ORÍ 14
“A Ti Fìmọ̀ Ṣọ̀kan”
Ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe ìpinnu pàtàkì kan tó mú káwọn ìjọ wà níṣọ̀kan
Ó dá lórí Ìṣe 15:13-35
1, 2. (a) Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ kí ìgbìmọ̀ olùdarí ti ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dáhùn? (b) Kí ló ran àwọn arákùnrin náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣèpinnu tó tọ́?
GBOGBO wọn ń retí ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tí wọ́n pé jọ sínú yàrá ní Jerúsálẹ́mù ń wojú ara wọn, wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ ńlá tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu pàtàkì nípa ẹ̀ ló délẹ̀ yìí. Awuyewuye tó wáyé lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ ti mú káwọn ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ. Ṣé dandan ni káwọn Kristẹni máa pa Òfin Mósè mọ́? Ṣé ó yẹ kí ìyàtọ̀ wà láàárín àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù?
2 Àwọn ọkùnrin tó jẹ́ alábòójútó ti gbé ẹ̀rí tó pọ̀ yẹ̀ wò. Wọ́n ń ronú nípa Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀rí tó lágbára táwọn fúnra wọn rí nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bójú tó nǹkan àti bó ṣe ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti sọ tẹnu ẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló sì fi hàn gbangba pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí wọn. Àmọ́, ṣáwọn èèyàn yìí máa ṣe ohun tí ẹ̀mí mímọ́ bá darí wọn láti ṣe?
3. Àwọn nǹkan wo la máa kọ́ tá a bá ṣàyẹ̀wò ìwé Ìṣe orí 15?
3 Ó gba ìgbàgbọ́ àti ìgboyà gan-an kí wọ́n tó lè fara mọ́ ibi tí ẹ̀mí mímọ́ bá darí wọn sí lórí ọ̀rọ̀ náà. Ìpinnu tí wọ́n bá ṣe lè mú káwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù túbọ̀ kórìíra wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn tó ti pinnu pé àwọn á mú káwọn èèyàn Ọlọ́run pa dà máa pa Òfin Móse mọ́ lè kẹ̀yìn sí wọn nínú ìjọ. Kí ni ìgbìmọ̀ olùdarí máa wá ṣe báyìí? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ náà. Bá a sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa rí báwọn ọkùnrin yẹn ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí. Àpẹẹrẹ wọn tún máa ran àwa náà lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tàbí tá a bá ń kojú ìṣòro nígbèésí ayé wa.
“Ọ̀rọ̀ Àwọn Wòlíì . . . Bá Èyí Mu” (Ìṣe 15:13-21)
4, 5. Ibo ni Jémíìsì ti fa ọ̀rọ̀ yọ láti fi tànmọ́lẹ̀ sórí ohun tí wọ́n ń jíròrò?
4 Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ìyá Jésù ló bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn.a Ó dà bíi pé òun ni alága ìpàdé náà. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣàlàyé ibi tó ṣeé ṣe kí ìgbìmọ̀ náà fẹnu ọ̀rọ̀ yẹn kò sí. Ó sọ fáwọn ọkùnrin tó pé jọ náà pé: “Símíónì ti ròyìn ní kíkún bí Ọlọ́run ṣe yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn. Ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì sì bá èyí mu.”—Ìṣe 15:14, 15.
5 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí Símíónì, tàbí Símónì Pétérù sọ àti ẹ̀rí tí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn, ló mú kí Jémíìsì rántí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ohun tí wọ́n ń jíròrò náà mu. (Jòhánù 14:26) Lẹ́yìn tí Jémíìsì ti sọ pé “ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì . . . bá èyí mu,” ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Émọ́sì 9:11, 12. Apá ibi tí wọ́n to orúkọ àwọn ìwé tí wọ́n sábà máa ń pè ní “àwọn Wòlíì” sí nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ni ìwé Émọ́sì wà. (Mát. 22:40; Ìṣe 15:16-18) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jémíìsì fà yọ yàtọ̀ díẹ̀ sí àwọn tá à ń kà nínú ìwé Émọ́sì báyìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì, ló ti fa ọ̀rọ̀ náà yọ.
6. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe tànmọ́lẹ̀ sórí kókó tí wọ́n ń jíròrò?
6 Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Émọ́sì pé àkókò kan ń bọ̀ tí Òun máa gbé “àtíbàbà Dáfídì” dìde, ìyẹn ìdílé tí Ọba Ìjọba Mèsáyà ti máa wá. (Ìsík. 21:26, 27) Ṣéyẹn wá fi hàn pé Jèhófà máa pa dà bá àwọn Júù nípa tara lò gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè, táá sì jẹ́ pé àwọn nìkan láá máa ṣojúure sí? Rárá o. Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi kún un pé, a óò kó “àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè” jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “àwọn tí à ń fi orúkọ [Ọlọ́run] pè.” Ẹ rántí pé kò tíì pẹ́ tí Pétérù jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run ò “fi ìyàtọ̀ kankan sáàárín àwa [àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni] àti àwọn [àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù], àmọ́ ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.” (Ìṣe 15:9) Lédè míì, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé káwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù láǹfààní láti di ajogún Ìjọba náà. (Róòmù 8:17; Éfé. 2:17-19) Kò síbì kankan tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti sọ pé àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dádọ̀dọ́ tàbí kí wọ́n di aláwọ̀ṣe.
7, 8. (a) Kí ni Jémíìsì dábàá pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò? (b) Kí lọ̀rọ̀ tí Jémíìsì sọ túmọ̀ sí?
7 Lẹ́yìn tí Jémíìsì ronú lórí àwọn ẹ̀rí tó wá látinú Ìwé Mímọ́ àtohun tó gbọ́ látẹnu àwọn èèyàn, ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ó wá sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Torí náà, ìpinnu mi ni pé kí a má dààmú àwọn tó ń yíjú sí Ọlọ́run látinú àwọn orílẹ̀-èdè, àmọ́ kí a kọ̀wé sí wọn láti ta kété sí àwọn ohun tí àwọn òrìṣà ti sọ di ẹlẹ́gbin, sí ìṣekúṣe, sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa àti sí ẹ̀jẹ̀. Torí pé láti ìgbà láéláé ni Mósè ti ní àwọn tó ń wàásù nípa rẹ̀ láti ìlú dé ìlú, torí wọ́n ń ka ìwé rẹ̀ sókè nínú àwọn sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì.”—Ìṣe 15:19-21.
8 Nígbà tí Jémíìsì sọ pé “torí náà, ìpinnu mi ni pé,” ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé ó fẹ́ lo àṣẹ lórí ìgbìmọ̀ yẹn, kó sì pinnu ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe torí pé òun ni alága ìpàdé náà? Rárá o! Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìpinnu mi ni” tún lè túmọ̀ sí “mo lérò pé” tàbí “mò dábàá pé.” Torí náà, kì í ṣe pé Jémíìsì ń jẹ gàba lórí àwọn tó kù nínú ìgbìmọ̀ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń dábàá pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí táwọn míì fi ti ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ lẹ́yìn àti ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.
9. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú àbá tí Jémíìsì mú wá?
9 Ṣé àbá tí Jémíìsì mú wá yìí dáa? Bẹ́ẹ̀ ni, torí ohun tó sọ yẹn làwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó kù wá ṣe. Àǹfààní wo nìyẹn mú wá? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àbá tí Jémíìsì mú wá yìí ò ní jẹ́ kí wọ́n “dààmú” àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni tàbí ‘yọ wọ́n lẹ́nu’ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa pa Òfin Mósè mọ́. (Ìṣe 15:19; Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Àǹfààní míì ni pé ìpinnu yìí ò ní jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó máa kó bá ẹ̀rí ọkàn àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni. Ó ṣe tán, ọjọ́ pẹ́ táwọn Júù yẹn ti ń gbọ́ nípa “Mósè . . . torí wọ́n ń ka ìwé rẹ̀ sókè nínú àwọn sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì.”b (Ìṣe 15:21) Ohun tí Jémíìsì sọ yìí á tún jẹ́ káwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni túbọ̀ sún mọ́ra wọn dáadáa. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ó máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn, torí ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn máa bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Ẹ ò rí i pé ìpinnu yìí máa wúlò gan-an láti yanjú ìṣòro tó fẹ́ ba àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ Ọlọ́run jẹ́! Àpẹẹrẹ tó dáa lèyí sì jẹ́ fáwa Kristẹni lónìí!
10. Lóde òní, báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
10 Bá a ṣe sọ nínú orí tó ṣáájú, ohun tí ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń ṣe náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lóde òní. Wọ́n máa ń jẹ́ kí Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti Jésù Kristi, tó jẹ́ Orí ìjọ darí wọn nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe.c (1 Kọ́r. 11:3) Lọ́nà wo? Arákùnrin Albert D. Schroeder, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí látọdún 1974 títí dìgbà tó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé ní March 2006, ṣàlàyé pé: “Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń pàdé pọ̀ lọ́jọ́ Wednesday, wọ́n máa ń fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìpàdé wọn, wọ́n sì máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ máa tọ́ àwọn sọ́nà. Wọ́n máa ń rí i dájú pé gbogbo ọ̀rọ̀ táwọn bójú tó àti gbogbo ìpinnu táwọn ṣe bá ohun tí Bíbélì sọ mu.” Bákan náà, Arákùnrin Milton G. Henschel, tóun náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún ọ̀pọ̀ ọdún, tó sì parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé ní March 2003, bi àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Kíláàsì Kọkànlélọ́gọ́rùn-ún (101) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ìbéèrè pàtàkì kan. Ó bi wọ́n pé: “Ṣé ètò míì tún wà láyé yìí táwọn tó ń múpò iwájú láàárín wọn máa ń wo inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì?” Ó dájú pé kò sí.
Wọ́n “Rán Àwọn Ọkùnrin Tí Wọ́n Yàn” (Ìṣe 15:22-29)
11. Báwo ni àwọn ará tó wà nínú ìjọ ṣe gbọ́ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe?
11 Ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù ti fìmọ̀ ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́. Àmọ́, káwọn ará tó wà nínú ìjọ lè máa wà nísọ̀kan, wọ́n ní láti fi ìpinnu tí wọ́n ṣe tó wọn létí, kí wọ́n sọ ọ́ lọ́nà tó máa yé wọn, táá sì gbé wọn ró. Báwo ni wọ́n ṣe máa wá ṣe é? Bíbélì sọ pé: “Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ pinnu láti rán àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn láàárín wọn lọ sí Áńtíókù, pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà; wọ́n rán Júdásì tí wọ́n ń pè ní Básábà àti Sílà, àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn ará.” Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kọ lẹ́tà kan, wọ́n sì fi rán àwọn ọkùnrin yìí kí wọ́n lè kà á ní gbogbo ìjọ tó wà ní Áńtíókù, Síríà àti Sìlíṣíà.—Ìṣe 15:22-26.
12, 13. Àwọn àṣeyọrí wo ló wáyé bí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe (a) rán Júdásì àti Sílà sáwọn ìjọ? (b) kọ lẹ́tà?
12 Bíi ti “àwọn [ọkùnrin] tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn ará,” Júdásì àti Sílà náà kúnjú ìwọ̀n láti ṣojú fún ìgbìmọ̀ olùdarí. Àwọn ọkùnrin mẹ́rin yìí máa jẹ́ káwọn ará rí i pé kì í ṣe torí kí wọ́n lè dáhùn ìbéèrè wọn ni ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe rán wọn wá, àmọ́ kí wọ́n lè mọ ìlànà tuntun tó wá látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí. Bí àwọn “ọkùnrin tí wọ́n yàn” yìí ṣe máa wà láàárín àwọn ará máa mú kí àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí mọ́gbọ́n dání gan-an, ó sì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará! Ó dájú pé èyí á jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan jọba láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.
13 Lẹ́tà náà sọ ìlànà tó ṣe kedere fáwọn Kèfèrí tó di Kristẹni, kì í ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ nìkan, àmọ́ ó tún kan ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ojú rere Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀. Apá tó ṣe pàtàkì nínú lẹ́tà náà kà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ọn pé ká má ṣe dì kún ẹrù yín, àyàfi àwọn ohun tó pọn dandan yìí: láti máa ta kété sí àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà, láti máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀, sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa àti sí ìṣekúṣe. Tí ẹ bá ń yẹra fún àwọn nǹkan yìí délẹ̀délẹ̀, ẹ ó láásìkí. Kí ara yín ó le o!”—Ìṣe 15:28, 29.
14. Kí ló mú kí àwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé ti dojú rú tí ìyapa sì ń pọ̀ sí i?
14 Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ (8,000,000), a sì wà láwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000). Ohun kan náà ni gbogbo wa gbà gbọ́, ìṣọ̀kan sì wà láàárín wa. Kí ló mú ká wà níṣọ̀kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé ti dojú rú tí ìyapa sì ń pọ̀ sí i? Ohun pàtàkì tó mú ká wà níṣọ̀kan ni ọ̀nà tí Jésù Kristi, tó jẹ́ Orí ìjọ ń gbà darí wa nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ìyẹn Ìgbìmọ̀ Olùdarí. (Mát. 24:45-47) Ohun míì tó jẹ́ ká wà níṣọ̀kan ni báwọn ará wa kárí ayé ṣe máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ń wá látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí, tí wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ tinútinú.
“Ìṣírí Tí Wọ́n Rí Gbà Mú Inú Wọn Dùn” (Ìṣe 15:30-35)
15, 16. Ibo ni awuyewuye tó wáyé lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ já sí, kí ló sì mú kọ́rọ̀ náà yanjú?
15 Ohun tó wà nínú ìwé Ìṣe jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà táwọn arákùnrin tí wọ́n rán láti Jerúsálẹ́mù dé Áńtíókù, “wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, wọ́n sì fi lẹ́tà náà lé wọn lọ́wọ́.” Báwo ni ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe rí lára àwọn ará náà? “Lẹ́yìn tí wọ́n ka [lẹ́tà náà], ìṣírí tí wọ́n rí gbà mú inú wọn dùn.” (Ìṣe 15:30, 31) Yàtọ̀ síyẹn, Júdásì àti Sílà “fi ọ̀pọ̀ àsọyé gba àwọn ará níyànjú, wọ́n sì fún wọn lókun.” Torí pé àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí ń sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fáwọn èèyàn, wọ́n jẹ́ “wòlíì,” bíi ti Bánábà, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì.—Ìṣe 13:1; 15:32; Ẹ́kís. 7:1, 2.
16 Ó dájú pé Jèhófà bù kún gbogbo ètò tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe, torí pé awuyewuye náà yanjú, inú gbogbo ìjọ sì dùn. Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ náà yanjú? Ó dájú pé ìtọ́ni tó ṣe kedere tó sì bọ́ sákòókò tó wá látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí ni, torí wọ́n jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ darí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tí wọ́n rán pé kí wọ́n jábọ̀ ìpinnu yẹn fáwọn ìjọ fìfẹ́ ṣe é.
17. Báwo ni iṣẹ́ táwọn alábòójútó àyíká ń ṣe lónìí ṣe jọ táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
17 Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti òde òní náà ń fún àwa ará kárí ayé ní ìtọ́ni tó bọ́ sákòókò. Tí wọ́n bá ti ṣe ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ kan, wọ́n á fi tó àwọn ìjọ létí ní tààràtà, wọ́n á sì sọ ọ́ lọ́nà tó máa yé wọn. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìgbà táwọn alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ wò. Àwọn arákùnrin yìí máa ń ṣiṣẹ́ wọn tinútinú. Bí wọ́n ṣe ń lọ láti ìjọ kan sí òmíì, wọ́n máa ń fún àwọn ará ní ìtọ́ni tó ṣe kedere, wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí. Bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n máa ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, “wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ Jèhófà, àwọn àti ọ̀pọ̀ àwọn míì.” (Ìṣe 15:35) Bíi ti Júdásì àti Sílà, wọ́n máa ń “fi ọ̀pọ̀ àsọyé gba àwọn ará níyànjú,” wọ́n sì máa ń fún wọn lókun.
18. Kí ló máa jẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa rí ìbùkún Jèhófà?
18 Kí ló máa mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ìjọ kárí ayé láti wà lálàáfíà, kí wọ́n sì ṣera wọn lọ́kan nínú ayé tí ò sí ìṣọ̀kan yìí? Ẹ má gbàgbé pé ọmọ ẹ̀yìn náà, Jémíìsì, sọ nígbà tó yá pé: “Ọgbọ́n tó wá láti òkè á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó ṣe tán láti ṣègbọràn . . . Bákan náà, ibi tí àlàáfíà bá wà la máa ń gbin èso òdodo sí fún àwọn tó ń wá àlàáfíà.” (Jém. 3:17, 18) A ò lè sọ bóyá ìpàdé tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù ni Jémíìsì ní lọ́kàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́, lẹ́yìn tá a ti gbé ohun tó wà nínú Ìṣe orí 15 yẹ̀ wò, a ti rí i pé ìgbà tá a bá wà níṣọ̀kan tá a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nìkan la lè rí ìbùkún Jèhófà.
19, 20. (a) Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ Áńtíókù? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wá láǹfààní láti ṣe?
19 Ó ti wá hàn báyìí pé àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ tó wà ní Áńtíókù. Dípò káwọn ará tó wà ní Áńtíókù máa bá àwọn ará tó wá láti Jerúsálẹ́mù fa ọ̀rọ̀, wọ́n mọyì bí Júdásì àti Sílà ṣe bẹ̀ wọ́n wò. Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀, àwọn ará yọ̀ǹda wọn kí wọ́n máa lọ, wọ́n ní kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn tó rán wọn wá láyọ̀,” ìyẹn ni pé kí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù.d (Ìṣe 15:33) Ó dájú pé inú àwọn ará tó wà ní Jerúsálẹ́mù náà máa dùn nígbà táwọn ọkùnrin méjì yẹn ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi tí wọ́n rán wọn lọ. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ló jẹ́ kí ohun tí wọ́n lọ ṣe yọrí sí rere!
20 Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ò tíì kúrò ní Áńtíókù, torí náà wọn á lè máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ bí wọ́n ṣe ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àwọn alábòójútó àyíká ṣe ń ṣe lónìí náà nìyẹn tí wọ́n bá ń bẹ ìjọ wò. (Ìṣe 13:2, 3) Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá nìyẹn jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà! Báwo wá ni Jèhófà ṣe túbọ̀ lo àwọn òjíṣẹ́ méjèèjì tó nítara yìí, tó sì bù kún wọn? Ìyẹn la máa jíròrò nínú orí tó kàn.
a Wo àpótí náà, “Jémíìsì—‘Àbúrò Olúwa.’”
b Ó bọ́gbọ́n mu bí Jémíìsì ṣe fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ìwé tí Mósè kọ. Ara àwọn ìwé náà ni Òfin Mósè àtàwọn àkọsílẹ̀ tó jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fáwa èèyàn kí Òfin Mósè tó dé. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí àlàyé tó ṣe kedere nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀jẹ̀, àgbèrè àti panṣágà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì. (Jẹ́n. 9:3, 4; 20:2-9; 35:2, 4) Lọ́nà yìí, Jèhófà jẹ́ ká mọ àwọn ìlànà tó yẹ kí gbogbo èèyàn máa tẹ̀ lé, bóyá wọ́n jẹ́ Júù tàbí Kèfèrí.
c Wo àpótí náà, “Bá A Ṣe Ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí Lóde Òní.”
d Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan fi kún un ní ẹsẹ 34 pé Sílà pinnu pé òun á máa gbé ní Áńtíókù. (Bibeli Mimọ) Àmọ́, ó dà bíi pé ṣe ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí kún un nígbà tó yá.