Ẹ Maa Kọni ni Gbangba ati Lati Ile De Ile
“Emi ko súnrakì lati . . . maa kọ yin ni gbangba ati lati ile de ile.”—IṢE 20:20, “Byington.”
1. Bawo ni alufaa Katolik kan ṣe lohunsi igbeṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile awọn Ẹlẹrii Jehofa?
“AWỌN Katolik Nmu Ihinrere Lọ Lati Ile de Ile.” Bẹẹni akọle kan ninu The Providence Sunday Journal ti October 4, 1987 ṣe ka. Iwe-irohin naa rohin pe olori ete igbokegbodo yii ni lati “kesi awọn ọmọ ijọ wọn alaiṣiṣẹmọ lati pada si igbesi-aye onitara ninu ijọ.” Alufaa John Allard, oludari Ọfiisi fun Ihinrere ni Agbegbe Abẹ-aṣẹ Biṣọọbu ti Ọlọrun-olupese, ni a fa ọrọ rẹ yọ pe: “Dajudaju, ẹmi iyemeji pupọ yoo nilati wa. Awọn eniyan yoo wipe, ‘Ẹ wo bi wọn ṣe nlọ, gan-an bi awọn Ẹlẹrii Jehofa.’ Ṣugbọn awọn Ẹlẹrii Jehofa gbeṣẹ, abi bẹẹkọ? O da mi lójú pe ẹyin le lọ sinu Gbọngan Ijọba ni ipinlẹ [ti Rhode Island, U.S.A.,] ki ẹ si ri awọn ijọ ti wọn kun fun awọn Katolik tẹlẹri.”
2. Ibeere wo ni a gbe dide lọna yiyẹ?
2 Bẹẹni, awọn Ẹlẹrii Jehofa ni a mọ daradara fun iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile gbigbeṣẹ wọn. Ṣugbọn eeṣe ti wọn fi nlọ lati ile de ile?
Ọ̀nà tí awọn Apọsteli Ngba Ṣe É
3. (a) Iṣẹ-aṣẹ wo ni Jesu Kristi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ? (b) Ni ọna pataki wo ni awọn ọmọlẹhin Kristi ijimiji gba mu iṣẹ-aṣẹ wọn ṣẹ?
3 Jesu Kristi fun awọn ọmọlẹhin rẹ ni iṣẹ-aṣẹ ti o kun fun itumọ yii: “Nitorinaa ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ sì maa baptisi wọn ni orukọ Baba, ati niti Ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW], ati niti Ẹmi Mimọ: ki ẹ maa kọ wọn lati maa kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa ni aṣẹ fun yin: ẹ si kiyesi, emi wa pẹlu yin nigbagbogbo, titi o fi de opin aye.” (Matiu 28:19, 20) Ọ̀nà pataki kan ti a o fi ma ṣe iṣẹ naa wa ṣe kedere kete lẹhin ọjọ Pentecost 33 C.E. “Ni ojoojumọ ninu tẹmpili ati lati ile de ile wọn nbaalọ laiṣaarẹ ni kikọni ati ni pipolongo ihinrere nipa Kristi, Jesu.” (Iṣe 5:42, NW) Nnkan bii 20 ọdun lẹhin naa, apọsteli Pọọlu nlọwọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile, nitori oun rán awọn alagba Kristian lati ilu Efesu leti pe: “Emi ko fasẹhin kuro ninu sisọ fun yin eyikeyii ninu awọn nnkan naa ti o lere tabi kikọ yin ni gbangba ati lati ile de ile.”—Iṣe 20:20, NW.
4. Eeṣe ti a fi le sọ pe Iṣe 5:42 ati Iṣe 20:20 tumọsi pe iwaasu awọn ọmọlẹhin Jesu ni a pinkiri lati ile de ile?
4 Ni Iṣe 5:42 awọn ọ̀rọ̀ naa “lati ile de ile” ni a tumọ lati inu kat’ oiʹkon. Nihin-in ka·taʹ ni a lò ni ero-itumọ ti “ipinkiri.” Fun idi yii, iwaasu awọn ọmọ-ẹhin naa ni a pinkiri lati ile kan si omiran. Ni lilohunsi ọrọ lori Iṣe 20:20, Randolph O. Yeager kọwe pe Pọọlu kọni “ni gbangba awọn apejọ fun gbogbo eniyan [de·mo·siʹa] ati lati ile de ile ([ka·taʹ] ti ipinkiri eyi ti o ni ọrọ ti ọrọ-iṣe nṣiṣẹ lelori taarata). Pọọlu ti lo ọdun mẹta ni Efesu. Oun ṣebẹwo si gbogbo ile, tabi o keretan oun waasu fun gbogbo awọn eniyan (ẹsẹ-iwe 26). Òté-ọlá-àṣẹ ti o ba iwe mimọ mu niyi fun ijihinrere lati ile de ile ati eyi ti a nṣe ni ipade fun gbogbo eniyan.”
5. Ni Iṣe 20:20, eeṣe ti Pọọlu ko fi tọka kiki si ikesini ẹgbẹ oun ọgba sọdọ awọn alagba tabi kiki si ibẹwo oluṣọ-agutan?
5 Ìlò ka·taʹ ti o ba eyi dọ́gba farahan ni Luku 8:1 (NW), ti o sọrọ nipa iwaasu Jesu “lati ilu de ilu ati lati abule de abule.” Pọọlu lo kat’ oiʹkous ti o jẹ ọlọrọ isọdipupọ ni Iṣe 20:20. Nihin-in awọn itumọ Bibeli kan kà pe “ninu awọn ile yin.” Ṣugbọn apọsteli naa kò tọkasi ikesini ẹgbẹ-oun-ọgba sọdọ awọn alagba tabi awọn ibẹwo oluṣọ agutan sinu ile awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni. Awọn ọrọ rẹ ti o tẹle e fihan pe oun nsọrọ nipa iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile laaarin awọn alaigbagbọ nitori oun wipe: “Ṣugbọn mo jẹrii jalẹjalẹ fun awọn Júù ati awọn Giriiki nipa ironupiwada si Ọlọrun ati igbagbọ ninu Jesu Oluwa wa.” (Iṣe 20:21, NW) Awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni ti ronupiwada ṣaaju wọn si ti mu igbagbọ lò ninu Jesu. Fun idi yii, Iṣe 5:42 ati Iṣe 20:20 niiṣe pẹlu wiwaasu fun awọn alaigbagbọ “lati ile de ile,” tabi lati ẹnu ọna de ẹnu ọna.
Ko Si Àfidípò fun Un
6. Kinni a ti sọ nipa bi iṣẹ iwaasu Pọọlu ni Efesu ṣe ri?
6 Nigba ti o nṣalaye lori awọn ọrọ Pọọlu ni Iṣe 20:20, ni 1844 Abiel Abbot Livermore kọwe pe: “Oun kò ni itẹlọrun kiki lati funni ni awiye ninu apejọ fun gbogbo eniyan, ki o sì ka awọn ohun amulo miiran si alaiwulo, ṣugbọn oun fi titaratitara ba iṣẹ titobi rẹ niṣo ni ikọkọ, ati lati ile de ile, o si gbe otitọ atọrunwa naa wa si ile ni taarata, si ilé ati ọkan-aya awọn ará Efesu.” Lẹnu aipẹ yii, a ti ṣakiyesi pe: “Titan ihinrere kalẹ lati ile de ile jẹ animọ ti o fi awọn Kristian ọrundun kin-inni han yatọ lati ibẹrẹ (fiwe Iṣe 2:46; 5:42). . . . [Pọọlu] ti mu ẹru-iṣẹ rẹ fun awọn Júù ati Keferi ni Efesu ṣẹ jalẹjalẹ, a si fi wọn silẹ laini awawi bi wọn ba ṣègbé ninu awọn ẹṣẹ wọn.”—The Wesleyan Bible Commentary, Idipọ 4, oju-iwe 642-3.
7. Eeṣe ti a fi le sọ pe Ọlọrun fọwọsi iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile awọn Ẹlẹrii Jehofa?
7 Bi o tilẹ jẹ pe sisọrọ ní itagbangba ní ipo tirẹ ninu pipolongo ihinrere naa, kii ṣe afidipo fun biba awọn eniyan pade lojukoju ni ẹnu ọna. Nipa eyi, ọmọwe akẹkọọgboye naa Joseph Addison Alexander wipe: “Ṣọọṣi ko tii humọ ohunkohun sibẹ lati fi dipo tabi figagbaga pẹlu ipa ti iwaasu ńní ninu ṣọọṣi ati agbo ile.” Gẹgẹbi ọmọwe akẹkọọgboye O. A. Hills ti sọ ọ: “Ikọnilẹkọọ ni gbangba ati ikọnilẹkọọ lati ile-de-ile gbọdọ lọ ni ifẹgbẹkẹgbẹ.” Awọn Ẹlẹrii Jehofa npese itọni nipasẹ awọn awiye ni awọn Ipade Fun Gbogbo Eniyan lọsọọsẹ. Wọn tun ni ẹri ti o ṣe kedere pẹlu pe ọna ti awọn apọsteli ngba lati tan otitọ Bibeli kalẹ lati ile de ile gbeṣẹ. Jehofa si fọwọsi i dajudaju, nitori gẹgẹbi iyọrisi iru iṣẹ ojiṣẹ bẹẹ, oun nmu ki ẹgbẹẹgbẹrun maa rọ́ gìrọ́gìrọ́ wọnú ijọsin rẹ ti a gbega lọdọọdun.—Aisaya 2:1-4; 60:8, 22.
8. (a) Kinni a ti sọ nipa idi ti iwaasu ile-de-ile fi gbeṣẹ? (b) Bawo ni a ṣe le fi awọn Ẹlẹrii Jehofa we Pọọlu ninu iwaasu ẹnu ọna ati ijẹrii miiran?
8 Orisun ọla-aṣẹ miiran ti wipe: “Awọn eniyan rii pe o rọrun lati ranti ikọnilẹkọọ ni ẹnu ọna ilé wọn ju ti inu ṣọọṣi lọ.” O dara, Pọọlu maa nlọ si awọn ẹnu ọna deedee, ni fifi apẹẹrẹ rere lelẹ gẹgẹbi ojiṣẹ kan. “Oun ko nitẹẹlọrun pẹlu kikọni ati fifunni ni awiye ninu sinagọgu ati ni ọja,” ni ọmọwe akẹkọọgboye ninu Bibeli Edwin W. Rice kọwe. “Oun jẹ alaapọn nigbagbogbo ninu ‘kikọni’ ‘lati ile de ile.’ Ijakadi pẹlu bilisi lati ile-de-ile, ọwọ-de-ọwọ, ojú-ko-ojú, ni oun jà ni Efesu, lati jere awọn eniyan fun Kristi.” Awọn Ẹlẹrii Jehofa mọdaju pe awọn ijiroro laaarin ẹnikan ati ẹnikeji lẹnu ọ̀nà gbeṣẹ. Ju bẹẹ lọ, wọn nṣe awọn ipadabẹwo wọn si layọ lati ba awọn alatako sọrọ paapaa bi awọn ẹni wọnyi yoo ba yọnda fun awọn ijiroro ọlọgbọn-ninu. Ẹ wo bi o ti dabii ti Pọọlu to! Nipa rẹ, F. N. Peloubet kọwe pe: “Gbogbo iṣẹ Pọọlu kii ṣe ninu awọn ipade nikanṣoṣo. Ko si iyemeji pe oun bẹ ọpọlọpọ eniyan wo lẹnikọọkan ninu ile wọn nibikibi ti oun ba mọ pe ẹnikan nfẹ lati mọ̀ sii, tabi fifẹhan gidigidi tabi ti o tilẹ jẹ alatako paapaa bi o ba di ti sísọ̀rọ̀ nipa isin.”
Awọn Alagba lati Mu Ipo Iwaju
9. Apẹẹrẹ wo ni Pọọlu filelẹ fun awọn alagba ẹlẹgbẹ rẹ̀?
9 Apẹẹrẹ wo ni Pọọlu filelẹ fun awọn alagba ẹlẹgbẹ rẹ̀? Oun fihan pe wọn nilati jẹ alaiṣojo ati alaiṣaarẹ olupokiki ihinrere naa lati ile-de-ile. Ni 1879, J. Glentworth Butler kọwe pe: “[Awọn alagba Efesu] mọ pe ninu iwaasu [Pọọlu] ironu ewu si araarẹ̀ tabi jijẹ gbajumọ ko nipalori rẹ pín-ìnpín-ìn; pe oun ko fawọ ohunkohun sẹhin ninu otitọ ti a nilo; pe oun ko fi pẹlu iṣegbe sọrọ lọ titi lori apakan lara awọn otitọ ṣiṣajeji tabi eyi ti a kò gbọ rí, ṣugbọn oun ti gbaniniyanju nipa kiki ati gbogbo ohun ti o lérè ninu ‘ti a le lo lati laniloye,’ tabi gbeniro: gbogbo imọran Ọlọrun lẹkun-unrẹrẹ ati laini àbùlà! ‘Ifihan’ olotiitọ yii, ‘kikọni’ ni otitọ Kristian pẹlu igbona-ọkan yii si ti wá di aṣa rẹ, kii ṣe kiki ni ile-ẹkọ Tirannu ati ni awọn ibi miiran ti awọn ọmọ-ẹhin ti maa nkorajọpọ, ṣugbọn ni gbogbo agbo-ile ti o ṣee de. Lati ile de ile, ati lati ọkan de ọkan, ọjọ de ọjọ ni oun nmu làbárè alayọ lọ kaakiri pẹlu ifẹ-ọkan ati ìyánhànhàn bii ti Kristi. Si gbogbo ẹgbẹ ati iran, si awọn Júù alailẹmi ọrẹ ati Giriiki afiniṣẹsin, ẹṣin-ọrọ rẹ kanṣoṣo—eyi ti o jẹ pe, bi a ba ladii rẹ lẹkunrẹrẹ, o ni gbogbo awọn otitọ agbanila ṣiṣekoko miiran—ni ironupiwada siha ọdọ Ọlọrun, ati igbagbọ siha ọdọ Oluwa wa Jesu Kristi.”
10, 11. (a) Nipa iṣẹ-ojiṣẹ Kristian, kinni Pọọlu fojusọna fun lati ọdọ awọn alagba Efesu? (b) Bi Pọọlu, ninu iru ijẹrii wo ni awọn Ẹlẹrii Jehofa, papọ pẹlu awọn alagba, nlọwọ ninu rẹ?
10 Niti gidi, nigba naa, kinni Pọọlu reti lọdọ awọn alagba ni Efesu? Ọmọwe akẹkọọjinlẹ E. S. Young tún awọn ọrọ apọsteli naa sọ lọrọ miiran lọna yii: “Emi ko sọrọ ni itagbangba nikan, ṣugbọn mo ṣe làálàá lati ile de ile, pẹlu ẹgbẹ awọn eniyan gbogbo, ati awọn Júù ati Keferi. Ẹṣin-ọrọ iṣẹ-ojiṣẹ mi fun ẹgbẹ awọn eniyan gbogbo ni ‘ironupiwada siha ọdọ Ọlọrun ati igbagbọ ninu Oluwa wa Jesu Kristi.’” Ni sisọ awọn ọrọ Pọọlu lọna miiran, W. B. Riley kọwe pe: “Itumọ ṣiṣekedere naa ni pe: ‘Mo fojusọna pe ki ẹyin maa ba nnkan ti mo bẹrẹ lọ, lati maa ṣe e ati lati kọni, mo si reti pe ki ẹ durotiiri gẹgẹbi emi ti durotiiri; lati kọni ni ikọkọ ati ni gbangba gẹgẹ bi mo ti ṣe ni awọn opopo ọna ati lati ile de ile, lati jẹrii bakan naa fun awọn Júù ati fun awọn Giriiki ironupiwada siha ọdọ Ọlọrun ati igbagbọ siha ọdọ Oluwa wa Jesu Kristi, nitori iwọnyi ni awọn ohun ṣiṣekoko!’”
11 Ni kedere, ninu Iṣe ori 20, Pọọlu nfihan awọn alagba ẹlẹgbẹ rẹ pe a fojusọna pe ki wọn jẹ awọn Ẹlẹrii Jehofa lati ile-de-ile. Ni ọna yii, awọn alagba ọ̀rúndún kìn-ínní ni wọn nilati mu ipo iwaju, ni fifi apẹẹrẹ titọna lelẹ fun awọn mẹmba ijọ miiran. (Fiwe Heberu 13:17.) Nigba naa, bii ti Pọọlu, awọn Ẹlẹrii Jehofa nwaasu lati ile de ile, ni sisọ fun awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede nipa Ijọba Ọlọrun, ironupiwada siha ọdọ Rẹ, ati igbagbọ ninu Jesu Kristi. (Maaku 13:10; Luku 24:45-48) Ati ninu iru iṣẹ ile-de-ile bẹẹ, awọn alagba ti a yansipo laaarin awọn Ẹlẹrii ti òde-òní ni a reti pe ki wọn mu ipo iwaju.—Iṣe 20:28.
12. Kinni awọn alagba kan kọ̀ lati ṣe, ṣugbọn ninu kinni awọn alagba ti mu ipo iwaju lonii?
12 Ní 1879, Charles Taze Russell bẹrẹsii tẹ Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence, ti a npe ni Ilé-ìṣọ́nà Ti Ńṣèfilọ̀ Ijọba Jehofa nisinsinyi. Russell ati awọn Akẹkọọ Bibeli miiran polongo ihin-iṣẹ Ijọba naa ni ọna tí awọn apọsteli ngba ṣe e. Bi o ti wu ki o ri, ni awọn ọdun lẹhin igba naa, awọn alagba ijọ kan kò doju ìlà ẹru iṣẹ wọn lati jẹrii. Fun apẹẹrẹ, Ẹlẹrii kan kọwe: “Gbogbo nnkan nlọ deedee titi di igba tí ifilọ naa pe ki gbogbo eniyan maa kopa ninu jijẹrii lati ile-de-ile pẹlu iwe ikẹkọọ ati ni pataki iṣẹ ile-de-ile ni ọjọ Sunday—eyi ṣẹlẹ ni 1927. Awọn alagba wa ti a dìbòyàn ṣatako wọn si gbiyanju lati ko irẹwẹsi ba gbogbo ẹgbẹ naa lati maṣe bẹrẹ tabi lọwọ ninu apa eyikeyii lara iru iṣẹ bẹẹ.” Laipẹ, awọn ọkunrin ti wọn kò lọwọ ninu wiwaasu lati ile-de-ile ni wọn ko lanfaani lati ṣiṣẹsin gẹgẹbi alagba mọ́. Lonii, pẹlu, awọn wọnni ti wọn nṣiṣẹsin gẹgẹbi alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ni a reti pe ki wọn mu ipo iwaju ninu jijẹrii lati ile-de-ile ati iru iṣẹ-ojiṣẹ Kristian miiran.
Olukuluku Eniyan jẹ Ẹlẹrii
13. (a) Kinni a nilati ṣe ani bi awọn eniyan ko ba fetisilẹ si ihin-iṣẹ Ijọba naa? (b) Bawo ni a ṣe fi Pọọlu wera pẹlu Esekiẹli?
13 Pẹlu iranlọwọ Jehofa, awọn Kristian nilati polongo ihinrere Ijọba naa lati ile de ile, ani bi a kò bá tilẹ tẹwọgba a pẹlu imọriri paapaa. Gẹgẹbi ẹṣọkunrin Ọlọrun, Esekiẹli nilati kilọ fun awọn eniyan yala wọn fetisilẹ tabi bẹẹkọ. (Esekiẹli 2:5-7; 3:11, 27; 33:1-6) Ni fifa ibaradọgba yọ laaarin Esekiẹli ati Pọọlu, E. M. Blaiklock kọwe pe: “Lati inu [ọrọ-asọye Pọọlu ninu Iṣe ori-iwe 20] aworan ṣiṣekedere nipa iṣẹ-ojiṣẹ ni Efesu wa di mímọ̀. Ṣakiyesi ohun ti o tẹle e: Lakọọkọ, iṣotitọ onikanjukanju ti Pọọlu. Oun kò wá igbajumọ tabi jijẹ ẹni ti gbogbo eniyan tẹwọgba. O muratan bii Esekiẹli fun iṣẹ́ takuntakun ti jijẹ ẹṣọkunrin, oun mu iṣẹ́ rẹ ṣe pẹlu itara ati ọna iwa alailabosi lati ti ọrọ sisọ rẹ lẹhin. Ekeji, ibanikẹdun onifẹẹ rẹ. Oun kii ṣe ẹni ti ngbẹnu le awọn ọrọ àgbákò iparun laini ero imọlara. Ẹkẹta, iṣẹ ijihinrere aláìṣàárẹ̀ rẹ̀. Ni gbangba ati lati ile de ile, ninu ilu ati jakejado gbogbo àgbègbè naa, oun ti waasu ihinrere naa.”
14. Eeṣe ti ijẹrii fi jẹ ẹru-iṣẹ olukuluku ẹni ti o ti ṣe iyasimimọ si Jehofa Ọlọrun ninu adura nipasẹ Jesu Kristi?
14 Ọpọ yanturu ibukun Ọlọrun lori awọn iranṣẹ rẹ ti ode oni ko fi iyemeji eyikeyii silẹ pe oun nitẹẹlọrun lati jẹ ki wọn ni orukọ naa Ẹlẹrii Jehofa. (Aisaya 43:10-12) Yatọ si eyi, wọn jẹ ẹlẹrii Jesu pẹlu, nitori Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ pe: “Ẹyin yoo gba agbara, nigba ti ẹmi mimọ bá bà le yin: ẹ o si maa ṣe ẹlẹrii mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ-aye.” (Iṣe 1:8) Nitori naa jijẹrii jẹ ẹru-iṣẹ olukuluku eniyan ti o ṣe iyasimimọ si Jehofa Ọlọrun ninu adura nipasẹ Jesu Kristi.
15. Kinni a ti sọ nipa iṣẹ ijẹrii awọn Kristian ijimiji?
15 A ti sọ nipa ijẹrii pe: “O mu gbogbo ṣọọṣi lọwọ lodidi. Akitiyan ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ti ṣọọṣi ijimiji kii ṣe ẹru-iṣẹ ti Ẹgbẹ-awujọ Awọn Obinrin Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun tabi ti Igbimọ-abojuto Iranniniṣẹ si Ilẹ Ajeji. Bẹẹ si ni a ko fi iṣẹ ijẹrii silẹ fun awọn alefiṣiṣẹṣe bii awọn alagba, diakoni, tabi awọn apọsteli paapaa. . . . Ni awọn ọjọ ijimiji wọnni ṣọọṣi jẹ ile-iṣẹ Ọlọrun. Itolẹsẹẹsẹ ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ti ṣọọṣi ijimiji ni a gbekari ero ìtànmọ́ọ̀ meji: (1) Olori iṣẹ takuntakun ṣọọṣi ni sisọ ihinrere kari aye. (2) Ẹru-iṣẹ fun mimu iṣẹ takuntakun yii ṣe sinmilori gbogbo awujọ Kristian lodidi.”—J. Herbert Kane.
16. Ani awọn onkọwe Kristendom paapaa gba kinni nipa awọn Kristian ati ijẹrii?
16 Bi o tilẹ jẹ pe awọn onkọwe ode-oni ninu Kristendom ko fohunṣọkan pẹlu ihin iṣẹ Ijọba naa, awọn kan gba pe awọn Kristian ni iṣẹ aigbọdọmaṣe lati jẹrii. Fun apẹẹrẹ, ninu iwe naa Everyone a Minister, Oscar E. Feucht ṣakiyesi pe: “Ko si pastor kankan ti o le mu iṣẹ ojiṣẹ tí Ọlọrun fifun onigbagbọ kọọkan ṣẹ. Lọna ti o banininujẹ ironu akunfun iṣina fun ọpọ ọrundun ninu ṣọọṣi ti mu iṣẹ 500 awọn ara ṣọọṣi di iṣẹ pastor kanṣoṣo. Ko ri bẹẹ ninu ṣọọṣi ijimiji. Awọn ti wọn gbagbọ lọ sibi gbogbo lati waasu Ọ̀rọ̀ naa.”
17. Kinni a le sọ nipa ipo ti ijẹrii ní ninu igbesi-aye awọn Kristian ijimiji?
17 Jijẹrii ni o ṣaaju julọ ninu igbesi-aye awọn Kristian ijimiji, ani bi o ti ri laaarin awọn eniyan Jehofa lonii. Edward Caldwell Moore ti Harvard University kọwe pe: “Ki a sọ ọ gan-an bi o ṣe jẹ, itara ọkan nlanla fun titan igbagbọ kalẹ jẹ ohun ti a fi mọ ẹgbẹ́ Kristian ni ọrundun mẹta akọkọ. Ìgbónára Kristian jẹ fun iṣẹ ihinrere, sisọ ihin iṣẹ itunrapada. . . . Bi o ti wu ki o ri, ni akoko ijimiji lọhun-un, itankalẹ agbara idari ati awọn ẹkọ Jesu jẹ iṣẹ awọn ọkunrin ti o yẹ ki a pe ni awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ṣugbọn ni ìwọ̀n kekere. O jẹ aṣeyọri awọn eniyan lati inu gbogbo ẹgbẹ iṣowo ati iṣẹ ọwọ ati lati inu gbogbo eto ẹgbẹ awujọ. Aṣiri igbesi aye ti o tubọ jinlẹ, ẹmi ironu titun siha aye ni [wọn] gbe lọ si ibi ti o jinna julọ ninu ilẹ-ọba [Romu], eyi ti o jẹ igbala ninu iriri wọn. . . . [Isin-Kristian ijimiji] gbagbọ daju lọna jijinlẹ nipa opin eto-aye isinsinyi tí nsunmọtosi. O gbagbọ ninu idasilẹ eto-aye titun kan lojiji ati lọna iyanu.”
18. Ireti titobilọla wo ni o fi pupọpupọ tayọ àlá awọn aṣaaju oṣelu?
18 Ninu ijẹrii ile-de-ile ati awọn oriṣi iṣẹ-ojiṣẹ wọn miiran, awọn Ẹlẹrii Jehofa nfi tayọtayọ dari awọn olugbọ wọn taarata si aye titun tí Ọlọrun ti ṣeleri. Awọn ibukun rẹ ti iwalaaye ailopin ti a sọtẹlẹ fi pupọpupọ tayọ àlá àfọkànfẹ́ julọ ti awọn wọnni ti wọn fẹ lati kọ́ eto aye titun kan loni. (2 Peteru 3:13; Iṣipaya 21:1-4) Bi o tilẹ jẹ pe yoo dabi pe olukuluku yoo fẹ lati walaaye ninu aye titun agbayanu ti Ọlọrun, ọran ko ri bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹ jẹ ki a gbe awọn ọna gbigbeṣẹ diẹ yẹwo tẹle e ninu eyi ti awọn iranṣẹ Jehofa le kọ́ awọn wọnni ti wọn nwa ọna iye ayeraye.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ti Dahunpada
◻ Eeṣe ti a fi le wipe Iṣe 5:42 ati Iṣe 20:20 tumọsi pe awọn ọmọlẹhin Jesu nilati waasu lati ile de ile?
◻ Bawo ni a ṣe mọ pe Ọlọrun fọwọsi iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile awọn Ẹlẹrii Jehofa?
◻ Nipa iṣẹ-ojiṣẹ naa, kinni a beere lọwọ awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ?
◻ Ijẹrii nilati ni ipo wo ninu igbesi aye Kristian kan?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ni 33 C.E., awọn ọmọ-ẹhin Jesu jẹrii lati ile de ile laiṣaarẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Pọọlu kọ́ni “lati ile de ile.” Oriṣi iṣẹ-ojiṣẹ yii ni awọn Ẹlẹrii Jehofa nṣe lonii