“Kọ̀ Láti Gba Àwọn Ìtàn Èké”
BIBELI kún fún àwọn ìrírí àti ìtàn nípa àwọn ènìyàn. Kìí ṣe kìkì pé a ń gbádùn kíkà wọ́n nìkan ni ṣùgbọ́n a ń jàǹfààní láti inú wọn. Aposteli Paulu kọ̀wé sí ìjọ Kristian ní Romu: “Ohunkóhun tí a ti kọ tẹ́lẹ̀, a ti kọ ọ́ fún kíkọ́ wa, pé nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́ kí a lè ní ìrètí.”—Romu 15:4.
Paulu fúnraarẹ̀ kópa nínú sísọ àwọn ìrírí. Bibeli sọ nípa Paulu àti Barnaba lẹ́yìn òpin ìrìn-àjò iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn àkọ́kọ́ pé: “Nígbà tí wọ́n sì dé [sí Antioku ti Siria], tí wọ́n sì pe ìjọ jọ, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí Ọlọrun fi wọ́n ṣe.” (Iṣe 14:27) Kò sí iyèméjì pé àwọn ará ni a fún níṣìírí lọ́nà gíga nípasẹ̀ àwọn ìrírí wọ̀nyí.
Bí ó ti wù kí ó rí, kìí ṣe gbogbo ìrírí ní ń gbéniró. Lábẹ́ ìmísí, Paulu kìlọ̀ fún Timoteu pé: “Kọ̀ láti gba àwọn ìtàn èké èyí tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ èyí tí àwọn arúgbó obìnrin sì máa ń sọ.” (1 Timoteu 4:7, NW) Òun sì kọ̀wé sí Titu pé àwọn Kristian adúróṣinṣin kò níláti “fiyèsí ìtàn lásán ti àwọn Ju, àti òfin àwọn ènìyàn tí wọ́n yípadà kúrò nínú òtítọ́.”—Titu 1:14.
Kí ni àwọn ìtàn èké, tàbí ìtàn àlọ́ wọ̀nyí jẹ́? Gbólóhùn ọ̀rọ̀ méjèèjì wá láti inú Griki náà myʹthos (“àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́”). Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The International Standard Bible Encyclopaedia sọ pé ọ̀rọ̀ yìí ṣàpèjúwe “ìtàn (ìsìn) tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú òtítọ́.”
Ayé ìgbà Paulu kún fún irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìwé àpókírífà ti Tobit, tí ó ṣeéṣe kí a kọ ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú àkókò Paulu. Ìtàn yìí sọ nípa Tobit, Ju ẹlẹ́mìí-ìsìn kan, tí ó fọ́jú nígbà tí ìgbẹ́ ẹyẹ bọ sí i lójú. Lẹ́yìn náà ó rán ọmọ rẹ̀, Tobias, láti lọ gba owó tí wọ́n jẹ ẹ́ wá. Lójú ọ̀nà, lábẹ́ ìdarí angẹli kan, Tobias gba ọkàn, àti ẹ̀dọ̀, àti òróòro ẹja kan. Tẹ̀lé èyí ni ó ṣalábàápàdé opó kan ẹni ti ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ tí lọ́kọ fún ìgbà méje, ó ṣì jẹ́ wúndíá nítorí ọkọ kọ̀ọ̀kan ni àwọn ẹ̀mí búburú lùpa ní òru ọjọ́ ìgbéyàwó. Lábẹ́ ìsúnniṣe angẹli náà, Tobias fẹ́ ẹ ó sì lé àwọn ẹ̀mí-èṣù náà lọ nípa jíjó ọkàn àti ẹ̀dọ̀ ẹja náà. Pẹ̀lú òróòro ẹja náà, Tobias dá agbára ìríran baba rẹ̀ padà.
Ní kedere, ìtàn-àronúsọ yìí kìí ṣe tòótọ́. Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ ìhùmọ̀ lásán tí ó sì ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán nínú, àṣìṣe wà nínú rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ náà sọ pé Tobit fojúrí ìdìtẹ̀ ẹ̀yà ìhà àríwá àti lílé tí a lé àwọn ọmọ Israeli lọ sí Ninefe, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí 257 ọdún là láàárín nínú ọ̀rọ̀-ìtàn Israeli. Síbẹ̀ ìtàn náà sọ pé Tobit jẹ́ ẹni 112 ọdún nígbà tí ó kú.—Tobit 1:4, 11; 14:1, The Jerusalem Bible.
Irú àwọn ìtàn àlọ́ bẹ́ẹ̀ ṣàjèjì sí òtítọ́ “àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro” tí àwọn ènìyàn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun polongo. (2 Timoteu 1:13) Wọ́n jẹ́ àmújáde àwọn ìrònúwòye, tí ó lòdì sí àwọn ìtàn òtítọ́, irú èyí tí àwọn àgbà obìnrin aláìwà-bí-Ọlọ́run máa ń sọ. Irú àwọn ìtàn tí àwọn Kristian níláti kọ̀ láti gbà nìwọ̀nyí.
Dídán Àwọn Ọ̀rọ̀ Òtítọ́ Wò
Irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ pọ̀ jaburata lónìí. Paulu kọ̀wé pé: “Ìgbà yóò dé, tí [àwọn ènìyàn] kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro; ṣùgbọ́n . . . wọn ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.” (2 Timoteu 4:3, 4) Ní àwọn apá ibìkan ní ilẹ̀-ayé, àwọn ìtàn àròsọ nípa agbára tí ó ju ti ènìyàn lọ tàn kálẹ̀, ó sì gbajúmọ̀. Nítorí náà, àwọn Kristian ń fi pẹ̀lú ọgbọ́n “dán ọ̀rọ̀” ìtàn ìsìn “wò” láti rí bóyá wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli.—Jobu 12:11.
Ní kedere, ọ̀pọ̀ ni kò sí ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli. Fún àpẹẹrẹ ní àwọn apá ibi púpọ̀ nínú ayé, ó wọ́pọ̀ láti gbọ́ àwọn ìtàn tí ó ti èròngbà náà pé ọkàn ènìyàn jẹ àìlèkú lẹ́yìn. Àwọn ìtàn wọ̀nyí ń ṣàpèjúwe bí ènìyàn ṣe ń kú, kìkì láti tún padà wá bóyá bí ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí kan, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí kan, gẹ́gẹ́ bí ẹranko kan, tàbí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan ní ibòmíràn.
Bí ó ti wù kí ó rí, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fihàn pé ọkàn ènìyàn kìí ṣe aláìlèkú; ọkàn ń kú. (Esekieli 18:4) Síwájú síi, Bibeli sọ pé àwọn òkú jẹ́ aláìlẹ́mìí nínú sàárè, wọn kò lè ronú, sọ̀rọ̀, tabi ṣe ohunkohun. (Oniwasu 9:5, 10; Romu 6:23) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn wọnnì tí a ti tànjẹ nípasẹ̀ àwọn ìtàn èké tí ń gbé èròngbà náà pé ọkàn jẹ́ aláìlèkú lárugẹ ti “yípadà” kúrò nínú “ẹ̀kọ́” Bibeli “tí ó yè kooro” gẹ́gẹ́ bí Paulu ti sọ.
Àwọn Ìtàn Àròsọ Nípa Agbára Tí Ó Ju ti Ènìyàn Lọ
Àwọn ìtàn mìíràn dá lórí ìṣe àwọn àjẹ́ àti oṣó. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn apá ibìkan ní Africa, àwọn aṣebi wọ̀nyí ni a sọ pé wọ́n ní agbára bíbanilẹ́rù, tí wọ́n ní agbára láti yí araawọn tàbí àwọn ẹlòmíràn padà di ẹranko afàyàfà, ọ̀bọ, àti ẹyẹ; wọ́n lè gba inú afẹ́fẹ́ fò lọ láti ṣe iṣẹ́ wọn; wọ́n ní agbára láti farahàn kí wọ́n sì tún pòórá; wọ́n lè gba inú ògiri kọjá; wọ́n sì lè rí àwọn ohun tí a bò mọ́lẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.
Ọ̀pọ̀ jaburata irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀, àti ìtànkálẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú wọn, lè nítẹ̀sí láti nípalórí àwọn kan nínú ìjọ Kristian láti gbàgbọ́ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́. Wọ́n lè ronú pé nìgbà tí ó jẹ́ pé ènìyàn lásán kò lè ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, àwọn wọnnì tí wọ́n gba agbára tí ó ju ti ènìyàn lọ láti ọwọ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, àwọn ẹ̀mí-èṣù, lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí ó jọ bí ìpìlẹ̀ fún ìparí èrò yìí ní 2 Tessalonika 2:9, 10, tí ó sọ pé: “Wíwà [ọkùnrin ìwà-àìlófin] yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ Satani pẹ̀lú agbára gbogbo, àti àmì àti iṣẹ́ ìyanu èké, àti pẹ̀lú ìtànjẹ àìṣòdodo gbogbo fún àwọn tí ń ṣègbé; nítorí tí wọn kò gba ìfẹ́ òtítọ́ tí à bá fi gbà wọ́n là.”
Nígbà tí ó jẹ́ òtítọ́ pè ìwé mímọ́ yìí fihàn pé Satani lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ agbara, ó mẹ́nubà á pe Satani tún jẹ́ orísun “àmì àti iṣẹ́ ìyanu èké,” àti “ìtànjẹ àìṣòdodo” pẹ̀lú. Pẹ̀lú ìṣedéédéé, Bibeli fi Satani hàn pé ó jẹ́ olórí ẹlẹ̀tàn tí “ń tan gbogbo ayé jẹ́.” (Ìfihàn 12:9) Òun jẹ́ ọ̀gá ní mímú kí àwọn ènìyàn gba àwọn ohun tí kò jẹ́ òtítọ́ gbọ́.
Nítorí èyí, kódà àwọn ẹ̀rí àti ìjẹ́wọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n ti lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò àti iṣẹ́ àjẹ́ sábà máa ń jẹ́ èyí tí kò ṣeégbékẹ̀lé. Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ lè fi tọkàntọkàn gbàgbọ́ pé wọn ti rí, gbọ́, tàbí ní ìrírí àwọn ohun kan; síbẹ̀, níti gidi, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan wà tí wọ́n rò pé àwọn ti bá ẹ̀mí àwọn ẹni tí ó ti kú sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣe àṣìṣe, a sì ti tàn wọ́n jẹ, wọ́n jẹ́ òjìyà àdàkàdekè Satani. Bibeli sọ pè àwọn òkú “sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ìdákẹ́.”—Orin Dafidi 115:17.
Ní ríronú lórí àkọsílẹ̀ ẹ̀tàn Eṣu, ìjótìítọ́ àwọn ìtàn àròsọ nípa agbára tí ó ju ti ènìyàn lọ ṣeé ṣiyèméjì sí. Ọ̀pọ̀ jùlọ jẹ́ ìhùmọ̀ ìrònúwòye ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, tí a ṣàbùmọ́ nípa títún wọn sọ léraléra.
Títan irú àwọn ìtàn àlọ́ bẹ́ẹ̀ kálẹ̀ ń gbé ìfẹ́-ọkàn baba èké, Satani Eṣu lárugẹ. (Johannu 8:44) Wọ́n ń ru ìfẹ́-ọkàn sókè nínú àwọn iṣẹ́ awo tí wọ́n jẹ́ ìríra sí Jehofa. (Deuteronomi 18:10-12) Wọ́n ń dẹkùn mú àwọn ènìyàn nínú páńpẹ́ ìbẹ̀rù àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Abájọ tí Paulu fi gba àwọn Kristian nímọ̀ràn láti “má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn lásán.”—1 Timoteu 1:3, 4.
Kíkọ Àwọn Ìkéde Ẹ̀rí Ẹ̀mí-Èṣù Sílẹ̀
Bí ó ti wù kí ó rí, kí ni bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìtàn náà farahàn bí òtítọ́? Nígbà mìíràn àwọn ìrírí ní a sọ nípa àwọn ẹ̀mí tàbí àwọn abẹ́mìílò ti wọ́n ń jẹ́wọ́ àjùlọ Jehofa àti ìjótìítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Àwọn Kristian ha níláti máa tún irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ sọ bí?
Bẹ́ẹ̀kọ́, wọ́n kò níláti ṣe bẹ́ẹ̀. Bibeli sọ pé nígbà tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kígbe jáde pé Jesu jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọrun, ó “kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé, kí wọn kí ó máṣe fi òun hàn.” (Marku 3:12) Bákan náà, nígbà tí ẹ̀mí-èṣù àfọ̀ṣẹ fi agbára mú ọmọbìnrin kan láti fi Paulu àti Barnaba hàn gẹ́gẹ́ bí “ìránṣẹ́ Ọlọrun Ọ̀gá-ògo,” àti olùkéde “ọ̀nà ìgbàlà,” Paulu lé ẹ̀mí náà jáde kúrò nínú rẹ̀. (Iṣe 16:16-18) Kìí ṣe Jesu, Paulu, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe èyíkéyìí lára àwọn òǹkọ̀wé Bibeli ni ó yọ̀ǹda fún àwọn ẹ̀mí-èṣù láti jẹ́rìí nípa ète Ọlọrun tàbí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí òun yàn.
Ó tún yẹ fún àfiyèsí pẹ̀lú, pé, Jesu Kristi ti gbé ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí ṣáájú kí ó tó wá sórí ilẹ̀-ayé. Ó ti mọ Satani fúnraarẹ̀. Síbẹ̀ Jesu kò pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́rìn-ín pẹ̀lú ìtàn nípa ìgbòkègbodò Satani, bẹ́ẹ̀ ni òun kò pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí Eṣu lè ṣe àti ohun ti kò lè ṣe. Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ kìí ṣe ọ̀rẹ́ Jesu. Wọ́n jẹ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀, tí a ti lé jáde, akórìíra àwọn ohun mímọ́, àti ọ̀tá Ọlọrun.
Bibeli sọ ohun tí a níláti mọ̀ fún wa. Ó sọ àwọn ẹni tí ẹ̀mí-èṣù jẹ́, bí wọ́n ṣe ń ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà àti bí a ṣe lè yẹra fún wọn. Ó fihàn pé Jehofa àti Jesu lágbára ju àwọn ẹ̀mí-èṣù lọ. Ó sì fún wa ní ìtọ́ni pé bí a bá fi pẹ̀lú ìdúróṣinṣin ṣiṣẹ́sin Jehofa, àwọn ẹ̀mí búburú kò lè ṣe wá ni ìpalára tí ó wà títí lọ gbére.—Jakọbu 4:7.
Pẹ̀lú ìdí rere, nígbà náà, àwọn Kristian ń kọ̀ láti gba àwọn ìtàn èké, àwọn ìtàn ti kò ṣe ju gbígbé ire àwọn tí wọ́n tako Ọlọrun lárugẹ. Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti “jẹ́rìí sí òtítọ́,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí. (Johannu 18:37) Wọ́n fi pẹ̀lú ọgbọ́n tẹ̀lé ìṣílétí Bibeli pé: “Ohunkohun tíí ṣe òótọ́ . . . ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Filippi 4:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Gbogbo ìfihàn iṣẹ́ awo ni àwọn Kristian gbọ́dọ̀ yẹra fún pátápátá