ORÍ 14
Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn”
1, 2. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé ipò táwa èèyàn wà, kí sì ni ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà fún wa?
“GBOGBO ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora.” (Róòmù 8:22) Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí ṣàlàyé ipò tó ń bani nínú jẹ́ táwa èèyàn wà. Lójú àwa èèyàn, ó lè dà bíi pé a ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́ Jèhófà ò dà bí àwa èèyàn lásánlàsàn, kò sóhun tó ṣòro fún un láti ṣe. (Nọ́ńbà 23:19) Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ó sì ti ṣe ọ̀nà àbáyọ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ìpọ́njú tó ń dojú kọ wá. Ìràpadà lọ̀nà àbáyọ náà.
2 Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù tí Jèhófà fún àwa èèyàn ni ìràpadà. Ẹ̀bùn yìí ló mú ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Éfésù 1:7) Bákan náà, ìràpadà ló jẹ́ ká lè ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, ì báà jẹ́ ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 3:16; 1 Pétérù 1:4) Àmọ́, kí ni ìràpadà? Kí ló sì kọ́ wa nípa ìdájọ́ òdodo tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà?
Ìdí Tá A Fi Nílò Ìràpadà
3. (a) Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi yí ìdájọ́ ikú tó ṣe fún àwọn ọmọ Ádámù pa dà?
3 Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló mú ká nílò ìràpadà. Ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, torí náà àìsàn, ìbànújẹ́, ìrora àti ikú ni ogún tó fi sílẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; Róòmù 8:20) Ọlọ́run ò yí ìdájọ́ ikú tó ṣe fún wọn pa dà. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ó tẹ òfin ara rẹ̀ lójú nìyẹn, ìyẹn òfin tó sọ pé: “Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:23) Tí Jèhófà ò bá sì tẹ̀ lé òfin tóun fúnra rẹ̀ gbé kalẹ̀, ìyẹn máa dá wàhálà sílẹ̀ torí àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn ò ní rídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
4, 5. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kí Jèhófà wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà? (b) Ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà?
4 Bá a ṣe rí i ní Orí 12, ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì tún fa ìṣòro míì tó le gan-an. Sátánì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Ó sọ pé òpùrọ́ àti ìkà ni Jèhófà, bákan náà ó sọ pé Jèhófà máa ń fi òmìnira du àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Nígbà tí Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ńṣe ni Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ pé Ọlọ́run ò ní lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn pé àwọn olódodo á máa gbé ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Àìsáyà 55:10, 11) Ká ní Jèhófà ò ṣe nǹkan kan sọ́rọ̀ yìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn ò ní fọkàn tán an mọ́, wọn ò sì ní gbà pé àkóso ẹ̀ ló dáa jù.
5 Sátánì tún ba àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé ohun tí wọ́n ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ń mú kí wọ́n sìn ín àti pé tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn ò ní jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run mọ́. (Jóòbù 1:9-11) Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì ju gbogbo ìṣòro tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà fáwa èèyàn. Torí náà, Jèhófà rí i pé ó yẹ kóun ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun. Àmọ́, báwo ni Ọlọ́run ṣe máa yanjú ọ̀ràn yìí, tá á sì tún gba àwa èèyàn là?
Ìràpadà Ṣe Rẹ́gí Pẹ̀lú Ohun Tá A Pàdánù
6. Oríṣiríṣi ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe ohun tí Ọlọ́run ṣe kó lè gba àwa èèyàn là?
6 Ohun tí Jèhófà ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé onídàájọ́ òdodo àti aláàánú ni. Ohun tó ṣe náà rọrùn, ó sì mọ́gbọ́n dání. Kò séèyàn kankan tó lè ronú ẹ̀ láé. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé Ọlọ́run rà wá tàbí mú ká bá òun rẹ́, Bíbélì tún pè é ní ẹbọ ìpẹ̀tù àti ètùtù. (Sáàmù 49:8; Dáníẹ́lì 9:24; Gálátíà 3:13; Kólósè 1:20; Hébérù 2:17) Àmọ́ nínú gbogbo wọn, ọ̀rọ̀ tí Jésù fi ṣàpèjúwe ẹ̀ ló bá a mu jù lọ. Ó sọ pé: “Ọmọ èèyàn ò . . . wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́, kó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà [Gíríìkì, lyʹtron] ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”—Mátíù 20:28.
7, 8. (a) Kí ni “ìràpadà” túmọ̀ sí nínú Ìwé Mímọ́? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìràpadà túmọ̀ sí ohun tó ṣe rẹ́gí?
7 Kí ni ìràpadà? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò nínú ohun tí Jésù sọ yìí wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí “láti tú sílẹ̀ tàbí láti dá sílẹ̀.” Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi ṣàpèjúwe owó tí wọ́n máa ń san káwọn ọ̀tá lè tú àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú sílẹ̀. Torí náà, a lè sọ pé ìràpadà túmọ̀ sí ohun tá a san láti fi ra ohun kan pa dà. Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún “ìràpadà” (ìyẹn koʹpher) wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí “bo [nǹkan] mọ́lẹ̀.” Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé kó fi ọ̀dà bítúmẹ́nì “bo” (ìyẹn koʹpher) inú àti ìta áàkì. (Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun míì tí ìràpadà túmọ̀ sí ni láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
8 Ìwé Theological Dictionary of the New Testament sọ pé ọ̀rọ̀ náà (koʹpher) “túmọ̀ sí kí nǹkan bára mu,” tàbí kó ṣe rẹ́gí. Torí náà, láti san ìràpadà tàbí pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́, ó di dandan ká rí ohun kan tó bára mu tàbí tó ṣe rẹ́gí, táá lè kájú ohun tá a ti pàdánù. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi fún Ísírẹ́lì ní òfin tó sọ pé: “Kí o gba ẹ̀mí dípò ẹ̀mí, ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀.”—Diutarónómì 19:21.
9. Kí nìdí táwọn ẹni ìgbàgbọ́ fi ń fi ẹran rúbọ, ojú wo ni Jèhófà sì fi wo irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀?
9 Látìgbà ayé Ébẹ́lì làwọn ẹni ìgbàgbọ́ ti máa ń fi ẹran rúbọ sí Ọlọ́run. Ohun tí ẹbọ tí wọ́n ń rú yìí ń fi hàn ni pé wọ́n mọ̀ pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó nílò ìràpadà. Ó tún fi hàn pé wọ́n gbára lé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa gba aráyé là nípasẹ̀ “ọmọ” rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 4:1-4; Léfítíkù 17:11; Hébérù 11:4) Inú Jèhófà dùn sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀, ó sì ka àwọn olùjọsìn yẹn sí ẹni rere. Àmọ́, ẹran táwọn èèyàn fi ń rúbọ kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, torí pé àwọn ẹranko rẹlẹ̀ sí àwa èèyàn. (Sáàmù 8:4-8) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.” (Hébérù 10:1-4) Ńṣe ni ẹbọ táwọn èèyàn ń rú nígbà yẹn wulẹ̀ ń ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe máa fi ìràpadà mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá.
“Ìràpadà Tó Bá A Mu Rẹ́gí”
10. (a) Ta ni ẹni tó máa san ìràpadà náà ní láti bá dọ́gba, kí sì nìdí? (b) Kí nìdí tí kò fi pọn dandan kí ọ̀pọ̀ èèyàn kú ká tó lè ra àwọn ọmọ Ádámù pa dà?
10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo èèyàn . . . ń kú nínú Ádámù.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Torí náà, ká tó lè san ìràpadà, ẹnì kan tó jẹ́ ẹni pípé bíi ti Ádámù gbọ́dọ̀ kú. (Róòmù 5:14) Èyí ló máa yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó bá ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mu, torí ẹni pípé tí kò jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ Ádámù nìkan ló lè fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti san “ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí” pẹ̀lú ohun tí Ádámù gbé sọ nù. (1 Tímótì 2:6) Àmọ́, ṣé ó pọn dandan kí àìmọye èèyàn tó jẹ́ ẹni pípé kú ká tó lè ra ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Ádámù pa dà? Rárá o! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ẹnì kan [Ádámù] wọ ayé, . . . ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Torí náà, “bí ikú ṣe wá nípasẹ̀ ẹnì kan,” Ọlọ́run náà gba aráyé là “nípasẹ̀ ẹnì kan.” (1 Kọ́ríńtì 15:21) Báwo ni Jèhófà ṣe ṣe é?
“Ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí fún gbogbo èèyàn”
11. (a) Báwo lẹni tó fẹ́ san ìràpadà ṣe máa “tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn”? (b) Kí nìdí tí ìràpadà náà ò fi lè dá Ádámù àti Éfà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Jèhófà ṣètò pé kí ọkùnrin pípé kan fínnú-fíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. Bí Róòmù 6:23 ṣe sọ, “ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀.” Torí náà, ẹni tó fẹ́ san ìràpadà náà gbọ́dọ̀ “tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn,” ìyẹn ni pé ó máa san gbèsè táwa èèyàn jẹ torí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. (Hébérù 2:9; 2 Kọ́ríńtì 5:21; 1 Pétérù 2:24) Ìyẹn máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní tó pọ̀ gan-an. Torí ìràpadà máa fagi lé ìdájọ́ ikú tó wà lórí àwọn ọmọ Ádámù tó jẹ́ onígbọràn, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ò sì ní lágbára kankan lórí wọn mọ́ láé.a—Róòmù 5:16.
12. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé gbèsè tẹ́nì kan ṣoṣo san lè ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní.
12 Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé ilé iṣẹ́ ńlá kan wà nílùú tó ò ń gbé tó sì jẹ́ pé ibẹ̀ lọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ṣiṣẹ́. Ilé iṣẹ́ náà ń san owó tó jọjú fún ìwọ àtàwọn òṣìṣẹ́ tó kù, torí náà ẹ̀ ń gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Àmọ́, ọ̀gá ilé iṣẹ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í kówó jẹ, ni ilé iṣẹ́ náà bá wọko gbèsè. Bó ṣe di pé wọ́n ti ilé iṣẹ́ náà pa nìyẹn. Torí náà, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìwọ àtàwọn òṣìṣẹ́ tó kù, èyí wá mú kó nira fún yín láti rí owó ilé àti owó iná san, títí kan owó omi àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì. Ìwà ìbàjẹ́ tí ọkùnrin yẹn hù fa ìṣòro fún gbogbo àwọn tí ilé iṣẹ́ náà jẹ ní gbèsè. Ṣé ọ̀nà àbáyọ kankan wà fáwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn? Bẹ́ẹ̀ ni! Olówó kan tó lójú àánú dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó mọ̀ pé ilé iṣẹ́ yẹn wúlò gan-an, ó sì káàánú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ àti ìdílé wọn. Torí náà, ó san gbèsè tí ilé iṣẹ́ náà jẹ, ó sì ní kí wọ́n ṣí i. Ohun tó ṣe yẹn mú kí ara tu àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ náà àti ìdílé wọn, títí kan àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè. Bákan náà, Jésù san gbèsè tí Ádámù jẹ, ìyẹn sì ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní.
Ta Ló Pèsè Ìràpadà Náà?
13, 14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà fún wa? (b) Ta ló gba ìràpadà náà, kí sì nìdí tó fi yẹ kó rí bẹ́ẹ̀?
13 Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè pèsè “Ọ̀dọ́ Àgùntàn . . . tó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29) Àmọ́ o, kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ní kí ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì wá gba aráyé là. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó máa lè dáhùn gbogbo ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́nà tó dáa jù ni Jèhófà rán wá. Ohun tó ṣeyebíye jù lọ sí Jèhófà lọ̀rọ̀ yìí ná an! Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tó jẹ́ “àrídunnú rẹ̀ lójoojúmọ́” ló rán wá. (Òwe 8:30) Ọmọ Ọlọ́run yìí fínnú-fíndọ̀ “fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀,” títí kan gbogbo ògo tó ní lọ́run. (Fílípì 2:7) Jèhófà wá ṣe iṣẹ́ ìyanu kan, ó fi ẹ̀mí àkọ́bí Ọmọ ẹ̀ yìí sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. (Lúùkù 1:27, 35) Jésù ni wọ́n sọ ọ́ nígbà tí wọ́n bí i. Àmọ́, Bíbélì tún pè é ní Ádámù ìkẹyìn, torí pé ẹni pípé lòun náà bíi ti Ádámù. (1 Kọ́ríńtì 15:45, 47) Torí náà, Jésù lè fi ara rẹ̀ rúbọ láti ra àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà.
14 Ta la máa san ìràpadà yẹn fún? Sáàmù 49:7 sọ pé “Ọlọ́run” ló máa gba ìràpadà náà. Àmọ́, ṣebí Jèhófà fúnra ẹ̀ ló fún wa ní ìràpadà yẹn? Òun ni lóòótọ́, àmọ́ ìyẹn ò sọ ìràpadà di ohun tí kò nítumọ̀, bí ìgbà téèyàn mú owó jáde nínú àpò ọ̀tún tó sì fi sínú àpò òsì. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ìràpadà kì í kàn ṣe pàṣípààrọ̀ ohun kan tó ṣe é fojú rí. Kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ òfin ni, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Bí Jèhófà ṣe fún wa ní Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n láti san ìràpadà náà jẹ́ ká rí i pé ìgbà gbogbo ló máa ń ṣe ohun tó bá ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mu, tíyẹn bá tiẹ̀ máa ná an ní ohun tó pọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:7, 8, 11-13; Hébérù 11:17; Jémíìsì 1:17.
15. Kí nìdí tó fi pọn dandan kí Jésù jìyà kó sì kú?
15 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù Kristi gbà kí wọ́n fìyà jẹ òun kó lè san ìràpadà náà. Ó jẹ́ kí wọ́n fàṣẹ ọba mú òun, lẹ́yìn náà wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì kàn án mọ́ òpó igi oró. Ṣé ó pọn dandan kí Jésù jẹ ìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, torí èyí ló máa jẹ́ kó ṣe kedere pé irọ́ ni Sátánì ń pa nígbà tó sọ pé kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà kankan tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Ọlọ́run dáàbò bo Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé kí Hẹ́rọ́dù má bàa rí i pa. (Mátíù 2:13-18) Àmọ́ nígbà tí Jésù dàgbà, ó lè fara da gbogbo àtakò Sátánì torí pé wàhálà tí Sátánì dá sílẹ̀ yé e dáadáa.b Nǹkan kékeré kọ́ ni wọ́n fojú Jésù rí, síbẹ̀ ó jẹ́ “adúróṣinṣin, aláìṣẹ̀, aláìlẹ́gbin” àti “ẹni tí a yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà láwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí i lójú inúnibíni. (Hébérù 7:26) Abájọ tó fi jẹ́ pé kí Jésù tó kú, ó ké jáde pé: “A ti ṣe é parí!”—Jòhánù 19:30.
Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìràpadà Náà Parí
16, 17. (a) Kí ni Jésù ṣe kó lè ṣe iṣẹ́ ìràpadà náà parí? (b) Kí nìdí tó fi pọn dandan fún Jésù láti fara hàn “níwájú Ọlọ́run nítorí wa”?
16 Àmọ́ o, Jésù ò tíì ṣe iṣẹ́ ìràpadà náà parí. Ní ọjọ́ kẹta tí Jésù kú, Jèhófà jí i dìde. (Ìṣe 3:15; 10:40) Bí Jèhófà ṣe jí Ọmọ rẹ̀ dìde mú kó lè san èrè fún un torí pé ó jẹ́ olóòótọ́. Ìyẹn tún mú kó ṣeé ṣe fún Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà Ọlọ́run láti ṣe àwọn nǹkan tó kù tó yẹ kó ṣe ká lè jàǹfààní ìràpadà tó san. (Róòmù 1:4; 1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó ṣe náà, ó sọ pé: “Nígbà tí Kristi dé bí àlùfáà àgbà . . . , kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀ àìnípẹ̀kun fún wa. Torí Kristi ò wọnú ibi mímọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe, tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi, àmọ́ ọ̀run gangan ló wọ̀ lọ, tó fi jẹ́ pé ó ń fara hàn báyìí níwájú Ọlọ́run nítorí wa.”—Hébérù 9:11, 12, 24.
17 Kì í ṣe pé Kristi gbé ẹ̀jẹ̀ ara ẹ̀ lọ sọ́run. (1 Kọ́ríńtì 15:50) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀jẹ̀ náà dúró fún ló gbé lọ, ìyẹn ẹ̀tọ́ tó ní láti máa gbé ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn pípé. Lẹ́yìn náà, ó san ìràpadà ní ti pé ó gbé ẹ̀tọ́ tó ní láti máa gbé ayé lọ síwájú Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kó lè fi ṣe pàṣípààrọ̀ nítorí àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìgbà yẹn ni Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí ọgọ́fà (120) ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 2:1-4) Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wúni lórí lóòótọ́, àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ nìyẹn kàn jẹ́ lára àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa torí ìràpadà náà.
Àǹfààní Ìràpadà
18, 19. (a) Àwùjọ méjì wo ló jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi? (b) Ọ̀nà wo ni ìràpadà máa gbà ṣe àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” láǹfààní ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
18 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó sọ pé ẹbọ ìràpadà Kristi ló mú kí Ọlọ́run gbà káwa èèyàn pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwùjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà, ó pè wọ́n ní “àwọn ohun tó wà ní ọ̀run” àti “àwọn ohun tó wà ní ayé.” (Kólósè 1:19, 20; Éfésù 1:10) Àwọn tó wà nínú àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn Kristẹni tó nírètí láti lọ sí ọ̀run kí wọ́n lè di àlùfáà, kí wọ́n sì bá Kristi Jésù jọba lé ayé lórí. Iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000). (Ìfihàn 5:9, 10; 7:4; 14:1-3) Wọ́n máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù fún ẹgbẹ̀rún ọdún, káwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn lè jàǹfààní ìràpadà, títí wọ́n á fi di pípé.—1 Kọ́ríńtì 15:24-26; Ìfihàn 20:6; 21:3, 4.
19 “Àwọn ohun tó wà ní ayé” ni àwọn èèyàn tó nírètí láti gbádùn ayé títí láé nínú Párádísè. Ìfihàn 7:9-17 pè wọ́n ní “ogunlọ́gọ̀ èèyàn,” wọ́n sì máa la “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ já. Àmọ́, kò dìgbà tí wọ́n bá la ìpọ́njú ńlá já kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í jàǹfààní ìràpadà náà. Ní báyìí, wọ́n “ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Torí pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, wọ́n ń jàǹfààní àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fún wọn ní báyìí. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà kà wọ́n sí olódodo, ó sì pè wọ́n ní ọ̀rẹ́ rẹ̀! (Jémíìsì 2:23) Ẹbọ ìràpadà Jésù mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ‘sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ ní fàlàlà.’ (Hébérù 4:14-16) Tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run máa dárí jì wọ́n. (Éfésù 1:7) Bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, wọ́n lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Hébérù 9:9; 10:22; 1 Pétérù 3:21) Torí náà, kò dìgbà tí Párádísè bá dé kí wọ́n tó lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀ ní báyìí! (2 Kọ́ríńtì 5:19, 20) Tó bá sì di ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Ọlọ́run máa bù kún wọn gan-an. Díẹ̀díẹ̀, ó máa jẹ́ kí wọ́n dẹni tá a “dá . . . sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́” lẹ́yìn náà wọ́n máa “ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
20. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá ń ronú nípa ìràpadà?
20 “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi” torí ìràpadà náà! (Róòmù 7:25) Ó jọni lójú gan-an láti rí i pé ohun tó rọrùn tó sì bọ́gbọ́n mu ni Jèhófà ṣe láti gba àwa èèyàn là. (Róòmù 11:33) Tá a bá ń ronú nípa ìràpadà náà, àá túbọ̀ mọyì Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo, èyí á sì mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bíi ti onísáàmù náà, ó yẹ káwa náà máa yin Jèhófà torí pé ó “nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.”—Sáàmù 33:5.
a Ìràpadà náà ò lè dá Ádámù àti Éfà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ohun tí Òfin Mósè sọ nípa ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa èèyàn ni pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ gba ìràpadà fún ẹ̀mí apààyàn tí ikú tọ́ sí.” (Nọ́ńbà 35:31) Ó dájú pé ikú tọ́ sí Ádámù àti Éfà torí pé ńṣe ni wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé ohun tí wọ́n ṣe náà ò dáa. Torí náà, wọ́n pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé.
b Kí Jésù tó lè san ìràpadà tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Ádámù sọ nù, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni pípé tó ti dàgbà nígbà tó bá máa kú, kì í ṣe ọmọ kékeré. Rántí pé ṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, ó mọ̀ pé ohun tóun ṣe ò dáa àti pé Jèhófà máa fìyà jẹ òun tóun bá ṣe é. Torí náà, kí Jésù tó lè di “Ádámù ìkẹyìn” kó sì bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀, ó ti ní láti dàgbà torí ìyẹn lá jẹ́ kó mọ ohun tó ń ṣe, kó sì pinnu pé òun máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 15:45, 47) Nípa bẹ́ẹ̀, bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ àti bó ṣe kú torí àwa èèyàn jẹ́ “ìwà òdodo kan.”—Róòmù 5:18, 19.