Bawo Ni Ọ̀rọ̀-Ìtàn Bibeli Ti Péye Tó?
“OTITỌ ni emi ń sọ, emi kò ṣèké,” ni onkọwe Bibeli kan sọ fun ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ti o jẹ́ ọ̀dọ́. (1 Timoteu 2:7) Awọn ọ̀rọ̀ bi iyẹn ninu awọn lẹta Paulu gbé ipenija kalẹ fun awọn aṣelámèyítọ́ Bibeli.a Ohun eti o ju 1,900 ọdun lọ ti kọja lẹhin ti Paulu kọ awọn lẹta rẹ̀. Lẹhin gbogbo akoko yẹn, kò sí ẹnikẹni ti o tíì dá a lábàá ki o sì fi aṣeyọrisirere fi ẹ̀rí koko kanṣoṣo ti kò péye hàn ninu awọn lẹta rẹ̀.
Onkọwe Bibeli naa Luku tun fi idaniyan kan fun ìpéye hàn. Ó ṣe akọsilẹ iṣẹlẹ kan nipa igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu tí akọsilẹ-iṣẹlẹ rẹ̀ tí a pè ni Iṣe Awọn Aposteli tẹle. “Mo ti wadii ohun gbogbo kínníkínní . . . lati ipilẹṣẹ,” ni Luku kọwe.—Luku 1:3.
Awọn Ẹ̀rí Ìpéye
Awọn aṣelámèyítọ́ Bibeli ti ibẹrẹ ọrundun kọkandinlogun pe ìpéye Luku níjà gẹgẹ bi opitan kan. Ju bẹẹ lọ, wọn jẹwọ pe ìtàn ti ó wà ninu iwe Iṣe ni a hùmọ̀ rẹ̀ ni aarin ọrundun keji C.E. Awalẹpitan ọmọ ilẹ Britain naa Sir William Mitchell Ramsay jẹ́ ẹnikan ti ó gba eyi gbọ́. Ṣugbọn lẹhin wiwadii awọn orukọ ati ibi ti Luku mẹnukan, ó fi ijẹwọ rẹ̀ hàn pe: “A fi kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yí mi lérò padà pe ninu oniruuru awọn kulẹkulẹ ìtàn naa fi agbayanu otitọ hàn.”
Nigba ti Ramsay kọ ohun ti ó wà loke yii, ariyanjiyan kan nipa ìpéye Luku ni a kò tíì yanju. Ó niiṣe pẹlu awọn ilu-nla ti wọn tan mọ́ra pẹkipẹki naa, Ikonioni, Listra ati Derbe. Luku dọgbọn sọ pe Ikonioni jẹ́ agbegbe ti o yatọ si Listra ati Derbe, ni ṣiṣapejuwe eyi ti o gbẹhin yii gẹgẹ bi “ilu Likaonia.” (Iṣe 14:6) Sibẹ, gẹgẹ bi aworan-ilẹ ti o bá a rìn yii ti fihàn, Listra sunmọ Ikonioni ju Derbe lọ. Awọn opitan atijọ kan ṣapejuwe Ikonioni gẹgẹ bi apakan Likaonia; fun idi yii, awọn aṣelámèyítọ́ pe Luku níjà fun àìṣe bẹ́ẹ̀ pẹlu.
Lẹhin naa, ni 1910, Ramsay ṣàwárí ohun iranti kan ninu awọn awókù Ikonioni ti ń fihàn pe Frigia ni èdè ilu-nla yẹn kìí sìí ṣe Likaonia. “Iye awọn ikọwe miiran lati Ikonioni ati agbegbe rẹ̀ ti otitọ naa lẹhin pe ilu-nla naa ni a lè ṣapejuwe gẹgẹ bi Frigia niti ẹ̀yà-ìran,” ni Dokita Merrill Unger sọ ninu iwe rẹ̀ Archaeology and the New Testament. Nitootọ, ilu Ikonioni ìgbà ọjọ Paulu jẹ́ alaṣa-ibilẹ kan-naa pẹlu Frigia ó sì jẹ́ agbegbe ti o yatọ si “ilu Likaonia,” nibi ti awọn eniyan ti ń sọrọ “ni èdè Likaonia.”—Iṣe 14:6, 11.
Awọn aṣelámèyítọ́ Bibeli tun gbé ibeere dide si lílò ti Luku lo ọ̀rọ̀ naa “politarchs” (gomina awọn ọlọ̀tọ̀) fun awọn oluṣakoso ilu-nla Tessalonika. (Iṣe 17:6, akiyesi ẹsẹ-iwe) Ọ̀rọ̀ yii ni a kò mọ̀ ninu awọn iwe Griki. Lẹhin naa ẹnu-ọna birikiti kan ti o ni awọn orukọ oluṣakoso ti a ṣapejuwe gẹgẹ bi “politarchs”—ọ̀rọ̀ naa gan-an ti Luku lò ni a rí ni ilu-nla igbaani naa. “Ìpéye Luku ni a ti dalare nipa ìlò èdè-ìsọ̀rọ̀ naa,” ni W. E. Vine ṣalaye ninu iwe atúmọ̀ èdè rẹ̀ Expository Dictionary of Old and New Testament Words.
Irin-Ajo Luku Lójú Òkun
Awọn ogbontagi ọmọ-ogun oju-omi ti ṣayẹwo awọn kulẹkulẹ rírì-ọkọ̀ ti a ṣapejuwe ninu Iṣe ori 27. Gẹgẹ bi Luku ti wi, ọkọ̀ oju-omi ńlá naa ti oun ati Paulu wọ̀ ni ìjì-líle apa-iha ariwa-ila-oorun kọlù nitosi erekuṣu kekere ti Cauda, ti awọn atukọ̀-òkun sì bẹru dídi ẹni ti ìgbì-omi tì lu etíkun oníyanrìn ti ó lewu kuro ni etíkun ariwa Africa. (Iṣe 27:14, 17, akiyesi ẹsẹ-iwe) Nipasẹ ìjáfáfá atukọ̀-òkun, wọn dọgbọn dari ọkọ̀ naa kuro ni Africa gba ipa-ọna ti iwọ-oorun lọ. Ìjì-líle naa ń baa lọ láìrọlẹ̀, ati ní asẹhinwa-asẹhinbọ ọkọ̀ oju-omi naa forílé erekuṣu Melita, bi o ti kari ọ̀nà ti ó jìn tó 870 kilomita. Awọn ogbontagi ọmọ-ogun oju-omi ṣírò rẹ̀ pe yoo gba ọkọ̀ oju-omi ńlá kan ti ń rìn lori omi oníjì líle ni ohun ti o ju ọjọ 13 lọ lati di eyi ti a tù dé iru iwọn jíjìnnà bẹẹ. Iṣiro wọn bá akọsilẹ-iṣẹlẹ Luku mu, eyi ti o sọ pe ọkọ̀-rírì naa wáyé ni ọjọ kẹrinla. (Iṣe 27:27, 33, 39, 41) Lẹhin wiwadii gbogbo kulẹkulẹ irin-ajo ojú-òkun Luku, ọlọ́kọ̀ oju-omi James Smith pari-ero pe: “Ìtàn awọn iṣẹlẹ gidi ni, tí ẹni kan ti ó lọwọ ninu wọn funraarẹ kọ . . . Kò si ọkunrin kan ti kìí ṣe atukọ̀ òkun ti ó lè ti kọ iru ìtàn irin-ajo òkun ti o ṣedeedee délẹ̀ ni gbogbo apa bẹẹ, ayafi nipasẹ akiyesi tààràtà.”
Nitori iru awọn awari bẹẹ, awọn ẹlẹkọọ-isin kan wà ni imuratan lati gbeja Iwe Mimọ Kristian Lede Griki gẹgẹ bi ìtàn pípéye. Ṣugbọn ki ni nipa ìtàn ijimiji ti a rí ninu Iwe Mimọ Lede Heberu? Ọpọ awọn alufaa-ṣọọṣi gbà pẹlu ọgbọn-imọ-ọran ode-oni wọn sì polongo pe ó ní awọn àlọ́ ninu. Bi o ti wu ki o ri, iye awọn kulẹkulẹ ìtàn Bibeli ijimiji kan ni a ti tun fẹ̀rí ijotitọ wọn hàn, si ìrúlójú awọn aṣelámèyítọ́. Fun apẹẹrẹ, gbé awari Ilẹ-ọba Assiria ti a ti figba kan rí gbagbe yẹwo.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tun wo Romu 9:1; 2 Korinti 11:31; Galatia 1:20.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 3]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
FRIGIA
LIKAONIA
Ikonioni
Listra
Derbe
ÒKUN MEDITERENIANI
KIPRU