Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àjíǹde Ti Lágbára Tó?
“Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.”—JÒHÁNÙ 11:25.
1, 2. Èé ṣe tí olùjọ́sìn Jèhófà fi nílò ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìrètí àjíǹde?
BÁWO ni ìrètí rẹ nínú àjíǹde ti lágbára tó? Ó ha ń fún ọ lókun láti kojú ìbẹ̀rù ikú, kí ó sì tù ọ́ nínú nígbà tí o bá pàdánù àwọn olólùfẹ́ nínú ikú? (Mátíù 10:28; 1 Tẹsalóníkà 4:13) Ìwọ ha dà bí ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ìgbà láéláé, tí wọ́n fara da ìnàlọ́rẹ́, ìfiṣẹlẹ́yà, ìdálóró, àti ìdè ẹ̀wọ̀n, àwọn tí ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde fún wọn lókun?—Hébérù 11:35-38.
2 Bẹ́ẹ̀ ni, kò yẹ kí ẹni tí ń fi òtítọ́ inú jọ́sìn Jèhófà ṣiyèméjì rárá pé àjíǹde yóò wà, ó sì yẹ kí ìbàlẹ̀ ọkàn tí ó ní nípa lórí bí ó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Ó jẹ́ ohun àgbàyanu láti ronú lórí òtítọ́ náà pé nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, òkun, ikú, àti Hédíìsì yóò jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn, àwọn wọ̀nyí tí a jí dìde yóò sì ní ìrètí wíwàláàyè títí láé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 20:13; 21:4, 5.
Iyèméjì Nípa Ìwàláàyè Ọjọ́ Iwájú
3, 4. Ìgbàgbọ́ wo ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ní nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?
3 Ó ti pẹ́ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ń kọ́ni pé ìwàláàyè ń bẹ lẹ́yìn ikú. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn náà, U.S. Catholic, sọ pé: “Àtọdúnmọ́dún ni àwọn Kristẹni ti ń làkàkà láti fara da ìjákulẹ̀ àti ìyà inú ayé yìí nípa wíwọ̀nà fún ayé mìíràn, tí ó jẹ́ ti àlàáfíà àti ìtẹ́lọ́rùn, ti ìbàlẹ̀ àyà àti ayọ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́pọ̀ ilẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù, afẹ́ ayé ti gba àwọn èèyàn lọ́kàn, tí ẹ̀sìn kò sì jọ wọ́n lójú mọ́, síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì gbà pé nǹkan kan ń bẹ lẹ́yìn ikú. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nǹkan ń bẹ tí wọn kò lóye.
4 Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn náà, Time, ṣàlàyé pé: “Àwọn ènìyàn ṣì gbà gbọ́ nínú [ìwàláàyè lẹ́yìn ikú]: ó kàn jẹ́ pé òye wọn nípa ohun tí ó jẹ́ gan-an ti pòkúdu, wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ kí àwọn pásítọ̀ wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́.” Kí ló dé tí àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn kò sọ̀rọ̀ mọ́ bí ti tẹ́lẹ̀ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú? Jeffrey Burton Russell, tí í ṣe ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn, sọ pé: “Mo rò pé [àwọn àlùfáà] fẹ́ jánu lórí ọ̀rọ̀ yìí nítorí wọ́n nímọ̀lára pé iyèméjì tí ó ṣòro láti borí ti gbòde kan báyìí.”
5. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí fi ń wo ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì?
5 Nínú ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, ìwàláàyè lẹ́yìn ikú wé mọ́ ọ̀run àti ọ̀run àpáàdì. Bí kò bá sì yá àwọn àlùfáà lára láti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run, ẹnu wọ́n ti wá rọ báyìí láti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpáàdì. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Lóde ìwòyí, kódà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ìdálóró ayérayé ní ọ̀run àpáàdì . . . kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́.” Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn kò ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀run àpáàdì mọ́ pé ó jẹ́ ibi ìdálóró, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń kọ́ni ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fara mọ́ èrò “oníyọ̀ọ́nú” nípa ọ̀run àpáàdì. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ elérò ìgbàlódé ti wí, kì í kúkú ṣe pé a ń dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọ̀run àpáàdì lóró, ṣùgbọ́n wọ́n ń jìyà nítorí tí wọ́n “pínyà nípa tẹ̀mí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
6. Báwo ni àwọn kan ṣe wá mọ̀ pé ìgbàgbọ́ àwọn kò kúnjú ìwọ̀n nígbà tí wọ́n dojú kọ àjálù?
6 Pípẹ̀rọ̀ sí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kí a má bàa tàpá sí ẹ̀mí àìráragba-nǹkan-sí òde òní lè gba àwọn kan lọ́wọ́ dídi aláìlókìkí, ṣùgbọ́n ó ń da àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì ríborìbo nípa ohun tí ó yẹ kí wọ́n gbà gbọ́. Abájọ, nígbà tí ikú bá fẹjú mọ́ wọn, ṣe ni wọ́n sábà máa ń rí i pé ìgbàgbọ́ àwọn mẹ́hẹ. Ìṣarasíhùwà wọn dà bí ti obìnrin tí ó pàdánù àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ mélòó kan nínú jàǹbá burúkú kan. Nígbà tí wọ́n bi í nípa bóyá ìgbàgbọ́ rẹ̀ tù ú nínú, pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀, ó fèsì pé, “Ó jọ bẹ́ẹ̀.” Ṣùgbọ́n ká tilẹ̀ sọ pé ó fọwọ́ sọ̀yà pé ìgbàgbọ́ òun ran òun lọ́wọ́, ire pípẹ́títí wo ni yóò jẹ́ bí àwọn ohun tí ó gbà gbọ́ kò bá lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? Èyí gbèrò, nítorí pé, ká sòótọ́, ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni nípa ọjọ́ ọ̀la yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni.
Ojú Ìwòye Kirisẹ́ńdọ̀mù Nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú
7. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì gbà gbọ́? (b) Báwo ni ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn kan ṣe ṣàlàyé ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn?
7 Láìka àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ètò ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù sí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni ó gbà pé ènìyàn ní àìleèkú ọkàn tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú. Ọ̀pọ̀ jù lọ gbà gbọ́ pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, ọkàn rẹ̀ lè lọ sí ọ̀run. Àwọn kan ń bẹ̀rù pé ọkàn àwọn lè lọ sí ọ̀run àpáàdì tàbí sínú pọ́gátórì. Ṣùgbọ́n èròǹgbà àìleèkú ọkàn ni ojú ìwòye wọn nípa ọjọ́ ọ̀la sinmi lé. Oscar Cullmann, tí í ṣe ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn, sọ̀rọ̀ nípa èyí nínú àròkọ kan tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé náà, Immortality and Resurrection. Ó kọ̀wé pé: “Lónìí, bí a bá bi Kristẹni kan léèrè . . . ohun tí ó rò pé ó jẹ́ ẹ̀kọ́ Májẹ̀mú Tuntun nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn lẹ́yìn ikú, yàtọ̀ sí ìwọ̀nba díẹ̀, ìdáhùn tí a óò gbọ́ ni: ‘Àìleèkú ọkàn.’” Ṣùgbọ́n, Cullmann wá fi kún un pé: “Èròǹgbà yìí, tí a tẹ́wọ́ gbà kárí ayé, ni ọ̀kan lára àwọn àṣìlóye tí ó burú jù lọ nínú ẹ̀sìn Kristẹni.” Cullmann sọ pé nígbà tí òun kọ́kọ́ sọ èyí, arukutu sọ. Síbẹ̀, ó tọ̀nà.
8. Ìrètí wo ni Jèhófà fi sí iwájú ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́?
8 Jèhófà Ọlọ́run kò dá àwọn ènìyàn láti lọ sí ọ̀run lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Kì í ṣe ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí wọ́n tilẹ̀ kú rárá. Ẹni pípé ni a dá Ádámù àti Éfà, a sì fún wọn ní àǹfààní láti fi àwọn ọmọ òdodo kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Diutarónómì 32:4) A sọ fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pé wọn yóò kú kìkì bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ká ní wọ́n jẹ́ onígbọràn sí Baba wọn ọ̀run ni, wọn ì bá wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.
9. (a) Kí ni òtítọ́ nípa ọkàn ẹ̀dá ènìyàn? (b) Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà tí ó bá kú?
9 Ṣùgbọ́n, ó ṣeni láàánú pé Ádámù àti Éfà kùnà láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé àbájáde búburú tí ó jẹyọ, pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Dípò wíwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, Ádámù àti Éfà kú. Kí wá ni ó ṣẹlẹ̀? Wọ́n ha ní àìleèkú ọkàn tí a lè wá fi ránṣẹ́ sí ọ̀run àpáàdì nísinsìnyí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn? Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé ṣáájú àkókò yẹn, nígbà tí a dá Ádámù, ó “wá di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) A kò fún ènìyàn ní ọkàn; òun ni ó di ọkàn, ènìyàn alààyè. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Họ́wù, Ádámù nìkan kọ́ ni “alààyè ọkàn” ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí èdè Hébérù tí a fi kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì ti fi hàn, “alààyè ọkàn” ni àwọn ẹranko rírẹlẹ̀ pẹ̀lú! (Jẹ́nẹ́sísì 1:24) Nígbà tí Ádámù àti Éfà kú, wọ́n di òkú ọkàn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, bí Jèhófà ti wí gan-an ni ó rí fún Ádámù, pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.
10, 11. Kí ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, jẹ́wọ́ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa ọkàn, báwo sì ni èyí ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ?
10 Ní àkópọ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, fara mọ́ èyí. Nínú àpilẹ̀kọ rẹ̀, “Ọkàn (nínú Bíbélì),” ó sọ pé: “Kò sí pípín ara àti ọkàn níyà nínú ML [“Májẹ̀mú Láéláé,” tàbí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù].” Ó fi kún un pé nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn,” “kò fi ìgbà kankan túmọ̀ sí ọkàn tí ó yàtọ̀ gédégbé sí ara tàbí ẹni náà gan-an.” Ní tòótọ́, ọkàn sábà máa “ń túmọ̀ sí ẹ̀dá náà gan-an, yálà ẹranko tàbí ènìyàn.” Irú àìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ bẹ́ẹ̀ dára, ṣùgbọ́n ìdí tí a kò fi jẹ́ kí àwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì ní gbogbo gbòò mọ òtítọ́ yìí ṣeni ní kàyéfì.
11 Ẹ wo hílàhílo àti ìbẹ̀rù tí àwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì ì bá ti yọ nínú rẹ̀ ká ní wọ́n ti mọ òtítọ́ Bíbélì rírọrùn pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú,” kì í ṣe pé yóò máa jìyà ní ọ̀run àpáàdì! (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun ti Kirisẹ́ńdọ̀mù fi ń kọ́ni, ó bára mu rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n sọ lábẹ́ ìmísí: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́ [nínú ìgbésí ayé yìí], nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn. Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [sàréè gbogbo aráyé], ibi tí ìwọ ń lọ.”—Oníwàásù 9:5, 10.
12. Ibo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ti rí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa àìleèkú ọkàn?
12 Èé ṣe tí Kirisẹ́ńdọ̀mù fi ń kọ́ni ní ohun tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì sọ? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, sọ nínú àpilẹ̀kọ rẹ̀, “Ọkàn, Ẹ̀dá Ènìyàn, Àìleèkú,” pé Àwọn Baba Ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí kò rí ìtìlẹyìn nínú Bíbélì fún ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn, ṣùgbọ́n wọ́n rí ìtìlẹyìn nínú “àwọn akéwì àti onímọ̀ ọgbọ́n orí àti èròǹgbà àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Gíríìkì . . . Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yàn láti máa lo ẹ̀kọ́ Plato tàbí àwọn ìlànà Aristotle.” Ó sọ pé “agbára èrò tuntun ti Plato”—títí kan ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn—wọnú “gbogbo ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Kristẹni” níkẹyìn.
13, 14. Èé ṣe tí kò fi lọ́gbọ́n nínú láti yíjú sí àwọn kèfèrí onímọ̀ ọgbọ́n orí, tí í ṣe Gíríìkì abọ̀rìṣà fún ìlàlọ́yẹ̀?
13 Ṣé ó yẹ kí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni yíjú sí àwọn kèfèrí onímọ̀ ọgbọ́n orí, tí í ṣe Gíríìkì, láti lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun kan tí ó ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ bí ìrètí ìwàláàyè lẹ́yìn ikú? Kò yẹ bẹ́ẹ̀ rárá. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí ń gbé ní Kọ́ríńtì, ni ilẹ̀ Gíríìsì, ó wí pé: “Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àlùmọ̀kọ́rọ́yí àwọn fúnra wọn.’ Àti pẹ̀lú: ‘Jèhófà mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.’” (1 Kọ́ríńtì 3:19, 20) Abọ̀rìṣà ni àwọn Gíríìkì ìgbàanì. Báwo wá ni wọ́n ṣe lè jẹ́ orísun òtítọ́? Pọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ìfohùnṣọ̀kan wo . . . ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà? Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè; gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé: ‘Èmi yóò máa gbé láàárín wọn, èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.’”—2 Kọ́ríńtì 6:16.
14 A kọ́kọ́ pèsè Ìṣípayá àwọn òtítọ́ mímọ́ nípasẹ̀ orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì. (Róòmù 3:1, 2) Lẹ́yìn ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a pèsè rẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí a fòróró yàn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ó sọ pé: “Àwa ni Ọlọ́run ti ṣí [àwọn ohun tí a pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀] payá fún nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 2:10; tún wo Ìṣípayá 1:1, 2.) Ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù nípa àìleèkú ọkàn wá láti inú ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì. A kò ṣí i payá nípasẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣí payá fún Ísírẹ́lì tàbí nípasẹ̀ ìjọ ọ̀rúndún kìíní ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró.
Ìrètí Tòótọ́ fún Àwọn Òkú
15. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti wí, kí ni ìrètí tòótọ́ fún àwọn òkú?
15 Bí kò bá sí àìleèkú ọkàn, kí wá ni ìrètí tòótọ́ fún àwọn òkú? Họ́wù, àjíǹde ni, tí í ṣe ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ àgbàyanu ìlérí àtọ̀runwá ní tòótọ́. Jésù nawọ́ ìrètí àjíǹde jáde nígbà tí ó sọ fún Màtá ojúlùmọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 11:25) Láti gba Jésù gbọ́ túmọ̀ sí gbígba àjíǹde gbọ́, kì í ṣe àìleèkú ọkàn.
16. Èé ṣe tí ó fi bọ́gbọ́n mu láti ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde?
16 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde nígbà tí ó sọ fún àwọn Júù kan pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Ohun tí Jésù ṣàlàyé níhìn-ín yàtọ̀ pátápátá sí àìleèkú ọkàn tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara ti kú, tí ó sì lọ tààrà sí ọ̀run. Ó jẹ́ ‘jíjáde wá’ ní ọjọ́ iwájú, ti àwọn ènìyàn tí ó wà ní sàréè, ọ̀pọ̀ nínú wọ́n ti wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, tàbí kódà fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún. Ó jẹ́ àwọn òkú ọkàn tí ń padà bọ̀ sí ìyè. Kò ṣeé ṣe kẹ̀? Ó ṣeé ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run “tí ń sọ òkú di ààyè, tí ó sì ń pe àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.” (Róòmù 4:17) Àwọn oníyèméjì lè fi èròǹgbà pé àwọn ènìyàn yóò padà wá láti inú òkú ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ó bára mu rẹ́gí pẹ̀lú òtítọ́ náà pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” àti pé òun ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—1 Jòhánù 4:16; Hébérù 11:6.
17. Kí ni Ọlọ́run yóò ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ àjíǹde?
17 Ó ṣe tán, báwo ni Ọlọ́run ṣe lè sẹ̀san fún àwọn tí ó jẹ́ “olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú” bí òun kò bá mú wọn padà wá sí ìyè? (Ìṣípayá 2:10) Àjíǹde tún jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti ṣe àṣeparí ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa rẹ̀: “Fún ète yìí ni a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere, èyíinì ni, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Ní ọgbà Édẹ́nì, Sátánì di ẹni tí ó pa gbogbo ìran ènìyàn nígbà tí ó mú àwọn òbí wa àkọ́kọ́ wọnú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Jòhánù 8:44) Jésù bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ àwọn iṣẹ́ Sátánì túútúú nígbà tí ó fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ṣíṣerẹ́gí, èyí tí ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún aráyé láti gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ìsìnrú ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá tí ó jẹyọ láti inú àìgbọràn tí Ádámù dìídì ṣe. (Róòmù 5:18) Àjíǹde àwọn tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù yìí yóò jẹ́ títúbọ̀ fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.
Ara àti Ọkàn
18. Kí ni ìhùwàpadà àwọn kan lára àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì sí gbólóhùn Pọ́ọ̀lù pé a ti jí Jésù dìde, èé sì ti ṣe?
18 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà ní Áténì, ó wàásù ìhìn rere fún ogunlọ́gọ̀ tí ó ní àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì nínú. Wọ́n fetí sí ìjíròrò rẹ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà àti ìkésíni rẹ̀ fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n kí ni ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e? Pọ́ọ̀lù kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀, nípa sísọ pé: “[Ọlọ́run] ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i dìde kúrò nínú òkú.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fa arukutu. “Nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹlẹ́yà.” (Ìṣe 17:22-32) Oscar Cullmann, tí í ṣe ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn, ṣàlàyé pé: “Fún àwọn Gíríìkì tí ó gba àìleèkú ọkàn gbọ́, ó lè nira gan-an fún wọn láti tẹ́wọ́ gba ìwàásù Kristẹni nípa àjíǹde ju bí ó ṣe rí fún àwọn mìíràn. . . . Ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ọgbọ́n orí bí Socrates àti Plato kò lè bá ti Májẹ̀mú Tuntun mu lọ́nàkọnà.”
19. Báwo ni àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe gbìyànjú láti mú ẹ̀kọ́ àjíǹde bá ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn mu?
19 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn ìpẹ̀yìndà ńlá tí ó wáyé lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn jà raburabu láti da ẹ̀kọ́ Kristẹni nípa àjíǹde pọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ Plato nínú àìleèkú ọkàn. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn kan gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ: Wọ́n ní nígbà tí èèyàn bá kú ọkàn rẹ̀ ni a óò yà nípa (“yóò gbòmìnira,” gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti pè é) sí ara. Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Outlines of the Doctrine of the Resurrection, láti ọwọ́ R. J. Cooke, ti wí, ní Ọjọ́ Ìdájọ́ “ara kọ̀ọ̀kan yóò tún so pọ̀ mọ́ ọkàn tirẹ̀, tí ọkàn kọ̀ọ̀kan yóò sì so mọ́ ara tirẹ̀.” Àtúnsopọ̀ ọjọ́ iwájú ti ara àti ọkàn rẹ̀ tí kò lè kú ni àwọn kan ń pè ní àjíǹde.
20, 21. Àwọn wo ni ó ti ń kọ́ni ní òtítọ́ nípa àjíǹde láìyẹsẹ̀, báwo sì ni èyí ṣe ṣe wọ́n láǹfààní?
20 Àbá èrò orí yìí ṣì ni ẹ̀kọ́ tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńláńlá fàṣẹ sí. Bí irú èrò bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ jọ pé ó bọ́gbọ́n mu lójú ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn, kò yé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì. Ìgbàgbọ́ wọn kò ju pé ọ̀run tààrà ni àwọn ń lọ bí wọ́n bá kú. Fún ìdí yìí, nínú ìtẹ̀jáde May 5, 1995, ti ìwé ìròyìn náà, Commonweal, òǹkọ̀wé náà, John Garvey là á mọ́lẹ̀ pé: “Ó jọ pé ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni [lórí ọ̀ràn ìwàláàyè lẹ́yìn ikú] fara mọ́ ẹ̀kọ́ Plato tímọ́tímọ́ ju ti ẹ̀sìn Kristẹni lọ, kò sì ní ìpìlẹ̀ kankan nínú Bíbélì.” Ká sòótọ́, nípa fífi ẹ̀kọ́ Plato rọ́pò ti Bíbélì, àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ti paná ìrètí àjíǹde tí a gbé ka Bíbélì lọ́kàn àwọn ọmọ ìjọ wọn.
21 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ ìmọ̀ ọgbọ́n orí kèfèrí, wọ́n sì rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa àjíǹde. Lójú tiwọn, irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ gbámúṣé, ó ń fini lọ́kàn balẹ̀, ó ń tuni nínú. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e, àwa yóò rí i bí ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa àjíǹde ti lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó, tí ó sì bọ́gbọ́n mu tó, fún àwọn tí ó ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé àti fún àwọn tí ó ní ìrètí àjíǹde ìyè ti ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí ara ìmúrasílẹ̀ fún àpilẹ̀kọ wọ̀nyí, a dámọ̀ràn pé kí o fara balẹ̀ ka lẹ́tà àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, orí 15.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a gbé ìgbẹ́kẹ̀lé lílágbára ró nínú àjíǹde?
◻ Ìrètí wo ni Jèhófà gbé ka iwájú Ádámù àti Éfà?
◻ Èé ṣe tí kò fi mọ́gbọ́n dání láti wá òtítọ́ lọ sínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì?
◻ Èé ṣe tí àjíǹde fi jẹ́ ìrètí tí ó lọ́gbọ́n nínú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Nígbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣẹ̀, wọ́n pàdánù ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ìgbàgbọ́ Plato nínú àìleèkú ọkàn wá nípa lórí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ inú Ṣọ́ọ̀ṣì
[Credit Line]
Musei Capitolini, Roma