“Nínú Àwọn Ewu Odò”
ILẸ̀ ti ṣú, ààjìn ti jìn, ọkọ̀ òkun kan tó kó èèyàn ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́rìnlélógún [276] ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé erékùṣù kan ní Mẹditaréníà. Ìjì líle tó ń jà, èyí tó ń gbé ọkọ̀ náà síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí omi fún ọjọ́ mẹ́rìnlá ti mú kó rẹ àwọn atukọ̀ àtàwọn èrò ọkọ̀ náà tẹnutẹnu. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, tí wọ́n rí ibi ìyawọlẹ̀ omi òkun kan, wọ́n gbìyànjú láti mú ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sí èbúté. Ṣùgbọ́n ọkọ̀ náà fẹnu gúnlẹ̀ débi pé kò lè lọ síwájú mọ́, ẹ̀fúùfù sì fọ́ ìdí ọkọ̀ náà sí wẹ́wẹ́. Ni gbogbo èrò inú ọkọ̀ náà bá fi ọkọ̀ sílẹ̀, wọ́n sì gbìyànjú láti wẹ̀ lọ sí etídò Málítà, àwọn mìíràn sì rọ̀ mọ́ àfọ́kù pákó tàbí nǹkan mìíràn tó lè léfòó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òtútù mú wọn, tí ó sì ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n wọ́ ara wọn kúrò nínú ìjì líle náà. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lára èrò ọkọ̀ yìí. Wọ́n ń gbé e lọ sí Róòmù láti lọ jẹ́jọ́.—Ìṣe 27:27-44.
Ní ti Pọ́ọ̀lù o, ọkọ̀ tó rì ní erékùṣù Màlítà yìí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ikú máa fẹjú mọ́ ọn lórí òkun. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ó kọ̀wé pé: “Ìgbà mẹ́ta ni mo ní ìrírí ọkọ̀ rírì, òru kan àti ọ̀sán kan ni mo ti lò nínú ibú.” Ó fi kún un pé òun ti wà “nínú àwọn ewu odò” rí. (2 Kọ́ríńtì 11:25-27) Rírin ìrìn àjò lórí òkun ti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un gẹ́gẹ́ bí “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.”—Róòmù 11:13.
Ṣùgbọ́n báwo ni ìrìn àjò lórí òkun ṣe máa ń pẹ́ tó ní ọ̀rúndún kìíní? Ipa wo ni ìrìn àjò lórí omi kó nínú títan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀? Báwo ló ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó? Irú ọkọ̀ wo ni wọ́n ń lò láyé ìgbà yẹn? Ibò sì ni àwọn èrò máa ń sùn sí?
Róòmù Nílò Òwò Ojú Omi
Àwọn ará Róòmù máa ń pe Mẹditaréníà ní Mare Nostrum—Òkun Wa. Kì í ṣe tìtorí ọ̀ràn ológun nìkan ni Róòmù kò fi fi àwọn ọ̀nà tí ọkọ̀ lè gbà lójú òkun ṣeré. Ọ̀pọ̀ ìlú tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù ló jẹ́ pé bí kò bá jẹ́ èbúté, a jẹ́ pé wọ́n gbára lé èbúté. Fún àpẹẹrẹ, èbúté ti Róòmù wà nítòsí Ostia, nígbà tí Kọ́ríńtì ń lo Lechaeum àti Kẹnkíríà, èbúté tó wà ní Séléúkíà sì ni Síríà ti Áńtíókù gbára lé. Ètò òwò ojú omi tó gún régé tó so àwọn èbúté wọ̀nyí pọ̀ mú kí fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ yá kánkán láàárín àwọn ìlú pàtàkì-pàtàkì, ó sì tún mú kí ìṣàkóso àwọn ẹkùn Róòmù gbéṣẹ́.
Róòmù tún gbára lé ètò ìrìnnà ojú omi rẹ̀ fún kíkó oúnjẹ wọ̀lú. Pẹ̀lú àwọn olùgbé Róòmù tí wọ́n tó nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́, iye ọkà tí ìlú náà nílò pọ̀ gan-an—nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ sí ogún ọ̀kẹ́ (250,000 sí 400,000) tọ́ọ̀nù lọ́dún kan. Ibo ni gbogbo ọkà yìí ti ń wá? Flavius Josephus fa ọ̀rọ̀ Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kejì yọ ní sísọ pé oṣù mẹ́jọ láàárín ọdún kan ni Àríwá Áfíríkà fi ń bọ́ Róòmù, nígbà tó sì jẹ́ pé Íjíbítì ló ń kó ọkà tí ó tó wá láti ran ìlú náà lọ́wọ́ fún oṣù mẹ́rin tó kù. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkọ̀ òkun ni wọ́n ń lò láti kó ọkà lọ sí ìlú náà.
Láti lè pèsè ohun tí àwọn ará Róòmù nílò fún afẹ́, òwò ojú omi tó ń gbèrú ń pèsè onírúurú ọjà. Wọ́n ń fi ọkọ̀ òkun kó ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀, òkúta iyebíye, àti mábìlì wá láti Kípírọ́sì, ilẹ̀ Gíríìsì, àti Íjíbítì, wọ́n sì ń kó gẹdú wá láti Lẹ́bánónì. Wáìnì ń wá láti Símínà, ẹ̀pà ń wá láti Damásíkù, èso déètì sì ń wá láti Palẹ́sìnì. Òróró ìpara àti rọ́bà ń wá láti Sìlíṣíà, irun àgùntàn ń ti Mílétù àti Laodíkíà wá, aṣọ ń wá láti Síríà àti Lẹ́bánónì, Tírè àti Sídónì sì ni aṣọ aláwọ̀ àlùkò ti ń wá. Tíátírà ni wọ́n ti ń kó aró wá, dígí sì ń wá láti Alẹkisáńdíríà àti Sídónì. China àti Íńdíà sì ni aṣọ ṣẹ́dà, òwú, eyín erin, àti èròjà amóúnjẹ-tasánsán ti ń wọlé.
Kí la wá lè sọ nípa ọkọ̀ òkun tó rì ní Màlítà tí Pọ́ọ̀lù sì wà nínú rẹ̀? Ọkọ̀ òkun tó kó ọkà ni, nítorí a pè é ní, “ọkọ̀ ojú omi kan láti Alẹkisáńdíríà tí ń lọ sí Ítálì.” (Ìṣe 27:6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Àwọn ará ilẹ̀ Gíríìsì, Foniṣíà, àti Síríà ló ni òbítíbitì ẹrù ọkà náà, àwọn ló sì láṣẹ lórí wọn. Àmọ́ ṣá o, Ìjọba háyà àwọn ọkọ̀ náà ni. Òpìtàn William M. Ramsay sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí Ìjọba ti ṣe ní ti ọ̀ràn gbígba owó ibodè, ó rọ ìjọba lọ́rùn jù láti gbé iṣẹ́ náà fún àwọn agbaṣẹ́ṣe ju kí ó máa fúnra rẹ̀ wá àwọn èèyàn tí yóò ṣiṣẹ́ bàǹtà-banta náà, kó sì máa ṣe wàhálà ṣíṣètò bí wọn yóò ṣe ṣe iṣẹ́ ọ̀hún.”
Ọkọ̀ tí ó ní ère orí ọkọ̀ náà, “Àwọn Ọmọ Súsì” ni ó gbé Pọ́ọ̀lù dé Róòmù. Èyí pẹ̀lú jẹ́ ọkọ̀ àwọn ará Alẹkisáńdíríà. Ó gúnlẹ̀ sí Pútéólì tí ń bẹ ní Ìyawọlẹ̀ Omi Naples, èbúté tí a sábà máa ń já òbítíbitì ẹrù ọkà sí. (Ìṣe 28:11-13) Láti Pútéólì—táa ń pè ní Pozzuoli lónìí—a óò já ẹrù náà sórí ilẹ̀ tàbí kí a tún fi àwọn ọkọ̀ òkun kéékèèké kó o lọ sí ìhà àrìwá lọ́nà etíkun, títí lọ sí Odò Tiber ní àárín gbùngbùn Róòmù.
Èrò Nínú Ọkọ̀ Akẹ́rù Kẹ̀?
Kí ló mú Pọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ wọ ọkọ̀ akẹ́rù? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ó yẹ ká mọ ohun tí rírìnrìn àjò lórí òkun gẹ́gẹ́ bí èrò ọkọ̀ túmọ̀ sí láyé ọjọ́un.
Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, kò sí ohun tó ń jẹ́ ọkọ̀ òkun akérò. Gbogbo ọkọ̀ òkun tí àwọn arìnrìn-àjò ń lò akẹ́rù ni wọ́n. Onírúurú àwọn èèyàn ló sì ti lè wọ̀ wọ́n—títí kan àwọn aṣojú Ìjọba, àwọn ọ̀mọ̀wé, àwọn oníwàásù, àwọn oníṣẹ́ oṣó, àwọn oníṣọ̀nà, àwọn eléré ìdárayá, àwọn oníṣòwò, àwọn arìnrìn-àjò afẹ́, àti àwọn arìnrìn-àjò sí ilẹ̀ mímọ́.
Àmọ́ ṣá o, àwọn ọkọ̀ ojú omi tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi wà tí wọ́n fi ń kérò, tí wọ́n sì fi ń kó ẹrù létíkun. Ó ti lè jẹ́ pé irú ọkọ̀ gbádìígbádìí yẹn ní Pọ́ọ̀lù lò “rékọjá wá sí Makedóníà” láti Tíróásì. Ó lè ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí ó jẹ́ pé ọkọ̀ ojú omi tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi ló ń wọ̀ wá sí Áténì, tó sì ń wọ̀ padà. Pọ́ọ̀lù sì tún lè lo ọkọ̀ gbádìígbádìí nínú ìrìn àjò tó rìn lẹ́yìn ìgbà yẹn láti Tíróásì lọ sí Pátárà, nípa gbígba àwọn erékùṣù tó wà nítòsí èbúté Éṣíà Kékeré. (Ìṣe 16:8-11; 17:14, 15; 20:1-6, 13-15; 21:1) Lílo àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké máa ń yá, ṣùgbọ́n wọn kò lè lọ sójú agbami. Nítorí náà, irú ọkọ̀ ojú omi tó gbé Pọ́ọ̀lù lọ sí Kípírọ́sì, kó tó wá gbé e wá sí Panfílíà, àti ọkọ̀ tó wọ̀ láti Éfésù lọ sí Kesaréà pẹ̀lú èyí tó wọ̀ láti Pátárà lọ sí Tírè gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkọ̀ ńlá. (Ìṣe 13:4, 13; 18:21, 22; 21:1-3) Bákan náà ọkọ̀ ojú omi tí Pọ́ọ̀lù wọ̀, tó rì ní Málítà gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkọ̀ ńlá. Báwo ni irú àwọn ọkọ̀ wọ̀nyẹn ṣe tóbi tó?
Ìsọfúnni láti inú àwọn ìwé kan sún ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan láti sọ pé: “[Ọkọ̀ òkun] tó ní àyè dáadáa tí ó wúlò gan-an fún àwọn ará ìgbàanì lè kó tó ẹrù àádọ́rin sí ọgọ́rin tọ́ọ̀nù. Ní sànmánì àwọn Hélénì, èyí tó wọ́pọ̀ jù lọ lè kó tó ẹrù àádóje [130] tọ́ọ̀nù. Èyí tó máa ń kó tó ẹrù àádọ́talérúgba [250] tọ́ọ̀nù kò wọ́pọ̀, àmọ́, ó tóbi dáadáa. Nígbà ayé àwọn ará Róòmù, ọkọ̀ òkun tó jẹ́ ti ìjọba tún tóbi ju àwọn táa ti mẹ́nu kàn tẹ́lẹ̀ lọ, ó lè kó tó ẹrù òjìlélọ́ọ̀ọ́dúnrún tọ́ọ̀nù [340]. Ọkọ̀ òkun tó tóbi jù lọ nígbà náà lè kó tó ẹrù ẹgbẹ̀rún lé ní ọ̀ọ́dúnrún tọ́ọ̀nù [1,300], ó ṣeé ṣe kí èyí fi díẹ̀ tóbi ju àwọn yòókù lọ.” Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni kan tí a kọ ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa ti wí, ọkọ̀ ojú omi tí ń kó ọkà wá láti Alẹkisáńdíríà, tí wọ́n ń pè ní Isis, lé ní mítà márùndínlọ́gọ́ta ní gígùn, ó sì fẹ̀ tó mítà mẹ́rìnlá, ibi ìkẹ́rùsí rẹ̀ nínú jìn tó nǹkan bíi mítà mẹ́tàlá, ó sì lè gba ọkà tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún tọ́ọ̀nù àti èrò bí ọgọ́rùn-ún.
Báwo lá ṣe wá ń bójú tó àwọn arìnrìn-àjò nínú ọkọ̀ òkun tí a fi ń kó ọkà? Níwọ̀n tó ti jẹ́ pé ẹrù ni wọ́n dìídì ṣe ọkọ̀ yìí fún, wọ́n fi ń gbé èrò bí àyè bá wà. Wọn kì í fún wọn lóúnjẹ tàbí tọ́jú wọn, omi nìkan ni wọ́n ń fún wọn. Orí ọkọ̀ ni wọ́n máa ń sùn sí, bóyá lábẹ́ àgọ́ àfiṣelé tí wọ́n máa ń ta ni alaalẹ́, tí wọ́n sì ń ká kúrò ní àràárọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè yọ̀ọ̀da fún àwọn arìnrìn-àjò láti lo ilé ìdáná tó wà nínú ọkọ̀ láti gbọ́únjẹ wọn, wọ́n ti ní láti kó gbogbo ohun tí wọ́n á fi dáná, tí wọ́n á fi jẹun, èyí tí wọ́n á fi wẹ̀, àti èyí tí wọ́n á fi sùn dáni—tó fi mọ́ abọ́ ìdáná àti àwo ìjẹun, títí kan aṣọ ìbora àtèyí tí a óò tẹ̀ lé ibùsùn.
Rírìnrìn Àjò Lórí Òkun —Báwo Ló Ṣe Fini Lọ́kàn Balẹ̀ Tó?
Láìní irinṣẹ́ kankan—kódà atọ́ka lásán—ohun tí àwọn atukọ̀ ọ̀rúndún kìíní bá fi ojúyòójú rí nìkan ni wọ́n mọ̀. Nítorí náà, ìgbà tí wọ́n bá lè ríran rí ọ̀ọ́kán dáadáa ni ìrìn àjò fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ—lọ́pọ̀ ìgbà ìyẹn máa ń jẹ́ ní apá ìparí oṣù May sí àárín oṣù September. Ní oṣù méjì tó ṣáájú àti lẹ́yìn àkókò yẹn, àwọn oníṣòwò lè fara wewu ìrìn àjò orí òkun. Àmọ́ nígbà ọ̀gìn-nìtìn, ìrì àti kùrukùru máa ń bo ojú ọ̀nà, ó tún ń bo ojú oòrùn lọ́sàn-án àti ojú ìràwọ̀ lóru pàápàá. Láti November 11 títí di March 10 kò sẹ́ni tó tún ń wakọ̀ lójú omi (lédè Látìn, mare clausum ni wọ́n ń pe àkókò yìí), àyàfi tó bá di kàráǹgídá tàbí tó di kánjúkánjú. Àwọn tó bá rìnrìn àjò nígbà tí àkókò táa mẹ́nu kàn ṣáájú bá ti ń parí lọ lè lọ́ kó sí ìgbà ọ̀gìn-nìtìn ní èbúté tí wọn yóò gúnlẹ̀ sí ní ilẹ̀ òkèèrè.—Ìṣe 27:12; 28:11.
Yàtọ̀ sí ewu tó wà nínú ìrìn àjò lójú òkun àti pé ó lásìkò tí ìrìn àjò ṣeé lọ lójú òkun, ǹjẹ́ ó sàn ju gbígba orí ilẹ̀ lọ? Ó kúkú sàn ju lọ dáadáa! Rírìnrìn àjò lórí òkun kì í jẹ́ kó tètè rẹni, owó rẹ̀ kò pọ̀, ó sì yá ju fífẹsẹ̀ rìn lọ. Bí ojú ọjọ́ bá dára, ọkọ̀ òkun kan lè rin nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà lóòjọ́. Bó sì ti wù kí ẹnì kan lè yára rìn tó, kò lè fẹsẹ̀ rìn ju kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n lọ lóòjọ́.
Ẹ̀fúùfù ló máa ń pinnu bí ìrìn àjò lójú òkun yóò ti pẹ́ tàbí yá tó. Bí ẹnì kan bá ń rìnrìn àjò lójú òkun láti Íjíbítì sí Ítálì, àní nígbà tí ojú ọjọ́ bá dára jù lọ pàápàá, ṣe ni yóò máa bá ẹ̀fúùfù jà bó ti ń lọ. Ọ̀nà tó yá jù lọ ni ọ̀nà Ródésì tàbí Máírà tàbí èbúté mìíràn tó wà ní etíkun Líkíà ní Éṣíà Kékeré. Ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé lẹ́yìn tí ìjì ti fi ojú ọkọ̀ òkun tí ń kó ọkà, táa pe orúkọ rẹ̀ ní Isis, rí màbo, tí ọkọ̀ náà sì ṣìnà, ló wá gúnlẹ̀ sí Piraeus lẹ́yìn àádọ́rin ọjọ́ tó ti gbéra ní Alẹkisáńdíríà. Pẹ̀lú ẹ̀fúùfù láti àríwá ìwọ̀ oòrùn tó gba ojú ọjọ́, tó ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn, àtipadà sí Ítálì kò lè nira, kò lè gbà ju ìrìn àjò ogúnjọ́ sí ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí yóò fi délé. Bó bá wá jẹ́ pé olúwa ẹ̀ fẹsẹ̀ rìn ni, ìrìn àjò kan náà ní àlọ àbọ̀ yóò gbà ju àádọ́jọ ọjọ́ lọ, ìyẹn tójú ọjọ́ bá dára o.
A Mú Ìhìn Rere Lọ Sí Òkè Òkun
Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ewu wà nínú rírin ìrìn àjò lórí òkun nígbà tí ojú ọjọ́ kò bá dára. Ó tilẹ̀ kìlọ̀ pé kí a má rìnrìn àjò ní apá ìparí oṣù September àti ìbẹ̀rẹ̀ October, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, mo róye pé ìtukọ̀ yóò mú òfò àti àdánù ńlá lọ́wọ́, kì í ṣe kìkì sí ẹrù àti ọkọ̀ ojú omi nìkan ni, ṣùgbọ́n sí ọkàn wa pẹ̀lú.” (Ìṣe 27:9, 10) Àmọ́, ọmọ ogun tí àṣẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ kò ka ọ̀rọ̀ yìí sí, èyí ló sì fa ọkọ̀ tó rì ní Málítà.
Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù fi máa parí iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀, ó kéré tán, ọkọ̀ tì rì í tó ìgbà mẹ́rin. (Ìṣe 27:41-44; 2 Kọ́ríńtì 11:25) Síbẹ̀síbẹ̀, àníyàn tí kò nídìí nípa irú ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò dí àwọn oníwàásù ìhìn rere náà ní ìgbàanì lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lójú òkun. Wọ́n lo gbogbo àǹfààní ọ̀nà ìrìn àjò tó wà ní ìkáwọ́ wọn láti tan iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀. Ní ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jésù, wọ́n jẹ́rìí jákèjádò ayé. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8) A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá fún ìtara wọn, a dúpẹ́ fún ìgbàgbọ́ àwọn tí wọ́n ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, àti ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, tí ó mú kí ìhìn rere náà ti dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé tí ènìyàn ń gbé.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.