-
“Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
11. Kí làwọn alàgbà sọ pé kí Pọ́ọ̀lù ṣe, àmọ́ kí ló dájú pé Pọ́ọ̀lù ò ní fọwọ́ sí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àhesọ táwọn èèyàn yẹn sọ kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ò tíì tán lọ́kàn àwọn Júù tó di Kristẹni náà. Èyí ló mú kí àwọn alàgbà náà sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ọkùnrin mẹ́rin wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. Mú àwọn ọkùnrin yìí dání, kí o wẹ ara rẹ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin, kí o sì bójú tó ìnáwó wọn, kí wọ́n lè fá orí wọn. Nígbà náà, gbogbo èèyàn á mọ̀ pé kò sí òótọ́ kankan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ tí wọ́n ń gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ pé ò ń rìn létòlétò àti pé ìwọ náà ń pa Òfin mọ́.”c—Ìṣe 21:23, 24.
12. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun ò rin kinkin mọ́ èrò òun, tó sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù?
12 Pọ́ọ̀lù lè sọ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ àhesọ tí wọ́n sọ nípa òun ló fa wàhálà, pé àwọn Júù tó di onígbàgbọ́ yẹn gan-an ni, torí pé wọ́n rin kinkin mọ́ Òfin Mósè. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù gbà láti ṣe ohun táwọn alàgbà yẹn sọ torí kò ta ko ìlànà Ọlọ́run. Ó ti kọ́kọ́ kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Nítorí àwọn tó wà lábẹ́ òfin, mo dà bí ẹni tó wà lábẹ́ òfin, bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ò sí lábẹ́ òfin, kí n lè jèrè àwọn tó wà lábẹ́ òfin.” (1 Kọ́r. 9:20) Torí náà, Pọ́ọ̀lù gbà láti ṣe ohun táwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ní kó ṣe, èyí sì mú kó dà bí “ẹni tó wà lábẹ́ òfin.” Àpẹẹrẹ rere lohun tó ṣe yìí jẹ́ fún wa lónìí, káwa náà máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, ká má máa sọ pé èrò tiwa nìkan ló tọ̀nà.—Héb. 13:17.
-
-
“Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
c Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àwọn ọkùnrin náà ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì. (Nọ́ń. 6:1-21) Òótọ́ ni pé Òfin Mósè tó ní káwọn èèyàn máa jẹ́ irú ẹ̀jẹ́ yìí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ronú pé kò sóhun tó burú nínú káwọn ọkùnrin yẹn mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ fún Jèhófà ṣẹ. Torí náà, kò sóhun tó burú bí Pọ́ọ̀lù ṣe bójú tó ìnáwó wọn tó sì tẹ̀ lé wọn. A ò mọ irú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ gan-an, àmọ́ èyí ó wù kó jẹ́, kò dájú pé Pọ́ọ̀lù á fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fi ẹran rúbọ sí Jèhófà (báwọn Násírì ti máa ń ṣe), torí wọ́n gbà gbọ́ pé ìyẹn á wẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn mọ́. Ẹbọ pípé tí Kristi fi ara rẹ̀ rú ti fòpin sírú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ táwọn èèyàn fi ń ṣètùtù. Ohun yòówù kí Pọ́ọ̀lù ṣe, ó dájú pé kò ní gbà láti ṣe ohunkóhun tó lè kó bá ẹ̀rí ọkàn ẹ̀.
-