Wọn Kìí Ṣe Akirità Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
“AWA ń ta iṣẹ-ojiṣẹ wa lati gba owó.” Iyẹn jẹ ọ̀rọ̀ “ojiṣẹ aládùúrà ori tẹlifoonu” kan tẹlẹri ti a fọrọwalẹnuwo ninu irohin kan ti ń ṣewadii nipa awọn ajihinrere ori tẹlifiṣọn ti America ni iha opin ọdun 1991.
Eto yii kó afiyesi jọ sori awọn ẹgbẹ-ojiṣẹ ajihinrere ori tẹlifiṣọn mẹta ni United States. O tú àṣírí pe araadọta-ọkẹ mẹwaa mẹwaa owó dollar lọdọọdun ni jìbìtì ti awọn mẹta pere yii ń lu awọn eniyan. “Ẹgbẹ-ojiṣẹ” kan ni a ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bii “ilé-iṣẹ́ ti a fi ọgbọ́n ìhùmọ̀ ode-oni gbekalẹ fun gbigba awọn ọrẹ itilẹhin.” Gbogbo wọn ni a sọ pe wọn lọwọ ninu ọpọlọpọ jìbìtì. Eyi ha ta ọ kìjí bi?
Isin Wà Labẹ Àyẹ̀wò Fínnífínní
Kìí ṣe kiki ijihinrere ori tẹlifiṣọn nikan ṣugbọn awọn isin atẹwọgba ẹkọ-isin gbogbogboo paapaa ati awọn kò-ṣeku-kò-ṣẹyẹ ni awọn ijọba, awọn ẹgbẹ aladaani ti ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lodisi ìfiṣòfò, àdánù tabi awọn iṣe alaibofinmu, ati awọn eniyan lapapọ ti ń kiyesi lọ́wọ́lẹ́sẹ̀. Ninu awọn ọ̀ràn kan awọn iwe-ẹri owó ìdókòwò tí ṣọọṣi ní, ṣiṣe ti isin ń ṣe onígbọ̀wọ́ fun ire iṣelu, ati igbesi-aye jayéjayé tí awọn ẹgbẹ alufaa ti a ń sanwo nlanla fún ń gbé ti gbe awọn ibeere dide nipa boya o yẹ ki o ri bẹẹ.
Bawo ni awọn aṣaaju isin kan ti ṣe dójú ìlà akawe ti o gbayì nipa iṣẹ-ojiṣẹ Kristian eyi ti aposteli Paulu fi funni ni nǹkan bii 2,000 ọdun sẹhin? O kọwe pe: “Awa kìí ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọrun gẹgẹ bi ọ̀pọ̀ awọn eniyan ti jẹ, ṣugbọn gẹgẹ bii nipa otitọ-inu, bẹẹ ni, bi ẹni ti a rán lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, ni iwaju Ọlọrun, ni ibakẹgbẹpọ pẹlu Kristi ni awa ń sọrọ.” (2 Korinti 2:17, NW) Ta ni o bá akawe yii mu lonii?
Lati ràn ọ́ lọwọ lati wọn awọn ọ̀ràn wò, jẹ ki a ṣe akiyesi kínníkínní nipa bi a ti ṣe bojuto ọ̀ràn inawo iṣẹ-ojiṣẹ Kristian ti Paulu ati awọn alabaakẹgbẹpọ rẹ̀. Ni ọ̀nà wo ni o gbà yatọ si ti awọn ẹlomiran ni ìgbà ayé rẹ̀?
Awọn Oniwaasu Arìnrìn-àjò ti Ọrundun Kìn-ín-ní
Gẹgẹ bi oniwaasu ti ń rìnrìn-àjò, Paulu kìí ṣe alailẹgbẹ. Ni ìgbà yẹn, ọpọ a maa mú ọ̀nà pọ̀n lati lè gbe oju-iwoye tiwọn nipa isin ati àbá èrò-orí larugẹ. Òǹkọ̀wé Bibeli naa Luku sọ nipa “awọn Ju kan alarinkiri, alẹ́mìí-èṣù-jáde.” (Iṣe 19:13) Nigba ti Jesu Kristi dẹbi fun awọn Farisi, ó fikun un pe: “Ẹyin ń yí òkun ati ilẹ̀ ká lati sọ eniyan kan di alawọṣe.” (Matteu 23:15) Jesu fúnraarẹ̀ jẹ ojiṣẹ arìnrìn-àjò. Ó kọ́ awọn aposteli rẹ̀ ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati ṣafarawe rẹ̀ nipa wiwaasu kìí ṣe ni kiki Judea ati Samaria nikan ṣugbọn “titi de opin ilẹ̀-ayé.”—Iṣe 1:8.
Nigba awọn ìrìn-àjò wọn, awọn ọmọlẹhin Jesu bá awọn oniwaasu ti kìí ṣe Ju pade. Ni Ateni, Paulu wàákò pẹlu awọn ọlọgbọn imọ-ọran ti Epikurei ati Stoiki. (Iṣe 17:18) Jakejado Ilẹ̀-ọba Romu, awọn Cynic ń lo ìyíniléròpadà nipa bíbúmọ́ni. Awọn olufọkansin fun Isis ati Serapis mu ki agbara-idari wọn gbooro sii lori awọn obinrin ati ẹrú pẹlu awọn ileri ibaradọgba niti isin ati ẹgbẹ-oun-ọgba pẹlu awọn eniyan ti o wa lominira. Awọn ẹgbẹ-imulẹ ti ìmú-irú-ọmọ jade ti iha Ila-oorun ni wọn pese ipilẹ fun ọpọlọpọ awọn isin aláwo ti ìgbà ayé Griki ati Romu. Ileri ti ṣíṣètùtù fun ẹ̀ṣẹ̀ ati ifẹ lati ṣajọpin awọn àṣírí atọrunwa pẹlu ẹni fa awọn ọmọlẹhin mọ́ra sọdọ awọn ọlọrun èké bii Demeter, Dionysus, ati Cybele.
Bawo Ni Wọn Ṣe Ń Kájú Ọ̀ràn Inawo?
Bi o ti wu ki o ri, rírin ìrìn-àjò gbówólórí. Yatọ si owó ti ẹrù, ibode, ati ìrìn ojú òkun ń náni, awọn arìnrìn-àjò nilo ounjẹ, ibugbe, igi ìdáná, aṣọ wíwọ̀, ati itọju iṣegun. Awọn oniwaasu, olukọni, ọ̀mọ̀ràn, ati aláwo maa ń yanju awọn aini wọnyi ni ọ̀nà pataki marun-un. Wọn (1) kọni fun owó ọ̀yà; (2) wá iṣẹ́ ṣe ni ṣiṣe awọn iṣẹ́ ati òwò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́; (3) tẹwọgba fifi ẹmi alejo-ṣiṣe hàn ati awọn ọrẹ àtinúwá; (4) ti araawọn mọ́ awọn babasàlẹ̀ ọlọ́lá lọrun, lọpọ ìgbà gẹgẹ bi olukọ adani wọn; ati (5) ṣagbe. Lati mura araarẹ̀ silẹ fun ìyọṣùtí, olokiki atọrọbárà onisin Cynic naa Diogenes tilẹ tọrọ agbe lọwọ awọn ère alailẹmii.
Paulu gbọ́ nipa awọn oniwaasu kan ti wọn fẹnusọ pe awọn jẹ ojiṣẹ Kristian ṣugbọn, bii ti awọn ọ̀mọ̀ràn Griki kan, wọn bá awọn ọlọ́rọ̀ dọ́rẹ̀ẹ́ wọn sì ń já nǹkan gbà lọwọ awọn talaka. Oun bá ijọ ti o wà ni Korinti wí, ni sisọ pe: “Ẹyin farada . . . bi ẹnikan bá jẹ yin run, bi ẹnikan bá gbà lọwọ yin.” (2 Korinti 11:20) Jesu Kristi kò já ohunkohun gbà, bẹẹ si ni Paulu ati awọn alabaaṣiṣẹpọ rẹ̀ kò ṣe bẹẹ. Ṣugbọn awọn ajihinrere oniwọra ti Korinti jẹ “awọn èké Aposteli, awọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn,” ati iranṣẹ Satani.—2 Korinti 11:13-15.
Awọn itọni Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣèdíwọ́ fun kikọni fun owó ọ̀yà. “Ọ̀fẹ́ ni ẹyin gbà, ọ̀fẹ́ ni ki ẹ fi funni,” ni oun funni nimọran. (Matteu 10:8) Bi o tilẹ jẹ pe titọrọ bárà wọ́pọ̀, a fi oju àbùkù wò ó ni ọjọ wọnni. Ninu ọ̀kan lara awọn àkàwé rẹ̀, Jesu fi ẹrú kan hàn pe o ń wi pe, “lati ṣagbe oju ń tì mi.” (Luku 16:3) Nitori eyi, kò si ibi ti a ti ríi ninu awọn ìtàn Bibeli rara pe awọn ọmọlẹhin Jesu oluṣotitọ ń tọrọ owó tabi awọn ohun eelo. Wọn gbe ni ibamu pẹlu ilana yii: “Bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun.”—2 Tessalonika 3:10.
Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ niṣiiri lati yanju awọn aini wọn ní awọn ọ̀nà meji. Lakọọkọ, wọn lè, gẹgẹ bi Paulu ti ṣe sọ ọ, “maa jẹ nipa ihinrere.” Bawo? Nipa titẹwọgba ẹmi ifẹ alejo ti a finnufindọ fihàn síni. (1 Korinti 9:14; Luku 10:7) Ekeji, wọn lè pese fun araawọn nipa ti ara.—Luku 22:36.
Awọn Ilana ti Paulu Múlò
Bawo ni Paulu ṣe lo awọn ilana ti a ṣẹṣẹ mẹnukan tán yii? O dara, nipa ti ìrìn-àjò ijihin-iṣẹ Ọlọrun ẹlẹẹkeji ti aposteli naa, Luku kọwe pe: “Awa ṣíkọ̀ ni Troasi a ba ọ̀nà tàrà lọ si Samotrakea, ni ijọ keji a si de Neapoli; lati ibẹ awa si lọ si Filippi, tii ṣe ilu Makedonia, olu-ilu iha ibẹ̀, ilu labẹ Romani: awa si jokoo ni ilu yii fun ijọ melookan.” Gbogbo ìrìn-àjò, ounjẹ, ati ibi àgbàwọ̀ ti o ní ninu ni a bojuto lati ọwọ́ awọn runraawọn.—Iṣe 16:11, 12.
Lẹhin-ọ-rẹhin, obinrin kan ti a pe orukọ rẹ̀ ni Lidia “fetisi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ. Nigba ti a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ilé rẹ̀, o bẹ̀ wa, wi pe, bi ẹyin ba kà mi ni oloootọ si Oluwa, ẹ wá si ilé mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ. O si rọ̀ wa.” (Iṣe 16:13-15) Boya o kere tan lapakan nititori ifẹ alejo ti Lidia, ni Paulu fi lè kọwe si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ ni Filippi pe: “Mo ń dupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigba gbogbo ti mo ba ranti yin ninu gbogbo ẹ̀bẹ̀ mi fun gbogbo yin, bi mo ti ń fi ìdùnnú-ńlá gba àdúrà-ẹ̀bẹ̀ mi, nitori iranlọwọ-itilẹhin ti ẹ ti ṣe fun ihinrere lati ọjọ́ kìn-ìn-ní titi di ìṣẹ́jú yii.”—Filippi 1:3-5, NW.
Luku tọkasi ọpọlọpọ awọn ọ̀ràn iṣẹlẹ nipa awọn eniyan tí ń tẹwọgba awọn Kristian òṣìṣẹ́ arìnrìn-àjò wọnyi. (Iṣe 16:33, 34; 17:7; 21:7, 8, 16; 28:2, 7, 10, 14) Ninu awọn lẹta onimiisi rẹ̀, Paulu jẹwọ o si dupẹ fun ẹmi alejo ati awọn ẹ̀bùn tí oun ti gbà. (Romu 16:23; 2 Korinti 11:9; Galatia 4:13, 14; Filippi 4:15-18) Sibẹ, kò si eyikeyii ninu oun tabi awọn alabaakẹgbẹ rẹ̀ ti o tanilólobó pe a nilati fun awọn ní àwọn ẹbun tabi itilẹhin ninu ọ̀ràn inawo. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè sọ pe iṣarasihuwa didara yii ni a ṣì lè rí laaarin awọn alaboojuto arìnrìn-àjò wọn.
Kò Gbarale Ẹmi Alejo-ṣiṣe
Paulu kò gbarale ẹmi alejo-ṣiṣe. Oun ti kọ́ iṣẹ́ kan ti o beere fun iṣẹ́ alagbara ati akoko gigun ṣugbọn ti o mu owó-ọ̀yà táṣẹ́rẹ́ wọle. Nigba ti aposteli naa de Korinti gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ Ọlọrun, “O sì rí Ju kan ti a ń pè ni Akuila . . . pẹlu Priskilla aya rẹ̀ . . . o si tọ̀ wọn wá. Ati itori tii ṣe oniṣẹ ọnà kan-naa, o bá wọn jokoo, o si ń ṣiṣẹ: nitori àgọ́ pípa ni iṣẹ ọnà wọn.”—Iṣe 18:1-3.
Lẹhin naa, ni Efesu, Paulu ṣì jẹ́ aláápọn lẹnu iṣẹ́. (Fiwe Iṣe 20:34; 1 Korinti 4:11, 12.) Oun ti le mọ nipa fifi cilicium ṣiṣẹ daradara, ohun eelo awọ-ewúrẹ́, ti ko fi bẹẹ dán lara ti o ti agbegbe ilu ibilẹ rẹ̀ wá. A le foju inu wo Paulu ti o jokoo sori àtàpó, ni bibẹrẹ mọ́ ori ijokoo gbọọrọ ti o fi ń ṣiṣẹ, ti o ń gé ti o si ń rán awọ titi di ọ̀gánjọ́ òru. Niwọn bi ariwo ilé-iṣẹ́ ti mọ níwọ̀n, ni mimu ki o rọrun lati sọrọ bi iṣẹ́-òpò ti ń lọ lọwọ, Paulu le ti ni anfaani naa lati jẹrii fun onile-iṣẹ, awọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, ẹrú, oníbàárà, ati ọ̀rẹ́.—Fiwe Tessalonika 2:9.
Ojihin-iṣẹ Ọlọrun naa Paulu kọ̀ lati fi iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ ṣòwò tabi funni ní òye ti pe oun ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fun gbígbọ́ bùkátà araarẹ̀. Ó sọ fun awọn ara Tessalonika pe: “Ẹyin tikaraayin mọ̀ bi o ti yẹ ki ẹyin naa farawe wa: nitori awa kò rìn ségesège laaarin yin; bẹẹni awa kò si jẹ ounjẹ ẹnikẹni lọfẹẹ; ṣugbọn ninu aápọn ati làálàá ni a ń ṣiṣẹ lọsan-an ati loru, ki awa ki o má baa [dẹrupa] ẹnikẹni ninu yin: kìí ṣe pe awa kò ni agbara, ṣugbọn awa ń fi araawa ṣe apẹẹrẹ fun yin ki ẹyin ki o lè maa farawe wa.”—2 Tessalonika 3:7-9.
Awọn Alafarawe ti Ọrundun Lọna Ogun
Titi di oni yii awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹle apẹẹrẹ daradara ti Paulu. Awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kìí gba owó oṣù tabi koda owó àpò-àlùfáà lọwọ awọn ijọ ti wọn ń ṣiṣẹsin. Kaka bẹẹ wọn ń pese fun awọn idile wọn gẹgẹ bi olukuluku ti ń ṣe, eyi ti o pọ̀jù ninu wọn nipa wíwá iṣẹ́ ṣe. Awọn ojiṣẹ aṣaaju-ọna alakooko kikun bakan naa ń pese fun araawọn, ti pupọ wọn ń ṣiṣẹ kiki ki o ṣá ti tó lati kaju awọn aini ṣiṣekoko. Lọdọọdun awọn Ẹlẹ́rìí kan ń rìnrìn-àjò ni fifunraawọn bojuto inawo araawọn lati waasu ihinrere ni awọn agbegbe ti o jìnnà ti o jẹ́ pe lẹẹkan lọ́gbọ̀n ni a ń mú ihinrere lọ sibẹ. Bi awọn idile adugbo ba fun wọn ni ikesini lati ṣajọpin ninu ounjẹ tabi ibugbe, wọn ń mọriri eyi ṣugbọn wọn kìí ṣi iru ẹmi alejo-ṣiṣe bẹẹ lò.
Gbogbo wiwaasu ati kikọni tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe jẹ afinnufindọ ṣe, wọn kìí sìí beere pe ki a sanwó fun iṣẹ-ojiṣẹ wọn. Bi o ti wu ki o ri, awọn ọ̀rẹ́ ti o wà niwọntunwọnsi ti a fi ń ṣetilẹhin fun iṣẹ́ iwaasu wọn kari-aye ni a ń tẹwọgba ti a si ń fi ranṣẹ si Watch Tower Society fun ète yẹn. (Matteu 24:14) Iṣẹ-ojiṣẹ ti awọn Ẹlẹ́rìí kìí ṣe ti ìṣòwò lọnakọna. Bii ti Paulu olukuluku wọn le fi tootọtootọ sọ pe: “Mo ti waasu ihinrere Ọlọrun fun yin lọfẹẹ.” (2 Korinti 11:7) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí ṣe “akirità ọ̀rọ̀ Ọlọrun.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
BI AWỌN KAN ṢE Ń ṢE ITILẸHIN FUN IṢẸ IJỌBA NAA
◻ AWỌN ỌRẸ FUN IṢẸ YÍKÁ-AYÉ: Ọpọlọpọ ya iye kan sọtọ tabi ṣeto iye owó kan ti wọn ń fi sinu awọn apoti ọrẹ ti a lẹ isọfunni naa: “Awọn Ọrẹ fun Iṣẹ Society Yíka-aye’—Matteu 24:14” mọ́ lara. Loṣooṣu ni ijọ ń fi awọn owó wọnyi ranṣẹ yala si orílé-iṣẹ́ agbaye ni Brooklyn, New York, tabi si ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ti o sunmọ wọn julọ.
◻ AWỌN Ẹ̀BÙN: Awọn itọrẹ owó ti a fínnúfíndọ̀ ṣe ni a lè fi ranṣẹ ni taarata si Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201, tabi si ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ adugbo ti Society. Okuta iyebiye ti a fi ń ṣẹ̀ṣọ́ tabi awọn nǹkan iyebiye miiran ni a lè fi tọrẹ pẹlu. Lẹta ṣoki kan ti o sọ pe iru eyi jẹ́ ẹbun patapata nilati bá awọn ọrẹ wọnyi rìn.
◻ IṢETO ÌTỌRẸ ONIPO AFILELẸ: Owó ni a lè fifun Watch Tower Society lati maa lò bii ohun afunniṣọ titi fi di ìgbà iku olutọrẹ naa, pẹlu ipese pe ti ọ̀ràn ìlò ara-ẹni kan bá dide, a o da a pada fun ẹni ti o fi tọrẹ.
◻ OWÓ ÌBÁNIGBÓFÒ: Watch Tower Society ni a lè darukọ gẹgẹ bi olujanfaani ilana eto ìbánigbófò iwalaaye tabi ninu ìwéwèé owó asanfunni fun ifẹhinti lẹnu iṣẹ́. Society ni a gbọdọ fi iru awọn iṣeto bẹẹ tó leti.
◻ AWỌN OWÓ AFIPAMỌ SI BANKI: Awọn owó afipamọ si Banki, awọn iwe ẹ̀rí owó idokowo, tabi owó ifẹhinti lẹnu iṣẹ ẹnikọọkan ti a fi pamọ ni a lè fi sikaawọ tabi mu ki o ṣee san nigba iku fun Watch Tower Society, ni ibamu pẹlu awọn ohun abeere fun ti banki adugbo naa. Society ni a gbọdọ fi iru awọn iṣeto bẹẹ tó leti.
◻ AWỌN IWE Ẹ̀TỌ̀ LORI OWÓ IDOKOWO ATI IWE Ẹ̀TỌ̀ LORI OWÓ TI A FI YÁNI: Awọn iwe ẹ̀tọ́ lori owó idokowo ati iwe ẹ̀tọ́ lori owó ti a fi yáni ni a lè fi tọrẹ fun Watch Tower Society yala gẹgẹ bi ẹbun patapata kan tabi labẹ iṣeto kan nibi ti a o ti maa baa lọ ni sisan owó ti o wọle wá lori eyi fun olutọrẹ naa.
◻ ILÉ TABI ILẸ̀: Awọn ilé tabi ilẹ̀ ti o ṣeétà ni a lè fi tọrẹ fun Watch Tower Society yala nipa ṣiṣe e ni ẹbun patapata kan tabi nipa pipa a mọ gẹgẹ bi ohun-ìní olutọrẹ naa nigba ti o bá ṣì walaaye, ẹni ti o ṣì lè maa baa lọ lati gbe ninu rẹ̀ nigba ayé rẹ̀. Ẹni kan nilati kàn si Society ṣaaju fifi iwe aṣẹ sọ ilé tabi ilẹ̀ eyikeyii di ti Society.
◻ AWỌN IWE ÌHÁGÚN ATI OHUN-ÌNÍ ÌFISÍKÀÁWỌ́: Dúkìá tabi owó ni a lè fisilẹ bí ogún fun Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania nipasẹ iwe ìhágún ti a muṣẹ labẹ ofin, tabi ti a lè darukọ Society gẹgẹ olujanfaani iru iwe adehun fifi ohun-ìní síkàáwọ́ ẹni bẹẹ. Awọn ohun-ìní ìfisíkàáwọ́ tí eto-ajọ isin kan ń janfaani ninu rẹ̀ le pese awọn anfaani melookan ninu ọ̀ràn owó ori. Ẹ̀dà kan ninu iwe ìhágún tabi iwe ohun-ìní ìfisíkàáwọ́ ni a nilati fi ranṣẹ si Society.
Fun isọfunni siwaju sii nipa awọn koko ọ̀ràn bẹẹ, kọwe si Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society, P.M.B. 1090 Benin City, Edo State. Nigeria.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ó FẸ́ LATI ṢERANLỌWỌ
TIFFANY ọmọ ọdun 11 jẹ ọdọmọbinrin ọmọ ile-ẹkọ kan ni Baton Rouge, Louisiana, U.S.A. Laipẹ yii, ọdọ Ẹlẹ́rìí Jehofa yii kọ àròkọ kan lori akori naa “Ẹkọ-iwe ni America.” Ni iyọrisi eyi, awọn òbí rẹ̀ Ẹlẹ́rìí gba lẹta yii lati ọdọ olukọni àgbà ile-ẹkọ rẹ̀ pe:
“Lakooko ọ̀sẹ̀ Ẹkọ-iwe ni America, àròkọ kan ti o tayọ julọ lati ọ̀dọ̀ kilaasi ile-ẹkọ kọọkan ni a kà lori ẹ̀rọ ibanisọrọ. Mo layọ lati lo àròkọ ti Tiffany láàárọ̀ yii. Oun jẹ ọdọmọdebinrin kan ti o ṣàrà-ọ̀tọ̀ nitootọ. Oun jẹ ẹni ti ara rẹ̀ balẹ̀, ti ó dá ara rẹ̀ loju, ẹlẹ́bùn àrà-ọ̀tọ̀, ti o sì ṣènìyàn. Mo fẹrẹẹ má tíì rí ọmọ kilaasi keji ni ile-ẹkọ alakọọkọbẹrẹ ti o ni iru awọn animọ ti o pọ tó iwọnyi. Tiffany jẹ aṣeyebiye kan fun ile-ẹkọ wa.”
Tiffany gba ipò akọkọ ninu idije àròkọ naa. Lẹhin naa oun wá kọwe si Watch Tower Society o si wi pe: “Boya mo wulẹ gbẹyẹ ninu idije naa nititori itẹjade naa Questions Young People Ask—Answers That Work. . . . Mo lo awọn akori ọ̀rọ̀ lori ẹkọ́-ìwé. . . . Ẹ ṣun pupọ fun titẹ iwe wiwulo ati afúnni-lókun yii jade. Niti gbigbẹyẹ ti mo gbẹyẹ ninu àròkọ, mo gba ẹbun owó dollar meje. Emi ń fi dollar 7 yii ṣetọre ati 13 sii, ti o papọ jẹ 20 dollar fun iṣẹ́ iwaasu kari-aye naa. . . . Nigba ti mo bá dagba, mo ni ireti lati yọnda araami fun iṣẹ-isin ni Beteli pẹlu.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nigba miiran, Paulu ń gbọ́ bukata araarẹ̀ nipa pípa àgọ́