Òtítọ́ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
Dídi ojúlùmọ̀ ẹnì kan sábà máa ń wé mọ́ kíkọ́ nípa ìdílé ẹni náà. Bẹ́ẹ̀ náà ni mímọ Jehofa Ọlọrun rí. Ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ju wíwulẹ̀ kọ́ orúkọ rẹ̀ lọ. A tún gbọ́dọ̀ mọ ohun kan nípa “ìdílé” rẹ̀ ní òkè ọ̀run. (Fi wé Efesu 3:14, 15.) Bibeli pe àwọn áńgẹ́lì ní “àwọn ọmọ” Ọlọrun. (Jobu 1:6) Bí a bá ronú nípa bí ipa iṣẹ́ wọn ti ṣe pàtàkì tó nínú Bibeli, ó yẹ kí a fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa wọn, láti lóye àyè wọn nínú ète Ọlọrun.
ÀṢÀ kan tí ó tinú àṣà wá ń jẹyọ. Kì í wulẹ̀ ṣe pé àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ń sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú áńgẹ́lì; iye tí ń pọ̀ sí i ń jẹ́wọ́ pé, wọ́n ti nípa lórí àwọn ní àwọn ọ̀nà kan. Nígbà tí a béèrè lọ́wọ́ 500 ará America pé, “O ha ti fìgbà kan rí nímọ̀lára ipá áńgẹ́lì kan nínú ìgbésí ayé rẹ bí?” ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdá kan nínú mẹ́ta ni ó sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Ohun tí ó tún yani lẹ́nu ni iye àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú áńgẹ́lì—gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ní United States ti sọ, odindi ìpín 76 nínú ọgọ́rùn-ún! Ó hàn gbangba pé, àwọn ènìyàn lọ́kàn ìfẹ́ nínú àwọn áńgẹ́lì. Ṣùgbọ́n báwo ni ìrònú lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa áńgẹ́lì ṣe bá òtítọ́ Bibeli mu tó?
Títẹ́ḿbẹ́lú Ipa Tí Satani Ń Kó
Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì, a kò ní láti gbàgbé àwọn áńgẹ́lì burúkú, àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí Bibeli sọ pé, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun. Satani ni ó mú ipò iwájú lára wọn. Ìwé lílókìkí kan tí a pè ní Ask Your Angels dámọ̀ràn pé Satani wulẹ̀ jẹ́ “apá kan Ọlọrun” tí ń ran àwọn ẹ̀dá ènìyàn lọ́wọ́ láti mú “iṣan tẹ̀mí” wọn lókun sí i nípa ìdánwò àtìgbàdégbà. Òǹkọ̀wé náà sọ pé, láìka “ìrònú onífẹ̀ẹ́” tí Satani ní sí, a ti fi àṣìṣe mọ̀ ọ́n mọ ohun búburú, jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún. Wọ́n fi kún un pé Satani àti Jesu, “bí wọn kò tilẹ̀ bára dọ́gba pátápátá, ó kéré tan, wọ́n ní góńgó kan náà, wọ́n jẹ́ apá kan odindi ẹnì kan náà.” Ìfìtẹnumọ́ kéde yíyani lẹ́nu ni ìwọ̀nyí jẹ́, ṣùgbọ́n, kí ni Bibeli sọ?
Bibeli mú un ṣe kedere pé, Satani kì í ṣe “apá kan Ọlọrun,” bí kò ṣe, ọ̀tá Ọlọrun. (Luku 10:18, 19; Romu 16:20) Ó ta ko ipò ọba aláṣẹ Jehofa, ó sì dájú pé, àwọn ìgbèrò rẹ̀ sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn kì í ṣe “onífẹ̀ẹ́.” Ó ń fi àìláàánú tú ìbínú rẹ̀ dà sórí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lórí ilẹ̀ ayé. Ó ń fẹ̀sùn kàn wọ́n níwájú Ọlọrun tọ̀sántòru!a (Ìṣípayá 12:10, 12, 15-17) Ìgbèrò Satani ni láti bà wọ́n jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà. Inúnibíni aláìláàánú rẹ̀ sí ọkùnrin olódodo náà, Jobu, táṣìírí ìwà ọ̀dájú rẹ̀ sí ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn.—Jobu 1:13-19; 2:7, 8.
Dájúdájú Satani àti Jesu kì í ṣe “ohun kan náà,” iná òun ẹ̀tù ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Họ́wù, kò sí iyèméjì pé Satani ni ó sún Herodu láti pàṣẹ pípa àwọn ọmọdé jáǹtìrẹrẹ—kìkì lórí ìsapá láti rẹ́yìn ọmọ kékeré náà, Jesu! (Matteu 2:16-18) Ìkọlù Satani tí kò dáwọ́ dúró sì bá a nìṣó títí di ìgbà ikú Jesu. (Luku 4:1-13; Johannu 13:27) Nípa báyìí, kàkà kí wọ́n jẹ́ “apá kan odindi ẹnì kan náà,” iná òun ẹ̀tù ni Jesu àti Satani. Àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fi hàn pé ìṣọ̀tá wọn kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. (Genesisi 3:15) Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, Jesu tí a jí dìde náà ni yóò pa Satani run, nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọrun.—Ìṣípayá 1:18; 20:1, 10.
Ta Ni Ó Yẹ Láti Gbàdúrà Sí?
Àwọn alágbàwí kan lórí èró wíwọ́pọ̀ nípa áńgẹ́lì dábàá àṣàrò àti àwọn ọ̀nà mìíràn láti lè bá àwọn áńgẹ́lì sọ̀rọ̀. Ìwé kan sọ pé: “Ìbéèrè àtọkànwá kan láti ní àjọṣe pẹ̀lú mẹ́ḿbà èyíkéyìí ti ìdílé òkè ọ̀run ni a kì yóò ṣá tì. Ẹ béèrè, a óò sì fi fún un yín.” Mikaeli, Gabrieli, Uriel, àti Raphael wà lára àwọn áńgẹ́lì tí ìwé náà dámọ̀ràn pé kí a bá ní àjọṣe.b
Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà sí Ọlọrun, kì í ṣe sí àwọn áńgẹ́lì. (Matteu 6:9, 10) Bákan náà, Paulu kọ̀wé pé: “Ninu ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà ati ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ papọ̀ pẹlu ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ awọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọrun.” (Filippi 4:6) Nítorí náà, nínú àdúrà wọn, àwọn Kristian kì í tọ ẹlòmíràn lọ àyàfi Jehofa, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jesu Kristi.c—Johannu 14:6, 13, 14.
Àwọn Áńgẹ́lì Ha Jẹ́ Aláìlẹ́sìn Bí?
Gẹ́gẹ́ bí Eileen Elias Freeman, ẹni tí ń darí Ètò Ẹ̀ṣọ́ Áńgẹ́lì ti sọ, “àwọn áńgẹ́lì ré kọjá gbogbo ìsìn, gbogbo àbá èrò orí, gbogbo ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́. Ní tòótọ́, àwọn áńgẹ́lì kò ní ohun kankan tí ń jẹ́ ìsìn.”
Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli mú un ṣe kedere pé, àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́ ní ìsìn; wọ́n ń jọ́sìn Ọlọrun tòótọ́, Jehofa, tí kò fàyè gba ìbánidíje kankan láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọrun mìíràn. (Deuteronomi 5:6, 7; Ìṣípayá 7:11) Nípa báyìí, áńgẹ́lì kan bẹ́ẹ̀ ṣàpèjúwe ara rẹ̀ fún aposteli Johannu gẹ́gẹ́ bí “ẹrú ẹlẹgbẹ́” àwọn tí ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọrun. (Ìṣípayá 19:10) Kò sí ibikíbi nínú Bibeli, tí a ti kà pé àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́ ń gbé irú ìjọsìn mìíràn lárugẹ. Wọ́n ń fún Jehofa ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé.—Eksodu 20:4, 5.
“Baba Irọ”
Ọ̀pọ̀ ìṣalábàápàdé àwọn áńgẹ́lì tí a fẹnu lásán pè bẹ́ẹ̀, ní bíbókùú sọ̀rọ̀ nínú. Obìnrin kan tí ń jẹ́ Elise, lẹ́yìn tí ó rí ohun tí ó pè ní àmì, sọ pé: “Mo rò pé ẹ̀gbọ́n mi ti rí ọ̀nà láti dé ọ̀dọ̀ mi, tí ó sì jẹ́ kí ń mọ̀ pé òun láyọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.” Terri rántí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n kan tí ó dolóògbé bákan náà. Ó sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìsìnkú náà, ó wá sọ́dọ̀ mi nínú ohun tí mo rò pé ó jẹ́ àlá. Ó sọ fún mi pé n kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ lílọ òun, nítorí pé, òun láyọ̀, òun sì wà ní àlàáfíà.”
Ṣùgbọ́n Bibeli sọ pé, àwọn òkú “kò mọ ohun kan.” (Oniwasu 9:5) Ó tún sọ pé, nígbà tí ẹnì kan bá kú, “ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.” (Orin Dafidi 146:4, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Bí ó ti wù kí ó rí, Satani ni “baba irọ́.” (Johannu 8:44) Òun ni ó pilẹ̀ irọ́ náà pé, ọkàn ẹ̀dá ènìyàn máa ń la ikú já. (Fi wé Esekieli 18:4.) Ọ̀pọ̀ ènìyàn gba èyí gbọ́ lónìí, èyí bá ètè Satani mu, nítorí ó bẹ́gi dí àìní náà fún ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde—ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìsìn Kristian. (Johannu 5:28, 29) Nítorí náà, bíbókùú sọ̀rọ̀ tàbí dídà bí ẹni pé a ń gba ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ wọn tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn nípa èrò wíwọ́pọ̀ tí Ọlọrun kò fọwọ́ sí nípa áńgẹ́lì.
Àwọn Áńgẹ́lì Ni A Ń Tọ̀ Lọ, Tàbí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù?
Ọ̀pọ̀ nínú èrò wíwọ́pọ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa áńgẹ́lì ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ awo. Gbé ìrírí Marcia yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Láti September sí December 1986, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbà ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ ‘àwọn ajẹ̀dálọ.’ Mo rí àwọn iwin, mo sì lá àlá ‘ìgbésí ayé àtẹ̀yìnwá.’ Mo ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí ó ti kú, mo sì nírìírí ọ̀pọ̀ èrò ìmọ̀lára àtinúwá, tí mo fi mọ nǹkan nípa àwọn ènìyàn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bá pàdé. A tún fi ẹ̀bùn ìkọ̀wé láìròtì àti gbígba ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí jíǹkí mi. Àwọn kan, tí n kò bá pàdé rí nínú ìgbésí ayé wọn lórí ilẹ̀ ayé, yóò rán mi níṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn.”
Lílo ìwoṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti “bá” àwọn áńgẹ́lì “sọ̀rọ̀” kì í ṣe ohun tuntun. Orísun kan fún àwọn òǹkàwé rẹ̀ níṣìírí pàtó láti lo òkúta idán, káàdì ìwọṣẹ́, ìwé I Ching, ẹyọwó, àyẹ̀wò ilà àtẹ́lẹwọ́, àti ìwòràwọ̀. Òǹkọ̀wé náà kọ̀wé pé: “Jẹ́ kí orí inú rẹ darí rẹ sọ́dọ̀ awo tí ó tọ́, kí o sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé áńgẹ́lì kan yóò pàdé rẹ níbẹ̀.”
Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, ohunkóhun ‘tí ó bá pàdé rẹ níbẹ̀,’ dájúdájú kì í ṣe ọ̀kan lára áńgẹ́lì Ọlọrun. Èé ṣe? Nítorí pé ìwoṣẹ́ ta ko Ọlọrun ní tààràtà, àti pé, àwọn olùjọsìn tòótọ́—lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé—kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú rẹ̀. Họ́wù, ìwoṣẹ́ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú ní Israeli! Òfin náà wí pé: “Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ìríra ni sí OLUWA.”—Deuteronomi 13:1-5; 18:10-12.
“Áńgẹ́lì Ìmọ́lẹ̀”
Kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé, Èṣù lè mú kí ìwoṣẹ́ dà bí ohun tí ń mú àǹfààní wá, àní tí àwọn áńgẹ́lì tì lẹ́yìn. Bibeli sọ pé, Satani ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Korinti 11:14) Ó tilẹ̀ lè hùmọ̀ àmì ìṣẹ̀lẹ̀, kí ó sì mú kí wọ́n ṣẹ, ní títan àwọn òǹwòran jẹ láti ronú pé, àmì ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. (Fi wé Matteu 7:21-23; 2 Tessalonika 2:9-12.) Ṣùgbọ́n gbogbo iṣẹ́ Satani—láìka bí wọ́n ṣe lè dà bí ohun rere tàbí adámọ̀ràn ibi tó—ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀kan lára àwọn ète méjì yìí: láti kẹ̀yìn àwọn ènìyàn sí Jehofa tàbí láti wulẹ̀ fọ́ ojú inú wọn, kí ‘ìmọ́lẹ̀ títàn ìhìn rere ológo nipa Kristi má baà mọ́lẹ̀ wọlé.’ (2 Korinti 4:3, 4) Ọ̀nà ẹ̀tàn tí a mẹnu kàn kẹ́yìn yìí, ni ó sábà ń gbéṣẹ́ jù lọ.
Gbé àkọsílẹ̀ Bibeli nípa ìránṣẹ́bìnrin kan ní ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò. Àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ mú èrè gọbọi wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ó tẹ̀ lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní sísọ pé: “Awọn ọkùnrin wọnyi ni ẹrú Ọlọrun Ẹni Gíga Jù Lọ, awọn ẹni tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà gbangba fún yín.” Òtítọ́ kúkú ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé, ẹ̀mí kan ń ṣàkóso rẹ̀, kì í ṣe áńgẹ́lì, bí kò ṣe “ẹ̀mí-èṣù ìwoṣẹ́.” Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Paulu “yípadà ó sì wí fún ẹ̀mí naa pé: ‘Mo pa àṣẹ ìdarí fún ọ ní orúkọ Jesu Kristi lati jáde kúrò ninu rẹ̀.’ Ó sì jáde ní wákàtí yẹn gan-an.”—Ìṣe 16:16-18.
Èé ṣe tí Paulu fi lé ẹ̀mí yìí jáde? Ó ṣe tán, ó ń mú owó wọlé fún àwọn ọ̀gá ọmọbìnrin tí ó lẹ́mìí-èṣù náà. Pẹ̀lú agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ, ìránṣẹ́bìnrin náà ti lè sọ ìgbà tí àwọn àgbẹ̀ yóò gbin nǹkan fún wọn, ó ti le sọ ìgbà láti ṣègbéyàwó fún àwọn omidan, àti ibi tí wúrà wà fún àwọn awakùsà. Họ́wù, ẹ̀mí yìí tilẹ̀ sún ọmọbìnrin náà láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ díẹ̀, ni yíyin àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní gbangba!
Síbẹ̀síbẹ̀, “ẹ̀mí-èṣù ìwoṣẹ́” ni. Nítorí bẹ́ẹ̀, kò ní ẹ̀tọ́ láti pòkìkí Jehofa àti ìpèsè rẹ̀ fún ìgbàlà. Ọ̀rọ̀ ìkansáárá rẹ̀, bóyá tí ó sọ láti lè gbóríyìn fún ìsọtẹ́lẹ̀ ìránṣẹ́bìnrin náà, pe àfiyèsí àwọn òǹwòran kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́. Pẹ̀lú ìdí rere, Paulu kìlọ̀ fún àwọn ará Korinti pé: “Ẹ̀yin kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jehofa’ ati tábìlì awọn ẹ̀mí-èṣù.” (1 Korinti 10:21) Kò yani lẹ́nu pé, àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní sun gbogbo ìwé wọn, tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìwoṣẹ́ níná.—Ìṣe 19:19.
“Áńgẹ́lì . . . Tí Ń Fò Ní Agbedeméjì Ọ̀run”
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, Bibeli táṣìírí púpọ̀ lára èrò wíwọ́pọ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa áńgẹ́lì bí èyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Elénìní Ọlọrun, Satani Èṣù. Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn áńgẹ́lì mímọ́ kì í lọ́wọ́ nínú àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn bí? Ní òdì kejì, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ lílágbára lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí. Iṣẹ́ wo ni? Láti dáhùn, a gbọ́dọ̀ gbé ìwé Ìṣípayá nínú Bibeli yẹ̀ wò. A mẹ́nu kan àwọn áńgẹ́lì nínú ìwé yìí ju ìwé mìíràn lọ nínú Bibeli.
Ní Ìṣípayá 14:6, 7, a ka àkọsílẹ̀ aposteli Johannu nípa ìran alásọtẹ́lẹ̀ kan tí ó rí gbà pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìnrere àìnípẹ̀kun lati polongo gẹ́gẹ́ bí awọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún awọn wọnnì tí ń gbé lórí ilẹ̀-ayé, ati fún gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ahọ́n ati ènìyàn, ó ń wí ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nitori wákàtí ìdájọ́ lati ọwọ́ rẹ̀ ti dé, ati nitori naa ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run ati ilẹ̀-ayé ati òkun ati awọn ìsun omi.’”
Ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí tẹnu mọ́ iṣẹ́ pàtàkì jù lọ tí àwọn áńgẹ́lì ń ṣe lónìí. Wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àyànfúnni kan tí ó gbapò kìíní—pípòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun. Iṣẹ yìí ni Jesu ń sọ nípa rẹ̀, nígbà ti ó ṣèlérí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mo wà pẹlu yín ní gbogbo awọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” (Matteu 28:18-20) Báwo ni Jesu ṣe wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Ọ̀nà kan ni, nípa pípèsè ìrànwọ́ àwọn áńgẹ́lì fún wọn, kí wọ́n baà lè ṣàṣeparí iṣẹ́ pípabambarì yìí.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń lo wákàtí tí ó lé ní bílíọ̀nù kan lọ́dọọdún ní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun. Bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí, wọ́n ń rí ẹ̀rí pé àwọn áńgẹ́lì ń tọ́ wọn sọ́nà. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé wọn, ó ti ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé, wọ́n ti kàn sí àwọn kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà fún ìrànwọ́ láti lè lóye àwọn ète Ọlọrun tán. Ìtọ́sọ́nà àwọn áńgẹ́lì, pa pọ̀ pẹ̀lú ìdánúṣe àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn, ti yọrí sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ń wá mọ Jehofa lọ́dọọdún!
Ìwọ́ ha ń tẹ́tí sí áńgẹ́lì náà tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run bí? Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá kàn sí ọ, èé ṣe tí o kò fi túbọ̀ bá wọn jíròrò ìhìn iṣẹ́ áńgẹ́lì yìí ní kíkún?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà “Satani” àti “Èṣù” túmọ̀ sí “alátakò” àti “abanijẹ́.”
b Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a mẹ́nu kan Mikaeli àti Gabrieli nínú Bibeli, inú ìwé Apocrypha, tí kì í ṣe apá kan ìwé Bibeli, ni orúkọ Raphael àti Uriel ti hàn.
c Ṣàkíyèsí pé a ń gbàdúrà nípasẹ̀ Jesu, kì í ṣe sí i. A ń gbàdúrà lórúkọ Jesu nítorí pé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a tà sílẹ̀ ni ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti tọ Ọlọrun lọ.—Efesu 2:13-19; 3:12.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
ÀWỌN WO NI ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ?
NÍ ÌYÀTỌ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbàgbọ́, àwọn áńgẹ́lì kì í ṣe àwọn ọkàn àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ti kú. Bibeli sọ kedere pé àwọn òkú “kò mọ ohun kan.” (Oniwasu 9:5) Nígbà náà, ibo ni àwọn áńgẹ́lì ti wá? Bibeli tọ́ka sí i pé Ọlọrun dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣáájú dídá ayé. (Jobu 38:4-7) Bí ìdílé ọ̀run ti Ọlọrun ti tóbi tó lè jẹ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́, bóyá ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ! Àwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Satani nínú ọ̀tẹ̀ rẹ̀.—Danieli 7:10; Ìṣípayá 5:11; 12:7-9.
Níwọ̀n bí Jehofa ti jẹ́ Ọlọrun ètò, kò yani lẹ́nu pé ìdílé ńlá ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ wà létòlétò.—1 Korinti 14:33.
• Áńgẹ́lì tí ó gbawájú jù lọ, ní ti agbára àti ọlá àṣẹ, ni olú áńgẹ́lì náà, Jesu Kristi, tí a tún ń pè ní Mikaeli. (1 Tessalonika 4:16; Juda 9) Àwọn séráfù, kérúbù, àti áńgẹ́lì wà lábẹ́ ọlá àṣẹ rẹ̀.
• Àwọn séráfù wà níbi ìtẹ́ Ọlọrun. Ní kedere, iṣẹ́ẹ wọn ní pípolongo ìjẹ́mímọ́ Ọlọrun àti mímú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní nínú.—Isaiah 6:1-3, 6, 7.
• Àwọn kérúbù pẹ̀lú máa ń wà níwájú Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ru ìtẹ́ Ọlọrun, tàbí tí ń dáàbò bò ó, wọ́n ń gbé ọlá ńlá Jehofa ga.—Orin Dafidi 80:1; 99:1; Esekieli 10:1, 2.
• Àwọn áńgẹ́lì (tí ó túmọ̀ sí “àwọn ìránṣẹ́”) jẹ́ aṣojú àti ikọ̀ fún Jehofa. Wọ́n máa ń mú ìfẹ́ inú Ọlọrun ṣẹ, yálà ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdáǹdè àwọn ènìyàn Ọlọrun tàbí ìparun àwọn ẹni ibi.—Genesisi 19:1-26.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìwọ́ ha ń tẹ́tí sí áńgẹ́lì náà tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run bí?