Apẹẹrẹ Onimiisi Ti Iṣẹ Ijihin-Iṣẹ-Ọlọrun Kristian Ni Ilẹ Ajeji
“Ẹ maa ṣe afarawe mi, àní gẹgẹ bi emi ti ń ṣe afarawe Kristi.”—1 KORINTI 11:1.
1. Ki ni diẹ ninu awọn ọ̀nà ti Jesu gbà fi apẹẹrẹ titayọ kan lélẹ̀ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati ṣafarawe? (Filippi 2:5-9)
Ẹ WO apẹẹrẹ titayọ kan ti Jesu fi lélẹ̀ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀! Oun fi tayọtayọ fi ogo rẹ̀ ọ̀run silẹ lati sọkalẹ wá sori ilẹ̀-ayé lati gbé laaarin awọn eniyan ẹlẹṣẹ. Oun muratan lati farada ijiya ńláǹlà fun igbala araye ati, ni pataki ju, fun isọdi mímọ́ orukọ Baba rẹ̀ ọ̀run. (Johannu 3:16; 17:4) Nigba ti ó ń jẹ́jọ́ fun iwalaaye rẹ̀, Jesu fi igboya polongo pe: “Nitori eyi ni a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo sì ṣe wá sí ayé, ki emi ki o lè jẹrii si otitọ.”—Johannu 18:37.
2. Eeṣe ti Jesu ti a jí dide fi lè paṣe fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati maa bá iṣẹ ti oun ti bẹrẹ lọ?
2 Ṣaaju ikú rẹ̀, Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni idanilẹkọọ titayọlọla ki wọn baa lè maa baa lọ ninu iṣẹ jijẹrii si otitọ Ijọba. (Matteu 10:5-23; Luku 10:1-16) Nipa bayii, lẹhin ajinde rẹ̀, Jesu lè pa aṣẹ naa pe: “Ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa baptisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin, ati ti ẹmi mímọ́, ki ẹ maa kọ́ wọn lẹkọọ lati fisọra kiyesi ohun gbogbo ti mo ti paṣẹ fun yin.”—Matteu 28:19, 20, NW.
3. Bawo ni sisọni di ọmọ-ẹhin naa ṣe gbooro, ṣugbọn ni ẹkùn wo ni ó ti rinlẹ ni pataki?
3 Fun ọdun mẹta ati aabọ ti o tẹle e, awọn ọmọ-ẹhin Jesu ṣegbọran si aṣẹ yii ṣugbọn wọn fi sisọni di ọmọ-ẹhin ti wọn ń ṣe mọ sọdọ awọn Ju, alawọṣe Ju, ati awọn ará Samaria ti a kọnila. Nigba naa, ni 36 C. E., Ọlọrun dari pe ki ihinrere naa di eyi ti a waasu rẹ̀ fun ọkunrin alaikọla kan, Korneliu, ati agbo-ile rẹ̀. Ni ẹwadun ti o tẹle e, awọn Keferi miiran ni a mú wá sinu ijọ. Bi o ti wu ki o ri, ọpọ julọ ninu iṣẹ naa ni ó dabi eyi ti a ti fimọ si ẹkùn ìhà ila-oorun Mediterranean.—Iṣe 10:24, 44-48; 11:19-21.
4. Ìdàgbàsókè pataki wo ni o wáyé ni nǹkan bii 47 si 48 C.E.?
4 Ohun kan ni a nilo lati sún tabi mú ki o ṣeeṣe fun awọn Kristian lati sọ awon Ju ati Keferi ni awọn ẹkùn ti o tubọ jinna réré di ọmọ-ẹhin. Nitori naa, ni nǹkan bii 47 si 48 C. E., awọn alagba ijọ Antioku ti Siria gba ihin-iṣẹ atọrunwa yii: “Ẹ ya Barnaba oun Saulu sọtọ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pe wọn si.” (Iṣe 13:2) Ṣakiyesi pe Paulu ni a mọ̀ pẹlu orukọ rẹ̀ ipilẹṣẹ, Saulu. Ṣakiyesi, pẹlu, pe Ọlọrun darukọ Barnaba ṣaaju Paulu, boya nitori pe ni akoko yẹn Barnaba ni a kà sí aṣaaju ninu awọn mejeeji.
5. Eeṣe ti akọsilẹ nipa irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji Paulu ati Barnaba fi ṣeyebiye gidi fun awọn Kristian lonii?
5 Kulẹkulẹ akọsilẹ nipa irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji Paulu ati Barnaba jẹ́ iṣiri ńláǹlà fun Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ni pataki fun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ati awọn aṣaaju-ọna ti wọn ti ṣí lọ kuro ni ilu wọn lati ṣiṣẹsin Ọlọrun ninu awujọ ìdálẹ̀ kan. Siwaju sii, atunyẹwo Iṣe ori 13 ati 14 yoo tubọ sún sibẹ awọn pupọ sii dajudaju lati ṣafarawe Paulu ati Barnaba ki wọn sì mú ṣiṣe ajọpin wọn ninu iṣẹ ti ó ṣe pataki julọ naa ti sisọni di ọmọ-ẹhin gbooro sii.
Erekuṣu Kipru
6. Apẹẹrẹ wo ni awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa fi lélẹ̀ ni kipru?
6 Laijafara awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa tukọ lati èbúté Siria ti Seleukia lọ si erekuṣu Kipru. Lẹhin gígúnlẹ̀ si Salami, a kò pa wọ́n léte dà ṣugbọn “wọn ń waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni sinagogu awọn Ju.” Ni titẹle apẹẹrẹ Kristi, kò tẹ́ wọn lọrun lati fidi kalẹ ni ilu yẹn ki wọn sì duro de awọn ará erekuṣu naa lati tọ̀ wọn wá. Dipo bẹẹ, wọn mú ọ̀nà wọn pọ̀n “la gbogbo erekuṣu já.” Laiṣiyemeji eyi ní ninu fífi ẹsẹ̀ rìn pupọ ati ọpọlọpọ iyipada ibugbe, niwọn bi Kipru ti jẹ́ erekuṣu ńlá, tí irin-ajo wọn sì mú wọn la òró ìpín ti ó tobi julọ ninu rẹ̀ kọjá.—Iṣe 13:5, 6.
7. (a) Iṣẹlẹ titayọ wo ni o wáyé ni Pafo? (b) Akọsilẹ yii fun wa niṣiiri lati ni iṣarasihuwa wo?
7 Ni opin ibẹwo wọn, awọn ọkunrin mejeeji ni a san èrè fun pẹlu iriri agbayanu ni ilu Pafo. Oluṣakoso erekuṣu naa, Sergiu Paulu, fetisilẹ si ihin-iṣẹ wọn ó sì “gbagbọ.” (Iṣe 13:7, 12) Paulu kọwe lẹhin naa pe: “Ẹ sa wo ìpè yin, ará, bi o ti ṣe pe kì í ṣe ọpọ awọn ọlọgbọn eniyan nipa ti ara, kì í ṣe ọpọ awọn alagbara, kì í ṣe ọpọ awọn ọlọla ni a pe.” (1 Korinti 1:26) Sibẹ, lara awọn alagbara ti wọn dahunpada ni Sergiu Paulu wà. Iriri yii gbọdọ fun gbogbo wa niṣiiri, ni pataki awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji, lati ni iṣarasihuwa onifojusọna si rere nipa jijẹrii fun awọn ijoye oṣiṣẹ ijọba, àní bi a ti fun wa niṣiiri lati ṣe ni 1 Timoteu 2:1-4. Awọn eniyan alaṣẹ nigba miiran ti fun awọn iranṣẹ Ọlọrun ni iranlọwọ ńlá.—Nehemiah 2: 4-8.
8. (a) Iyipada ninu ipo ibatan wo ni o farahan laaarin Barnaba ati Paulu lati akoko yii lọ? (b) Ni ọ̀nà wo ni Barnaba gbà jẹ́ apẹẹrẹ rere?
8 Labẹ agbara idari ẹmi Jehofa, Paulu kó ipa ti o tobi jù ninu iyilọkanpada Sergiu Paulu. (Iṣe 13:8-12) Pẹlupẹlu, lati akoko yii lọ, ó farahan pe Paulu mú ipo iwaju. (Fiwe Iṣe 13:7 pẹlu Iṣe 13:15, 16, 43.) Eyi wà ni ibamu pẹlu iṣẹ-aṣẹ atọrunwa naa ti Paulu ti gbà ni akoko iyilọkanpada rẹ̀. (Iṣe 9:15) Boya iru iṣẹlẹ titun kan bẹẹ dán irẹlẹ Barnaba wò. Bi o ti wu ki o ri, dipo wiwo iyipada yii gẹgẹ bii iṣafojudi sini, ó dabii pe Barnaba gbé ni ibamu pẹlu itumọ orukọ rẹ̀, “Ọmọ-Ìtùnú,” ti ó sì fi iduroṣinṣin ti Paulu lẹhin jalẹ irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa ati lẹhin naa nigba ti awọn Kristian kan ti wọn jẹ Ju pe iṣẹ-ojiṣẹ wọn fun awọn Keferi ti a kò kọnila nija. (Iṣe 15:1, 2) Iru apẹẹrẹ rere wo ni eyi jẹ́ fun gbogbo wa, papọ pẹlu awọn ti wọn ń gbé ninu ile ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ati Beteli! A gbọdọ maa muratan nigba gbogbo lati tẹwọgba iṣatunṣebọsipo ti iṣakoso Ọlọrun ki a sì fi itilẹhin wa kikun fun awọn wọnni ti a yàn sipo lati mú ipo iwaju laaarin wa.—Heberu 13:17.
Ilẹ Pẹrẹsẹ ti Asia Kekere
9. Ẹ̀kọ́ wo ni a kọ́ lati inu imuratan Paulu ati Barnaba lati rinrin-ajo lọ si Antioku ti Pisidia?
9 Lati Kipru, Paulu ati Barnaba tukọ̀ lọ sí ìhà ariwa àgbáálá-ilẹ̀ Asia. Fun idi kan ti a kò sọ, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa kò duro ni ẹkùn etikun ṣugbọn wọn rin irin-ajo gigun ti ó sì léwu fun nǹkan bii ibusọ 110 lọ si Antioku ti Pisidia, ti ó wà laaarin ilẹ pẹrẹsẹ ti Asia Kekere. Eyi ní ninu pípọ́nkè kọja awọn ọ̀nà aarin-oke ati sisọkalẹ lọ si pẹtẹlẹ ti ó fi 3,500 ẹsẹ-bata ga ju ìwọ̀n oju-omi òkun. Ọmọwe Bibeli J. S. Howson sọ pe: “Iwa ailofin ati iwa ìdigunjalè awọn ti ń gbé awọn oke wọnni ti ó ya ilẹ pẹrẹsẹ sọtọ kuro lara awọn pẹtẹlẹ ti wọn wà ni guusu etikun, ni okiki rẹ̀ kàn ninu gbogbo apá ìtàn igbaani.” Ni afikun, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa dojukọ ewu lati inu awọn ohun adanida. Howson fikun un pe, “kò si agbegbe kan ni Asia Kekere, ti a dá mọ̀ yatọ pẹlu ‘ìkún omi’ rẹ̀ ju gbalasa ilẹ Pisidia lọ, nibi ti awọn odò ti bú jade lati abẹ́ apata gàǹgà, tabi ń rọ́ gidigidi wálẹ̀ la afonifoju jijin tooro já.” Awọn kulẹkulẹ wọnyi ràn wá lọwọ lati foju inu yaworan iru irin-ajo ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa muratan lati rìn nititori títan ihinrere kalẹ. (2 Korinti 11:26) Bakan-naa lonii, ọpọlọpọ awọn iranṣẹ Jehofa fàyàrán oniruuru oke iṣoro ki wọn baa lè dé ọdọ awọn eniyan ki wọn sì ṣajọpin ihinrere pẹlu wọn.
10, 11. (a) Bawo ni Paulu ṣe wà ni ipilẹ ajọfohunṣọkan pẹlu awujọ olùgbọ́ rẹ̀? (b) Eeṣe ti ó fi ṣeeṣe ki o ya ọpọ awọn Ju lẹnu lati gbọ nipa ijiya Messia? (c) Iru igbala wo ni Paulu nawọ rẹ̀ siwaju awọn olùgbọ rẹ̀?
10 Niwọn bi sinagogu awọn Ju ti wà ni Antioku ti Pisidia, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa kọ́kọ́ lọ sibẹ ki wọn baa lè fun awọn wọnni tí wọn ti mọ̀ nipa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun julọ ni anfaani lati gba ihinrere. Nigba ti a késí i lati sọrọ, Paulu dide duro ó sì sọ asọye itagbangba ọ̀kanṣoṣo-ọ̀gá. Jalẹ ọrọ-asọye naa, ó wà ni ipilẹ ajọfohunṣọkan pẹlu awọn Ju ati alawọṣe Ju ti wọn wà ni ìkàlẹ̀. (Iṣe 13:13-16, 26) Lẹhin inasẹ-ọrọ rẹ̀, Paulu ṣatunyẹwo ìtàn gbígbajúmọ̀ ti awọn Ju, ní rírán wọn létí pe Jehofa ti yàn awọn babanla wọn ó sì dá wọn nídè kuro ni Egipti nigba naa, ati bakan-naa bi o ti ràn wọn lọwọ lati ṣẹgun awọn olugbe Ilẹ Ileri. Lẹhin naa Paulu tẹnumọ awọn ibalo Jehofa pẹlu Dafidi. Iru isọfunni bẹẹ jẹ awọn Ju lọkan ni ọrundun kìn-ín-ní nitori pe wọn ń reti pe ki Ọlọrun gbé atọmọdọmọ Dafidi kan dide gẹgẹ bi olugbala ati oluṣakoso ainipẹkun. Lori kókó yii, Paulu fi tigboyatigboya kede pe: “Lati inu iru-ọmọ ọkunrin yii [Dafidi] ni Ọlọrun ti gbé Jesu Olugbala dide fun Israeli gẹgẹ bi ileri.”—Iṣe 13:17-23.
11 Bi o ti wu ki o ri, iru olugbala ti ọpọ awọn Ju ń duro dè ni akọni ológun ti yoo dá wọn nídè kuro labẹ ijẹgaba Romu ki ó sì gbé orilẹ-ede Ju ga bori gbogbo awọn miiran. Fun idi yii, laiṣiyemeji ẹnu yà wọn lati gbọ́ ki Paulu sọ pe Messia ni a ti fà kalẹ fun ifiya-iku-jẹ́ lati ọwọ́ awọn aṣaaju-isin wọn funraawọn. “Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu òkú,” ni Paulu fi igboya polongo. Ní ìhà ipari ọrọ-asọye rẹ̀, ó fihàn awọn olùgbọ́ rẹ̀ pe ọwọ wọn lè tẹ iru igbala agbayanu kan. Ó sọ pe, “Ki ó yé yin, . . . pe nipasẹ ọkunrin yii ni a ń waasu idariji ẹṣẹ fun yin: ati nipa rẹ̀ ni a ń dá olukuluku ẹni ti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò lè dá yin lare ninu ofin Mose.” Paulu pari ọrọ-asọye rẹ̀ nipa rírọ awọn olùgbọ́ rẹ̀ lati máṣe wà lara awọn ọpọlọpọ ti Ọlọrun sọtẹlẹ pe yoo ṣàìnáání ipese agbayanu fun igbala yii.—Iṣe 13:30-41.
12. Ki ni ó jẹ jade lati inu awiye Paulu, bawo sì ni eyi ṣe gbọdọ fun wa niṣiiri?
12 Ẹ wo iru awiye ti a gbékarí Bibeli ti a sọ daradara ti eyi jẹ́! Bawo ni awujọ olùgbọ́ naa ṣe dahunpada? “Ọpọ ninu awọn Ju ati ninu awọn olufọkansin alawọṣe tẹle Paulu oun Barnaba.” (Iṣe 13:43) Eyi ti jẹ́ iṣiri fun wa tó lonii! Ǹjẹ́ ki a ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe lati gbé otitọ kalẹ lọna gbigbeṣẹ bakannaa, yala ninu iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba tabi ninu ọ̀rọ̀ ilohunsi ati ọrọ-asọye ni awọn ipade ijọ.—1 Timoteu 4:13-16.
13. Eeṣe ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa fi nilati fi Antioku ti Pisidia silẹ, awọn ibeere wo si ni ó dide nipa awọn ọmọ-ẹhin titun?
13 Awọn olufifẹhan titun naa ni Antioku ti Pisidia kò lè pa ihinrere yii mọ sọdọ araawọn. Gẹgẹ bi iyọrisi eyi, “ni ọjọ isinmi keji, gbogbo ilu sì fẹrẹẹ pejọ tán lati gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.” Laipẹ ihin-iṣẹ naa sì tankalẹ rekọja ilu naa. Nitootọ “A sì tan ọ̀rọ̀ Oluwa [“Jehofa,” NW] ká gbogbo ẹkùn naa.” (Iṣe 13:44, 49) Dipo gbígba otitọ yii, awọn Ju òjòwú pari rẹ̀ si lílé awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa jade kuro ni ilu. (Iṣe 13:45, 50) Bawo ni eyi ṣe nipa lori awọn ọmọ-ẹhin titun naa? Wọn ha di ẹni ti o rẹwẹsi ki wọn sì dawọduro bi?
14. Eeṣe ti awọn alatako kò fi lè fopin si iṣẹ ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa ti bẹrẹ, ẹ̀kọ́ wo ni a sì kọ lati inu eyi?
14 Bẹẹkọ, nitori pe iṣẹ Ọlọrun ni eyi. Pẹlupẹlu, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa ti fi ipilẹ alagbara ti igbagbọ ninu ajinde Oluwa Jesu Kristi lélẹ̀. Lọna ti o ṣe kedere, nigba naa, awọn ọmọ-ẹhin titun naa ka Kristi, kì í sìí ṣe awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa, sí Aṣaaju wọn. Nipa bayii, a kà pe wọn “kún fun ayọ ati fun ẹmi mimọ.” (Iṣe 13:52) Ẹ wo bi eyi ti jẹ́ iṣiri tó fun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ati awọn olùsọni di ọmọ-ẹhin miiran lonii! Bi a bá fi tirẹlẹtirẹlẹ ati titaratitara ṣe ipa tiwa, Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi yoo bukun iṣẹ-ojiṣẹ wa.—1 Korinti 3:9.
Ikonioni, Listra, ati Derbe
15. Ọ̀nà igbaṣe wo ni awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa tẹle ni Ikonioni, pẹlu iyọrisi wo sì ni?
15 Paulu ati Barnaba wá rinrin-ajo nǹkan bii 90 ibusọ nisinsinyi síhà guusu lọ si ilu ti ó tẹle e, Ikonioni. Ibẹru inunibini kò dí wọn lọwọ lati maṣe tẹle ọ̀nà igbaṣe kan-naa bii ti Antioku. Gẹgẹ bi iyọrisi eyi, Bibeli sọ pe: “Ọpọlọpọ awọn Ju ati awọn Hellene [Griki] gbagbọ.” (Iṣe 14:1) Lẹẹkan sii, awọn Ju ti kò gba ihinrere gbọ́ ru àtakò soke. Ṣugbọn awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa farada a wọn sì lo akoko ti ó pọ̀ diẹ ni Ikonioni ni ríran awọn ọmọ-ẹhin titun lọwọ. Wàyí o, lẹhin mímọ̀ pe awọn Ju alatako wọn ti fẹ́ sọ wọn ni okuta, lọna ti ó bọgbọnmu Paulu ati Barnaba fi ọgbọ́n sá lọ si ipinlẹ ti o tẹle e, “Listra ati Derbe . . . ati si agbegbe ti o yika.”—Iṣe 14:2-6.
16, 17. (a) Ki ni ó ṣẹlẹ si Paulu ni Listra? (b) Bawo ni awọn ibalo Ọlọrun pẹlu aposteli naa ṣe nipa lori ọdọmọkunrin kan lati Listra?
16 Pẹlu igboya “wọn si ń waasu ihinrere” ni ipinlẹ titun, ti a ṣẹṣẹ ń ṣe fun ìgbà akọkọ yii. (Iṣe 14:7) Nigba ti awọn Ju ni Antioku ti Pisidia ati Ikonioni gbọ́ nipa eyi, wọn wá lati iyànníyàn Listra wọn sì yi awọn ogunlọgọ lọkan pada lati sọ Paulu lokuuta. Laisi akoko lati sálà, Paulu ni a sọ ni okuta, debi pe awọn alatako rẹ̀ fi ní idaniloju pe ó ti kú. Wọn wọ́ ọ jade kuro ninu ilu.—Iṣe 14:19.
17 Iwọ ha lè finuro idaamu ti eyi fà fun awọn ọmọ-ẹhin titun bi? Ṣugbọn pabambarì, nigba ti wọn yí Paulu po, oun díde duro! Bibeli kò sọ boya ọdọmọkunrin kan ti ń jẹ́ Timoteu jẹ́ ọ̀kan lara awọn ọmọ-ẹhin titun wọnyi. Dajudaju awọn ibalo Ọlọrun pẹlu Paulu ni akoko kan di mímọ̀ fun un ó sì fa èrò tí ó jinlẹ ninu ọkàn ọ̀dọ́ rẹ̀. Paulu kọwe ninu lẹta rẹ̀ keji si Timoteu pe: “Ṣugbọn iwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, igbesi-aye mi, . . . awọn ohun ti o dé bá mi ni Antioku, ni Ikonioni ati ni Listra; awọn inunibini ti mo farada: Oluwa sì gbà mi kuro ninu gbogbo wọn.” (2 Timoteu 3:10, 11) Ni nǹkan bi ọdun kan tabi meji lẹhin ti a sọ Paulu lokuuta, ó pada si Listra ó sì rí i pe Timoteu ọ̀dọ́ jẹ́ Kristian awofiṣapẹẹrẹ kan, “ti a rohin rẹ̀ rere lọdọ awọn arakunrin ti ó wà ni Listra ati Ikonioni.” (Iṣe 16:1, 2) Nitori naa Paulu yàn án gẹgẹ bi alábàárìnrìn-àjò rẹ̀. Eyi ran Timoteu lọwọ lati dagba ni ìwọ̀n idagba tẹmi, ati bi akoko ti ń lọ ó tootun lati di ẹni ti Paulu rán lati bẹ oriṣiriṣi awọn ijọ wò. (Filippi 2:19, 20; 1 Timoteu 1:3) Bakan-naa, lonii, awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn ní ìtara jẹ́ agbara idari agbayanu lori awọn ọ̀dọ́ eniyan, ọpọ ninu awọn ti wọn dagba di iranṣẹ Ọlọrun ti ó ṣeyebiye, bii Timoteu.
18. (a) Ki ni ó ṣẹlẹ si awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa ni Derbe? (b) Anfaani wo ni ó ṣí silẹ nisinsinyi fun wọn, ipa-ọna wo ni wọn sì yàn?
18 Ni òwúrọ̀ ọjọ keji ti o tẹle àjàbọ́ rẹ̀ kuro lọwọ ikú ni Listra, Paulu lọ si Derbe pẹlu Barnaba. Lakooko yii, kò si alatako kankan ti ó tẹle wọn, Bibeli sì wi pe ‘wọn sọ awọn diẹ di ọmọ-ẹhin.’ (Iṣe 14:20, 21) Lẹhin ti wọn ti fidi ijọ kan mulẹ ni Derbe, Paulu ati Barnaba nilati ṣe ipinnu kan. Oju-ọna ti awọn ará Romu kan ti a ń rìn deedee kọja lọ lati Derbe si Tarsu. Lati ibẹ̀ ó jẹ́ ọ̀nà kukuru pada si Antioku ti Siria. Ó ṣeeṣe kì íyẹn jẹ́ ọ̀nà ti ó rọrun julọ lati pada, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji wọnni sì lè ti nimọlara pe awọn lẹtọọsi isinmi nisinsinyi. Bi o ti wu ki o ri, ni afarawe Ọ̀gá wọn, Paulu ati Barnaba fòye mọ aini ti ó tubọ pọ sii.—Marku 6:31-34.
Ṣiṣe Iṣẹ Ọlọrun ni Kíkún
19, 20. (a) Bawo ni Jehofa ṣe bukun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa fun pipada si Listra, Ikonioni, ati Antioku? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni eyi pese fun awọn eniyan Jehofa lonii?
19 Dipo gbígba oju-ọna àbùjá naa pada si ile, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa fi igboya ṣẹ́rí wọn sì pada bẹ awọn ilu ti iwalaaye wọn ti wà ninu ewu gan-an wo lẹẹkan sii. Jehofa ha bukun wọn fun idaniyan alaimọtara-ẹni-nikan fun awọn agutan titun naa bi? Bẹẹni, nitootọ, nitori pe akọsilẹ naa sọ pe wọn ṣaṣeyọri ninu ‘mímú awọn ọmọ-ẹhin ni ọkàn le, wọn ń gbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ.’ Lọna ti o baamu, wọn sọ fun awọn ọmọ-ẹhin titun naa pe: “Ninu ipọnju pipọ ni awa ó fi wọ ijọba Ọlọrun.” (Iṣe 14:21, 22) Paulu ati Barnaba tun rán wọn létí nipa ìpè wọn gẹgẹ bi ajumọjogun ninu Ijọba Ọlọrun ti ń bọ̀wá. Lonii, a gbọdọ fun awọn ọmọ-ẹhin titun ni iṣiri ti o jọra. A lè fun wọn lokun lati farada awọn adanwo nipa nínawọ́ ifojusọna ìyè ainipẹkun lori ilẹ̀-ayẹ́ labẹ iṣakoso Ijọba Ọlọrun yẹn kan-naa nipa eyi ti Paulu ati Barnaba waasu rẹ̀ siwaju wọn.
20 Ki wọn tó fi ilu kọọkan silẹ, Paulu ati Barnaba ran ijọ adugbo lọwọ lati ní iṣetojọ daradara. Lọna ti ó hàn gbangba, wọn dá awọn ọkunrin ti wọn tootun lẹkọọ wọn sì yàn wọn sipo lati mú ipo iwaju. (Iṣe 14:23) Laisiyemeji eyi setilẹhin fun imugbooro siwaju sii. Bakan-naa lonii, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ati awọn miiran, lẹhin ríran awọn ti wọn kò niriiri lọwọ lati tẹsiwaju titi di ìgbà ti wọn lè gbé ẹrù-iṣẹ́, maa ń ṣí lọ nigba miiran wọn sì ń bá iṣẹ rere wọn lọ ni awọn ibomiran nibi ti aini ti tubọ pọ sii.
21, 22. (a) Ki ni ó ṣẹlẹ lẹhin ti Paulu ati Barnaba ti pari irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji wọn? (b) Awọn ibeere wo ni eyi gbé dide?
21 Nigba ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa pada nigbẹhingbẹhin si Antioku ti Siria, wọn lè ni imọlara itẹlọrun jijinlẹ. Nitootọ, akọsilẹ Bibeli sọ pe wọn ti “ṣe” iṣẹ ti Ọlọrun gbé lé wọn lọwọ “pari.” (Iṣe 14:26) Bi a ti le reti, sisọ awọn iriri wọn ṣokunfa “ayọ ńlá fun gbogbo awọn arakunrin.” (Iṣe15:3) Ṣugbọn ki ni nipa ọjọ-iwaju? Wọn yoo ha jokoo gẹ̀lẹ̀tẹ̀ ki wọn sì káwọ́lẹ́rán, gẹgẹ bi a ti maa ń sọ nisinsinyi bi? Dajudaju bẹẹkọ. Lẹhin ṣiṣebẹwo sọdọ ẹgbẹ oluṣakoso ni Jerusalemu lati gba ipinnu kan lori ọ̀ràn ìkọ̀là, awọn mejeeji jade lọ lẹẹkansii fun irin-ajo ijihin iṣẹ Ọlọrun. Lọ́tẹ̀ yii wọn lọ sí ìhà ọtọọtọ. Barnaba mú Johannu Marku ó sì lọ si Kipru, nigba ti Paulu rí ẹnikeji titun, Sila, ti wọn sì rinrin-ajo la Siria ati Kilikia lọ. (Iṣe 15:39-41) Nigba irin-ajo yii ni ó yan Timoteu ọ̀dọ́ ti ó sì mu un dani.
22 Bibeli kò sọ iyọrisi irin-ajo keji ti Barnaba. Niti Paulu, ó ń baa lọ ni ipinlẹ titun ó sì fidii awọn ijọ mulẹ ni ó keretan ilu marun-un—Filippi, Berea, Tessalonika, Korinti, ati Efesu. Ki ni kọkọrọ si aṣeyọrisirere titayọ ti Paulu? Awọn ilana kan-naa ha ṣiṣẹ fun awọn Kristian olùsọni di ọmọ-ẹhin lonii bi?
Iwọ Ha Sọyeranti Bi?
◻ Eeṣe ti Jesu fi jẹ apẹẹrẹ titayọ lati ṣafarawe?
◻ Ni ọ̀nà wo ni Barnaba gbà jẹ́ apẹẹrẹ kan?
◻ Ki ni a kọ́ lati inu awiye Paulu ni Antioku ti Pisidia?
◻ Bawo ni Paulu ati Barnaba ṣe ṣe iṣẹ-ayanfunni wọn ni kikun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ifarada inunibini aposteli Paulu ní ipa jijinlẹ pipẹtiti lori ọdọmọkunrin naa Timoteu