ORÍ 16
Ẹgbẹ́ Ará Tó Wà Níṣọ̀kan
NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan ààbọ̀ (1,500) ni Jèhófà Ọlọ́run fi yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láàyò, tó sì fi orúkọ rẹ̀ pè wọ́n. Nígbà tó yá, Jèhófà “yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.” (Ìṣe 15:14) Àwọn èèyàn tí Jèhófà yàn fún orúkọ rẹ̀ máa jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀, èrò wọn àti ìṣe wọn sì máa ṣọ̀kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń gbé láyé. Iṣẹ́ tí Jésù ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe máa mú kí wọ́n lè kó àwọn èèyàn láti ibi gbogbo jọ fún orúkọ Jèhófà. Jésù ní: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́. Ẹ wò ó! Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 28:19, 20.
O di ara ẹgbẹ́ ará kárí ayé, tó wà níṣọ̀kan. Lóòótọ́ ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá, ẹ̀yà wa yàtọ̀ síra, a sì rí já jẹ jura wa lọ, síbẹ̀ a ò jẹ́ kí àwọn nǹkan yìí pín wa níyà
2 Nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, o di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. O di ara ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó wà níṣọ̀kan. Lóòótọ́ ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá, ẹ̀yà wa yàtọ̀ síra, a sì rí já jẹ jura wa lọ, síbẹ̀ a ò jẹ́ kí àwọn nǹkan yìí pín wa níyà. (Sm. 133:1) Èyí mú kó o nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ, kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Ìlú tẹ́ ẹ ti wá tàbí orílẹ̀-èdè yín lè yàtọ̀ síra, ó sì ṣeé ṣe kẹ́ ẹ kàwé ju ara yín lọ, ó tiẹ̀ lé jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí, o kì í bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ da nǹkan pọ̀. Àmọ́ ní báyìí, okùn ìfẹ́ tó so yín pọ̀ lágbára gan-an, kódà ó lágbára ju ohunkóhun tó lè so àwọn èèyàn pọ̀ láyé, ì báà jẹ́ ẹgbẹ́, ẹ̀sìn tàbí mọ̀lẹ́bí.—Máàkù 10:29, 30; Kól. 3:14; 1 Pét. 1:22.
Ó LÈ GBA PÉ KÉÈYÀN YÍ ÈRÒ RẸ̀ PA DÀ
3 Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún àwọn kan láti fi ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀tanú òṣèlú, kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tàbí àwọn ìwà ẹ̀tanú míì sílẹ̀. Á dáa kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ronú nípa ohun tí àwọn Júù tó di Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe kí wọ́n lè máa fi ojú tó tọ́ wo àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí Jèhófà ní kí Pétérù lọ sí ilé ọ̀gágun ará Róòmù kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù, Jèhófà fìfẹ́ múra ọkàn Pétérù sílẹ̀ kó lè ṣe iṣẹ́ náà.—Ìṣe, orí 10.
4 Nínú ìran, a sọ fún Pétérù pé kó pa àwọn ẹranko kan táwọn Júù kà sí aláìmọ́, kó sì jẹ wọ́n. Nígbà tí Pétérù kọ̀, ohùn kan sọ fún un látọ̀run pé: “Yéé pe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” (Ìṣe 10:15) Àfìgbà tí ohùn kan látọ̀run bá Pétérù sọ̀rọ̀ ni Pétérù tó pèrò dà tó sì gbà láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ rán an, pé kó lọ sílé ọkùnrin kan tí kì í ṣe Júù. Nígbà tí Pétérù ń jẹ́ iṣẹ́ tí Jèhófà ràn an yìí, ó sọ fún àwọn tó kóra jọ síbẹ̀ pé: “Ẹ̀yin náà mọ̀ dáadáa pé kò bófin mu rárá fún Júù láti dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ẹ̀yà míì tàbí kó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ Ọlọ́run fi hàn mí pé kí n má ṣe pe èèyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́. Nítorí náà, mo wá láìjanpata nígbà tí wọ́n ránṣẹ́ pè mí.” (Ìṣe 10:28, 29) Lẹ́yìn náà, Pétérù rí ẹ̀rí pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba Kọ̀nílíù àti agbo ilé rẹ̀.
5 Farisí tó ka ìwé gan-an ni Sọ́ọ̀lù ará Tásù, síbẹ̀ ó ní láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó lè máa bá àwọn tó kórìíra tẹ́lẹ̀ kẹ́gbẹ́. Kódà, ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n fún un. (Ìṣe 4:13; Gál. 1:13-20; Fílí. 3:4-11) Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ìyípadà kékeré làwọn èèyàn bíi Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, Díónísíù, Dámárì, Fílémónì, Ónísímù àtàwọn míì ṣe nínú ìrònú wọn, nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sí di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi.—Ìṣe 13:6-12; 17:22, 33, 34; Fílém. 8-20.
OHUN TÁ À Ń ṢE KÁ LÈ TÚBỌ̀ MÁA WÀ NÍṢỌ̀KAN
6 Ó dájú pé lára ohun tó mú kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kó o sì wá sínú ètò rẹ̀ ni bó o ṣe fojú ara rẹ rí i pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ ara wọn. O kíyè sí àmì ìfẹ́ tí Jésù Kristi sọ pé a máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ nígbà tó sọ pé: “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:34, 35) O túbọ̀ mọyì Jèhófà àti ètò rẹ̀ nígbà tó o wá mọ̀ pé kékeré ni ìfẹ́ tó wà nínú ìjọ jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìfẹ́ tó so ẹgbẹ́ ará kárí ayé pọ̀. Ìwọ náà ń fojú ara rẹ rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé àwọn èèyàn máa wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n á sì máa jọ́sìn Jèhófà ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan.—Míkà 4:1-5.
7 Pẹ̀lú bí oríṣiríṣi nǹkan ṣe ń fa ìpínyà lóde òní, a lè ronú pé bóyá ni ìṣọ̀kan lè wà láàárín àwọn èèyàn “látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n.” (Ìfi. 7:9) Ronú nípa ìyàtọ̀ tó wà lágbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ayé àtàwọn tó ṣì ń tẹ̀ lé àwọn àṣà àtijọ́. Wo bí àwọn èèyàn tó wá láti ìlú àti orílẹ̀-èdè kan náà ṣe ń bá ara wọn jà torí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń hùwà orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá, bẹ́ẹ̀ ni òṣèlú túbọ̀ ń kẹ̀yìn àwọn èèyàn síra. Tó o bá wo ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ tó wà láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tí kò rí já jẹ pẹ̀lú àìmọye nǹkan míì tó ń pín àwọn èèyàn níyà, wàá gbà pé iṣẹ́ ìyanu gbáà ni pé àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti àwùjọ tó yàtọ̀ síra lè wà níṣọ̀kan, tí àlàáfíà sì jọba láàárín wọn. Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ṣoṣo ló lè ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí.—Sek. 4:6.
8 Ìṣọ̀kan àárín wa kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu, àtìgbà tí ìwọ náà ti ya ara rẹ sí mímọ́, tó o ṣèrìbọmi, tó o sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ti wà nínú ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan yìí. Bí ìwọ náà ṣe ń jàǹfààní ìṣọ̀kan yìí, ó yẹ kó o jẹ́ kó máa gbèrú sí i. Wàá lè ṣe èyí tó o bá ń fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Gálátíà 6:10 sílò pé: “Nígbà tí a bá ti láǹfààní rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ṣe rere fún gbogbo èèyàn, àmọ́ ní pàtàkì fún àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” A tún ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbínú tàbí ìgbéraga mú yín ṣe ohunkóhun, àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ, bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.” (Fílí. 2:3, 4) Ẹni ọ̀wọ́n ni Jèhófà ka àwọn ará wa sí, táwa náà bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa kà wọ́n sẹ́ni ọ̀wọ́n, tá a sì ń gbójú fo àìpé wọn, àá túbọ̀ máa gbádùn àlàáfíà àti àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú wọn.—Éfé. 4:23, 24.
À Ń GBA TI ARA WA RÒ
9 Nínú àkàwé kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe, ó ṣe kedere pé kò sí ìpínyà nínú ìjọ, kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ àwọn ará wa máa ń jẹ wá lógún. (1 Kọ́r. 12:14-26) Lóòótọ́, ọ̀nà wa lè jìn sí àwọn kan nínú ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún. Tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sáwọn ará wa níbì kan, ó máa ń dun àwa tó kù gan-an. Tá a bá gbọ́ pé nǹkan dẹnu kọlẹ̀ fún àwọn ará wa tàbí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí ìjábá, ogun tàbí rògbòdìyàn ìlú ṣẹlẹ̀ sí wọn, kíá làwa yòókù máa ń dìde ìrànwọ́ tá a sì máa ń gbàdúrà tìtorí wọn.—2 Kọ́r. 1:8-11.
10 Ó yẹ kí gbogbo wa máa gbàdúrà fáwọn ará wa lójoojúmọ́. Àwọn ará wa kan wà tí wọ́n ń dójú kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́. Ó ṣeé ṣe ká gbọ́ pé ìyà ń jẹ àwọn ará wa kan. Síbẹ̀, àwọn míì ń dojú kọ àwọn ìṣòro tá ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ nípa wọn, irú bí àtakò látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ìdílé wọn tí kò sí nínú òtítọ́. (Mát. 10:35, 36; 1 Tẹs. 2:14) À ń ṣàníyàn nípa àwọn náà torí pé ẹgbẹ́ ará kárí ayé ni gbogbo wa. (1 Pét. 5:9) Àwọn kan wà lára wa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tí wọ́n ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù àti nínú ìjọ. Àwọn míì tún wà tó jẹ́ iṣẹ́ tiwọn ni láti máa bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe kárí ayé. Ká tiẹ̀ ní kò sí nǹkan míì tá a lè ṣe láti ṣètìlẹyìn, ẹ jẹ́ ká máa rántí gbogbo wọn nínú àdúrà wa, nípa bẹ́ẹ̀ à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ wá lógún lóòótọ́.—Éfé. 1:16; 1 Tẹs. 1:2, 3; 5:25.
11 Nítorí gbogbo rúkèrúdò tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwa èèyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ múra tán láti ran ara wa lọ́wọ́. Nígbà míì, àwọn àjálù bí ìmìtìtì ilẹ̀ àti omíyalé lè ṣẹlẹ̀, tó sì máa nílò pé ká pèsè ọ̀pọ̀ nǹkan tara fún àwọn tí àjálù dé bá, ká sì bá wọn tún àwọn ohun tó bà jẹ́ ṣe. Àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi àpẹẹrẹ irú ìwà rere bẹ́ẹ̀ lélẹ̀. Wọ́n rántí ìmọ̀ràn Jésù, ìdí nìyẹn táwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Áńtíókù ṣe fàwọn nǹkan tara ránṣẹ́ sáwọn ará ní Jùdíà. (Ìṣe 11:27-30; 20:35) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará ní Kọ́ríńtì pé kí wọ́n ṣe ipa tiwọn kí ètò ìrànwọ́ náà lè lọ létòlétò. (2 Kọ́r. 9:1-15) Lóde òní, nígbà tí nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará wa, tí wọ́n sì nílò àwọn nǹkan tara, ètò Ọlọ́run àtàwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kì í jáfara láti pèsè àwọn ohun tí wọ́n bá nílò fún wọn.
A YÀ WÁ SỌ́TỌ̀ LÁTI ṢE ÌFẸ́ JÈHÓFÀ
12 Torí ká lè máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà la ṣe ṣètò ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé yìí, tó sì wà níṣọ̀kan. Lákòókò yìí, ìfẹ́ Jèhófà ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní gbogbo ayé kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè. (Mát. 24:14) Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí, Jèhófà fẹ́ ká máa fi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ hùwà. (1 Pét. 1:14-16) Ó yẹ kí gbogbo wa máa bọ̀wọ̀ fún ara wa, ká sì máa ṣe ohun táá mú kí ìhìn rere yìí tẹ̀ síwájú. (Éfé. 5:21) Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní nígbèésí ayé wa dípò tí a ó fi máa lépa àwọn nǹkan ti ara wa. (Mát. 6:33) Tá a bá fi èyí sọ́kàn, tí gbogbo wa sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nítorí ìhìn rere, àá ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nísinsìnyí, ìbùkún ayérayé sì ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú.
13 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò láfiwé, a yàtọ̀ sáwọn èèyàn tó kù nítorí pé a wà ní mímọ́, a sì ń fi ìtara sin Ọlọ́run wa. (Títù 2:14) Ìjọsìn Jèhófà ló mú ká yàtọ̀. Yàtọ̀ sí pé à ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa kárí ayé, èdè òtítọ́ kan náà là ń sọ, ìwà wa sì bá òtítọ́ tá à ń wàásù rẹ̀ mu. Jèhófà ti sọ èyí tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Sefanáyà pé: “Màá yí èdè àwọn èèyàn pa dà sí èdè mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìṣọ̀kan.”—Sef. 3:9.
14 Lẹ́yìn náà, Jèhófà mí sí Sefanáyà láti ṣàpèjúwe ẹgbẹ́ ará kárí ayé tí à ń rí lóde òní, ó sọ pé: “Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì kò ní hùwà àìṣòdodo; wọn kò ní parọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní fi ahọ́n wọn tanni jẹ; wọ́n á jẹun, wọ́n á sì dùbúlẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.” (Sef. 3:13) Nítorí pé a lóye Ọ̀rọ̀ òtítọ́, tá a ti yí èrò inú wa pa dà, tá a sì ti mú ìgbésí ayé wa bá àwọn ìlànà òdodo Jèhófà mu, èyí mú ká lè máa ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan. Ohun tí ẹ̀dá èèyàn rò pé kò lè ṣeé ṣe ni àwa èèyàn Jèhófà ti ṣe láṣeyọrí. Ó dájú pé a yàtọ̀ lóòótọ́, èèyàn Ọlọ́run ni wá, a sì ń bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run wa níbi gbogbo láyé.—Míkà 2:12.