan Jésù] àti àwọn ará.”—Ìṣe 12:17.
5. Báwo ni a ṣe mú ìyípadà dé bá àwọn tí ó para pọ̀ di ẹgbẹ́ olùṣàkóso lẹ́yìn ikú ajẹ́rìíkú Jákọ́bù?
5 Ṣáájú, lẹ́yìn tí Júdásì Ísíkáríótù, ọ̀dàlẹ̀ àpọ́sítélì náà, pa ara rẹ̀, wọ́n fòye mọ àìní kan láti fi “ipò iṣẹ́ àbójútó rẹ̀” gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, fún ẹnì kan tí ó ti wà pẹ̀lú Jésù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí ikú àti àjíǹde rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tí a pa Jákọ́bù, arákùnrin Jòhánù, kò sí ẹni tí ó gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn 12. (Ìṣe 1:20-26; 12:1, 2) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìtọ́ka mìíràn tí Ìwé Mímọ́ ṣe sí ẹgbẹ́ olùṣàkóso fi hàn pé a ti mú un gbòòrò sí i. Nígbà tí awuyewuye dìde lórí bóyá kí àwọn Kèfèrí, tí wọ́n tẹ̀ lé Jésù, fi ara wọn sábẹ́ Òfin Mósè, a mú ọ̀ràn náà lọ sọ́dọ̀ “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù,” láti ṣe ìpinnu lórí rẹ̀. (Ìṣe 15:2, 6, 20, 22, 23; 16:4) Èé ṣe tí “àwọn àgbà ọkùnrin,” lọ́nà tí ó ṣe kedere, fi wà lára ẹgbẹ́ olùṣàkóso nísinsìnyí? Bíbélì kò sọ, ṣùgbọ́n àǹfààní tí ó ṣe kedere fara hàn. Ikú Jákọ́bù àti ìfisẹ́wọ̀n Pétérù ti fi hàn pé, lọ́jọ́ kan, a lè ju àwọn àpọ́sítélì sẹ́wọ̀n tàbí kí a pa wọ́n. Nítorí irú ipò tí ó ṣeé ṣe yìí, fífi àwọn alàgbà míràn tí wọ́n tóótun, tí wọ́n nírìírí bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ń ṣiṣẹ́, kún wọn, yóò mú kí àbójútó létòlétò máa bá a lọ.
6. Báwo ni ẹgbẹ́ olùṣàkóso ṣe ń báṣẹ́ lọ ní Jerúsálẹ́mù, kódà nígbà tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ àkọ́kọ́ ti fi ìlú náà sílẹ̀?
6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Tiwa, ó kàn sì Jákọ́bù, Bíbélì sì sọ pé, “gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin sì wà níbẹ̀.” (Ìṣe 21:18) Èé ṣe tí a kò fi mẹ́nu kan àwọn àpọ́sítélì nínú ìpàdé yìí? Lẹ́ẹ̀kan sí i, Bíbélì kò sọ ìdí. Ṣùgbọ́n, òpìtàn náà, Eusebius, sọ lẹ́yìn náà pé ní àkókò kan ṣáájú ọdún 66 Sànmánì Tiwa, “a lé àwọn àpọ́sítélì yòó kù kúrò ní Jùdíà, nítorí ẹ̀mí wọ́n wà nínú ewu, nítorí a ń gbìmọ̀ lẹmọ́lemọ́ láti pa wọ́n. Ṣùgbọ́n, láti fi ìhìn iṣẹ́ wọn kọ́ni, wọ́n rìnrìn àjò lọ sí gbogbo ilẹ̀, ní agbára Kristi.” (Eusebius, Ìwé III, V, v. 2) Lóòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ Eusebius kì í ṣe ara àkọsílẹ̀ tí a mí sí, ṣùgbọ́n wọ́n bá ohun tí àkọsílẹ̀ náà sọ mu. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ó máa fi di ọdún 62 Sànmánì Tiwa, Pétérù ti wà ní Bábílónì—ibi tí ó jìnnà sí Jerúsálẹ́mù. (Pétérù Kíní 5:13) Síbẹ̀, ní ọdún 56 Sànmánì Tiwa, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́ títí di ọdún 66 Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ olùṣàkóso kan ṣì ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹwu ní Jerúsálẹ́mù.
Ìṣàbójútó ní Òde Òní
7. Ní fífi í wéra pẹ̀lú ẹgbẹ́ olùṣàkóso ọ̀rúndún kìíní, ìyàtọ̀ títayọ lọ́lá wo ni ó wà nínú àwọn tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso lónìí?
7 Láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa, títí di ìgbà ìpọ́njú Jerúsálẹ́mù, ó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Júù ni wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ olùṣàkóso. Nígbà ìbẹ̀wò rẹ̀ ní ọdún 56 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Júù ní Jerúsálẹ́mù, láìka pé wọ́n “di ìgbàgbọ́ Olúwa wa Jésù Kristi” mú, ṣì “jẹ́ onítara fún Òfin [Mósè].”c (Jákọ́bù 2:1; Ìṣe 21:20-25) Ó lè ti ṣòro gan-an fún irú àwọn Júù bẹ́ẹ̀ láti finú wòye pé Kèfèrí kan lè wà nínú ẹgbẹ́ olùṣàkóso. Ṣùgbọ́n, ní òde òní, ìyípadà míràn ti wà nínú àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ yìí. Lónìí, kìkì àwọn Kèfèrí tí wọ́n di Kristẹni tí a fòróró yàn ni ó jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀, Jèhófà sì ti bù kún àbójútó wọn ní jìngbìnnì.—Éfésù 2:11-15.
8, 9. Àwọn ìdàgbàsókè wo ni ó ti ṣẹlẹ̀ nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ní òde òní?
8 Láti ìgbà tí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ti di ilé iṣẹ́ tí a gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin ní 1884 títí di 1972, ààrẹ Society máa ń lo agbára ńlá nínú ètò àjọ Jèhófà, nígbà tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sì so pọ̀ pẹ́kípẹ́kí mọ́ ìgbìmọ̀ alábẹ ṣékélé ti Society. Ìbùkún tí wọ́n gbádùn ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn fẹ̀rí hàn pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìṣètò yẹn. Láàárín 1972 sí 1975, a mú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gbòòrò sí i sí mẹ́ńbà 18. Àwọn nǹkan túbọ̀ jọ ti ìṣètò ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí a gbé ọlá àṣẹ ńlá lé ẹgbẹ́ tí a ti mú gbòòrò yí lọ́wọ́, díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ yìí jẹ́ olùdarí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
9 Láti 1975, díẹ̀ lára àwọn ẹni 18 wọ̀nyẹn ti parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n ti ṣẹ́gun ayé, wọ́n sì ti ‘jókòó pẹ̀lú Jésù lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.’ (Ìṣípayá 3:21) Fún ìdí yìí àti fún àwọn ìdí mìíràn, mẹ́ńbà mẹ́wàá ni ó wà nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso nísinsìnyí, pẹ̀lú ọ̀kan tí a fi kún un ní 1994. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni wọ́n ti darúgbó. Ṣùgbọ́n, a ń ṣe ìtìlẹ́yìn dáradára fún àwọn arákùnrin ẹni àmì òróró wọ̀nyí, bí wọ́n ti ń bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn wíwúwo. Níbo ni a ti rí ìtìlẹ́yìn yẹn? Wíwo ìdàgbàsókè tí ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run fìrí dáhùn ìbéèrè yẹn.
Ìtìlẹ́yìn fún Ísírẹ́lì Ọlọ́run
10. Àwọn wo ni wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, báwo ni a sì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa èyí?
10 Ní 1884, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run ni wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró. Ṣùgbọ́n, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú, a sì wá mọ ẹgbẹ́ yìí sí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” inú Ìṣípayá orí 7, ní 1935. Ní níní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé, àwọn wọ̀nyí dúró fún “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” tí Jèhófà pète láti kó jọ pa pọ̀ nínú Kristi. (Éfésù 1:10) Wọ́n dúró fún “àwọn àgùntàn míràn” inú àkàwé Jésù nípa agbo àgùntàn. (Jòhánù 10:16) Láti 1935, àwọn àgùntàn míràn ti rọ́ wá sínú ètò àjọ Jèhófà. Wọ́n “ń fò bí àwọsánmà, àti bí àwọn ẹyẹlé sí ojúlé wọn.” (Aísáyà 60:8) Nítorí ìbísí nínú iye ogunlọ́gọ̀ ńlá àti ìpẹ̀dín nínú ẹgbẹ́ ẹni àmì òróró, bí ọ̀pọ̀ ti ń parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àgùntàn míràn tí wọ́n tóótun ti bẹ̀rẹ̀ sí í kópa pàtàkì nínú ìgbòkègbodò Kristẹni. Ní àwọn ọ̀nà wo?
11. Àwọn àǹfààní wo, tí a fi mọ sọ́dọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tẹ́lẹ̀, ni a ti fún àwọn àgùntàn míràn?
11 Pípolongo ìtayọlọ́lá Jèhófà káàkiri ti fìgbà gbogbo jẹ́ ẹrù iṣẹ́ àkànṣe fún “orílẹ̀-èdè mímọ́” Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ inú tẹ́ńpìlì, àwọn tí yóò di “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” ni Jésù sì fún níṣẹ́ náà láti wàásù àti láti kọ́ni. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; Pétérù Kíní 2:4, 9; Mátíù 24:14; 28:19, 20; Hébérù 13:15, 16) Síbẹ̀síbẹ̀, ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ August 1, 1932 (Gẹ̀ẹ́sì), fún àwọn tí Jónádábù dúró fún ní ìṣírí láti nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò yí. Ní tòótọ́, púpọ̀ lára àwọn àgùntàn míràn náà ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn àgùntàn míràn ni ó ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìwàásù náà, gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì ‘ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run tọ̀sán tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.’ (Ìṣípayá 7:15) Lọ́nà kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn àwọn ènìyàn Jèhófà òde òní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni wọ́n jẹ́ alàgbà, “ìràwọ̀” ní ọwọ́ ọ̀tún Jésù Kristi. (Ìṣípayá 1:16, 20) Ṣùgbọ́n ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ May 1, 1937 (Gẹ̀ẹ́sì), kéde pé àwọn àgùntàn míràn tí wọ́n tóótun lè di ìránṣẹ́ ìjọ (alábòójútó olùṣalága). Bí àwọn ẹni àmì òróró bá tilẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó, a lè lo àwọn àgùntàn míràn, bí kò bá ṣeé ṣe fún àwọn ẹni àmì òróró náà láti gbé ẹrù iṣẹ́ yìí. Lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àgùntàn míràn ni gbogbo àwọn alàgbà ìjọ.
12. Àwọn àpẹẹrẹ ìṣáájú inú Ìwé Mímọ́ wo ni ó wà fún fífún àwọn àgùntàn míràn tí ó tóótun ní ẹrù iṣẹ́ wíwúwo nípa ìṣètò?
12 Ó ha lòdì láti fún àwọn àgùntàn míràn ní irú ẹrù iṣẹ́ wíwúwo bẹ́ẹ̀? Rárá o, a wulẹ̀ ń tẹ̀ lé ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ni. Àwọn àjèjì aláwọ̀ṣe kan (àwọn àtìpó olùgbé) di ipò pàtàkì mú ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Sámúẹ́lì Kejì 23:37, 39; Jeremáyà 38:7-9) Lẹ́yìn tí wọ́n ti ìgbèkùn Bábílónì dé, a fún àwọn Nétínímù (àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì) tí ó tóótun ní àǹfààní ṣíṣiṣẹ́ sìn nínú tẹ́ńpìlì, iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì nìkan tẹ́lẹ̀ rí. (Ẹ́sírà 8:15-20; Nehemáyà 7:60) Ní àfikún sí i, Mósè, tí a rí nínú ìran ìyípadà ológo pẹ̀lú Jésù, tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn àtàtà tí Jẹ́tírò ará Mídíánì fún un. Lẹ́yìn náà, ó ní kí ọmọkùnrin Jẹ́tírò, Hóbábù, ṣamọ̀nà wọn la aginjù já.—Ẹ́kísódù 18:5, 17-24; Númérì 10:29.
13. Ní fífi ìrẹ̀lẹ̀ yan iṣẹ́ fún àwọn àgùntàn míràn tí ó tóótun, àpẹẹrẹ àtàtà ti ta ni àwọn ẹni àmì òróró ń fara wé?
13 Bí 40 ọdún nínú aginjù ti ń parí lọ, Mósè gbàdúrà pé kí Jèhófà pèsè agbapò, ní mímọ̀ pé òun kò ní wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 27:15-17) Jèhófà sọ fún un pé kí ó yan Jóṣúà níwájú gbogbo ènìyàn, Mósè sì ṣe bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ṣì lágbára, kò sì ṣíwọ́ ṣíṣiṣẹ́ sin Ísírẹ́lì lójú ẹsẹ̀. (Diutarónómì 3:28; 34:5-7, 9) Pẹ̀lú irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kan náà, àwọn ẹni àmì òróró ti ń fún àwọn ọkùnrin tí ó tóótun láàárín àwọn àgùntàn míràn ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i.
14. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ó tọ́ka sí ipa tí ń pọ̀ sí i tí àwọn àgùntàn míràn yóò máa kó nínú ètò àjọ náà?
14 Ipa tí ń pọ̀ sí i tí àwọn àgùntàn míràn ń kó nínú ètò àjọ tún jẹ́ ọ̀ràn alásọtẹ́lẹ̀. Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn Filísínì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì yóò dà “bíi séríkí ní Júdà.” (Sekaráyà 9:6, 7, NW) Àwọn séríkí jẹ́ olórí ẹ̀yà, nítorí náà, Sekaráyà ń sọ pé ọ̀tá Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀ rí yóò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́, yóò sì wá dà bí olórí ẹ̀yà ní Ilẹ̀ Ìlérí. Síwájú sí i, nígbà tí ó ń bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run sọ̀rọ̀, Jèhófà sọ pé: “Àwọn àlejò yóò sì dúró, wọn óò sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran yín, àwọn ọmọ àlejò yóò sì ṣe atulẹ̀ yín, àti olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà yín. Ṣùgbọ́n a óò máa pè yín ní Àlùfáà Olúwa: wọn óò máa pè yín ní Ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.” (Aísáyà 61:5, 6) Àwọn àgùntàn míràn ni “àlejò” àti “ọmọ àlejò” náà. A ti yan iṣẹ́ fún àwọn wọ̀nyí kí wọ́n baà lè ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ sí i, bí àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tí wọ́n ti darúgbó ṣe ń parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n sì ń lọ ṣiṣẹ́ sìn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà Olúwa” ní ọ̀run, tí wọ́n yóò sì yí ìtẹ́ ògo Jèhófà ká gẹ́gẹ́ bí “ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.”—Kọ́ríńtì Kíní 15:50-57; Ìṣípayá 4:4, 9-11; 5:9, 10.
“Ìran Náà . . . Tí Ń Bọ̀”
15. Ní àkókò òpin yìí, ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni wo ni wọ́n ti dé “ọjọ́ ogbó,” ẹgbẹ́ wo sì ni ó dúró fún ‘ìran náà tí ń bọ̀’?
15 Àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti ń hára gàgà láti dá àwọn àgùntàn míràn lẹ́kọ̀ọ́ nítorí àfikún ẹrù iṣẹ́. Orin Dáfídì 71:18 (NW) sọ pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.” Ní sísọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ yìí, Ilé Ìṣọ́ December 15, 1948 (Gẹ̀ẹ́sì), ṣàlàyé pé ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti darúgbó. Ó ń bá a lọ láti sọ pé àwọn ẹni àmì òróró ń fayọ̀ “fojú sọ́nà nínú ìmọ́lẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, wọ́n sì rí ìran tuntun kan.” Àwọn wo ní pàtàkì ni èyí ń tọ́ka sí? Ilé Ìṣọ́ náà sọ pé: “Jésù sọ nípa wọn gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn àgùntàn míràn’ rẹ̀.” ‘Ìran náà tí ń bọ̀’ tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí yóò gbé lábẹ́ ìṣàkóso tuntun ti ilẹ̀ ayé tí Ìjọba ọ̀run yóò ṣàkóso.
16. Àwọn ìbùkún wo ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ‘ìran náà tí ń bọ̀’ ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún?
16 Bíbélì kò sọ ní kedere ìgbà tí gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò fi àwọn arákùnrin wọn ti ‘ìran náà tí ń bọ̀’ yí sílẹ̀, tí a óò sì ṣe wọ́n lógo pẹ̀lú Jésù Kristi. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ní ìdánilójú pé àkókò fún èyí ti sún mọ́lé. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ ńlá ti Jésù nípa “ìgbà ìkẹyìn,” ti ń ṣẹ láti 1914, ní fífihàn pé ìparun ayé yìí ti sún mọ́lé. (Dáníẹ́lì 12:4; Mátíù 24:3-14; Máàkù 13:4-20; Lúùkù 21:7-24) Láìpẹ́, Jèhófà yóò mú ayé tuntun kan wọlé, nínú èyí tí ‘ìran náà tí ń bọ̀’ yóò ‘jogún ìjọba [sàkáání ayé] tí a ti pèsè sílẹ̀ fún wọn láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.’ (Mátíù 25:34) Inú wọ́n dùn láti fojú sọ́nà fún ìmúpadàbọ̀sípò Párádísè àti jíjí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òkú dìde láti inú Hédíìsì. (Ìṣípayá 20:13) Àwọn ẹni àmì òróró yóò ha wà níbẹ̀ láti kí àwọn tí a jí dìde wọ̀nyí káàbọ̀ bí? Ní 1925, Ilé Ìṣọ́ May 1 (Gẹ̀ẹ́sì) sọ pé: “Kò yẹ kí a lo èrò orí wa lásán láti sọ ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe tàbí kì yóò ṣe. . . . [Ṣùgbọ́n] a mú wa dórí ìpinnu náà pé, a óò ṣe àwọn mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì [àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró] lógo ṣáájú àjíǹde àwọn ẹni àtijọ́ títóótun náà [àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ ṣáájú ìgbà Kristẹni].” Ní jíjíròrò ohun kan náà lórí bóya díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti kí àwọn tí a jí dìde káàbọ̀, Ilé-Ìṣọ́nà ti September 1, 1989 sọ pé: “Eyi kì yoo pọndandan.”d
17. Àwọn àǹfààní àgbàyanu wo ni àwọn ẹni àmì òróró, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, yóò ṣàjọpín pẹ̀lú Jésù Kristi, Ọba tí a ti gbé gun orí ìtẹ́?
17 Ní tòótọ́, a kò mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn Kristẹni ẹni àmì òróró kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n, wíwà tí Mósè àti Èlíjà wà pẹ̀lú Jésù nínú ìran ìyípadà ológo náà fi hàn pé a retí pé kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí a jí dìde wà pẹ̀lú Jésù nígbà tí ó bá wá nínú ògo láti “san èrè iṣẹ́ fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí rẹ̀,” bí ó ti ń ṣe ìdájọ́, tí a sì ń mú un ṣẹ. Síwájú sí i, a rántí ìlérí Jésù pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n bá “ṣẹ́gun” yóò ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú ‘fífi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè’ ní Amágẹ́dọ́nì. Nígbà tí Jésù yóò bá wá nínú ògo, wọn yóò jókòó pẹ̀lú rẹ̀ ní “ṣíṣèdájọ́ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” Pẹ̀lú Jésù, wọn yóò ‘tẹ Sátánì rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.’—Mátíù 16:27–17:9; 19:28; Ìṣípayá 2:26, 27; 16:14, 16; Róòmù 16:20; Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Orin Dáfídì 2:9; Tẹsalóníkà Kejì 1:9, 10.
18. (a) Ibo ni a bá ‘kíkó àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run jọ pa pọ̀ nínú Kristi’ dé? (b) Kí ni a lè sọ nípa ‘kíkó àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé jọ pa pọ̀ nínú Kristi’?
18 Ní bíbá ṣíṣe àbójútó àwọn nǹkan nìṣó, Jèhófà ń tẹ̀ síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láti “kó ohun gbogbo pa pọ̀ nínú Kristi.” Ní ti “àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run,” ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú ète rẹ̀ ṣẹ tán. Síso Jésù pọ̀ pẹ̀lú gbogbo 144,000 ní ọ̀run fún “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ti sún mọ́lé. Nítorí náà, a ti yan àwọn ẹrù iṣẹ́ wíwúwo fún ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tí wọ́n dàgbà dénú, tí wọ́n ti pẹ́ nínú òtítọ́, tí wọ́n jẹ́ àgùntàn míràn, tí wọ́n dúró fún “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró. Ẹ wo irú àkókò amóríyá tí a ń gbé nínú rẹ̀! Ẹ wo bí ó ti múni láyọ̀ tó láti rí ète Jèhófà tí ń tẹ̀ síwájú sí ìmúṣẹ rẹ̀! (Éfésù 1:9, 10; 3:10-12; Ìṣípayá 14:1; 19:7, 9) Ẹ sì wo bí inú àwọn àgùntàn míràn ti dùn tó láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró, bí ẹgbẹ́ méjèèjì ti ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan,” ní ìtẹríba fún Ọba náà, Jésù Kristi, àti fún ògo Ọba Aláṣẹ Àgbáyé náà, Jèhófà Ọlọ́run!—Jòhánù 10:16; Fílípì 2:9-11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ile-Iṣọ Naa August 1, 1981, ojú ìwé 16 sí 26.
b Fún àpẹẹrẹ, bẹ̀rẹ̀ láti 1914, a fi “The Photo-Drama of Creation” (Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá)—ìgbékalẹ̀ aláwòrán tí a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, tí ó jẹ́ alápá mẹ́rin—han àwọn ènìyàn tí wọ́n kún inú àwọn ilé ìwòran ńlá káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé.
c Fún àwọn ìdí tí ó ṣeé ṣe tí àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ Júù fi jẹ́ onítara fún Òfin, wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 1163 àti 1164.
d Wo Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1990, ojú ìwé 30, 31; December 15, 1990, ojú ìwé 30.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni ètò àjọ Ọlọ́run ṣe tẹ̀ síwájú ní ọ̀rúndún kìíní?
◻ Báwo ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ṣe gbèrú nínú ìtàn òde òní ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
◻ Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ó fọwọ́ sí fífún àwọn àgùntàn míràn ní ọlá àṣẹ nínú ètò àjọ Jèhófà?
◻ Báwo ni a ṣe kó “àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run” àti “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” jọ pa pọ̀ nínú Kristi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kódà nígbà tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ àkọ́kọ́ kò sí ní Jerúsálẹ́mù mọ́, ẹgbẹ́ olùṣàkóso kan ń báṣẹ́ lọ níbẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n dàgbà dénú ti jẹ́ ìbùkún fún àwọn ènìyàn Jèhófà
C. T. Russell 1884 sí 1916
J. F. Rutherford 1916 sí 1942
N. H. Knorr 1942 sí 1977
F. W. Franz 1977 sí 1992
M. G. Henschel 1992-