Ìsìn Kristẹni Dé Éṣíà Kékeré
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ ìjọ Kristẹni ń gbèrú ní Éṣíà Kékeré, tí apá tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ jẹ́ ara orílẹ̀-èdè Turkey òde òní. Ìdí táwọn ìjọ náà sì fi ń gbèrú ni pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti Kèfèrí kọbi ara sí ìhìn rere táwọn Kristẹni ń wàásù. Ìwé kan tó ń túmọ̀ èdè Bíbélì sọ pé: “Tá a bá yọwọ́ ilẹ̀ Síríà mọ́ ilẹ̀ Palẹ́sínì, Éṣíà Kékeré tún ni ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni ti kọ́kọ́ wáyé, tí ìjọ Kristẹni sì ti gbilẹ̀.”
Ká lè túbọ̀ mọ bí ìsìn Kristẹni ṣe dèyí tó gbilẹ̀ ní Éṣíà Kékeré, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí onírúurú ìwé sọ nípa rẹ̀, ká sì wo bá a ṣe lè jàǹfààní nínú àkọsílẹ̀ wọn.
Àwọn Ará Éṣíà Kékeré Tó Kọ́kọ́ Di Kristẹni
Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì àkọ́kọ́ nínú ìtàn bí ìsìn Kristẹni ṣe gbilẹ̀ ní Éṣíà Kékeré wáyé lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Lọ́jọ́ yẹn, àwọn àpọ́sítélì Jésù wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń sọ onírúurú èdè tí wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù. Lára wọn ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé lájò (ìyẹn àwọn Júù tí wọn ò gbé nílẹ̀ Palẹ́sìnì) àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù. Ìtàn Bíbélì sọ fún wa pé àwọn kan lára wọn wá láti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àgbègbè Éṣíà,a Fíríjíà àti Panfílíà. Àwọn ibi tá a dárúkọ yìí sì jẹ́ apá tó pọ̀ gan-an nínú Éṣíà Kékeré. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lára àwọn tó kóra jọ náà ló gba ìwàásù àwọn àpọ́sítélì Jésù gbọ́ tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Wọ́n wá padà sí Éṣíà Kékeré tàwọn ti ìsìn Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà yẹn.—Ìṣe 2:5-11, 41.
Àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìrìn àjò tí Pọ́ọ̀lù rìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì tún jẹ́ ká mọ bí ìsìn Kristẹni ṣe dé Éṣíà Kékeré. Nígbà ìrìn àjò rẹ̀ àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ọdún 47 sí 48 Sànmánì Kristẹni, ọkọ̀ òkun lòun àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò wọ̀ lọ sí Éṣíà Kékeré láti Kípírọ́sì, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí Pẹ́gà ní Panfílíà. Nígbà tí wọ́n dé ìlú Áńtíókù ní Písídíà, àwọn Júù tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wọn, wọ́n sì tún ń ta kò wọ́n nítorí àṣeyọrí iṣẹ́ ìwàásù wọn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì kúrò níbẹ̀ lọ sí Íkóníónì lápá gúúsù ìwọ̀ oòrùn, àwọn Júù tó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbìmọ̀ pọ̀ láti hùwà àfojúdi sí wọn. Nígbà tí wọ́n sì dé Lísírà, ńṣe làwọn èèyàn kan kọ́kọ́ ń polongo pé òrìṣà ni Pọ́ọ̀lù nítorí iṣẹ́ àrà tí wọ́n rí. Àmọ́ nígbà táwọn Júù alátakò dé láti Áńtíókù àti Íkóníónì, wọ́n yí àwọn èèyàn náà lọ́kàn padà débi táwọn yẹn fi sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta títí tí wọ́n fi rò pé ó ti kú. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí Déébè tó wà ní Gálátíà tí í ṣe àgbègbè kan lábẹ́ ilẹ̀ ọba Róòmù, táwọn èèyàn ibẹ̀ ń sọ èdè Likaóníà. Wọ́n ṣètò àwọn ìjọ wọ́n sì yan àwọn alàgbà. Èyí fi hàn pé ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìsìn Kristẹni ti fìdí múlẹ̀ dáadáa ní Éṣíà Kékeré.—Ìṣe 13:13–14:26.
Nígbà ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù ẹlẹ́ẹ̀kejì ní nǹkan bí ọdún 49 sí 52 Sànmánì Kristẹni, Lísírà lòun àtàwọn tí wọ́n bá a rìn kọ́kọ́ lọ. Wọn ò gba orí omi lọ́tẹ̀ yìí, ojú títì ni wọ́n gbà, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gba ìlú Pọ́ọ̀lù, ìyẹn Tásù tó wà ní Sìlíṣíà, kọjá. Lẹ́yìn tí wọ́n ti bẹ àwọn ará tó wà ní Lísírà wò lẹ́ẹ̀kejì tí wọ́n sì lọ sí apá àríwá, Pọ́ọ̀lù gbìyànjú láti ‘sọ ọ̀rọ̀ náà’ ní àgbègbè Bítíníà àti Éṣíà. Àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ ò gbà á láyè nítorí pé àkókò kò tíì tó láti wàásù níbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run darí rẹ̀ lọ sí ìlú Tíróásì tó wà létíkun lápá àríwá ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan pé kó lọ wàásù ìhìn rere ní ilẹ̀ Yúróòpù.—Ìṣe 16:1-12; 22:3.
Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì Pọ́ọ̀lù ẹlẹ́ẹ̀kẹta ní nǹkan bí ọdún 52 sí 56 Sànmánì Kristẹni, ó tún lọ sí Éṣíà Kékeré. Ó dé Éfésù tó jẹ́ ìlú etíkun pàtàkì kan ní Éṣíà. Ó dúró díẹ̀ ní Éfésù yìí nígbà tó ń padà bọ̀ láti ìrìn àjò rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì. Àwọn Kristẹni wà níbẹ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, nǹkan bí ọdún mẹ́ta sì ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n bá a rìnrìn àjò lò lọ́dọ̀ wọn nígbà ìrìn àjò rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta yìí. Láàárín àkókò yìí, ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ewu ni wọ́n là kọjá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà nílùú Éfésù dá rúkèrúdò kan sílẹ̀ nítorí pé wọn ò fẹ́ kí nǹkan kan ṣàkóbá fún iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọ́n máa ń tà lówó gọbọi fáwọn abọ̀rìṣà.—Ìṣe 18:19-26; 19:1, 8-41; 20:31.
Ó hàn gbangba pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí Pọ́ọ̀lù ṣe ní àkókò tó lò ní Éfésù yìí ṣe àwọn ibòmíì láǹfààní. Ìṣe 19:10 sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń gbé àgbègbè Éṣíà . . . gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì.”
Ìtẹ̀síwájú Bá Ìsìn Kristẹni ní Éṣíà Kékeré
Nígbà tó kù díẹ̀ kí Pọ́ọ̀lù kúrò ní Éfésù, ó kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Àwọn ìjọ Éṣíà kí yín.” (1 Kọ́ríńtì 16:19) Àwọn ìjọ wo ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara wọn ni àwọn ìjọ tó wà ní Kólósè, Laodíkíà àti Hirapólísì. (Kólósè 4:12-16) Ìwé náà, Paul—His Story [Ìtàn Nípa Ìgbésí Ayé Pọ́ọ̀lù], sọ pé: “Ó bọ́gbọ́n mu téèyàn bá gbà pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó wà ní Éfésù ló bí àwọn ìjọ tó wà ní Símínà, Págámù, Sádísì àti Filadẹ́fíà. . . . Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ìlú yìí tó jìnnà ju igba ó dín mẹ́jọ [192] kìlómítà lọ sí Éfésù, ọ̀nà tó dáa gan-an ló sì so gbogbo wọn pọ̀.”
Èyí fi hàn pé ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìjọ Kristẹni tó pọ̀ díẹ̀ ti wà ní apá gúúsù àti ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré. Àwọn apá ibi tó kù ní Éṣíà Kékeré ńkọ́?
Àwọn Tí Pétérù Kọ Lẹ́tà Sí
Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ìyẹn láàárín ọdún 62 sí 64 Sànmánì Kristẹni, ni àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run mí sí. Ó kọ ọ́ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà, Éṣíà àti Bítíníà. Lẹ́tà tó kọ yẹn fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ìjọ wà ní àwọn àgbègbè yìí, torí ó gba àwọn alàgbà wọn níyànjú pé kí wọ́n “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo.” Ìgbà wo ni wọ́n dá àwọn ìjọ náà sílẹ̀?—1 Pétérù 1:1; 5:1-3.
Pọ́ọ̀lù ti wàásù láwọn àgbègbè bí Éṣíà àti Gálátíà kí Pétérù tó kọ lẹ́tà ránṣẹ́ sí wọn. Àmọ́ kò wàásù ní Kapadókíà àti Bítíníà. Bíbélì ò sọ bí ìsìn Kristẹni ṣe dé àwọn ibi méjèèjì yìí, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà táwọn Júù tàbí àwọn aláwọ̀ṣe Júù tí wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni padà lọ síbẹ̀ ni wọ́n mú ìsìn Kristẹni débẹ̀. Lọ́rọ̀ kan ṣá, nígbà tí Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ó jọ pé ìjọ ti “wà káàkiri Éṣíà Kékeré,” gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ.
Ìjọ Méje Inú Ìwé Ìṣípayá
Ọ̀tẹ̀ táwọn Júù ṣe sáwọn ará Róòmù ló jẹ́ kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí mú káwọn Kristẹni kan ní Jùdíà lọ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní Éṣíà Kékeré.b
Nígbà tí ọ̀rúndún kìíní ń parí lọ, Jésù Kristi tipasẹ̀ àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé sí ìjọ méje ní Éṣíà Kékeré. Àwọn ìjọ náà ni Éfésù, Símínà, Págámù, Tíátírà, Sádísì, Filadẹ́fíà àti Laodíkíà. Àwọn ìwé tó kọ sáwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà Kékeré yìí fi hàn pé lákòókò yẹn, onírúurú nǹkan ló jẹ́ ewu fáwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀, irú bí ìṣekúṣe, ẹ̀ya ìsìn àti ìpẹ̀yìndà.—Ìṣípayá 1:9, 11; 2:14, 15, 20.
Díẹ̀ La Mọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù Tí Wọ́n Fi Tọkàntọkàn Ṣe
Ó dájú pé kì í ṣe àwọn ibi tá a kà nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì nìkan ni ìsìn Kristẹni tàn kálẹ̀ dé ní ọ̀rúndún kìíní. Àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ló ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tá a kà nínú ìwé Ìṣe. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn míì tá ò mọ̀ ń wàásù láwọn ibòmíì nígbà yẹn. Ìtẹ̀síwájú tó wáyé ní Éṣíà Kékeré fi hàn dájúdájú pé àwọn Kristẹni tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mátíù 28:19, 20.
Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn o. Ìwọ̀nba díẹ̀ lára iṣẹ́ Ọlọ́run táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ń ṣe ló máa ń hàn sí gbogbo ẹgbẹ́ ará wa tó kárí ayé. Bó ṣe rí fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó fi tọkàntọkàn wàásù ní Éṣíà Kékeré ní ọ̀rúndún kìíní náà ló ṣe rí fún ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń wàásù lónìí. Àwọn míì wà tá ò tiẹ̀ gbórúkọ wọn rárá. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó jẹ́ iṣẹ́ aláyọ̀, inú wọn sì ń dùn gan-an pé àwọ́n ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run nípa ṣíṣiṣẹ́ takuntakun láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà.—1 Tímótì 2:3-6.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ibi tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì àti àpilẹ̀kọ yìí pè ní “Éṣíà” ni apá ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré tó wà lábẹ́ ilẹ̀ ọba Róòmù láyé ọjọ́un, kì í ṣe ilẹ̀ ńlá Éṣíà tá a mọ̀ lóde òní, tó ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nínú.
b Òpìtàn Eusebius (tó gbé láyé lọ́dún 260 sí 340 Sànmánì Kristẹni) sọ pé ní àkókò díẹ̀ ṣáájú ọdún 66 Sànmánì Kristẹni, “àwọn àpọ́sítélì ní láti kúrò ní Jùdíà nítorí pé ìgbà gbogbo lẹ̀mí wọn máa ń wà nínú ewu látàrí bí wọ́n ṣe ń gbìmọ̀ pọ̀ láti pa wọ́n. Àmọ́ lọ́lá agbára Kristi, wọ́n ń lọ sí gbogbo ìlú káàkiri láti máa wàásù ìhìn rere.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
ÌSÌN KRISTẸNI ÌJÍMÌJÍ NÍ BÍTÍNÍÀ ÀTI PỌ́ŃTÙ
Bítíníà àti Pọ́ńtù jẹ́ àgbègbè kan ní Etíkun Òkun Dúdú ní Éṣíà Kékeré. Ìwé tí Pliny Kékeré tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ àgbègbè náà kọ sí Trajan tí í ṣe olú ọba ilẹ̀ Róòmù jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àwọn èèyàn tó ń gbé lágbègbè yìí.
Nǹkan bí àádọ́ta [50] ọdún lẹ́yìn tí ìwé tí Pétérù kọ ti lọ káàkiri gbogbo ìjọ tó wà lágbègbè yìí ni Pliny ní kí Trajan gba òun nímọ̀ràn nípa bóun ṣe máa ṣe ọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni sí. Ó kọ̀wé sí Trajan pé: “Mi ò tíì lọ síbi tí àwọn Kristẹni ti ń jẹ́jọ́ rí. Nítorí náà, mi ò mọ bí ìyà tí wọ́n fi ń jẹ wọ́n ṣe pọ̀ tó.” Ó tún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára wọn lọ́kùnrin lóbìnrin, láti onírúurú ipò àti ọjọ́ orí, ni wọ́n ń mú lọ jẹ́jọ́, ó sì ṣeé ṣe kéyìí máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Àwọn ìlú ńlá nìkan kọ́ ni ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí ń kéèràn ràn o, wọ́n tún ń kéèràn ran àwọn abúlé àtàwọn ìgbèríko pẹ̀lú.”
[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÌRÌN ÀJÒ PỌ́Ọ̀LÙ
Ìrìn Àjò Míṣọ́nnárì Àkọ́kọ́
KÍPÍRỌ́SÌ
PANFÍLÍÀ
Pẹ́gà
Áńtíókù (ti Písídíà)
Íkóníónì
Lísírà
Déébè
Ìrìn Àjò Míṣọ́nnárì Ẹlẹ́ẹ̀kejì
SÌLÍṢÍÀ
Tásù
Déébè
Lísírà
Íkóníónì
Áńtíókù (ti Písídíà)
FÍRÍJÍÀ
GÁLÁTÍÀ
Tíróásì
Ìrìn Àjò Míṣọ́nnárì Ẹlẹ́ẹ̀kẹta
SÌLÍṢÍÀ
Tásù
Déébè
Lísírà
Íkóníónì
Áńtíókù (ti Písídíà)
Éfésù
ÉṢÍÀ
Tíróásì
[Ìjọ méje]
Págámù
Tíátírà
Sádísì
Símínà
Éfésù
Filadẹ́fíà
Laodíkíà
[Àwọn ibi mìíràn]
Hirapólísì
Kólósè
LÍKÍÀ
BÍTÍNÍÀ
PỌ́ŃTÙ
KAPADÓKÍÀ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Áńtíókù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Tíróásì
[Credit Line]
© 2003 BiblePlaces.com
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Gbọ̀ngàn Ìwòran ní Éfésù.—Ìṣe 19:29
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Apá ìsàlẹ̀ pẹpẹ Súúsì ní Págámù. Àwọn Kristẹni ìlú náà ń gbé “níbi tí Sátánì ń gbé.”—Ìṣípayá 2:13
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.