Ìjàkadì Nítorí Ìhìn Rere Ní Ìlú Tẹsalóníkà
Ìlú Tẹsalóníkà tí wọ́n tún ń pè ní Tẹsalóníki tàbí Salóníkà lóde òní, jẹ́ èbúté òkun tí ọrọ̀ ajé ti búrẹ́kẹ́ ní ìhà àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Gíríìsì. Ìlú yìí kó ipa pàtàkì nínú ìtàn àwọn Kristẹni ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, pàápàá nínú iṣẹ́ ìwàásù tí Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè ṣe.—ÌṢE 9:15; RÓÒMÙ 11:13.
PỌ́Ọ̀LÙ àti Sílà tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò, lọ sí ìlú Tẹsalóníkà ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni. Ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù ń rìn nìyí, ó sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa wàásù ìhìn rere nípa Kristi dé agbègbè tí a wá mọ̀ sí Yúróòpù lónìí.
Bí wọ́n ṣe dé ìlú Tẹsalóníkà yìí, ó dájú pé wọ́n á ṣì máa rántí bí àwọn kan ṣe lù wọ́n, tí wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n nílùú Fílípì, ìyẹn ìlú tó gbawájú lágbègbè Makedóníà. Kódà, Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ sọ fún àwọn ará Tẹsalóníkà lẹ́yìn náà pé nígbà tí òun wá sọ́dọ̀ wọn, òun wàásù ‘ìhìn rere Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.’ (1 Tẹsalóníkà 2:1, 2) Nígbà tí wọ́n wà nílùú Tẹsalóníkà, ṣé nǹkan rọrùn fún wọn ju ìgbà tí wọ́n wà ní ìlú Fílípì lọ? Nígbà tí wọ́n ń wàásù nílùú Tẹsalóníkà, kí ló ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ǹjẹ́ ìwàásù wọn kẹ́sẹ járí? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ìlú àtijọ́ yìí ná.
Ìlú Tí Ọ̀pọ̀ Ogun Ti Jà Látijọ́
Tẹsalóníkà tó jẹ́ orúkọ ìlú náà wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì tó túmọ̀ sí “àwọn ará Tẹ́sálì” àti “ìṣẹ́gun,” èyí tó tọ́ka sí ìjàkadì àti ìjà. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé lọ́dún 352 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọba Fílípì Kejì ti ìlú Makedóníà, ìyẹn bàbá Alẹkisáńdà Ńlá, ṣẹ́gun ẹ̀yà kan láti àárín gbùngbùn ilẹ̀ Gíríìsì ní ìlú Tẹ́sálì. Ó wá sọ ọkàn lára àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní Tẹsalónísì láti máa fi rántí bó ṣe jagun ṣẹ́gun. Ọmọbìnrin náà ló di aya ọ̀gágun Kasáńdà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó rọ́pò Alẹkisáńdà tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọmọbìnrin náà. Ní nǹkan bí ọdún 315 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Kasáńdà kọ́ ìlú kan sí apá ìwọ̀ oòrùn Ìyawọlẹ̀ Omi Chalcidice, ó sì fi orúkọ aya rẹ̀ Tẹsalónísì sọ ìlú náà, ó pè é ní Tẹsalóníkà. Ọ̀rọ̀ bí ogun bí ogun kì í tán lọ́rọ̀ ìlú Tẹsalóníkà láti ayé àtijọ́ tó ti wà.
Ìlú ọlọ́rọ̀ tún ni ìlú Tẹsalóníkà. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú èbúté tó dára jù fún ọkọ̀ òkun láti gúnlẹ̀ sí ní etí Òkun Aegean. Nígbà ìjọba Róòmù àtijọ́, ọ̀nà kan tí àwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó, ìyẹn Via Egnatia, gba ibẹ̀ kọjá. Níwọ̀n bí ìlú Tẹsalóníkà ti wà ní ibi pàtàkì kan tí àwọn tó ń rìnrìn àjò lórí òkun àti orí ilẹ̀ ń gbà kọjá, ó jẹ́ ọ̀kan nínú ibi tí ọjà tó ń wọ Ilẹ̀ Ọba Róòmù àti èyí tó ń jáde níbẹ̀ máa ń gbà kọjá. Torí pé ó jẹ́ ìlú tó lọ́rọ̀, láti ayé àtijọ́ ló ti jẹ́ ibi tí àwọn ẹ̀yà Goth, ẹ̀yà Slav, ẹ̀yà Frank, àwọn ará ìlú Venice àti àwọn ará ilẹ̀ Tọ́kì, máa ń fẹ́ jẹ gàba lé lórí. Ṣe ni àwọn míì lára àwọn ẹ̀yà yìí fipá ṣẹ́gun ìlú náà tí wọ́n sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù sí ìlú yìí, nígbà tí ìjàkadì, ìyẹn akitiyan nítorí ìhìn rere ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀.
Pọ́ọ̀lù Dé sí Ìlú Tẹsalóníkà
Tí Pọ́ọ̀lù bá ti dé ìlú kan, ó máa ń kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù nítorí pé, bí wọ́n ṣe ti mọ̀ nípa Ìwé Mímọ́, wọ́n á lè jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, á sì tipa bẹ́ẹ̀ là wọ́n lóye nípa ìhìn rere. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù sábà máa ń ṣe yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn Júù èèyàn rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún gan-an, tàbí kó jẹ́ pé ó ń gbìyànjú láti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwàásù lọ́dọ̀ àwọn Júù àti àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run kó lè ráyè wàásù fún àwọn Kèfèrí.—Ìṣe 17:2-4.
Torí náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Tẹsalóníkà, ó wọ inú sínágọ́gù lọ, ó ń “bá [àwọn Júù] fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́, ó ń ṣàlàyé, ó sì ń fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka pé ó pọndandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú òkú, ó sì wí pé: ‘Èyí ni Kristi náà, Jésù yìí tí mo ń kéde fún yín.’”—Ìṣe 17:2, 3, 10.
Ohun tó ṣì ń fa àríyànjiyàn ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lé lórí, ìyẹn ẹni tó jẹ́ Mèsáyà àti ojúṣe rẹ̀. Àwọn Júù kò rò pé Mèsáyà máa wá jìyà tó bá dé. Ohun tí wọ́n retí ni pé ṣe lá máa jagun láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá àwọn. Láti lè yí àwọn Júù lọ́kàn pa dà, Pọ́ọ̀lù “bá wọn fèrò-wérò,” ‘ó ṣàlàyé,’ ‘ó sì fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka’ láti inú Ìwé Mímọ́, ohun tí olùkọ́ tó pegedé sì máa ń ṣe nìyẹn.a Àmọ́, báwo wá ni gbogbo àlàyé kíkún tí Pọ́ọ̀lù ṣe yẹn ṣe rí lára àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀?
Iṣẹ́ Ìwàásù Rẹ̀ Kẹ́sẹ Járí, Ṣùgbọ́n Ìṣòro Wáyé
Àwọn Júù kan àti ọ̀pọ̀ àwọn Gíríìkì tó jẹ́ aláwọ̀ṣe tẹ́wọ́ gba ìwàásù Pọ́ọ̀lù, bákan náà “kì í ṣe díẹ̀ lára àwọn sàràkí-sàràkí obìnrin ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.” Gbólóhùn náà “àwọn sàràkí-sàràkí obìnrin” bá a mu gan-an torí pé ipò ọlá làwọn obìnrin ilẹ̀ Makedóníà máa ń wà. Wọ́n máa ń wà nípò ńlá láwùjọ, wọ́n ní ọlá àti ọlà, wọ́n máa ń fún wọn ní àwọn ẹ̀tọ́ kan láwùjọ, wọ́n sì máa ń ṣòwò gan-an. Kódà wọ́n tiẹ̀ máa ń gbé àwọn ohun ìrántí kalẹ̀ fún wọn láti fi yẹ́ wọn sí. Bí obìnrin oníṣòwò ará Fílípì yẹn tó ń jẹ́ Lìdíà ṣe tẹ́wọ́ gba ìhìn rere, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin jàǹkàn-jàǹkàn ará Tẹsalóníkà yìí ṣe, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn obìnrin tí wọ́n jáde nílé ire tàbí ìyàwó àwọn ẹni ńlá nílùú.—Ìṣe 16:14, 15; 17:4.
Àmọ́ ṣe ni àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara. Wọ́n lọ kó “àwọn ọkùnrin burúkú kan tí wọ́n jẹ́ aláìríkan-ṣèkan ibi ọjà wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì kó àwùjọ onírúgúdù jọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ìlú ńlá náà sínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀.” (Ìṣe 17:5) Irú èèyàn wo ni àwọn ọkùnrin yẹn? Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ “àwọn òkúùgbẹ́ àti èèyànkéèyàn.” Ó sì tún sọ pé: “Ó jọ pé kò sí èyí tó tiẹ̀ kàn wọ́n rárá nínú ohun yòówù kí Pọ́ọ̀lù máa sọ; àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn ọ̀dàlúrú, ṣe ni wọ́n kàn jẹ́ aríjàyọ̀ tó máa ń gba wàhálà kanrí.”
Àwùjọ èèyànkéèyàn yẹn wá “fipá kọlu ilé Jásónì [ẹni tó gba Pọ́ọ̀lù lálejò], wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti mú wọn wá síwájú àwùjọ màdàrú náà.” Nígbà tí wọn kò rí Pọ́ọ̀lù, wọ́n gba ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè ìlú náà lọ. “Wọ́n wọ́ Jásónì àti àwọn arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ àwọn olùṣàkóso ìlú ńlá náà, wọ́n ń ké jáde pé: ‘Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí wọ́n ti sojú ilẹ̀ ayé tí a ń gbé dé ti dé síhìn-ín pẹ̀lú.’”—Ìṣe 17:5, 6.
Torí pé Tẹsalóníkà jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Makedóníà, wọ́n fún wọn láyè láti máa dá ṣe ìjọba ara wọn dé ìwọ̀n àyè kan. Lára ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣèjọba ara wọn ni pé wọ́n ní àpéjọ ìlú tàbí ìgbìmọ̀ ìlú tó ń bójú tó ọ̀ràn àwọn aráàlú. “Àwọn olùṣàkóso ìlú ńlá”b yẹn sì jẹ́ àwọn ìjòyè ìlú, tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa rí sí i pé ìlú tòrò, kí wọ́n sì tètè máa yanjú gbogbo ohun tó bá máa mú kí àwọn ará Róòmù wá dá sí ọ̀rọ̀ ìlú náà, táá fi wá di pé ìlú náà pàdánù àwọn àǹfààní tí wọ́n fún wọn. Torí náà ìdààmú máa bá àwọn olùṣàkóso ìlú ńlá yẹn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn kan tí wọ́n pè ní oníjàngbọ̀n wá da ìlú rú.
Wọ́n tún wá fi ẹ̀sùn tó le ju ìyẹn kàn wọ́n pé: “Gbogbo ọkùnrin wọ̀nyí ni wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ ní ìlòdìsí àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ Késárì, wí pé ọba mìíràn wà, Jésù.” (Ìṣe 17:7) Ọ̀mọ̀wé kan tó ṣàlàyé lórí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé, ẹ̀sùn “ìdìtẹ̀ sí ìjọba àti ìṣọ̀tẹ̀” sí àwọn olú ọba ni wọ́n fi kàn wọ́n yìí, torí àwọn olú ọba “kì í gbà kí wọ́n tún máa dárúkọ ọba [míì] ní àgbègbè èyíkéyìí tí wọ́n bá ti ṣẹ́gun, àyàfi tí olú ọba bá fọwọ́ sí i.” Lẹ́yìn náà, bó ṣe jẹ́ pé torí ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ sí ìjọba yìí kan náà ni àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Róòmù yìí ṣe pa Jésù, ẹni tí Pọ́ọ̀lù ń sọ pé ó jẹ́ ọba yìí, ṣe ló máa dà bí pé òótọ́ ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Kristẹni yẹn.—Lúùkù 23:2.
Èyí kó ṣìbáṣìbo bá àwọn olùṣàkóso ìlú náà. Àmọ́ níwọ̀n bí kò tí sí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀, tí wọn kò sì tún rí àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà mú wá, ohun tí àwọn olùṣàkóso náà ṣe ni pé “lẹ́yìn kíkọ́kọ́ gba ohun ìdúró tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn yòókù,” wọ́n “jẹ́ kí wọ́n lọ.” (Ìṣe 17:8, 9) Ohun ìdúró tí wọ́n gbà lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn Kristẹni tó kù yìí jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n gbà fi dá àwọn aláṣẹ yẹn lójú pé Pọ́ọ̀lù máa kúrò ní ìlú náà, kò sì ní pa dà wá dá wàhálà sílẹ̀ níbẹ̀ mọ́. Bóyá ni kò fi ní jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òun fẹ́ pa dà sí ìlú náà, àmọ́ “Sátánì dábùú ọ̀nà” òun tí ìyẹn kò fi ṣeé ṣe.—1 Tẹsalóníkà 2:18.
Nítorí èyí, àwọn ará mú kí Pọ́ọ̀lù àti Sílà tètè kúrò níbẹ̀ lóru, kí wọ́n lọ sí ìlú Bèróà. Pọ́ọ̀lù tún ṣàṣeyege lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ ní Bèróà náà, àmọ́ èyí bí àwọn Júù alátakò rẹ̀ ní ìlú Tẹsalóníkà nínú gan-an débi pé wọ́n rìnrìn àjò ọgọ́rin [80] kìlómítà lọ sí ìlú Bèróà láti lọ yí àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ́kàn pa dà kí wọ́n lè gbógun ti Pọ́ọ̀lù àti Sílà. Láìpẹ́, Pọ́ọ̀lù tún gbéra, ó kọrí sọ́nà Áténì, àmọ́ ṣá àwọn ará Tẹsalóníkà ń bá ìjàkadì wọn nítorí ìhìn rere nìṣó.—Ìṣe 17:10-14.
Àwọn Ìṣòro Tó Bá Ìjọ Tuntun Yẹn
Ó dùn mọ́ni pé ìjọ kan fìdí múlẹ̀ ní ìlú Tẹsalóníkà, àmọ́ àtakò nìkan kọ́ ni ìṣòro àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. Àárín àwọn abọ̀rìṣà, níbi tí ìṣekúṣe ti wọ́pọ̀ ni wọ́n ń gbé, èyí kò sì jẹ́ kí ọkàn Pọ́ọ̀lù balẹ̀. Kò mọ bí nǹkan ṣe máa rí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tó wà níbẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 2:17; 3:1, 2, 5.
Àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà mọ̀ pé bí àwọn ṣe jáwọ́ nínú gbogbo afẹfẹyẹ̀yẹ̀ àwọn aráàlú àti ti ìsìn, inú àwọn ọ̀rẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá kò ní dùn, wọn yóò sì máa bínú sí àwọn. (Jòhánù 17:14) Yàtọ̀ síyẹn, Tẹsalóníkà jẹ́ ìlú tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúbọ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Gíríìsì, irú bíi Súúsì, Átẹ́mísì àti Àpólò àti àwọn òrìṣà ilẹ̀ Íjíbítì kan. Wọ́n tún ń bọ Késárì lójú méjèèjì ní ìlú náà, ọ̀ranyàn sì ni pé kí àwọn aráàlú lọ́wọ́ sí gbogbo ààtò tó jẹ mọ́ ọn pátá. Béèyàn bá kọ̀ láti kópa níbẹ̀, wọ́n lè kà á sí pé onítọ̀hún ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Róòmù.
Ṣe ni ìbọ̀rìṣà máa ń jẹ́ kí ìwà ìṣekúṣe tó burú jáì gbilẹ̀. Onírúurú ìṣekúṣe tó pọ̀ lápọ̀jù àti ọtí àmupara ni èyí tó pọ̀ jù lára ààtò tí wọ́n fi ń bọ òrìṣà Kabáírọ́sì tó jẹ́ olórí òòṣà tí wọ́n ń bọ ní Tẹsalóníkà, àṣà yìí kan náà sì ni wọ́n fi ń bọ òrìṣà Díónísọ́sì àti Áfúródáítì àti òrìṣà Ísísì láti ilẹ̀ Íjíbítì. Yíyan àlè àti aṣẹ́wó ṣíṣe sì gbilẹ̀ gan-an níbẹ̀. Lójú àwọn èèyàn náà, àgbèrè kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ rárá. Àwọn ará ìlú yẹn ti kó àṣà àwọn ará Róòmù, débi pé òǹkọ̀wé kan sọ nípa wọn pé, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkùnrin àti obìnrin ló wà ní ìlú náà, tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n kàn wà fún ni pé kí wọ́n máa tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ aráàlú lọ́rùn lọ́nàkọnà tí wọ́n bá ń fẹ́, àwọn aráàlú sì máa ń lọ háyà wọn, àwọn dókítà ibẹ̀ sì máa ń gbà wọ́n nímọ̀ràn pé ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn dára bẹ́ẹ̀.” Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n “ta kété sí àgbèrè” kí wọ́n sì yẹra fún “ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo” àti “ìwà àìmọ́.”—1 Tẹsalóníkà 4:3-8.
Wọ́n Borí Àwọn Ìṣòro Náà
Àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Tẹsalóníkà ní láti máa sa gbogbo agbára wọn láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn. Ṣùgbọ́n, láìka àtakò, ìjìyà àti bí wọ́n ṣe wà ní agbègbè tí ìbọ̀rìṣà àti ìṣekúṣe ti wọ́pọ̀ sí, wọ́n jẹ́ olóòótọ́ débi pé Pọ́ọ̀lù yìn wọ́n nítorí ‘ìṣòtítọ́ wọn, òpò onífẹ̀ẹ́ wọn àti ìfaradà wọn,’ àti bí wọ́n ṣe kópa gidigidi nínú wíwàásù ìhìn rere jákèjádò ibẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 1:3, 8.
Ní ọdún 303 Sànmánì Kristẹni, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó gbóná gan-an sí gbogbo àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Késárì Galerius tó ń gbé ní ìlú Tẹsalóníkà tó sì kọ́ àwọn ilé mèremère síbẹ̀ ló wà lẹ́yìn gbogbo inúnibíni yẹn. Àwọn tó bá rìnrìn àjò lọ sí ìlú Tẹsalóníkà ṣì máa ń rí àwókù àwọn ilé náà níbẹ̀.
Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Tẹsalóníki máa ń wàásù fún àwọn èèyàn níbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ pé iwájú àwọn ilé tí òǹrorò ọ̀tà Kristẹni yẹn kọ́ gan-an ni wọ́n ti máa ń wàásù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn àkókò kan wà nínú ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún tó kọjá lọ yìí, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn lójú àtakò líle koko níbẹ̀, síbẹ̀ nǹkan bí ọgọ́ta [60] ìjọ ló ti wà ní ìlú Tẹsalóníkà báyìí. Akitiyan wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù fi hàn pé ìjàkadì láti tan ìhìn rere kálẹ̀, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ṣì ń bá a lọ láìdáwọ́dúró, ó sì ń kẹ́sẹ járí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Sáàmù 22:7; 69:21; Aísáyà 50:6; 53:2-7; àti Dáníẹ́lì 9:26.
b Àwọn ọ̀mọ̀wé kò rí gbólóhùn yìí “àwọn olùṣàkóso ìlú ńlá” nínú ìwé àwọn òǹkọ̀wé lédè Gíríìkì. Àmọ́ wọ́n rí i lára àwọn àkọlé tí wọ́n wù jáde nínú ilẹ̀ lágbègbè Tẹsalóníkà, òmíì lára rẹ̀ sì ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èyí tó fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú ìwé Ìṣe yìí.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ọ̀nà Via Egnatia
MAKEDÓNÍÀ
Ìlú Fílípì
Áńfípólì
Tẹsalóníkà
Bèróà
TẸ́SÁLÌ
Òkun Aegean
ÁTÉNÌ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Òkè: Tẹsalóníki òde òní
Nísàlẹ̀ rẹ̀: ẹnubodè bìrìkìtì àti ilé ibùwẹ̀ ti àwọn ara Róòmù ní Agora
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ilé olóbìírípo tó wà nítòsí ẹnubodè bìrìkìtì ti Galerius; ère Késárì Galerius tí wọ́n gbẹ́; wíwàásù nítòsí ẹnubodè bìrìkìtì ti Galerius
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n ya orí sí: © Bibliothèque nationale de France; Ìkọ̀wé ara òkúta: Thessalonica Archaeological Museum, ẹ̀tọ́ àdàkọ jẹ́ ti Hellenic Ministry of Culture and Tourism
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwòrán méjì tó wà lápá òsì nísàlẹ̀: 16th Ephorate of Prehistoric and Classical Antiquities, ẹ̀tọ́ àdàkọ jẹ́ ti Hellenic Ministry of Culture and Tourism
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwòrán tó wà láàárín: Thessalonica Archaeological Museum, ẹ̀tọ́ àdàkọ jẹ́ ti Hellenic Ministry of Culture and Tourism