‘Wọ́n Ṣíkọ̀ Lọ sí Kípírọ́sì’
ÀWỌN ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni ìwé Ìṣe fi bẹ̀rẹ̀ ìròyìn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì nígbà tí wọn ṣèbẹ̀wò sí Kípírọ́sì ní nǹkan bí ọdún 47 Sànmánì Tiwa. Àwọn míṣọ́nnárì náà ni Pọ́ọ̀lù, Bánábà àti Jòhánù tí ń jẹ́ Máàkù. (Ìṣe 13:4) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àti lónìí yìí, Kípírọ́sì wà ní ipò pàtàkì ní ìlà oòrùn Mẹditaréníà.
Ojú àwọn ará Róòmù wọ erékùṣù yìí, ó sì bọ́ sábẹ́ àkóso wọn ní ọdún 58 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ohun pàtàkì tó gbàfiyèsí ti ṣẹlẹ̀ ní Kípírọ́sì. Àwọn ará Fòníṣíà, àwọn ará Gíríìkì, àwọn ará Ásíríà, àwọn ará Páṣíà àtàwọn ará Íjíbítì ti fìgbà kan rí jọba lé e lórí. Àwọn ajagun ìsìn, ẹ̀yà Frank, àtàwọn ará ìlú Venice sì wá gba erékùṣù náà ní ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbà Ọ̀làjú, lẹ́yìn náà, àwọn Ottoman tún gbà á. Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá gba erékùṣù náà ní ọdún 1914, wọ́n sì ṣàkóso lé e lórí títí di ìgbà tó gba òmìnira ni ọdún 1960.
Inú ìrìn àjò afẹ́ ni owó ti ń wọlé jù lọ fún erékùṣù Kípírọ́sì òde òní, àmọ́ nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀ pọ̀ gan-an ní erékùṣù yìí, àwọn ará Róòmù sì wá kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀ náà lọ sí ibi ìṣúra wọn ní Róòmù. Gẹ́rẹ́ tí wọ́n tẹ erékùṣù náà dó ni wọ́n rí idẹ níbẹ̀, wọ́n sọ pé nígbà tó fi máa di ìparí ìgbà ìjọba Róòmù, wọ́n ti yọ́ ọ̀kẹ́ méjìlá àbọ̀ [250,000] tọ́ọ̀nù idẹ jáde látinú ilẹ̀. Wọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbó run kí wọ́n bàa lè rí àyè fún ilé iṣẹ́ tó ń yọ́ idẹ níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ibi tí igbó wà ní erékùsù náà ni kò sí igbó níbẹ̀ mọ́ nígbà tí Pọ́ọ̀lù máa fi débẹ̀.
Kípírọ́sì Bọ́ Sábẹ́ Àkóso Àwọn Ará Róòmù
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ, Julius Caesar fi Kípírọ́sì fún Íjíbítì, nígbà tó yá Mark Antony tún ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Augustus ń ṣèjọba, Kípírọ́sì padà sọ́wọ́ Róòmù tí alákòóso ìbílẹ̀ tí òun fúnra rẹ̀ wà lábẹ́ Róòmù sì ń ṣàkóso rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Lúùkù tó kọ ìwé Ìṣe ṣe sọ. Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì ló jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀ náà nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù níbẹ̀.—Ìṣe 13:7.
Àlàáfíà tí ìjọba Róòmù mú kí ó wà kárí orílẹ̀-èdè náà ni wọ́n pè ní Pax Romana, èyí ló mú kí ibi ìwakùsà àti àwọn ilé iṣẹ́ ní Kípírọ́sì gbèrú sí i, tó sì mú kí ọrọ̀ ajé wọ́n búrẹ́kẹ́. Ibòmíràn tí owó tún ti ń wọlé jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun Róòmù àti àwọn arìnrìn-àjò ìsìn tí wọ́n wá ń júbà Áfúródáítì, tó jẹ́ òrìṣà ńlá tí wọ́n ń bọ ní erékùṣù náà. Nítorí èyí, wọ́n ṣe àwọn ojú ọ̀nà tuntun, wọ́n ṣe èbúté, wọ́n sì kọ́ àwọn ilé tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì. Èdè Gíríìkì ni gbogbo àwọn tó wà ní erékùṣù náà ń sọ, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń jọ́sìn Áfúródáítì, Àpólò àti Súúsì ní àfikún sí olú ọba Róòmù. Àwọn èèyàn náà láásìkí, wọ́n sì ń gbádùn àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.
Irú ipò wọ̀nyí ni Pọ́ọ̀lù ń bá pàdé nígbà tó ń rìnrìn àjò káàkiri Kípírọ́sì tó sì ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Kristi. Àmọ́ ṣá o, wọ́n ti mú ẹ̀sìn Kristẹni wọ ìlú Kípírọ́sì kí Pọ́ọ̀lù tó dé ibẹ̀. Ìròyìn inú ìwé Ìṣe sọ pé lẹ́yìn ikú Sítéfánù tó jẹ́ Kristẹni ajẹ́rìíkú àkọ́kọ́, àwọn kan lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sá lọ sí Kípírọ́sì. (Ìṣe 11:19) Bánábà ọmọ ìbílẹ̀ Kípírọ́sì, tó jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù, mọ erékùṣù náà dáadáa, láìsí àní-àní òun ló ń mú Pọ́ọ̀lù káàkiri nígbà tí wọ́n ń wàásù lágbègbè náà.—Ìṣe 4:36; 13:2.
Títọpa Ìrìn-Àjò Pọ́ọ̀lù ní Kípírọ́sì
Kò rọrùn láti tọpa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìrìn-àjò Pọ́ọ̀lù ní Kípírọ́sì. Bó ti wù kó rí, àwọn awalẹ̀pìtàn ní òye tó ṣe kedere nípa ojú ọ̀nà dáradára tó wà nígbà ìjọba Róòmù. Nítorí bí ojú ilẹ̀ erékùṣù náà ṣe rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà tí àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí yẹn gbà ni wọ́n gbé ojú ọ̀nà tòde òní gbà.
Pọ́ọ̀lù, Bánábà àti Jòhánù tó ń jẹ́ Máàkù ṣíkọ̀ láti Sìlúṣíà wọ́n sì gúnlẹ̀ sí èbúté Sálámísì. Kí ló fà á tó fi jẹ́ Sálámísì ni wọ́n ṣíkọ̀ lọ nígbà tó jẹ́ pé Páfósì ni olú ìlú tó sì jẹ́ pé ibẹ̀ ni èbúté pàtàkì wà? Ohun tó fà á ni pé Sálámísì wà ní etíkun ìlà oòrùn, igba [200] kìlómítà péré sì ni ibẹ̀ sí ìlú Sìlúṣíà tó wà lórí ilẹ̀ gbalasa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fi Páfósì rọ́pò Sálámísì gẹ́gẹ́ bí olú ìlú nígbà ìjọba Róòmù, síbẹ̀síbẹ̀ Sálámísì ṣì jẹ́ ibùdó àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti ìṣòwò fún erékùṣù náà. Àwọn Júù pọ̀ díẹ̀ ní Sálámísì, àwọn míṣọ́nnárì náà sì bẹ̀rẹ̀ sí “kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn sínágọ́gù àwọn Júù.”—Ìṣe13:5.
Lónìí, gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù sílùú Sálámísì ni àwọn àwókù tó wà níbẹ̀. Síbẹ̀ àwárí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe fi hàn pé ìlú náà ní ògo àti ọrọ̀ nígbà kan rí. Ibi ọjà tó jẹ́ ibi ìgbòkègbodò àwọn òṣèlú àtàwọn ẹlẹ́sìn, ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ ibi tó tóbi jù lọ ní Róòmù tí wọ́n tíì walẹ̀ kàn rí ní àgbègbè Mẹditaréníà. Àwọn àwókù tó ti wà látìgbà Ọ̀gọ́sítọ́sì Késárì jẹ́ ká rí àwọn òkúta wẹ́ẹ́wẹ̀ẹ̀wẹ́ ọlọ́pọ̀ ẹwà tá a fi ń tẹ́ ojú ilẹ̀, gbọ̀ngàn ìfarapitú, ọpọ́n ìlúwẹ̀ẹ́ tó gbayì, gbọ̀ngàn ìṣiré, àwọn ibojì mèremère, àti gbọ̀ngàn ìwòran ńlá tó gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] èèyàn! Ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀ sì ni tẹ́ńpìlì ràgàjì ti òrìṣà Súúsì wà.
Àmọ́, Súúsì kò lè gba ìlú náà sílẹ̀ nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ dé. Ìsẹ̀lẹ̀ ńlá tó wáyé ní ọdún 15 ṣáájú Sànmánì Tiwa ba ibi tó pọ̀ jẹ́ nínú ìlú Sálámísì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀gọ́sítọ́sì tún un kọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ní ọdún 77 Sànmánì Tiwa ìsẹ̀lẹ̀ tún pa Sálámísì run, wọ́n sì tún un kọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní ọ̀rúndún kẹrin, ọ̀wọ́ àwọn ìsẹ̀lẹ̀ pa Sálámísì run, ó sì pàdánù ògo tó ní. Nígbà tó máa fi di ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbà Ọ̀làjú, ẹrẹ̀ ti bo gbogbo èbúté rẹ̀, wọ́n sì pa á tì.
A ò sọ bóyá àwọn ará Sálámísì tẹ́wọ́ gba ìwàásù Pọ́ọ̀lù tàbí wọn kò tẹ́wọ́ gbà á. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù tún ní láti lọ wàásù fún àwọn èèyàn ìlú mìíràn pẹ̀lú. Bí àwọn míṣọ́nnárì náà ti kúrò ní Sálámísì, wọ́n lè gba ojú ọ̀nà mẹ́ta yìí: ọ̀nà kìíní lọ sí etíkun àríwá, ó gba àárín àwọn òkè Kíréníà kọjá; ọ̀nà kejì wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, ó gba pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mesaóríà sọ dá erékùṣù náà; ọ̀nà kẹta ni èyí tó gba etíkun gúúsù.
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ti sọ, ojú ọ̀nà kẹta ni Pọ́ọ̀lù gbà. Ọ̀nà yìí gba àárín oko ọlọ́ràá tó ní iyẹ̀pẹ̀ pupa. Téèyàn bá rin àádọ́ta kìlómítà sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn tó ku díẹ̀ kó dé ìlú Larnaca, ọ̀nà náà yà lọ sí àríwá ní inú lọ́hùn-ún.
‘Wọ́n La Gbogbo Erékùṣù Náà Já’
Ojú ọ̀nà yẹn dé ìlú àtijọ́ náà tó ń jẹ́ Ledra. Àmọ́ ní báyìí, ìlú Nicosia tí í ṣe olú ìlú Kípírọ́sì tòde òní ló wà níbi tí ìlú Ledra wà tẹ́lẹ̀. Kò sí ẹ̀rí kankan mọ́ tá a lè fi mọ̀ pé ìlú àtijọ́ kan wà níbẹ̀ nígbà kan rí. Ṣùgbọ́n, òpópónà tóóró tó ń jẹ́ Ledra tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń gbà kọjá wà ní àárín ìlú Venice tí wọ́n fi ògiri yí pò ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Bóyá Pọ́ọ̀lù lọ sí Ledra tàbí kò lọ, a kò mọ̀. Ohun tí Bíbélì wulẹ̀ sọ fún wa ni pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ “la gbogbo erékùṣù náà já.” (Ìṣe 13:6) Ìwé The Wycliffe Historical Geography of Bible Lands sọ pé “ọ̀rọ̀ náà lè túmọ̀ sí rírìn yí ká gbogbo ibi tí àwọn Júù ń gbé ní Kípírọ́sì.”
Ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Pọ́ọ̀lù ni pé kó bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ ní Kípírọ́sì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ ọ̀nà tó wà ní ìhà gúúsù tó jáde látinú ìlú Ledra sí ìlú Amathus ati sí ìlú Kourion ni Pọ́ọ̀lù gbà kọjá, àwọn ìlú ńlá méjì tí oríṣiríṣi èèyàn ń gbé.
Ìlú Kourion wà lórí òkè gàgàrà kan tó wà nítòsí òkun. Ìlú ológo ẹwà tó wà lábẹ́ àkóso Gíríìkì òun Róòmù yìí ni irú ìsẹ̀lẹ̀ tó pa ìlú Sálámísì run wá kọ lù ní ọdún 77 Sànmánì Tiwa. Àwókù tẹ́ńpìlì tí wọ́n dìídì kọ́ fún Àpólò ti wà níbẹ̀ láti ọdún 100 Sànmánì Tiwa. Ibi ìṣeré ìdárayá tó wà níbẹ̀ lè gba ẹgbàáta [6,000] òǹwòran. Àwọn òkúta wẹ́wẹ́ tó lẹ́wà tí wọ́n fi tẹ ilẹ̀ àwọn ilé àdáni wọn jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń gbé nílùú Kourion ń gbé ìgbésí ayé tó rọ̀ṣọ̀mù.
Wọ́n Lọ sí Páfósì
Ojú ọ̀nà tó dára tó wá látinú Kourion ń bá a lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ó sì gba inú àgbègbè tí wọ́n ti ń ṣe wáìnì kọjá, ọ̀nà náà wá kọrí sókè, lójijì ló tún dorí kọ ìsàlẹ̀, ó wá lọ́ kọ́lọkọ̀lọ gba orí àpáta gàǹgà tó dojú kọ etíkun tó ní ọ̀pọ̀ òkúta wẹ́wẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìwáṣẹ̀ àwọn ará Gíríìkì ti wí, ibí yìí gan-gan ni wọ́n gbà pé abo ọlọ́run tí ń jẹ́ Áfúródáítì ti jáde wá látinú òkun gẹ́gẹ́ bí ọmọ tuntun.
Abo ọlọ́run tí ń jẹ́ Áfúródáítì yìí ló gbajúmọ̀ jù lọ nínú àwọn ọlọ́run àjúbàfún táwọn ará Gíríìkì ń sìn ní Kípírọ́sì, wọ́n sì ń sìn ín tọkàntara títí di ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa. Ìlú Páfósì ni àwọn èèyàn máa ń péjọ sí láti jọ́sìn Áfúródáítì. Gbogbo ìgbà ìrúwé làwọn èèyàn máa ń ṣe àjọyọ̀ ńlá láti fi júbà rẹ̀. Àwọn arìnrìn-àjò ìsìn láti Éṣíà Kékeré, Íjíbítì, Gíríìsì títí dé ibi tó jìnnà bíi Páṣíà máa ń wá sí Páfósì ní tìtorí àjọyọ̀ yìí. Nígbà tí Kípírọ́sì wà lábẹ́ ìṣàkóso àwọn Tọ́lẹ́mì, àwọn ará Kípírọ́sì ń jọ́sìn Fáráò.
Páfósì ni olú ìlú Kípírọ́sì lábẹ́ ìjọba Róòmù, ibẹ̀ ni alákòóso ìbílẹ̀ máa ń gbé, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti máa ń ṣe owó ẹyọ onídẹ. Ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọdún 15 ṣááju Sànmánì Tiwa ló pa ìlú Páfósì run, Ọ̀gọ́sítọ́sì gbé owó kalẹ̀ pé kí wọ́n fi tún ìlú náà kọ́ gẹ́gẹ́ bó ti ṣe fún ìlú Sálámísì. Àwọn ohun tí wọ́n wà jáde látinú ilẹ̀ fi hàn pé ìgbésí ayé ọlọ́rọ̀ ni àwọn èèyàn ń gbé ní Páfósì, ojú pópó fífẹ̀, àwọn ilé tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì, ilé ẹ̀kọ́ orin, gbọ̀ngàn ìfarapitú àti àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá ló wà níbẹ̀.
Páfósì yìí ni Pọ́ọ̀lù, Bánábà àti Jòhánù tí ń jẹ́ Máàkù ṣèbẹ̀wò sí, ibẹ̀ sì ni Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì alákòóso ìbílẹ̀, “ọkùnrin onílàákàyè” ti fi “taratara wá ọ̀nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” láìka àtakò lílé látọ̀dọ̀ Élímà oníṣẹ́ oṣó sí. Alákòóso ìbílẹ̀ tá à ń wí yìí ni ‘háà ṣe sí ẹ̀kọ́ Jèhófà.’—Ìṣe 13:6-12.
Lẹ́yìn táwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí ti ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn ní Kípírọ́sì láṣeyọrí, wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ ní Éṣíà Kékeré. Ìrìn àjò àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù lọ yìí jẹ́ àṣeyọrí pàtàkì kan nínú mímú ẹ̀sìn Kristẹni dé ibi púpọ̀. Ìwé náà St. Paul’s Journeys in the Greek Orient pè é ní “ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Kristẹni àti . . . ti iṣẹ́ míṣọ́nnárì Pọ́ọ̀lù.” Ó fi kún un pé: “Èèyàn ò lè ṣe kó máà rí ipa ibi tí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ojú ọ̀nà òkun tó lọ sí Síríà, Éṣíà Kékeré, Gíríìsì àti Kípírọ́sì.” Àmọ́ ṣá o, ìbẹ̀rẹ̀ nìyẹn jẹ́ o. Ní ẹgbàá ọdún [2000] lẹ́yìn náà, iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti àwọn Kristẹni ṣì ń bá a lọ, a sì lè sọ pé ìhìn rere Ìjọba Jèhófà ti dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 20]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
KÍPÍRỌ́SÌ
NICOSIA (Ledra)
Sálámísì
Páfósì
Kourion
Amathus
Larnaca
ÒKÈ KÍRÉNÍÀ
PẸ̀TẸ́LẸ̀ MESAÓRÍÀ
ÒKÈ TROODOS
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó fọ́ Élímà oníṣẹ́ oṣó lójú ní ìlú Páfósì