Ẹ Máa Bọlá Fún Àwọn Tó Ní Ọlá Àṣẹ Lórí Yín
“Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ máa fi ọlá fún ọba.”—1 PÉTÉRÙ 2:17.
1, 2. Ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo àwọn aláṣẹ lóde òní? Èé ṣe?
ÌYÁ kan kédàárò pé: “Ohun tó wu àwọn ọmọ ni wọ́n ń ṣe. Kò sí ọ̀wọ̀ kankan fún òbí mọ́.” Bébà kan tí wọ́n ń lẹ̀ mọ́ nǹkan sọ pé: “Má Gba Gbẹ̀rẹ́ fún Àwọn Aláṣẹ.” Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ méjì lára ọ̀pọ̀ ojú ìwòye tó ń tọ́ka sí ipò kan tó yẹ kóo mọ̀ pé ó ti gbilẹ̀ báyìí. Àìbọ̀wọ̀ fún àwọn òbí, àwọn olùkọ́, àwọn agbanisíṣẹ́, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ti di ohun tó gbòde kan káàkiri ayé.
2 Àwọn kan wulẹ̀ lè sọ èjìká, kí wọ́n sọ pé, ‘Àgunlá, àwọn tó wà nípò àṣẹ kò ṣe ohun tó lè mú mi bọ̀wọ̀ fún wọn.’ Irú ọ̀rọ̀ yẹn lè ṣòroó já ní koro nígbà mìíràn. Ọ̀pọ̀ ìròyìn la máa ń gbọ́ nípa àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó ń hùwà ìbàjẹ́, àwọn agbanisíṣẹ́ tó jẹ́ jẹgúdújẹrá, àwọn olùkọ́ tí kò tóótun, àti àwọn òbí aṣeniléṣe. Inú wa dùn pé ṣàṣà làwọn Kristẹni tó ń fi irú ojú kan náà wo àwọn tó wà ní ipò àṣẹ nínú ìjọ.—Mátíù 24:45-47.
3, 4. Èé ṣe tó fi yẹ káwọn Kristẹni bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà ní ipò àṣẹ?
3 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ní “ìdí tí ń múni lọ́ràn-anyàn” láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ nínú ayé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú láti “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Róòmù 13:1, 2, 5; 1 Pétérù 2:13-15) Pọ́ọ̀lù tún fi hàn bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti ṣègbọràn sí ọlá àṣẹ tó wà nínú ìdílé, ó ní: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.” (Kólósè 3:18, 20) Ó yẹ kí a máa bọlá fún àwọn alàgbà ìjọ, nítorí pé ‘ẹ̀mí mímọ́ ti yàn wọ́n ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.’ (Ìṣe 20:28) Ọ̀wọ̀ táa ní fún Jèhófà ló ń mú ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ènìyàn tó jẹ́ aláṣẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí, bíbọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ Jèhófà ló máa ń gba ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa.—Ìṣe 5:29.
4 Ẹ jẹ́ kó wà lọ́kàn wa digbí pé ọlá àṣẹ gíga ti Jèhófà ò lẹ́gbẹ́, ká wá gbé àpẹẹrẹ àwọn kan tí ò bọlá fáwọn tó wà nípò àṣẹ yẹ̀ wò àti àwọn kan tó bọlá fún wọn.
Ìwà Àìlọ́wọ̀ Ń Yọrí sí Àìrí Ìtẹ́wọ́gbà
5. Ìwà àìlọ́wọ̀ wo ni Míkálì hù sí Dáfídì, kí sì ni ìyẹn yọrí sí?
5 A lè tinú ìtàn Dáfídì Ọba mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn tí wọ́n fojú tín-ínrín ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fúnni. Nígbà tí Dáfídì ní kí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì gbé e dé, Míkálì, ìyàwó rẹ̀ “rí Dáfídì Ọba tí ń fò sókè, tí ó sì ń jó yí ká níwájú Jèhófà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Ó yẹ kí Míkálì mọ̀ pé kì í ṣe pé Dáfídì jẹ́ olórí ìdílé nìkan ni, àmọ́ pé òun tún ni ọba ilẹ̀ náà. Síbẹ̀, ó fi tẹ̀gàntẹ̀gàn sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde pé: “Ẹ wo bí ọba Ísírẹ́lì ti ṣe ara rẹ̀ lógo tó lónìí nígbà tí ó tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò lónìí ní ojú àwọn ẹrúbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn akúrí ṣe ń tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò pátápátá!” Àbájáde ohun tó ṣe yìí ni pé Míkálì kò bímọ.—2 Sámúẹ́lì 6:14-23.
6. Ojú wo ní Jèhófà fi wo ìwà àìlọ́wọ̀ tí Kórà hù sí àwọn ẹni àmì òróró Rẹ̀?
6 Àpẹẹrẹ kan tó yọyẹ́ lórí ọ̀ràn àìbọlá fáwọn tí Ọlọ́run yàn sípò olórí nínú ètò ìṣàkóso rẹ̀ ni tí Kórà. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Kóhátì, ẹ wo àǹfààní ńlá tó ń gbádùn nípa sísin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn! Síbẹ̀síbẹ̀, ó ń fẹ̀sùn kan Mósè àti Áárónì, ìyẹn àwọn tí Ọlọ́run yàn ṣe olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kórà lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn ìjòyè mìíràn ní Ísírẹ́lì, ó ṣàyà gbàǹgbà, ó sì sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Gbogbo àpéjọ ni ó jẹ́ mímọ́ ní àtòkèdélẹ̀ wọn, Jèhófà sì wà ní àárín wọn. Kí wá ni ìdí tí ẹ fi gbé ara yín sókè lórí ìjọ Jèhófà?” Ojú wo ni Jèhófà fi wo ẹ̀mí tí Kórà àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ fi hàn? Ọlọ́run wo ìwà wọn bí ẹni pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ni wọ́n tàbùkù sí. Lẹ́yìn tí wọ́n fojú ara wọn rí i tí ilẹ̀ lanu tó gbé gbogbo àwọn tó wà ní ìhà ọ̀dọ̀ wọn mì tán ni iná láti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá pa Kórà àti àwọn àádọ́ta-lérúgba [250] ìjòyè náà run.—Númérì 16:1-3, 28-35.
7. Ǹjẹ́ “àwọn àpọ́sítélì adárarégèé” ní ìdí kankan láti bẹnu àtẹ́ lu ọlá àṣẹ Pọ́ọ̀lù?
7 Nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan wà níbẹ̀ tí wọn ò ka ọlá àṣẹ àtọ̀runwá sí. “Àwọn àpọ́sítélì adárarégèé” nínú ìjọ Kọ́ríńtì hu ìwà àìlọ́wọ̀ sí Pọ́ọ̀lù. Wọ́n bẹnu àtẹ́ lu bó ṣe ń sọ̀rọ̀, wọ́n ní: “Wíwàníhìn-ín òun alára jẹ́ aláìlera, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ní láárí.” (2 Kọ́ríńtì 10:10; 11:5) Yálà Pọ́ọ̀lù mọ ọ̀rọ̀ sọ tàbí kò mọ̀ ọ́n sọ, ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ àpọ́sítélì tó jẹ́ wọ̀ ọ́. Àmọ́, ṣé lóòótọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ò ní láárí ni? Àwọn àwíyé rẹ̀ táa kọ sínú Bíbélì fi hàn pé sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó lè yíni lérò padà ni. Họ́wù, ìjíròrò ráńpẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní pẹ̀lú Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì, tó jẹ́ “ògbógi nínú gbogbo . . . àwọn àríyànjiyàn tó ń lọ láàárín àwọn Júù,” ló mú kí ọba náà sọ pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni”! (Ìṣe 13:15-43; 17:22-34; 26:1-28) Síbẹ̀, ẹni yìí làwọn àpọ́sítélì adárarégèé ní Kọ́ríńtì sọ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní láárí! Ojú wo ni Jèhófà fi wo ìṣarasíhùwà wọn? Nínú iṣẹ́ kan tí Jésù Kristi rán sí àwọn alábòójútó tó wà nínú ìjọ Éfésù, ó kan sáárá sí àwọn tí wọn kò jẹ́ kí àwọn ‘tí wọ́n sọ pé àpọ́sítélì ni àwọn, ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀,’ fà wọ́n lọ.—Ìṣípayá 2:2.
Ọ̀wọ̀ Láìka Àìpé Sí
8. Báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí Jèhófà fún Sọ́ọ̀lù?
8 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ la rí nínú Bíbélì nípa àwọn tó bọlá fún àwọn aláṣẹ, kódà nígbà tí àwọn aláṣẹ wọ̀nyẹn ṣi ọlá àṣẹ wọn lò tàbí tí wọ́n lò ó nílòkulò pàápàá. Dáfídì jẹ́ ọ̀kan lára irú àpẹẹrẹ rere bẹ́ẹ̀. Sọ́ọ̀lù Ọba, tí Dáfídì ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí jowú àwọn àṣeyọrí rẹ̀, ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á. (1 Sámúẹ́lì 18:8-12; 19:9-11; 23:26) Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí àyè ṣí sílẹ̀ láti pa Sọ́ọ̀lù, Dáfídì sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, láti na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Jèhófà!” (1 Sámúẹ́lì 24:3-6; 26:7-13) Dáfídì mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù jẹ̀bi, ṣùgbọ́n ó fi í sílẹ̀ fún Jèhófà láti dá a lẹ́jọ́. (1 Sámúẹ́lì 24:12, 15; 26:22-24) Kò sọ̀rọ̀ Sọ́ọ̀lù láìdáa, bẹ́ẹ̀ sì ni kò bú u.
9. (a) Báwo ló ṣe rí lára Dáfídì nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń gbógun tì í? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ ni Dáfídì ní fún Sọ́ọ̀lù?
9 Ǹjẹ́ Dáfídì dààmú nígbà tí wọ́n ń gbógun tì í? Dáfídì ké gbàjarè sí Jèhófà pé: ‘Àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ wà tí ń wá ọkàn mi.’ (Sáàmù 54:3) Ó tú ọkàn-àyà rẹ̀ jáde sí Jèhófà pé: “Dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, ìwọ Ọlọ́run mi. . . . Àwọn alágbára gbéjà kò mí, láìsí ìdìtẹ̀ kankan níhà ọ̀dọ̀ mi, tàbí ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí níhà ọ̀dọ̀ mi, Jèhófà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìṣìnà kankan, wọ́n sáré, wọ́n sì múra sílẹ̀. Ta jí sí pípè mi, kí o sì rí i.” (Sáàmù 59:1-4) Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí—tí ẹnì kan tó jẹ́ aláṣẹ ò jẹ́ kóo rímú mí, láìṣẹ̀ láìrò? Dáfídì ò yéé bọlá fún Sọ́ọ̀lù. Kódà nígbà tí Sọ́ọ̀lù kú, kàkà tí ì bá fi máa fò fáyọ̀, orin arò ni Dáfídì kọ pé: “Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì, àwọn ẹni fífẹ́ àti ẹni gbígbádùnmọ́ni . . . Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n jẹ́ alágbára ńlá ju kìnnìún lọ. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì, ẹ sunkún lórí Sọ́ọ̀lù.” (2 Sámúẹ́lì 1:23, 24) Ẹ wo àpẹẹrẹ àtàtà tí èyí jẹ́ ní fífi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún ẹni àmì òróró Jèhófà, nígbà tó sì jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ló ṣàìdáa sí Dáfídì!
10. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ ní bíbọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún ẹgbẹ́ alákòóso, kí sì ni ìyẹn yọrí sí?
10 Ní sànmánì Kristẹni, a tún rí àwọn àpẹẹrẹ títayọlọ́lá ti àwọn tó bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fúnni. Fi ti Pọ́ọ̀lù ṣàpẹẹrẹ. Ó bọ̀wọ̀ fún àwọn ìpinnu tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù lọ sí Jerúsálẹ́mù kẹ́yìn, ẹgbẹ́ alákòóso gbà á nímọ̀ràn pé kí ó wẹ ara rẹ̀ lọ́nà ayẹyẹ kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé kò ní ohunkóhun lòdì sí Òfin Mósè. Pọ́ọ̀lù ì bá ti ronú pé: ‘Àwọn arákùnrin wọ̀nyí ló sọ pé kí n sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí wọ́n fẹ́ pa mí. Wọ́n tún wá fẹ́ kí n fi hàn ní gbangba báyìí pé mo bọ̀wọ̀ fún Òfin Mósè. Mo sì ti kọ̀wé sí àwọn ará Gálátíà pé kì í ṣe tiwọn láti máa pa Òfin mọ́ o. Tí n bá wá lọ sínú tẹ́ńpìlì báyìí, àwọn mìíràn lè ṣì mí lóye, kí wọ́n máa rò pé mo tí lọ lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn tó dá adọ̀dọ́.’ Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ò ṣe báyẹn ronú. Níwọ̀n bí kò ti sí ìlànà Kristẹni kankan tí ìyẹn lòdì sí, ó fi ọ̀wọ̀ hàn, ó sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ẹgbẹ́ alákòóso ọ̀rúndún kìíní. Àbájáde ojú ẹsẹ̀ ni pé bí kì í bá ṣe pé wọ́n gba Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Júù adárúgúdù-sílẹ̀ ni, wọn ò láwọn ò pa á, ẹ̀yìn ìyẹn ló wá lo ọdún méjì lẹ́wọ̀n. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe. Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí níwájú àwọn aláṣẹ onípò gíga ní Kesaréà, ẹ̀yìn ìyẹn ni ìjọba ṣètò, tí wọ́n sì mú un lọ sí Róòmù kó lè lọ jẹ́rìí níwájú Késárì pàápàá.—Ìṣe 9:26-30; 21:20-26; 23:11; 24:27; Gálátíà 2:12; 4:9, 10.
Ṣé O Máa Ń Fi Ọ̀wọ̀ Hàn?
11. Báwo la ṣe lè bọlá fún àwọn aláṣẹ inú ayé?
11 Ǹjẹ́ o máa ń fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn fún àwọn aláṣẹ? A pa á láṣẹ fún àwọn Kristẹni láti “fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, . . . ẹni tí ó béèrè fún ọlá, ẹ fún un ní irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.” Láìṣe àní-àní, kì í ṣe sísan owó orí nìkan ni fífi ara wa sábẹ́ “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ní nínú, ṣùgbọ́n ó tún wé mọ́ kí a máa fi ìwà àti ọ̀rọ̀ ẹnu wa bọlá fún àwọn aláṣẹ. (Róòmù 13:1-7) Táa bá bára wa níwájú àwọn aláṣẹ ìjọba tó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ adánilágara, kí la máa ṣe? Ní Ìpínlẹ̀ Chiapas, ní Mẹ́síkò, àwọn aláṣẹ tó wà ní àgbègbè kan gba ilẹ̀ oko àwọn ìdílé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé àwọn Kristẹni wọ̀nyí kò lọ́wọ́ nínú àwọn àjọyọ̀ ẹ̀sìn kan. Níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà, ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí mọ́ tónítóní, tí wọ́n sì múra nigín-nigín, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú iyì àti ọ̀wọ̀. Ẹjọ́ tí wọ́n wá dá ní ohun tó lé lọ́dún kan lẹ́yìn náà sì gbè wọ́n. Ìṣarasíhùwà wọn mú kí àwọn tó ń wo bí nǹkan ṣe ń lọ bọ̀wọ̀ fún wọn gan-an débi pé àwọn náà fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
12. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́?
12 Báwo lo ṣe lè bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ nínú ìdílé? Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ Jésù nínú jíjìyà ibi, ó sọ pé: “Lọ́nà kan náà, ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:1, 2; Éfésù 5:22-24) Níhìn-ín, Pétérù tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí aya wà ní ìtẹríba fún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkọ kan wà tí wọn ò ṣe ohunkóhun tí irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ fi tọ́ sí wọn. Ọ̀wọ̀ tí aya kan ń fi hàn lè mú kó jèrè ọkàn-àyà ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́.
13. Báwo ni àwọn aya ṣe lè bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ wọn?
13 Nínú àyíká ọ̀rọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, Pétérù pe àfiyèsí wa sí àpẹẹrẹ Sárà, tí ọkọ rẹ̀ Ábúráhámù jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títayọ. (Róòmù 4:16, 17; Gálátíà 3:6-9; 1 Pétérù 3:6) Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn aya tí ọkọ wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ máa fún ọkọ wọn ní ọ̀wọ̀ tó rẹlẹ̀ sí èyí tí àwọn aya tí ọkọ tiwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́ ń fún ọkọ wọn? Tó bá wá jẹ́ pé oò fara mọ́ ohun tí ọkọ rẹ wí lórí àwọn ọ̀ràn kan ńkọ́? Jésù fún wa ní àwọn ìmọ̀ràn kan tó ṣeé múlò ní gbogbo ọ̀nà níhìn-ín pé: “Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Mátíù 5:41) Ǹjẹ́ o máa ń bọlá fún ọkọ rẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tó fẹ́? Tó bá dà bí ẹni pé èyí fẹ́ le jù fún ọ, sọ èrò rẹ nípa ọ̀ràn náà fún un. Má ṣe rò pé ó mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ. Àmọ́, nígbà tí o bá ń ṣàlàyé ara rẹ fún un, ṣe àlàyé náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Kólósè 4:6.
14. Kí ni bíbọlá fún àwọn òbí ní nínú?
14 Ẹ̀yin ọmọ ńkọ́? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa á láṣẹ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí.” (Éfésù 6:1-3) Kíyè sí i pé ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn òbí ni ọ̀rọ̀ mìíràn tí a lò fún ‘bíbọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.’ Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “bọlá fún” ni ó tún ṣeé túmọ̀ sí “láti gbé gẹ̀gẹ̀” tàbí “láti fi ojú ribiribi wo nǹkan.” Nípa bẹ́ẹ̀, jíjẹ́ onígbọràn ní nínú ju pé kí o kàn máa fagídí tẹ̀ lé àṣẹ àwọn òbí rẹ tó dà bí èyí tí kò mọ́gbọ́n dání lójú rẹ. Ọlọ́run ní kí o buyì tó ga fún àwọn òbí rẹ, kí o sì fi ojú ribiribi wo ìtọ́sọ́nà wọn.—Òwe 15:5.
15. Báwo ni àwọn ọmọ ṣe lè máa fọ̀wọ̀ hàn nìṣó, kódà bí wọ́n bá rò pé àwọn òbí wọn ṣe àṣìṣe?
15 Bí àwọn òbí rẹ bá ṣe ohun kan tó fẹ́ jẹ́ kí ọ̀wọ̀ tóo ní fún wọn dín kù ńkọ́? Gbìyànjú láti wo ọ̀ràn náà bí wọ́n ṣe ń wò ó. Àbí àwọn kọ́ ló “bí ọ” tí wọ́n sì ń gbọ́ bùkátà rẹ ni? (Òwe 23:22) Ṣé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ ni? (Hébérù 12:7-11) Fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀, fi ẹ̀mí sùúrù ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ. Kódà bí wọ́n tiẹ̀ dá ọ lóhùn lọ́nà tí ó bí ọ nínú, má ṣe sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sí wọn. (Òwe 24:29) Rántí bí Dáfídì ṣe ń bá a nìṣó láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún Sọ́ọ̀lù, kódà nígbà tí ọba náà kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run mọ́. Bẹ Jèhófà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ìmọ̀lára rẹ. Dáfídì sọ pé: “Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi fún wa.”—Sáàmù 62:8; Ìdárò 3:25-27.
Bọlá fún Àwọn Tó Ń Mú Ipò Iwájú
16. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn olùkọ́ èké àti àwọn áńgẹ́lì?
16 Ẹ̀mí mímọ́ la fi yan àwọn alàgbà ìjọ, síbẹ̀ wọ́n kì í ṣe ẹni pípé, wọ́n sì máa ń ṣe àṣìṣe. (Sáàmù 130:3; Oníwàásù 7:20; Ìṣe 20:28; Jákọ́bù 3:2) Nítorí ìdí èyí, inú àwọn kan nínú ìjọ lè máà dùn sáwọn alàgbà. Báwo ló ṣe yẹ ká hùwà nígbà táa bá rò pé tàbí ká tiẹ̀ sọ pé ó jọ pé wọn kò bójú tó nǹkan kan lọ́nà tó yẹ nínú ìjọ? Kíyè sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn olùkọ́ èké ti ọ̀rúndún kìíní àti àwọn áńgẹ́lì: “Wọ́n jẹ́ aṣàyàgbàǹgbà [ìyẹn àwọn olùkọ́ èké], aṣetinú-ẹni, wọn kì í wárìrì níwájú àwọn ẹni ògo ṣùgbọ́n wọn a máa sọ̀rọ̀ tèébútèébú, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì, bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀ gidigidi ní okun àti agbára, kì í mú ẹ̀sùn wá lòdì sí wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ èébú, wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ọ̀wọ̀ fún Jèhófà.” (2 Pétérù 2:10-13) Nígbà tí àwọn olùkọ́ èké ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú sí “àwọn ẹni ògo”—ìyẹn àwọn alàgbà tí a fún ní ọlá àṣẹ nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní—àwọn áńgẹ́lì kò sọ̀rọ̀ tèébútèébú sí àwọn olùkọ́ èké tí ń fa ìpínyà láàárín àwọn ará. Níwọ̀n bí àwọn áńgẹ́lì ti wà nípò tó ga, tí ọ̀ràn ìdájọ́ òdodo sì máa ń ká wọn lára ju ènìyàn lọ, wọ́n mọ ohun tó ń lọ nínú ìjọ. Síbẹ̀, “nítorí ọ̀wọ̀ fún Jèhófà,” wọ́n fi ìdájọ́ lé Ọlọ́run lọ́wọ́.—Hébérù 2:6, 7; Júúdà 9.
17. Ipa wo ni ìgbàgbọ́ rẹ lè kó nígbà tó bá kan ọ̀ràn kíkojú àwọn ìṣòro tí o ti lérò pé àwọn alàgbà ṣe àṣìṣe?
17 Kódà, bí wọn ò bá ṣe ohun kan bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é, ǹjẹ́ kò ní dáa ká ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, tí ó wà láàyè, tí í ṣe Orí ìjọ Kristẹni? Ṣé kò mọ ohun tó ń lọ nínú ìjọ rẹ̀ jákèjádò ayé ni? Ǹjẹ́ kò yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ọ̀nà tó ń gbà bójú tó àwọn ipò tó ń yọjú, kí a sì gbà pé ó lágbára láti darí àwọn ọ̀ràn? Ní tòótọ́, ‘ta ni wá tí a fi ní láti máa ṣèdájọ́ aládùúgbò wa?’ (Jákọ́bù 4:12; 1 Kọ́ríńtì 11:3; Kólósè 1:18) O ò ṣe kúkú kó gbogbo àníyàn rẹ wá síwájú Jèhófà nínú àdúrà rẹ?
18, 19. Kí lo lè ṣe tóo bá rí i pé alàgbà kan ti ṣe àṣìṣe?
18 Nítorí àìpé ẹ̀dá, àwọn ìṣòro lè dìde. Alàgbà kan tiẹ̀ lè ṣisẹ̀ gbé nígbà mìíràn, kíyẹn sì wá da àwọn kan lọ́kàn rú. Báa tilẹ̀ kánjú gbégbèésẹ̀ lábẹ́ irú ipò yẹn, ẹ̀pa ò lè bóró mọ́. Ó tiẹ̀ lè sọ ìṣòrò náà di ńlá pàápàá. Àwọn tí wọ́n jẹ́ olóye nípa tẹ̀mí yóò dúró de Jèhófà láti mú àwọn nǹkan tọ́, kí ó sì pèsè ìbáwí tí ó bá yẹ ní àkókò tó fẹ́ àti lọ́nà tó wù ú.—2 Tímótì 3:16; Hébérù 12:7-11.
19 Bí àwọn ọ̀ràn kan bá kó ìdààmú ọkàn bá ọ ńkọ́? Dípò tí wàá fi máa sọ̀rọ̀ náà fún àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ, o ò ṣe kúkú fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tọ àwọn alàgbà lọ fún ìrànlọ́wọ́? Láìṣe àríwísí, ṣàlàyé ipa tí ọ̀ràn náà ti ní lórí rẹ. Gbogbo ìgbà ni kí o máa fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn sí wọn, kóo sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn bóo ti ń finú hàn wọ́n. (1 Pétérù 3:8) Kì í ṣe kóo máa pẹ̀gàn wọn, bí kò ṣe pé kóo nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ìdàgbàdénú wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Mọrírì ìṣírí èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ọ látinú Ìwé Mímọ́. Tó bá sì dà bí ẹni pé àwọn àtúnṣe mìíràn wà tó yẹ ní ṣíṣe, ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò darí àwọn alàgbà náà láti ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́.—Gálátíà 6:10; 2 Tẹsalóníkà 3:13.
20. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
20 Àmọ́ ṣá o, apá mìíràn tún wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò tó bá kan ọ̀ràn bíbọlá àti bíbọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ. Ǹjẹ́ kò yẹ káwọn táa fi sípò àṣẹ máa bọ̀wọ̀ fáwọn táa fi síkàáwọ́ wọn? Ẹ jẹ́ ká gbé ìyẹn yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni ìdí gúnmọ́ tó fi yẹ ká máa bọlá fún àwọn tó ní ọlá àṣẹ?
• Ojú wo ni Jèhófà àti Jésù fi ń wo àwọn tí kì í bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀?
• Àwọn àpẹẹrẹ àtàtà wo la ní nípa àwọn tó bọlá fáwọn táa fún ní ọlá àṣẹ?
• Kí la lè ṣe tó bá dà bíi pé ẹnì kan tó ní ọlá àṣẹ lé wa lórí ti ṣe àṣìṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Sárà bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọlá àṣẹ Ábúráhámù, ó sì láyọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Míkálì kò bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé àti ọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
“Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, . . . láti na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Jèhófà!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Èé ṣe tí o kò fi kó àwọn àníyàn rẹ wá síwájú Jèhófà nínú àdúrà rẹ?